Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbígbé Nínú Ayé Alálòsọnù

Gbígbé Nínú Ayé Alálòsọnù

Gbígbé Nínú Ayé Alálòsọnù

Ọ̀PỌ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí làwọn èèyàn tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ń kó dà nù. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa iye pàǹtírí tí wọ́n ń kó dà nù lọ́dọọdún ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n sọ pé “bó bá ṣe pé omi ni gbogbo ìdọ̀tí tá à ń sọ yìí ni, omi ọ̀hún á kún ẹgbàá mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [68,000] kùdu ìlúwẹ̀ẹ́, ìyẹn irú àwọn kùdu ìlúwẹ̀ẹ́ tí wọ́n máa ń lò fún ìdíje Òlíńpíìkì, èyí tó jẹ́ àádọ́ta mítà ní gígún.” Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, àwọn olùwádìí fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ohun táwọn olùgbé ìlú New York City nìkan ń kó dà nù lọ́dọọdún pọ̀ débi pé, ó lè bo Ọgbà Ìgbafẹ́ Ńlá tó wà ní ìgboro ìlú náà mọ́lẹ̀, síbẹ̀ kí ìdọ̀tí ọ̀hún ṣì tún ga gègèrè tó mítà mẹ́rin sókè! a

Abájọ tí wọ́n fi pe Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní “àpẹẹrẹ àríkọ́gbọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé yòókù” tá a bá ń sọ nípa “àwùjọ kan tó máa ń ra ohun èlò, tó sì tún máa ń yára gbé e sọ nù.” Àmọ́ kì í ṣe orílẹ̀-èdè yẹn nìkan lèyí ti ń ṣẹlẹ̀ o. Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye ohun táwọn èèyàn ilẹ̀ Jámánì máa ń kó dà nù lọ́dọọdún pọ̀ tó èyí tí wọ́n lè kó sínú ọkọ̀ ojú irin akẹ́rù tó kún fọ́fọ́, tí gígùn rẹ̀ sì tó láti ìlú Berlin tó jẹ́ olú ìlú Jámánì títí dé etíkun Áfíríkà, èyí tí ó fi ẹgbẹ̀sán [1,800] kìlómítà jìnnà. Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì rèé, wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ nígbà kan pé, ní ìpíndọ́gba, iye bébà tí ìdílé ẹlẹ́ni-mẹ́rin ń kó dà nù lọ́dún dọ́gba pẹ̀lú iye bébà tí igi mẹ́fà lè mú jáde.

Àpọ̀jù pàǹtírí kò yọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà sílẹ̀. Ìwé ìròyìn kan tó gbajúmọ̀ ròyìn pé: “Ìṣòro pàǹtírí ọ̀hún ń burú sí i ni, torí pé, ńṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn bílíọ̀nù mẹ́fà tó wà nínú ayé yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kó ìdọ̀tí tiwọn jọ ní rẹpẹtẹ, bíi ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tó ti gòkè àgbà.” Kò sí àní-àní pé, bóyá a fẹ́ o tàbí a kọ̀ o, ọ̀pọ̀ jù lọ wa lóde òní ló wà lára àwùjọ tó ń gbé nǹkan sọ nù.

Òótọ́ ni pé, ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń rí nǹkan gbé sọ nù. Àmọ́, àwọn oúnjẹ inú agolo, àtàwọn ọjà mìíràn tí wọ́n ti dì sílẹ̀ ti wá pọ̀ yamùrá báyìí ju bó ṣe rí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lọ. Èyí ló mú kí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń di nǹkan, téèyàn sì lè tètè jù sọ nù wà níbi gbogbo. Àwọn ìwé ìròyìn, ìwé àtìgbàdégbà, ìwé ìpolówó ọjà pélébé, àtàwọn ìwé títẹ̀ mìíràn náà sì ti wá pọ àpọ̀yamùrá báyìí.

Bí àwọn nǹkan tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń mú jáde ṣe kún inú ayé fọ́fọ́ sì tún ti dá oríṣi àwọn pàǹtírí tuntun mìíràn sílẹ̀. Ìwé ìròyìn Jámánì náà, Die Welt, sọ pé, “ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án làwọn èèyàn ń pa tì lọ́dọọdún ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ara Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù.” Pípalẹ̀ wọn mọ́ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ìṣòro kan tó nira láti wá ojútùú sí ni pé, Báwo la ṣe lè palẹ̀ àwọn ohun olóró mọ́ láìséwu, irú bí àjókù agolo bọ́ǹbù tàbí ìdọ̀tí oníkẹ́míkà? Ìròyìn fi hàn pé lọ́dún 1991, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní “ọ̀pọ̀ pàǹtírí olóró, àmọ́ kò sí ibi tí wọ́n lè rù wọ́n dà sí.” Bákan náà, àwọn àgbá tí wọ́n tó mílíọ̀nù kan, tí wọ́n kún fún májèlé olóró ló wà láwọn ibi ìkẹ́rùsí onígbà kúkúrú, tó sì jẹ́ pé ìgbàkigbà ni “wọ́n lè dàwátì tàbí kí olè jí wọn kó, tàbí kí àìsí àbójútó tó péye mú kí wọ́n fa ìbàyíkájẹ́.” Lọ́dún 1999 nìkan ṣoṣo, àwọn ilé iṣẹ́ aládàáni àti ti ìjọba tó jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà mú àwọn ìdọ̀tí tó lè ṣekú pani tó lé ní ogójì mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù jáde.

Ohun mìíràn tó ń dá kún àpọ̀jù pàǹtírí ni bí àwọn èèyàn tó wà lágbàáyé ṣe ń pọ̀ sí i, iye yìí sì tún ti lọ sókè gan-an ní ọ̀rúndún tó kọjá. Àbáyọrí èyí ni pé, báwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pàǹtírí ń pọ̀ sí i! Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn yìí ló sì jẹ́ pé àtimáa ra nǹkan ṣáá ló gbà wọ́n lọ́kàn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àjọ Tó Ń Rí Sí Ọ̀ràn Àgbáyé sọ pé: “Àwọn ohun ìní àti nǹkan amáyédẹrùn tá a lò látọdún 1950 sí àkókò yìí ju gbogbo èyí táwọn èèyàn ti lò nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn lọ.”

Ká sòótọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ló máa lè ṣe é káwọn máà ní gbogbo “àwọn ohun ìní àti nǹkan amáyédẹrùn” wọ̀nyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ náà mọ bó ṣe máa ń rọrùn tó láti lọ sọ́jà lọ ra èlò ọbẹ̀ tí wọ́n ti fi bébà tàbí àpò ọ̀rá dì sílẹ̀, kó o sì wá fi gbé e lọ sílé. Bó bá ṣàdéédéé ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn ò rí irú àwọn ohun èlò ìgbàlódé tá a fi ń di nǹkan bẹ́ẹ̀ mọ́, kíá ni wọn á wá rí i pé àwọ́n ti gbára lé wọn jù. Bá a bá sì wo bí irú àwọn ohun tá a fi ń di nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe mọ́ tónítóní sí, a ó gbà pé wọ́n ń jẹ́ kí ìlera èèyàn gbé pẹ́ẹ́lí sí i, lọ́nà kan ṣáá.

Àmọ́ ṣá o, láìka irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀ sí, ǹjẹ́ ó yẹ ká máa ṣàníyàn pé pàǹtírí táwọn èèyàn ń kó jọ gegere lóde òní ti pọ̀ jù? Ó hàn gbangba pé ó yẹ ká ṣàníyàn, torí pé ekukáká làwọn ọgbọ́n oríṣiríṣi tá à ń dá sí ọ̀ràn ọ̀hún fi ń yanjú ìṣòro àpọ̀jù pàǹtírí táwa ẹ̀dá èèyàn ń kó jọ. Èyí tó wá burú jù lọ ni pé, àwọn ìṣarasíhùwà tó ń sún àwọn èèyàn láti máa yára gbé nǹkan sọ nù lóde òní ní àwọn àbájáde mìíràn tó ń dani lọ́kàn rú gan-an.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọgbà yìí fẹ̀ ní ọ̀ọ́dúnrún ó lé mọ́kànlélógójì [341] hẹ́kítà níbùú lóròó.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Pípalẹ̀ àwọn ìdọ̀tí tó lè ṣekú pani mọ́ láìséwu máa ń mú ọ̀pọ̀ ìṣòro lọ́wọ́