Irú Àdúrà tí Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́
Ojú Ìwòye Bíbélì
Irú Àdúrà tí Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́
“Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. Nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà, àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún.”—LÚÙKÙ 11:9, 10.
Ọ̀PỌ̀ Kristẹni ló ń fi ìgbọ́kànlé wọn kíkún hàn nínú ọ̀rọ̀ Jésù Kristi tá a fà yọ lókè yìí nípa yíyíjú sí Ọlọ́run nínú àdúrà láti sọ fún un nípa ìṣòro wọn àti ẹ̀dùn ọkàn wọn, pẹ̀lú ìdánilójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé ó bìkítà fún wọn. Bó ti wù kó rí, ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń dé bá àwọn kan bí wọ́n ti ń retí pé kí Ọlọ́run tètè dáhùn àdúrà wọn. Ṣé o máa ń rò pé àdúrà rẹ kò ṣiṣẹ́? Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tó o bá ń gbàdúrà?
Ká tiẹ̀ ní ó jọ pé Ọlọ́run kò dáhùn àwọn àdúrà wa, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kò gbọ́ wọn. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pétérù 3:12) Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olódodo, ì báà jẹ́ èyí tí wọ́n gbà sókè tàbí èyí tí wọ́n rọra fi ọkàn gbà. (Jeremáyà 17:10) Jèhófà tún máa ń ṣàyẹ̀wò ohun tó mú kí ẹnì kan gbàdúrà tàbí èrò ọkàn onítọ̀hún, èyí tí ẹni tó ń gba àdúrà alára lè máà lóye délẹ̀délẹ̀ tàbí kó má tiẹ̀ mọ̀.—Róòmù 8:26, 27.
Àmọ́ ṣá o, kí àdúrà tó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun kan tí Ó ń béèrè. Lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ darí àdúrà sí—kì í ṣe sí Jésù, kì í ṣe sí “ẹni mímọ́ kan,” tàbí òrìṣà kan. (Ẹ́kísódù 20:4, 5) A tún gbọ́dọ̀ gba àdúrà ní orúkọ Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi. (Jòhánù 14:6) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Jésù á kọ́kọ́ gbọ́ àdúrà wa ná, tí yóò sì wá lọ jíṣẹ́ fún Ọlọ́run ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa gbígbàdúrà sí Jèhófà lórúkọ Jésù, à ń fi ara wa hàn ní ọmọ ẹ̀yìn Kristi, àti pé a gbà pé kìkì nípasẹ̀ ìràpadà rẹ̀ ló fi lè ṣeé ṣe fún wa láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.—Hébérù 4:14-16.
A gbọ́dọ̀ gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ gbangba pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè mọ̀ bóyá òún ní irú ìgbàgbọ́ yẹn? Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Jákọ́bù, dáhùn pé: “Èmi yóò . . . fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ mi.” (Jákọ́bù 2:18) Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ máa ń yọrí sí iṣẹ́, àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ló sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé à ń gbìyànjú láti múnú rẹ̀ dùn.
Bákan náà, àwọn olùjọsìn Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ káàárẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Jésù mú kí èyí ṣe kedere nínú Lúùkù 11:9, 10, tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Ó ṣe tán, bó bá jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni ẹnì kan gbàdúrà nípa ọ̀ràn kan, ṣé ìyẹn ò ní fi hàn pé ọ̀ràn náà kò ká onítọ̀hún lára?
Ohun Tí Ọlọ́run Ṣèlérí fún Wa
Bó ti wù ká fi taratara gbàdúrà lemọ́lemọ́ tó, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la ṣì ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun á láyọ̀, kò sọ pé wọn ò ní í níṣòro rárá nínú ìgbésí ayé wọn. (Mátíù 5:3-11) Síbẹ̀, ó sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣì lè láyọ̀ láìka ọ̀fọ̀, ebi, òùngbẹ àti inúnibíni sí.
Ayọ̀ tí Jésù ń sọ kò mọ sígbà tí ipò nǹkan bá fara rọ fún wa nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni ìtẹ́lọ́rùn àtinúwá tá a máa ní nítorí pé à ń sin Ọlọ́run. Fún ìdí yìí, a ṣì lè ní ayọ̀ dé ìwọ̀n àyè kan kódà tá a bá wà nínú ìṣòro pàápàá.—2 Kọ́ríńtì 12:7-10.
Bí A Ṣe Lè Kojú Àwọn Ìṣòro Wa
Ṣé pé fífi àkókò ṣòfò ló wá jẹ́ láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ọ̀ràn ara ẹni, irú bíi rírí ẹni tó yẹ láti fẹ́ tàbí kíkojú àwọn ìṣòro ìdílé, ìṣòro ìlera tàbí ìṣòro àìníṣẹ́lọ́wọ́? Ó tì o, torí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò ṣèlérí láti yí ipò ìgbésí ayé wa padà lọ́nà ìyanu, yóò fún wa ní ọgbọ́n láti kojú wọn pẹ̀lú àṣeyọrí. Nígbà tí Jákọ́bù ń kọ̀wé nípa ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú àdánwò, ó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Jákọ́bù 1:5) Nípa bẹ́ẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Jèhófà á tọ́ wa sọ́nà. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìlànà Bíbélì àti láti ṣàmúlò wọn nígbà tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu.
Lóòótọ́, kì í ṣe ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń ṣe ìpinnu fún wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa ní láti sapá. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ńṣe la ní ìṣòro kan, ǹjẹ́ a ti ṣe ìwádìí lórí rẹ̀, tá a sì ti ṣàyẹ̀wò oríṣiríṣi ohun tó wé mọ́ ipò náà? Èyí jẹ́ iṣẹ́ kan tí Ọlọ́run fi ń mọ̀ pé a ní ìgbàgbọ́. (Jákọ́bù 2:18) Ǹjẹ́ à ń tẹra mọ́ ìsapá wa láti wá bá a ṣe lè rí ojútùú sí ìṣòro wa, tá a sì ń sọ fún Ọlọ́run nígbà gbogbo pé kó tọ́ wa sọ́nà? (Mátíù 7:7, 8) Ǹjẹ́ a ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú ipò náà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú wa “pegedé ní kíkún” kó sì mú wa “gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run lè dá sí àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá èèyàn kó sì bá wa mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, ó fún àwọn ẹ̀dá èèyàn láyè láti lo òmìnira wọn bó ṣe wù wọ́n. Ó ṣeni láàánú pé, ńṣe ni ọ̀pọ̀ ń lo òmìnira tí wọ́n ní yìí láti ṣe ohun tó wù wọ́n lọ́nà tó ń ṣàkóbá fún àwọn mìíràn. Nípa báyìí, àwọn ìṣòro kan tá à ń gbàdúrà nípa wọn lè máa bá a nìṣó títí dìgbà tí ayé tuntun Ọlọ́run á fi dé. (Ìṣe 17:30, 31) Ó lè jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ń wáyé ní àgbègbè tí à ń gbé, irú bí ìwà ọ̀daràn tàbí ogun; ó sì lè ní í ṣe pẹ̀lú fífarada ìṣòro tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn alátakò. (1 Pétérù 4:4) A gbọ́dọ̀ gbà pé nínú ayé táwọn èèyàn kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí, àwọn ipò kan wà tí kò ní sàn sí i ju bí wọ́n ṣe wà lọ.
Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ ó sì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí Ìjọba rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé láìsí àtakò kankan, yóò mú gbogbo àwọn ìṣòro tó ń bani nínú jẹ́, èyí tó wà nínú ayé yìí kúrò pátápátá. (Ìṣípayá 21:3, 4) Títí di àkókò náà, a ní láti tẹra mọ́ bíbéèrè fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò mú ìlérí tó wà nínú Bíbélì ní Aísáyà 41:10 ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”