Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibi Ìsádi Fún Títẹ Bíbélì

Ibi Ìsádi Fún Títẹ Bíbélì

Ibi Ìsádi Fún Títẹ Bíbélì

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BELGIUM

Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún [500] sẹ́yìn, ìlú Antwerp, lórílẹ̀ èdè Belgium ni wọ́n ti tẹ àwọn ẹ̀dà Bíbélì ìjímìjí jáde lódindi. Kí ló mú kí ìlú yìí fa àwọn tó ń tẹ Bíbélì mọ́ra? Àwọn ewu wo ni wọ́n dojú kọ bí wọ́n ti ń tẹ Bíbélì? Ká tó lè rí ìdáhùn, a ní láti gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún yẹ̀ wò.

ÌLÚ Antwerp wà ní ibi ẹnu Odò Scheldt, ó sì jẹ́ kìlómítà mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89] sí Òkun Àríwá. Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, èyí tí wọ́n pè ní sànmánì aláásìkí ìlú náà, ọrọ̀ ajé Antwerp búrẹ́kẹ́ lọ́nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí. Àní sẹ́, kíákíá ni ìlú náà fẹjú, tí ó di etíkun tó tóbi jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù, tó sì wá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú díẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù táwọn olùgbé inú wọn lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún.

Bí Antwerp ṣe ń tóbi sí i yìí mú káwọn oníṣòwò káàkiri Yúróòpù nífẹ̀ẹ́ sí ìlú náà. Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú aásìkí rẹ̀ tó ń pọ̀ sí i, mú kó jẹ́ ìlú tí àwọn aláṣẹ rẹ̀ rí ara gba nǹkan sí, ó sì jẹ́ kí Antwerp di ibi tí onírúurú èròǹgbà tuntun ti gbilẹ̀ bí ọ̀wàrà òjò. Bí ìlú yìí ṣe rí ara gba nǹkan sí yìí mú kó fa àwọn tẹ̀wétẹ̀wé mọ́ra, nítorí wọ́n ronú pé kò ní í séwu fún àwọn níbẹ̀ láti tẹ ohun tó jẹ́ èrò ọkàn àwọn jáde àti láti pín in kiri. Kò pẹ́ kò jìnnà, ìlú Antwerp ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún wá di ilé fún àwọn òǹtẹ̀wé, òǹṣèwé, àtàwọn tàwétàwé tí iye wọ́n jẹ́ igba ó lé mọ́kànléláàádọ́rin [271]. Ńṣe làwọn adájọ́ ìgbà náà máa ń fi ìlú wọn yangàn pé ó jẹ́ “ibi ìsádi àti ilé gbogbo iṣẹ́ ọnà, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, ibi tí àwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè fìdí kalẹ̀ sí, ó sì jẹ́ ibùdó ìwà rere.”

Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Sun Ìwé Àtàwọn Ọkùnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé Nínú Iná

Lára àwọn èròǹgbà tuntun tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé nígbà náà tí wọ́n sì pín kiri ni èyí tí Martin Luther (1483-1546) tẹ̀ jáde. Òun ni aṣáájú Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn, ìyẹn ètò ìsìn kan tó wá di ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì lẹ́yìn náà. Kò ju oṣù mẹ́fà lọ tí àjọ yìí bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò wọn ni àwọn ìwé tí Luther kọ ti bẹ̀rẹ̀ sí í dé orí àtẹ láwọn ilé ìtàwé tó wà ní Antwerp. Kò yani lẹ́nu pé èyí kò dùn mọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nínú. Nígbà tó di oṣù July, ọdún 1521, ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì bá sọ pé kí wọ́n sun irínwó ìwé tó pè ní ti aládàámọ̀ níta gbangba ìlú Antwerp. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n sun àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Augustine láti ìlú Antwerp láàyè, nítorí pé wọ́n fara mọ́ èròǹgbà Luther.

Àmọ́ àwọn ìgbóguntì yìí kò dá àwùjọ àwọn tẹ̀wétẹ̀wé onígboyà kan nílùú Antwerp dúró lẹ́nu iṣẹ́ wọn o. Kì í ṣe ipa kékeré ni ìgboyà àwọn tẹ̀wétẹ̀wé wọ̀nyẹn kó nínú mímú kí àwọn gbáàtúù èèyàn di ẹni tó ní Bíbélì lọ́wọ́. Àwọn wo ni díẹ̀ lára àwọn tẹ̀wétẹ̀wé yẹn?

Tẹ̀wétẹ̀wé Di Ajẹ́rìíkú

Òǹtẹ̀wé àti tàwétàwé ni Adriaen van Berghen. Lọ́dún 1522, wọ́n de tọwọ́tẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ inú àbà nítorí pé ó ń ta àwọn ìwé tí Luther ṣe, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Wọ́n dárí jì í, àmọ́ kíá ló tún padà sídìí iṣẹ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀wé padà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, apá kan “Májẹ̀mú Tuntun” tí Luther tú sí èdè Dutch ló ń tẹ̀. Ó mú un jáde lọ́dún 1523, ọdún kan péré lẹ́yìn tí wọ́n mú “Májẹ̀mú Tuntun” tí Luther tú sí èdè Jámánì jáde.

Àmọ́ o, nígbà tó di ọdún 1542, tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìwé tí wọ́n ti fòfin dè nínú ilé Van Berghen nílùú Delft lórílẹ̀-èdè Netherlands, ni wọ́n bá tún kì í mọ́lẹ̀. Adájọ́ kan ti kọ́kọ́ fún un ní ìdájọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ le, ó ní kó lọ lo wákàtí méjì lórí pákó tí wọ́n ti máa ń pa àwọn ọ̀daràn “kí wọ́n sì so díẹ̀ lára àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè náà mọ́ ọn lọ́rùn.” Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yí ìdájọ́ Van Berghen padà sí ìdájọ́ ikú, bí wọ́n ṣe fi idà bẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé onígboyà yìí lórí nìyẹn.

Ẹ̀mí Rẹ̀ Ló Fi Dí Àlàyé Tó Ṣe Sí Etí Bíbélì

Lákòókò yẹn, ẹni tó ṣì tẹ Bíbélì èdè Dutch jáde lọ́pọ̀ yanturu jù lọ ni Jacob van Liesvelt. Oríṣiríṣi ẹ̀dà tó jẹ́ méjìdínlógún ni gbogbo Bíbélì tó mú jáde lédè Dutch. Lọ́dún 1526, ó tẹ odindi Bíbélì jáde lédè Dutch. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tí Bíbélì yìí ti jáde ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mú odindi Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀ lédè Faransé jáde, ọdún mẹ́sàn-án gbáko ló sì fi ṣáájú odindi Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì! Orí Bíbélì tí Luther ń tú lọ́wọ́ sí èdè Jámánì nígbà yẹn ni Van Liesvelt gbé Bíbélì rẹ̀ kà látòkèdélẹ̀.

Ẹ̀dà Bíbélì èdè Dutch ti ọdún 1542 tí Van Liesvelt mú jáde kẹ́yìn ní àwọn àwòrán nínú ó sì tún ní àwọn àlàyé tuntun léteetí. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Mátíù 4:3, àwòrán kan wà níbẹ̀ tó fi Èṣù hàn bí ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó ní irùngbọ̀n, tó mú ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà àwọn Kátólíìkì lọ́wọ́, tó sì ní ẹsẹ̀ ewúrẹ́. Àmọ́, àlàyé etí ìwé yẹn gan-an ló mú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fara ya. Àlàyé kan tó kà pé, “Ipasẹ̀ Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ni ìgbàlà fi ṣeé ṣe,” ni wọ́n lò láti fi dájọ́ ikú fún Van Liesvelt. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Van Liesvelt ṣàlàyé pé òún ti gba àṣẹ lọ́wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kóun tó ó tẹ Bíbélì náà, ńṣe ni wọ́n bẹ́ ẹ lórí sọ nù nílùú Antwerp lọ́dún 1545.

Wọ́n Kọ́kọ́ Fọwọ́ Sí I, Kò Pẹ́ Ni Wọ́n Bá Tún Fòfin Dè É

Láàárín àkókò yìí, ní ilẹ̀ Faransé, gbajúmọ̀ ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Jacques Lefèvre d’Étaples, ọmọ ìjọ Kátólíìkì ni, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn sì tún ni pẹ̀lú. Ńṣe ló ń bá iṣẹ́ títú Bíbélì láti èdè Látìn sí èdè Faransé lọ ní pẹrẹu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tún lo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀. D’Étaples fẹ́ kí àwọn gbáàtúù èèyàn náà ní Bíbélì lọ́wọ́. Ó kọ̀wé pé: “Ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á máa wàásù Kristi lọ́nà mímọ́ tí wọn ò sì ní í máa lú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, èyí tí kò tíì rí bẹ́ẹ̀ lásìkò tá a wà yìí.” Lọ́dún 1523, ó mú “Májẹ̀mú Tuntun” jáde lédè Faransé ní ìlú Paris. Àmọ́, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní Yunifásítì Sorbonne tó gbayì kò fọwọ́ sí ìtumọ̀ rẹ̀ nítorí pé èdè àbínibí ló tú u sí. Látàrí ogun tí wọ́n gbé dìde sí i, D’Étaples sá kúrò ní Paris lọ sí ìlú Strasbourg, lápá àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé.

Nítorí àtakò yìí, àwọn tẹ̀wétẹ̀wé ilẹ̀ Faransé kò tún gbójúgbóyà láti tẹ Bíbélì mọ́ lédè Faransé. Ibo wá ni D’Étaples ti máa rẹ́ni bá a tẹ Bíbélì rẹ̀ jáde? Ìlú Antwerp nìkan nibi tó bọ́gbọ́n mu tó lè lọ. Ẹ̀dà Bíbélì d’Étaples ti ọdún 1530 yìí, tí ọ̀gbẹ́ni Merten de Keyser tẹ̀ jáde nílùú Antwerp, ló wá di ìtumọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Faransé ní ìdìpọ̀ kan. Ó yẹ fún àfiyèsí pé, kí ọ̀gbẹ́ni De Keyser tó ó tẹ ìtumọ̀ yìí jáde, ó ti kọ́kọ́ gba àṣẹ lọ́wọ́ Catholic University ti ìlú Louvain, èyí tó jẹ́ yunifásítì tó lọ́jọ́ lórí jù lọ lórílẹ̀-èdè Belgium, bákan náà, ló tún gbàṣẹ lọ́wọ́ Olú Ọba Ilẹ̀ Róòmù Mímọ́ fúnra rẹ̀, ìyẹn Charles Karùn-ún! Àmọ́ láìfi ìyẹn pè, nígbà tó di ọdún 1546, ìtumọ̀ Bíbélì D’Étaples di èyí tí wọ́n kà mọ́ ara àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè pé àwọn tó jẹ́ Kátólíìkì kò gbọ́dọ̀ kà.

“Bíṣọ́ọ̀bù Fọwọ́ Mú Ìwé . . . Tyndale Fọwọ́ Mú Owó”

Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, láàárín àkókò yìí kan náà, William Tyndale, tí wọ́n fi joyè àlùfáà, fẹ́ láti tú Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́, ńṣe ni bíṣọ́ọ̀bù ìlú London, Cuthbert Tunstall, bẹnu àtẹ́ lù ú. Nígbà tí Tyndale rí i pé òun ò ní í lè ṣe ìtumọ̀ Bíbélì náà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ló bá sá lọ sí ilẹ̀ Jámánì. Níkẹyìn, ní February 1526, ó ṣàṣeyọrí, ó mú odindi Bíbélì rẹ̀ àkọ́kọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde, ìyẹn “Májẹ̀mú Tuntun.” Kò tó oṣù kan lẹ́yìn ìgbà náà tí àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́ nínú ìtumọ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tó wà lọ́kàn Bíṣọ́ọ̀bù Tunstall ni láti má ṣe jẹ́ kí àwọn gbáàtúù èèyàn rí Bíbélì kà. Bó ṣe kó gbogbo ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì Tyndale tọ́wọ́ ẹ̀ bà nìyẹn, tó sì sun wọ́n níná. Síbẹ̀, àwọn Bíbélì náà ṣì ń ti ọwọ́ ẹnì kan dé òmíràn. Ni bíṣọ́ọ̀bù náà bá dì í pẹ̀lú oníṣòwò kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Packington, ó ní kó ra gbogbo Bíbélì tí Tyndale ní lọ́wọ́ pátá kó tó ráyè kó wọn jáde kúrò lórílẹ̀ èdè náà lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Tyndale gba ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yìí ó sì lo owó náà láti fi mú kí iṣẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀ dára sí i, ó sì tún tẹ àwọn mìíràn tó dára ju ti àkọ́kọ́ lọ. Ẹnì kan tó wà láyé nígbà yẹn sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni òwò tí wọ́n jọ dàpọ̀ yìí bá mú kí iṣẹ́ rẹ̀ túbọ̀ yọrí sí dáadáa. Bíṣọ́ọ̀bù fọwọ́ mú ìwé, Packington gba o ṣeun, Tyndale sì fọwọ́ mú owó.” Bí bíṣọ́ọ̀bù ìlú London ṣe pèsè owó fún iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì Tyndale láìmọ̀ nìyẹn!

Bí Tyndale Ṣe Dèrò Antwerp

Àmọ́ kódà, lẹ́yìn tí wọ́n ti ra gbogbo ẹ̀dà yìí tí wọ́n sì ti sun wọ́n níná, “Májẹ̀mú Tuntun” tí Tyndale ṣe kò yéé ya wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Báwo nìyẹn ṣe ṣeé ṣe? Hans àti Christopher van Ruremond, àwọn tẹ̀wétẹ̀wé méjì tí wọ́n gbójúgbóyà ní ìlú Antwerp ti ń tẹ àwọn ẹ̀dà “Májẹ̀mú Tuntun” ti Tyndale lọ ní bòókẹ́lẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣi ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ inú àwọn Bíbélì wọ̀nyí tẹ̀, wìtìwìtì làwọn èèyàn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń rà wọ́n.

Àmọ́ ṣá o, lọ́dún 1528, wọ́n ju Hans sẹ́wọ̀n nílùú London nítorí pé ó tẹ ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ẹ̀dà Bíbélì “Májẹ̀mú Tuntun” ti Tyndale, àti pé ó kó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú rẹ̀ wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló kú sí. Lọ́dún 1531, wọ́n ju Christopher, àbúrò Hans náà sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń ta Bíbélì “Májẹ̀mú Tuntun” yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n ni Christopher náà kú sí.

“Ohun Tí Wọ́n Fi Ń Rántí Tyndale Jù Lọ” —Ìlú Antwerp Ni Wọ́n Ti Tẹ̀ Ẹ́

Ìlú Antwerp ni Tyndale fara sí jù láàárín ọdún 1529 sí 1535, níbi tó ti rọrùn fún un díẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Níbẹ̀, lọ́dún 1530, Merten de Keyser tẹ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tí Tyndale túmọ̀ jáde, inú rẹ̀ sì ni orúkọ Jèhófà ti kọ́kọ́ fara hàn lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ní oṣù May ọdún 1535, wọ́n fàṣẹ ọba mú Tyndale nílùú Antwerp. Ní gbogbo ìgbà tó fi wà lẹ́wọ̀n níbi tí ojú rẹ̀ ti ń rí màbo, Miles Coverdale, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ parí ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù èyí ti Tyndale bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀. Ní October 6, 1536, ní ìlú Vilvoorde lórílẹ̀-èdè Belgium, wọ́n de Tyndale mọ́gi, wọ́n fi okùn fún un lọ́rùn, wọ́n sì dáná sun ún. Gbólóhùn tó jáde lẹ́nu rẹ̀ kẹ́yìn ni: “Olúwa, la Ọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lójú!”

Ogún Tí Tyndale Fi Sílẹ̀

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa Tyndale, ni Ọba Henry Kẹjọ ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bá pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìtumọ̀ Bíbélì kan nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì. Matthias Crom, ọ̀gbẹ́ni kan tí òun náà jẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé nílùú Antwerp ló tẹ ìtumọ̀ tí wọ́n fàṣẹ ọba sí náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kìkìdá ohun tí Tyndale tú ló kúnnú Bíbélì yìí, èyí tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Bíbélì Matthew (orúkọ Thomas Matthew ni wọ́n ń fi pè é). a Ìjọlójú gbáà ló jẹ́ pé ìtumọ̀ Bíbélì táwọn bíṣọ́ọ̀bù ń dáná sun lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, tí wọ́n tún torí ẹ̀ pa Tyndale gan-an ni wọ́n tún wá ń lò báyìí!

Púpọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Tyndale lò ṣì wà nínú ìtumọ̀ King James Version. Nípa bẹ́ẹ̀, púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì King James Version, tó wá di pàtàkì nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì báyìí ló jẹ́ pé Tyndale ló ṣẹ̀dá wọn, ìlú Antwerp ni wọ́n sì ti kọ́kọ́ tẹ̀ wọ́n jáde. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Latré ti sọ, ipa tí Tyndale kó nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì ju èyí tí Shakespeare kó lọ fíìfíì!

Ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ìlú Antwerp kì í tún ṣe ìlú tó fàyè gba onírúurú ẹ̀sìn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe ibi ìsádi fún títẹ Bíbélì mọ́. Ohun tó túbọ̀ mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ni inúnibíni tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe tí Ìjọ Kátólíìkì dá sílẹ̀, láti ṣèdíwọ́ fún bí ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe ń fìdí múlẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ipa kékeré kọ́ ni ìgboyà àti ìfara-ẹni-rúbọ àwọn tó tẹ Bíbélì ní ìjímìjí, nílùú Antwerp kó nínú mímú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì káàkiri ayé lónìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orúkọ ìnagijẹ John Rogers ni Thomas Matthew, ọ̀rẹ́ ló jẹ́ fún Tyndale, alájọṣiṣẹ́ sì tún ni wọ́n.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Òkè: Fífi ọwọ́ to ọ̀rọ̀; Martin Luther níbi tó ti ń túmọ̀ Bíbélì; àwòrán ilẹ̀ ìlú Antwerp láyé ọjọ́un

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Orí ibi tí Jacob van Liesvelt ń pàtẹ ìwé sí

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Jacques Lefèvre d’Étaples àti ojú ìwé tí àkọlé Bíbélì rẹ̀ ti ọdún 1530 ti fara hàn, èyí tó tẹ̀ nílùú Antwerp

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Sísun Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì níná ní gbangba òde nílùú London

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

William Tyndale, ọ̀kan lára àwọn ojú ewé Bíbélì rẹ̀, àti Miles Coverdale

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Ojú ìwé 15: Ẹni tó ń fọwọ́ to ọ̀rọ̀: Printer’s Ornaments/by Carol Belanger Grafton/Dover Publications, Inc.; Luther: Látinú ìwé Bildersaal deutscher Geschichte; àwòrán ilẹ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen; ojú ìwé 17: Àwòrán: Látinú ìwé Histoire de la Bible en France; ojú ewé Bíbélì: © Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris; sísun Bíbélì: Látinú ìwé The Parallel Bible, The Holy Bible, 1885; ojú ìwé 18: Tyndale: Látinú ìwé The Evolution of the English Bible; Coverdale: Látinú ìwé Our English Bible: Its Translations and Translators