Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ a Lè Rí Ọgbọ́n Dá Sí I?

Ǹjẹ́ a Lè Rí Ọgbọ́n Dá Sí I?

Ǹjẹ́ a Lè Rí Ọgbọ́n Dá Sí I?

KÍ LÓ yẹ kó o ṣe sí ohun kan tó ò nílò mọ́? Ó ṣeé ṣe kó o kàn dáhùn pé: “Ńṣe ni màá wábi sọ ọ́ sí.” Àmọ́ ṣá, pípalẹ̀ pàǹtírí mọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn bẹ́ẹ̀ yẹn. Ibo la tiẹ̀ máa dà á nù sí? Ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ ti àwọn onímọ̀ nípa àyíká nílẹ̀ Ítálì fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, yóò gbà tó ẹgbẹ̀rún ọdún kí ìgò kan tá a bá jù sínú òkun tó lè jẹrà. Ní ìfiwéra, oṣù mẹ́ta péré ni bébà anùdọ̀tí máa ń gbà kó tó jẹrà. Àmukù sìgá kan lè sọ òkun di ẹlẹ́gbin fún ọdún márùn-ún kó tó jẹrà; àwọn àpò ọ̀rá á gba ọdún mẹ́wàá sí ogún ọdún; àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n fi ọ̀rá ṣe á gba

ọgbọ̀n sí ogójì ọdún; agolo á gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún; fóòmù polystrene á sì gba ẹgbẹ̀rún ọdún.

Ńṣe ni irú àwọn pàǹtírí bẹ́ẹ̀ yẹn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá. Lóde òní, àìmọye nǹkan ló wà lọ́jà fún títà, ńṣe làwọn olùpolówó ọjà á sì máa rọ̀ wá láti rà wọ́n bí ẹni pé gbogbo ọjà ọ̀hún la nílò. Ìwé ìròyìn The Guardian ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ rárá o, ó ní: “Àwọn olùpolówó ọjà ló máa ń tì wá láti ra àwọn ohun tá ò ní lọ́kàn láti rà tẹ́lẹ̀.” Ká sòótọ́, ńṣe ni wọ́n ń tàn wá ká lè máa ra àwọn ọjà tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí àtẹ, wọ́n á ní ká tètè ra irú àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ kó tóó tán. Bákan náà, àwọn olùpolówó ọjà tún máa ń mú ká gbà pé, ohun èlò “tuntun dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì lágbára sí i,” àmọ́ pé ti “àtijọ́ kò lágbára, kò sì bágbà mu mọ́.”

Ìdí rèé tí wọ́n fi sábà máa ń rọ̀ wá láti ra nǹkan tuntun dípò tí a ó fi máa tún ògbólógbòó ṣe. Wọ́n sọ pé pípààrọ̀ ohun kan tó ti pẹ́ ló dára jù, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn ṣọ́ owó ná ju títún wọn ṣe lọ. Èyí lè jóòótọ́ láwọn ìgbà míì. Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà, gbígbé àwọn nǹkan tó ti pẹ́ sọ nù láti fi tuntun rọ́pò rẹ̀ máa ń náni lówó gọbọi, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan.

Ọ̀pọ̀ ohun èlò tá à ń rà lónìí ni wọ́n ṣe ní àlògbésọnù. Irú àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ máa ń ṣòroó tún ṣe—ohun tó yẹ kéèyàn sì máa fi sọ́kàn nìyí tó bá fẹ́ ra nǹkan. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì kan tó wà fún ìpolówó ọjà sọ pé: “Àwọn ohun èlò tá à ń rà kì í lálòpẹ́ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Ohun kan tó ‘bóde mu’ lónìí lè máà ‘bóde mu’ mọ́ lọ́la, ni wọ́n á bá kó wọn dà sí ibi ìkódọ̀tísí. Nípa bẹ́ẹ̀, ojoojúmọ́ làwọn ohun èlò wọ̀nyí, tó jẹ́ èròjà pàtàkì tí àwọn ilé iṣẹ́ lè lò láti fi ṣe nǹkan mìíràn jáde máa ń di pàǹtírí tí kò wúlò mọ́!”

Ǹjẹ́ bí àwọn èèyàn ṣe ń ra nǹkan ṣáá láìdáwọ́dúró yìí ń ṣe àwọn fúnra wọn láǹfààní? Ní ti gidi, àwọn tó ń jàǹfààní ibẹ̀ làwọn oníṣòwò tí kò sí ohun méjì lọ́kàn wọn ju pé kí wọ́n pawó sápò ara wọn lọ. Ìwé ìròyìn ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kan nílẹ̀ Switzerland, tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Die Weltwoche sọ pé: “Kò sí àní-àní pé ọrọ̀ ajé á dẹnu kọlẹ̀ bó bá jẹ́ pé ńṣe ni gbogbo èèyàn ń lo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé wọn tàbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọ́n títí lọ gbére, tàbí kí wọ́n máa lò wọ́n fún ìlọ́po méjì àkókò tí wọ́n fi ń lò ó báyìí.” Àmọ́ kì í ṣe ìdẹnukọlẹ̀ ọrọ̀ ajé ló máa yanjú ìṣòro káwọn èèyàn máa lo nǹkan ní àlògbésọnù níwọ̀n bí èyí kì yóò ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti rówó ra ohun tí wọ́n nílò. Kí wá làwọn ohun tá a lè ṣe láti fi yanjú ọ̀rọ̀ àpọ̀jù pàǹtírí o?

Ká Sọ Ọ́ Nù Ni, Àbí Ká Tún Un Lò, Àbí Ká Kúkú Dín Ohun Tá À Ń Rà Kù?

Àwọn orílẹ̀-èdè kan tó ti gòkè àgbà máa ń gba ọ̀nà ẹ̀bùrú yanjú ìṣòro àpọ̀jù pàǹtírí yìí, ìyẹn ni nípa lílọ da àwọn ìdọ̀tí wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn kan fi hàn pé, “ní ibì kan tí wọ́n sábà máa ń da pàǹtírí sí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ tọ́ọ̀nù májèlé olóró ni wọ́n ṣàwárí pé ó ń jò látinú àwọn àgbá tó lé ní ẹgbàá mẹ́rin tí wọ́n ti dógùn-ún, tí wọ́n sì ti dípẹtà, èyí sì ń fa májèlé fún erùpẹ̀ àti omi abẹ́ ilẹ̀.” Pípalẹ̀ pàǹtírí mọ́ ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ yẹn kò lè yanjú ìṣòro ọ̀hún, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ìwà tó dára láti hù sáwọn ẹlòmíràn.

Tí a bá ní láti máa ṣàtúnlò àwọn ohun tá ò lò mọ́ dípò tá ó fi gbé wọn sọ nù ńkọ́? Dájúdájú, irú ètò ìṣàtúnlò bẹ́ẹ̀ á béèrè pé kí àwọn èèyàn máa ya àwọn pàǹtírí wọn sí ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kí wọ́n tó dà wọ́n nù. Wọ́n tiẹ̀ ti ṣòfin láwọn àdúgbò kan pé bẹ́ẹ̀ ni káwọn èèyàn máa ṣe. Àwọn òṣìṣẹ́ tó mọ̀ nípa ìṣàtúnlò lè sọ pé káwọn èèyàn máa ya pàǹtírí tí wọ́n fẹ́ dà nù sí onírúurú ìsọ̀rí. Bóyá kí pàǹtírí bébà wà lọ́nà kan, kí ti páálí sì wà lọ́nà mìíràn, kí pàǹtírí ti mẹ́táàlì wà lọ́tọ̀, ti ìgò lọ́tọ̀, kí ti àwọn èròjà tó ṣeé lò bí ajílẹ̀, irú bí òkú ẹran tàbí igi tó ti jẹrà náà sì wà lọ́tọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún lè ya ìgò sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ níbàámu pẹ̀lú àwọ̀ wọn.

Ó hàn gbangba pé, ṣíṣàtúnlò nǹkan ní àwọn àǹfààní tirẹ̀. Ìwé náà, 5000 Days to Save the Planet sọ pé, ṣíṣàtúnlò ohun èlò ayọ́ (aluminum) “máa ń dín ọ̀pọ̀ ohun àmúṣagbára kù,” ó sì lè “mú kí ìbàyíkájẹ́ tí wíwa ògidì ayọ́ (bauxite) jáde látinú ilẹ̀ máa ń fà dín kù.” Ìwé náà ṣàlàyé kúnnákúnná pé: “Láti lè pèsè iye bébà kan náà bíi tìgbà àkọ́kọ́, ṣíṣàtúnlò máa ń lo ìdajì ohun àmúṣagbára, àti ìdámẹ́wàá omi. . . . Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí mú jáde látinú pàǹtírí, ká tún wọn yí padà, ká sì tún máa lò wọ́n lákọ̀tun. . . . Kódà níbi táwọn ilé iṣẹ́ kò bá ti lè lo àwọn pàǹtírí wọn fúnra wọn, wọ́n lè tún wọn yí padà nígbà míì káwọn ẹlòmíràn bàa lè lò wọ́n . . . Ní orílẹ̀-èdè Netherlands, wọ́n ti ń lo ètò ìṣàtúnlò pàǹtírí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, wọ́n sì ti ń ṣàṣeyọrí nídìí rẹ̀.”

Dípò táwọn aláṣẹ mìíràn ì bá fi máa wá àwọn ọ̀nà oríṣiríṣi láti fi palẹ̀ àwọn pàǹtírí wọn mọ́, dídènà ìdọ̀tí ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ gbájú mọ́. Ìwé tá a mẹ́nu kàn lókè yìí kìlọ̀ pé “àfi ká yáa wá nǹkan ṣe ní kíákíá” bá ò bá fẹ́ kí ìran èèyàn “kàn máa fowó ṣòfò, . . . ńṣe ló yẹ kí wọ́n di àwùjọ tó ń ṣọ́ nǹkan lò, àwùjọ tó ń dín pàǹtírí kù, tó sì ń dín bí wọ́n ti ń ra nǹkan kù.”

Àmọ́ ṣá o, àwọn ẹni tí kò bá fẹ́ káwọn “kàn máa fowó ṣòfò,” gbọ́dọ̀ múra tán láti máa lo nǹkan tí wọ́n bá rà fún àkókò gígùn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kí wọ́n sì máa sọ ọ́ nù kìkì nígbà tí kò bá ṣeé tún ṣe mọ́. A lè fún àwọn ẹlòmíràn láwọn nǹkan tá ò bá fẹ́ mọ́ àmọ́ tó ṣì lè wúlò fún wọn. Àjọ German Öko-Institut, ìyẹn Àjọ Tó Ń Rí sí Àjọṣe Tó Wà Láàárín Àwọn Ohun Alààyè àti Àyíká Wọn, èyí tó wà nílùú Darmstadt, ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ṣírò rẹ̀ pé, ìwọ̀nba pàǹtírí ni agboolé kan tó bá ń fi ìlànà “Má-fi-ohun-tó-o-rà-ṣòfò” sílò á máa ní nígbà gbogbo, nítorí pé ìdọ̀tí tí wọ́n máa kó jọ á fi ìdá márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún dín sí èyí tí wọ́n máa ń sábà kó jọ láwọn agboolé mìíràn.

Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ọ̀pọ̀ agboolé á tẹ̀ lé irú ìlànà bẹ́ẹ̀? Kò dà bí ẹni pé èyí á ṣeé ṣe. Ìṣòro àpọ̀jù pàǹtírí tó ń dààmú aráyé wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan lára àwọn ìṣòro kíkàmàmà mìíràn ni. Nínú ayé tá à ń gbé lónìí, táwọn èèyàn ti máa ń gbé nǹkan sọ nù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ń dá àṣà kan tá a lè pè ní àṣà fífi nǹkan ṣòfò. Ẹ jẹ́ ká gbé ìṣarasíhùwà yẹn yẹ̀ wò—àti díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó lè yọrí sí.

Ewu Tó Wà Nínú Àṣà Fífi Nǹkan Ṣòfò

Àṣà yìí kò mọ sórí fífi ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ṣòfò. Ó tún lè sọ àwọn èèyàn di aláìmoore àti aláìnírònú, débi pé ńṣe ni wọ́n á kàn máa da ọ̀pọ̀ oúnjẹ tí wọn ò fọwọ́ kàn rárá nù, àtàwọn nǹkan mìíràn. Lemọ́lemọ́ ni àwọn tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, àtàwọn tó ń jẹ́ kí àwọn àṣà ìgbàlódé darí wọn láìnídìí, máa ń fẹ́ láti fi aṣọ tuntun, ohun ọ̀ṣọ́ ilé tuntun, àtàwọn ohun èlò mìíràn rọ́pò èyí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀.

Bó ti wù kó rí, àṣà ìfiṣòfò lè má mọ sórí àwọn ohun èlò nìkan. Ètò kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Jámánì, láti máa ṣàmúlò àwọn ohun èlò inú ilé táwọn èèyàn ti gbé sọ nù, ròyìn lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Ọ̀nà tá à ń gbà lo àwọn àga tá a kó sí pálọ̀, tí kì í tẹ́ wa lọ́rùn mọ́, tá a sì máa ń pa tì lẹ́yìn ọdún márùn-ún, torí ká bàa lè fi tuntun pààrọ̀ rẹ̀, la ti ń ṣàfarawé rẹ̀ nínú bá a ṣe ń hùwà sí àwọn ẹ̀dá èèyàn. Ìṣòro ibẹ̀ ni bó ṣe máa pẹ́ tó tí àwùjọ wa máa lè fàyè gba irú ìwà yìí.” Ìròyìn ọ̀hún ṣàlàyé pé: “Gbàrà tí ẹnì kan ò bá ti lè ṣiṣẹ́ dáadáa gẹ́gẹ́ bí a ti retí láwùjọ la máa ń fi ẹlòmíì rọ́pò onítọ̀hún. Ó ṣe tán, àìmọye òṣìṣẹ́ ló kún ìgboro!”

Nínú ìwé Earth in the Balance, èyí tí igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí, Al Gore kọ, ó béèrè ìbéèrè kan lórí ọ̀ràn yìí: “Bó bá jẹ́ pé ojú àlògbésọnù la fi ń wo àwọn ohun tá à ń lò báyìí, ṣé kì í ṣe pé a ti yí ojú tá a fi ń wo àwọn ọmọnìkejì wa padà bákan náà? . . . Ṣé a ti wá tipa báyìí di ẹni ti kò mọyì àwọn ẹlòmíràn mọ́ ni?”

Ó dà bí ẹni pé kò ní jẹ́ ohun tó ṣòro fún àwọn èèyàn tí kò mọyì àwọn ẹlòmíràn, tí kò sì bọ̀wọ̀ fún wọn láti pa àwọn ọ̀rẹ́ tàbí aláàbáṣègbéyàwó wọn tì kí wọ́n tilẹ̀ tún máa rò pé kò burú. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà Süddeutsche Zeitung, ṣe àlàyé kan lórí irú ìwà táwọn èèyàn ń hù yìí, ó ní: “Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún la máa ń ra aṣọ tuntun, ọdún mẹ́rin-mẹ́rin la máa ń ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun, ọdún mẹ́wàá-mẹ́wàá la sì máa ń ra àga ìjókòó tuntun sí pálọ̀ wa; ọdọọdún la máa ń wá àgbègbè tuntun tá a máa gbafẹ́ lọ; à ń pààrọ̀ ilé, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí iṣẹ́ ajé wa—bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló wá dé tá ò fi máa pààrọ̀ ọkọ wa tàbí aya wa?”

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sóhun táwọn èèyàn kan lóde òní ò ti múra tán láti gbé sọ nù gbàrà tí wọ́n bá ti rí i pé apá wọn ò ká a láti mójú tó o mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan ní Yúróòpù, àwọn olùwádìí fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ológbò tó tó ọ̀kẹ́ márùn-ún, àtàwọn ajá tó tó ọ̀kẹ́ mẹ́rin ó lé ẹgbàájọ làwọn olówó wọn pa tì ní ọdún 1999. Ẹnì kan níbẹ̀ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ bíbójútó àwọn ohun ọ̀sìn lọ́nà yíyẹ sọ pé àwọn aráàlú ẹlẹgbẹ́ òun “kì í ka níní ohun ọ̀sìn sí ojúṣe téèyàn máa ń ṣe fún ìgbà pípẹ́. Wọ́n á ra ọmọ ajá ní oṣù September, wọ́n á sì pa á tì [ní ọdún kan lẹ́yìn ìgbà yẹn nígbà tí wọ́n bá ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ] ní oṣù August.” Èyí tó burú jù lọ ni pé, àṣà ìfiṣòfò yìí ti nasẹ̀ dé fífi ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn ṣòfò pàápàá.

Ṣíṣàìfi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí máa ń rò pé ẹ̀mí àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan. Báwo lèyí ṣe rí bẹ́ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Yúróòpù kan sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé, ńṣe làwọn ọ̀dọ́ èèyàn túbọ̀ ń hára gàgà láti fẹ̀mí ara wọn wewu láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. A lè rí àpẹẹrẹ èyí nínú bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń hára gàgà láti kópa nínú àwọn eré ìdárayá tó léwu gan-an. Nítorí ìmóríyá ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, wọ́n múra tán láti sọ ìwàláàyè wọn nù! Ńṣe làwọn oníṣòwò tí owó ti fẹjú mọ́ máa ń yán hànhàn láti lo àǹfààní yìí láti páwo sápò ara wọn. Olóṣèlú ilẹ̀ Jámánì kan sọ pé, àwọn tó ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn eré ìdárayá tó léwu gan-an “sábà máa ń ka owó tí wọ́n máa rí sí ohun tó ṣe pàtàkì ju ìlera tàbí ẹ̀mí èèyàn lọ.”

Bó bá dọ̀ràn gbígbé àwọn ọmọ tá ò tí ì bí sọ nù ńkọ́? Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) fojú díwọ̀n rẹ̀ pé “kárí ayé, iye tó tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin ọmọ táwọn èèyàn ń lóyún rẹ̀ lọ́dọọdún ni kò sẹ́ni tó fẹ́ wọn rárá. Ìṣẹ́yún ni ohun kan ṣoṣo tí ọ̀pọ̀ obìnrin sì máa ń fi yanjú ọ̀ràn náà.” Kódà lẹ́yìn táwọn obìnrin bá bímọ tán pàápàá, àwọn ọmọ ọwọ́ ò tíì bọ́ lọ́wọ́ ewu. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil náà, O Estado de S. Paulo ṣe sọ “ńṣe làwọn ọmọ ọwọ́ tí wọ́n ń gbé sọ sójú títì túbọ̀ ń pọ̀ sí i.” Ṣé irú èyí ń ṣẹlẹ̀ ládùúgbò tìrẹ náà?

Lónìí, ibi gbogbo lágbàáyé la ti ń rí àmì pé ńṣe làwọn èèyàn ka ẹ̀mí ẹ̀dá èèyàn sí ohun tẹ́wúrẹ́ kan, tí kò ní láárí, ohun yẹpẹrẹ téèyàn kàn lè gbé sọ nù. A máa ń rí àpẹẹrẹ àṣà tó gbòde kan yìí nínú bí àwọn eré ìnàjú tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń wò ṣe kún fún ìwà ipá, tí “àwọn akọni inú eré” á máa ṣekú pa àìmọye “àwọn èèyàn tí wọ́n kà sí ẹni burúkú” nínú eré sinimá tàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n kan ṣoṣo. A máa ń rí i nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwà ipá tó gba gbogbo ayé kan, bí àwọn olè ṣe ń ṣekú pa àwọn èèyàn torí owó táṣẹ́rẹ́ kan—tàbí kí wọ́n kàn tiẹ̀ pa wọ́n dà nù ṣáá láìsí ìdí kankan. A sì tún máa ń rí i nígbà tá a bá ń gbọ́ àwọn ìròyìn tó ń múni gbọ̀n rìrì nípa báwọn apániláyà ṣe ń ṣọṣẹ́, báwọn ẹ̀yà oríṣiríṣi ṣe ń pa ara wọn, àti báwọn orílẹ̀-èdè àti ìsìn lónírúurú ṣe ń pa ara wọn nípakúpa. Gbogbo àwọn ìwà láabi wọ̀nyí ló sì ń gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn láìfi ojú àánú hàn rárá—táwọn èèyàn á máa fẹ̀mí ọmọnìkejì tó ṣeyebíye ṣòfò.

Ó lè máà ṣeé ṣe fún wa láti wá ibòmíì gbé ju inú ayé táwọn èèyàn ti ń yára gbé nǹkan sọ nù yìí, àmọ́ a lè yẹra fún àṣà fífi nǹkan ṣòfò. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á jíròrò ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro gbígbé nínú ayé alálòsọnù, bákan náà ló tún máa jíròrò àwọn ìṣarasíhùwà tí kò bójú mu tó máa ń bá àṣà yìí rìn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ní ọ̀pọ̀ àdúgbò, wọ́n ti ṣòfin pé káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé ètò ṣíṣàtúnlò

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé àwọn àṣà ìwọṣọ tó lòde, èyí tó máa ń yí padà ló máa ń sún ọ láti sọ àwọn aṣọ tó ṣì dára nù, kó o sì ra tuntun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ńṣe ló yẹ ká ṣìkẹ́ ọmọ tá ò tí ì bí, kì í ṣe pé ká máa yọ wọ́n sọ nù

[Credit Line]

Index Stock Photography Inc./BSIP Agency

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì gan-an ju ohun téèyàn kàn lè máa fi wewu lọ nítorí ìmóríyá lásán-làsàn