Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?

Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?

Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?

“Látọjọ́ tí mo ti ń wa ọkọ̀, mi ò fọkọ̀ jáàmù rí, torí náà kò sídìí tí màá fi máa ṣàníyàn nípa jàǹbá ọkọ̀.” “Àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ awakọ̀ àtàwọn tó máa ń wa ìwàkuwà nìkan ló lè fi mọ́tò jáàmù.” Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé jàǹbá ọkọ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sáwọn láé. Ṣé ohun tí ìwọ náà máa ń rò nìyẹn? Ǹjẹ́ jàǹbá ọkọ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ọ?

ÀWỌN ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn olùṣèṣirò ti fi hàn pé, bó bá jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lò ń gbé, ó ṣeé ṣe kó o fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀ ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan nínú ìgbésí ayé rẹ. Ọ̀pọ̀ ló tiẹ̀ máa ń kú. Kárí ayé, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] èèyàn báyìí tó ń kú lọ́dọọdún nínú jàǹbá ọkọ̀. Bóyá ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kú lọ́dún tó kọjá náà ló ti máa ń rò ó pé kò lè ṣẹlẹ̀ sáwọn láé. Kí lo lè ṣe láti dín ewu jàǹbá ọkọ̀ tó lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ alára kù? Sapá láti dènà rẹ̀. Wo bó o ṣe lè dènà jàǹbá ọkọ̀ tó lè wáyé nítorí títòògbé àti ọjọ́ ogbó.

Awakọ̀ Tó Ń Tòògbé

Àwọn ògbógi kan sọ pé títòògbé nígbà téèyàn bá ń wakọ̀ léwu gan-an, bí ìgbà tí ẹnì kan mutí tó tún ń wakọ̀ ló rí. Àwọn ìròyìn fi hàn pé ńṣe ni iye jàǹbá ọkọ̀ tó ń wáyé nítorí pé àwọn awakọ̀ ń tòògbé túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn Fleet Maintenance & Safety Report sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé, láàárín ọdún kan ṣoṣo, ìdá kan nínú méjìlá àwọn awakọ̀ ní orílẹ̀-èdè Norway ló sọ pé àwọ́n gbàgbé sùn lọ nígbà tí àwọ́n ń wakọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Star ti ìlú Johannesburg, ní orílẹ̀-èdè South Africa ti sọ, àárẹ̀ tó máa ń mú àwọn awakọ̀ ló ń fa nǹkan bí ìdá mẹ́ta gbogbo jàǹbá ọkọ̀ tó ń wáyé ní orílẹ̀-èdè ọ̀hún. Àwọn ìròyìn láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn fi hàn pé àárẹ̀ ara máa ń ṣàkóbá fún àwọn awakọ̀ níbi gbogbo. Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ awakọ̀ fi máa ń sùn nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀?

Ìgbésí ayé kòókòó jàn-ánjàn-án òde òní wà lára ohun tó ń dá kún ìṣòro náà. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé, ó dà bíi pé “iye oorun” tí àwọn ará Amẹ́ríkà “ń sùn mọ́jú báyìí ti fi wákàtí kan àti ààbọ̀ dín kù sí iye tí [wọ́n] ń sùn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí—àfàìmọ̀ sì ni ìṣòro yìí ò ní burú sí i.” Kí nìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Ìwé ìròyìn náà fa ọ̀rọ̀ Terry Young, ẹni tó jẹ́ ògbógi nípa oorun yọ, pé: “Àwọn èèyàn ti ka oorun sí ohun tó ṣeé rẹ́ jẹ. Wọ́n máa ń ka ẹni tó bá lè ṣiṣẹ́ kára àmọ́ tí kì í sùn púpọ̀ sí ọ̀jáfáfá èèyàn.”

Oorun wákàtí mẹ́fà àti ààbọ̀ sí wákàtí mẹ́sàn-án ló yẹ kéèyàn máa sùn lójoojúmọ́. Àmọ́, béèyàn ò bá ń sùn tó bó ṣe yẹ, díẹ̀díẹ̀ ni “gbèsè oorun” á di gọbọi sí onítọ̀hún lára. Ìwé pélébé kan tí Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ààbò Àwọn Ọlọ́kọ̀ Lójú Pópó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pín kiri sọ pé: “Kódà bí iye àkókò tí ẹnì kan fi ń sùn mọ́jú ní gbogbo ọjọ́ iṣẹ́ tó wà láàárín ọ̀sẹ̀ kan bá ń fi ọgbọ̀n tàbí ogójì ìṣẹ́jú dín kù sí iye tó yẹ kó jẹ́, èyí lè yọrí sí jíjẹ gbèsè oorun tí ó tó wákàtí mẹ́ta sí mẹ́rin tó bá fi máa di òpin ọ̀sẹ̀, ìyẹn sì lè jẹ́ kí oorun túbọ̀ máa kun onítọ̀hún ṣáá ní ojúmọmọ.”

Nígbà míì, ó lè máà ṣeé ṣe fún ọ láti sùn dáadáa lóru. Ìṣòro àìróorunsùn, títọ́jú ọmọ tó ń ṣàìsàn, tàbí àwọn nǹkan mìíràn tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lè máà jẹ́ kó o sun oorun àsùngbádùn. Èyí lè fa kí oorun máa kùn ọ́ bó o bá ń wakọ̀ lọ́jọ́ kejì. Kí ló wá yẹ kó o ṣe bí oorun bá ń kùn ọ́?

Mímu kọfí, ṣíṣí fèrèsé ọkọ̀, jíjẹ ṣingọ́ọ̀mù, tàbí jíjẹ nǹkan bí obì tàbí orógbó, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti sábà máa ń ṣe kò ní kéèyàn má tòògbé mọ́. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyí tó lè ní kí oorun dá wáí lójú rẹ. Kò sóhun méjì tó o nílò ju oorun lọ. O ò ṣe gbìyànjú láti fi oorun díẹ̀ rẹjú? Ìwé ìròyìn The New York Times dábàá pé: “Kò yẹ kí oorun tá a fi ń rẹjú lọ́sàn-án, èyí tó ń sọ agbára ẹni dọ̀tun, ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ; torí bó bá jù bẹ́ẹ̀ lọ, ńṣe ni oorun ọ̀hún á wọra, á sì ṣòro fún onítọ̀hún láti dìde ńlẹ̀.” Rírẹjú lè mú kó o pẹ́ díẹ̀ kó o tó dé ibi tó ò ń lọ, àmọ́ ó lè jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ gùn sí i.

Bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ lè mú kó túbọ̀ rọrùn fún ọ láti di awakọ̀ tó ń tòògbé. Ṣé o máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí wíwá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àbí o máa ń wo tẹlifíṣọ̀n di ọ̀gànjọ́ òru? Ṣé o máa ń lọ sí àwọn àpèjẹ tí wọ́n máa ń ṣe ní àṣemọ́jú? Má ṣe jẹ́ kí irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ máa fi oorun dù ọ́. Nígbà kan sẹ́yìn, Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba tẹnu mọ́ ọn pé, kódà, “ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi” ṣàǹfààní gan-an ni.—Oníwàásù 4:6.

Ìrírí Wà Lóòótọ́ àmọ́ Àgbà Ti Ń Dé

Àwọn awakọ̀ tó ti dàgbà ló sábà máa ń jẹ́ awakọ̀ tó nírìírí jù lọ lójú pópó. Láfikún sí i, wọn kì í sábà fẹ̀mí ara wọn wewu, wọ́n sì máa ń mọ ìwọ̀n ara wọn. Àmọ́ ṣá o, ewu jàǹbá ọkọ̀ kò yọ àwọn àgbàlagbà awakọ̀ sílẹ̀. Àní sẹ́, wọ́n lè tètè máa ní jàǹbá ọkọ̀ bí wọ́n ti ń dàgbà sí i. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà, Car & Travel sọ pé: “Ìdá mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè yìí ló ti lé ní àádọ́rin ọdún, àmọ́ wọ́n jẹ́ ìdá mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ ń ṣekú pa.” Ó ṣeni láàánú pé, ńṣe ni iye àwọn àgbàlagbà awakọ̀ tó ń ní jàǹbá ọkọ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Ronú lórí ohun tí Myrtle, ẹni ọgọ́rin ọdún sọ. a Ó ti lé ní ọgọ́ta ọdún tó ti ń wakọ̀, kò sì tíì fọkọ̀ jáàmù rí. Síbẹ̀, bó ti máa ń rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó ń nímọ̀lára pé àgbà ti ń dé sí òun—àwọn àmì wọ̀nyí sì lè jẹ́ kó tètè di ẹni tó máa fọkọ̀ jáàmù. Ó sọ fún akọ̀ròyìn Jí! lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Béèyàn bá ṣe ń dàgbà sí i, bẹ́ẹ̀ ni àtiṣe gbogbo nǹkan nínú ìgbésí ayé [títí kan ọkọ̀ wíwà] á máa di ẹtì sí i lọ́rùn.”

Kí lohun tó ṣe láti lè dín ewu níní jàǹbá ọkọ̀ kù? Myrtle sọ pé: “Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni mò ń ṣe ìyípadà tó máa bá ọjọ́ orí mi mu.” Bí àpẹẹrẹ, ó ti dín iye àkókò tó fi ń wakọ̀ kù, pàápàá bí ilẹ̀ bá ti ṣú. Ìwọ̀nba ìyípadà tó ṣe yìí ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti máa wakọ̀ láìní jàǹbá kankan, láìsí pé ó dáwọ́ ọkọ̀ wíwà dúró pátápátá.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe ohun téèyàn máa ń fẹ́ gbọ́, kò sẹ́ni tí ọjọ́ ogbó ò lè sọ di alára hẹ́gẹhẹ̀gẹ. (Oníwàásù 12:1-7) Àwọn ìṣòro ìlera lóríṣiríṣi á bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú, ara ò ní gbé kánkán bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ojú á sì máa kọṣẹ́ díẹ̀díẹ̀—gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló lè mú kó ṣòro láti wakọ̀ láìséwu. Àmọ́, pé ọjọ́ ogbó ń dé síni kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò lè wakọ̀ mọ́ rárá. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bí ẹni náà ṣe ń wakọ̀ dáradára sí. Gbígbà pé ara ò gbé kánkán bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ àti ṣíṣe àwọn àtúnṣe tó bá pọn dandan nínú ọ̀nà tí à ń gbà wakọ̀ lè jẹ́ kéèyàn máa wakọ̀ lọ́nà tó sunwọ̀n sí i.

Ìwọ alára lè má tètè fura, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni agbára ìríran rẹ ń dín kù. Bó o ti ń dàgbà sí i, wàá rí i pé ṣàṣà ni ibi tí ojú rẹ á lè ríran dé, àti pé ojú rẹ á máa nílò ìmọ́lẹ̀ tó pọ̀ sí i kó o lè ríran kedere. Ìwé pélébé kan tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ The Older and Wiser Driver sọ pé: “Awakọ̀ tó bá ti pé ọmọ ọgọ́ta ọdún nílò ìmọ́lẹ̀ tó tó ìlọ́po mẹ́ta èyí tí ọ̀dọ́langba kan nílò láti lè ríran kedere, yóò sì gbà á ní ìlọ́po méjì àkókò tí yóò gba ọ̀dọ́langba kan kí ojú rẹ̀ tó lè ríran nínú òkùnkùn lẹ́yìn tí ìmọ́lẹ̀ bá ti tàn sí i lójú.” Àwọn ìyípadà wọ̀nyí, tó ń wáyé nínú agbára ìríran wa ló máa ń jẹ́ kó ṣòro láti wakọ̀ lálẹ́.

Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin ni Henry, kò sì wakọ̀ jáàmù rí láti àádọ́ta ọdún ó lé tó ti ń wakọ̀. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé iná mọ́tò tó ń wọ òun lójú nígbà tóun bá ń wakọ̀ lálẹ́ ń mú kó ṣòro fún òun láti wakọ̀. Lẹ́yìn tó lọ ṣe àyẹ̀wò ojú rẹ̀, ó wá mọ̀ pé òún nílò awò ojú tó lè dín iná mọ́tò tó máa ń wọ̀ ọ́ lójú tó bá ń wakọ̀ lálẹ́ kù. Henry sọ pé: “Wíwakọ̀ alẹ́ kò nira fún mi mọ́.” Ìwọ̀nba ìyípadà tó ṣe yìí ràn án lọ́wọ́ gan-an nínú ọkọ̀ wíwà tirẹ̀. Àmọ́, ní ti irú àwọn èèyàn bíi Myrtle, ó lè jẹ́ pé dídáwọ́ ọkọ̀ wíwà lálẹ́ dúró pátápátá lóhun tó máa dára jù.

Ọjọ́ ogbó tún máa ń nípa lórí béèyàn ṣe ń tètè ṣiṣẹ́ lórí ìsọfúnni sí. Àwọn àgbàlagbà lè lọ́gbọ́n lórí ju àwọn ọ̀dọ́ lọ lóòótọ́, kí wọ́n sì tún lóye jù wọ́n lọ. Àmọ́, béèyàn bá ṣe ń dàgbà sí i ni yóò túbọ̀ máa gbà á ní àkókò gígùn láti ronú lórí ìsọfúnni èyíkéyìí, kó sì tètè ṣiṣẹ́ lé e lórí. Èyí máa ń mú kí ọkọ̀ wíwà túbọ̀ nira, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lemọ́lemọ́ ni ọ̀ràn lílọ-bíbọ̀ ọkọ̀ àtàwọn èèyàn tó ń rìn lójú pópó, àti ipò ojú ọ̀nà máa ń yí padà. A gbọ́dọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìyípadà tó ti dé bá ara wa láìjáfara, ká bàa lè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lásìkò.

Ìwé ìròyìn Car & Travel sọ pé “ohun tó sábà máa ń fa jàǹbá ọkọ̀ tó ń ṣekú pa àwọn àgbà awakọ̀ ni pé, wọ́n máa ń lọ fi mọ́tò kọ lu àwọn ohun èlò tó ń darí ètò ìrìnnà ọkọ̀ ojú pópó.” Kí nìdí tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀? Ìwé ìròyìn náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ó dà bíi pé . . . lára ohun tó ń fa ìṣòro náà ni pé àgbàlagbà awakọ̀ kan lè kùnà láti kọ́kọ́ wo apá òsì láti rí àwọn mọ́tò tó ń bọ̀, lẹ́yìn náà kó tún wo apá ọ̀tún, kó tó wá gbé mọ́tò jánà ní ìkóríta.”

Kí lohun tó o lè ṣe níwọ̀n bí ara rẹ ò ti gbé kánkán mọ́? Máa fara balẹ̀, kó o sì máa ṣọ́ra bó o bá ti fẹ́ dé ìkóríta. Máa rí i dájú pé mọ́tò kankan ò bọ̀ kó o tó gbé mọ́tò jánà. Máa ṣọ́ra gan-an nígbà tó o bá fẹ́ yà. Yíyà sí ọ̀nà mìíràn ní ìkóríta lè ṣekú pani, àgàgà bó bá jẹ́ pé ojú ọ̀nà táwọn mọ́tò mìíràn ń gbà bọ̀ lo fẹ́ yíwọ́ sí.

Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn jàǹbá ọkọ̀ tó ń wáyé ní ìkóríta, èyí tó ń ṣekú pa àwọn awakọ̀ tó ti lé ní ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin, ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n fẹ́ yíwọ́ sí apá òsì títì ló ń ṣẹlẹ̀. Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ààbò Àwọn Ọlọ́kọ̀ Lójú Pópó ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dá a lámọ̀ràn fún àwọn awakọ̀ tó wà lórílẹ̀-èdè náà pé: “Ó sàn kéèyàn máa yà sí ọ̀nà apá ọ̀tún nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti lè dé ibi tó ń lọ, dípò téèyàn á fi yà sí ọ̀nà apá òsì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” O lè fi ìlànà yìí sílò lọ́nà tó máa bá bí wọ́n ṣe ń wakọ̀ ní àdúgbò rẹ mu. Bó o bá ti pinnu ibi tó o máa yà sí ṣáájú àkókò, á ṣeé ṣe fún ọ láti lè yẹra fún àwọn ìkóríta tó léwu, tó sì tún nira láti yà.

Kókó Pàtàkì Kan Tó Yẹ Kó O Ronú Lé Lórí

Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe ń wakọ̀ dáradára sí? Bóyá o lè ní kí ọ̀rẹ́ rẹ pàtàkì kan tàbí ará ilé rẹ kan wọnú mọ́tò pẹ̀lú rẹ kó bàa lè díwọ̀n bó o ṣe jáfáfá sí nígbà tó o bá ń wakọ̀. Lẹ́yìn náà, fara balẹ̀ tẹ́tí sí àkíyèsí èyíkéyìí tó bá ṣe. O tún lè pinnu pé wàá lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí béèyàn ṣe lè wakọ̀ láìséwu. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ ló máa ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n dìídì ṣe fún àwọn àgbà awakọ̀. Bó bá ti ń pé ìgbà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó o ti ń bá ara rẹ nínú ipò eléwu, tó jẹ́ pé díẹ̀ ṣíún ló kù kó o ti kú tàbí kó o ti fara pa, ìyẹn lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ pé òye tó o ní nídìí ọkọ̀ wíwà kò fi bẹ́ẹ̀ já gaara mọ́ bíi ti ìgbà àtijọ́.

Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo máa kúkú dáwọ́ ọkọ̀ wíwà dúró bó bá yá nítorí ire ara rẹ. Àtiṣe irú ìpinnu yìí lè ro ọ́ lára gan-an ni. Myrtle, tá a mẹ́nu kàn níṣàájú, ti mọ̀ pé kò ní pẹ́ tóun fi máa dáwọ́ ọkọ̀ wíwà dúró. Bó ṣe ń rí i pé àkókò yẹn ti ń sún mọ́lé, ó ti ń gbà kí àwọn ẹlòmíràn máa wa òun lọ́pọ̀ ìgbà báyìí. Báwo ni jíjẹ kí ẹlòmíràn máa wà á kiri ṣe rí lára rẹ̀? Ó sọ pé: “Wíwọkọ̀ láìsí pé mò ń wà á fúnra mi gbádùn mọ́ mi, torí pé mi ò ṣe wàhálà kankan.”

Ìwọ náà lè wò ó pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tó o bá ti ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí. Bíbá ọ̀rẹ́ kan wọkọ̀ láti lọ ra nǹkan lọ́jà, láti lọ ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan létí ilé, tàbí láti lọ sí ibi tó o ti báwọn èèyàn ní àdéhùn tàbí ibi ìpàdé kan lè gbádùn mọ́ ọ gan-an ju kó jẹ́ ìwọ nìkan lo dá wakọ̀ lọ. Bóyá ọ̀rẹ́ kan tiẹ̀ lè fi mọ́tò rẹ gbé ọ lọ síbi tó o fẹ́ lọ. Wíwọkọ̀ lọ́nà yìí lè túbọ̀ dáàbò bò ọ́, ó sì tún lè gbádùn mọ́ ọ ju kó jẹ́ ìwọ nìkan lò ń wakọ̀ fúnra rẹ lọ. Ohun mìíràn tó o lè ṣe ni pé kó o máa wọ ọkọ̀ èrò, níbi tí èyí bá wà. Rántí pé kì í ṣe béèyàn ṣe mọ ọkọ̀ wà sí ló ń pinnu bó ṣe jẹ́ ẹni pàtàkì sí. Àwọn ànímọ́ rere tó o ní ló ń jẹ́ kí àwọn ará ilé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọyì rẹ gidigidi, ìwọ̀nyí ló sì ń jẹ́ kó o ṣeyebíye lójú Ọlọ́run.—Òwe 12:2; Róòmù 14:18.

Bóyá o ti dàgbà àbí o jẹ́ ọ̀dọ́, bóyá o jẹ́ ọ̀jáfáfá awakọ̀ tàbí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, jàǹbá ọkọ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ọ. Máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ tó gba ìrònújinlẹ̀ ni ọkọ̀ wíwà jẹ́. Máa ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe láti dín ewu jàǹbá ọkọ̀ kù. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè dáàbò bo ara rẹ àtàwọn ẹlòmíràn nínú gbogbo ọ̀pọ̀ ìrìn-àjò tó o ṣì máa rìn lọ́jọ́ iwájú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Máa rí i dájú pé ò ń rọ “epo ọkọ̀” tí ó tó sí ara rẹ, ìyẹn ni nípa sísùn mọ́jú dáadáa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Oorun díẹ̀ téèyàn fi rẹjú lè mú kó pẹ́ díẹ̀ kó tó dé ibi tó ń lọ, àmọ́ èyí lè gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn àgbàlagbà awakọ̀ ló ní ìrírí jù, ṣùgbọ́n wọ́n ń dojú kọ àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú kéèyàn máa bá ẹlòmíràn wọkọ̀ pọ̀