Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Ọ̀sìn Àtàtà Ni àbí Panipani Ẹhànnà?

Ohun Ọ̀sìn Àtàtà Ni àbí Panipani Ẹhànnà?

Ohun Ọ̀sìn Àtàtà Ni àbí Panipani Ẹhànnà?

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ POLAND

AJÁ rírorò kan bẹ̀rẹ̀ sí í bu ọkùnrin kan tó ń sáré ìmárale jẹ, ńṣe ni ẹ̀jẹ̀ sì dà lára rẹ̀ títí tó fi kú. Ọmọdébìnrin kan ní ajá gíga kan tó ní àwọ̀ dúdú, àmọ́ ajá ọ̀hún ló pa á. Ìṣojú àwọn òbí ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan ni ajá kan tó ń rìn gbéregbère ti ṣe ọmọ wọn ṣúkaṣùka. Díẹ̀ làwọn wọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ lára ọṣẹ́ táwọn oríṣi ẹ̀yà ajá kan nílẹ̀ Poland ń ṣe.

Láti dènà irú àwọn jàǹbá bẹ́ẹ̀, àwọn ìjọba ní àwọn àgbègbè kan kì í gbà kí àwọn èèyàn ní irú àwọn ẹ̀yà ajá kan pàtó àyàfi lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ní ìwé ẹ̀rí lọ́wọ́. Barbara Zaleska, tó jẹ́ mẹ́ńbà kan nínú Ẹgbẹ́ Tó Ń Ṣètọ́jú Ajá Nílẹ̀ Poland ṣàlàyé pé, orúkọ ẹni tó ni ajá ló yẹ kí wọ́n kọ sínú ìwé ẹ̀rí kì í ṣe orúkọ ajá náà “nítorí pé ohun tí ajá náà máa yà, bóyá ẹhànnà ni o tàbí pé á máa bá a lọ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ èèyàn, wà lọ́wọ́ ẹni tó ni ajá náà.”

Láwọn ìgbà mìíràn, ńṣe ni wọ́n máa ń dìídì dá àwọn ajá kan lẹ́kọ̀ọ́ láti di panipani. Lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n sọ pé àwọn tó ń dá ajá lẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń gbà ṣe èyí ni nípa lílù wọ́n àti nípa fífi ebi pa wọ́n. Kódà wọ́n tiẹ̀ tún máa ń jẹ́ kí wọ́n fi “gbígbẹ̀mí nǹkan dánra wò,” ìyẹn ní kíkọ́ ajá láti bá àwọn nǹkan kan tó dà bí èèyàn tàbí ẹranko jà kí wọ́n sì fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n á jẹ́ kí ajá náà bá àwọn ajá tí kò lágbára tó o jà, àwọn ajá tí wọ́n ti fẹ́ kó kú tẹ́lẹ̀. Tí wọ́n bá ti wá dá a lẹ́kọ̀ọ́ tán, ajá náà ṣe tán láti bá àwọn ajá mìíràn jà nìyẹn, èyí tó máa ń jẹ́ ìdùnnú àwọn atatẹ́tẹ́ àtàwọn olùwòran tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ.

Bíbélì sọ fún wa ní kedere, irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo híhu ìwà ìkà sí ẹranko. Ó sọ pé: “Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìkà ni àánú àwọn ẹni burúkú.” (Òwe 12:10) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ láti múnú Ọlọ́run dùn kì í hùwà ìkà bíburú jáì sí ẹranko. A lè láyọ̀ pé, nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àṣà ká máa dá àwọn ẹranko lẹ́kọ̀ọ́ láti di panipani, yálà fún eré ìdárayá tàbí fún ìdí èyíkéyìí mìíràn, kò ní í sí mọ́.—Sáàmù 37:9-11.