Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Ìjà Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́—Ṣé ó Dájú Pé Àwọn Ẹni Ibi Lè Lò ó?

Àwọn Ohun Ìjà Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́—Ṣé ó Dájú Pé Àwọn Ẹni Ibi Lè Lò ó?

Àwọn Ohun Ìjà Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́—Ṣé ó Dájú Pé Àwọn Ẹni Ibi Lè Lò ó?

ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń fi àrùn ṣekú pa àwọn ọ̀tá lásìkò ogun. Ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, ní ìlà oòrùn Yúróòpù, àwọn ológun kan ju òkú àwọn tí àrùn plague pa gba orí odi ìlú kan tí wọ́n sàga tì, láti kó àrùn ọ̀hún ran àwọn olùgbé ìlú náà. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ní irínwó ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mọ̀ọ́mọ̀ fún àwọn Àmẹ́ríńdíà ní àwọn bùláńkẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ti fi kòkòrò àrùn ìgbóná sínú rẹ̀ níbi àpérò kan tí wọ́n ṣe láti pẹ̀tù sí aáwọ̀, nígbà Ogun Tó Wáyé Láàárín Àwọn Faransé Àtàwọn Íńdíà. Ìyẹn jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn kan gbèèràn, èyí tó mú kí àwọn Àmẹ́ríńdíà túúbá. Àmọ́ ṣá o, òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé àwọn kòkòrò àrùn ló ń ṣokùnfà àwọn àrùn tí ń gbèèràn. Òye táwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ní yìí ló jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí hùmọ̀ àwọn ọ̀nà tuntun àtàwọn ọgbọ́n aṣeni-ní-jàǹbá lónírúurú, tí wọ́n lè fi lo àrùn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà.

Kà sòótọ́, ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló mú káwọn oògùn àti abẹ́rẹ́ àjẹsára nítorí àrùn ṣeé ṣe. Ìwọ̀nyí ti ṣèrànwọ́ tó gadabú nínú wíwo àrùn sàn àti dídènà rẹ̀. Síbẹ̀, láìka gbogbo ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí sí, àwọn àrùn tí ń gbèèràn ṣì jẹ́ ọ̀tá tí kò ṣeé ṣẹ́gun, nítorí àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣekú pa lọ́dọọdún lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún—ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lójoojúmọ́. Ó bani nínú jẹ́ pé: Níbi táwọn ọkùnrin àtobìnrin tí orí wọn pé ti ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn wá bí àrùn ò ṣe ní gbé mùtúmùwà dè, ibẹ̀ làwọn kan wà tó jẹ́ pé orí tiwọn náà pé wọ́n sì ń fìtara ṣiṣẹ́, àmọ́ bí wọ́n ṣe máa fi àrùn ṣe ọmọ ẹ̀dá lọ́ṣẹ́ ni wọ́n ń fojoojúmọ́ ayé bá kiri.

Akitiyan Láti Fòfin De Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn

Fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́, àtàwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan fi ń fi tọ̀sántòru gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn. Ṣùgbọ́n lọ́dún 1972, àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé fohùn ṣọ̀kan láti fòfin de àwọn ohun ìjà wọ̀nyí. Àmọ́ ṣá o, àwọn orílẹ̀-èdè kan ṣì ń mú àwọn èròjà kòkòrò àrùn aṣekúpani jáde, tí wọ́n sì ń bá ìwádìí lọ lórí wọn ní bòókẹ́lẹ́. Wọ́n ń to àwọn èròjà kòkòrò àrùn aṣekúpani wọ̀nyí jọ pelemọ, tí wọ́n sì ń hùmọ̀ oríṣiríṣi iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n lè fi lò wọ́n.

Kí ló mú káwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé pinnu láti fòfin de àwọn ohun ìjà wọ̀nyí? Ibi tí òye wọn mọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970 sí 1979 ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èròjà kòkòrò àrùn léwu gan-an, síbẹ̀, wọn kò lè fi bẹ́ẹ̀ wúlò lójú ogun. Ohun kan tó mú kí wọ́n ronú lọ́nà yìí ni pé, àbájáde wọn kì í ṣe ojú ẹsẹ̀—ó máa ń gba àkókò kí àmì àrùn wọn tó fara hàn. Ìdí mìíràn tí wọ́n fi fòfin dè é ni pé, bí atẹ́gùn bá ṣe ń fẹ́ sí i àti bí ipò ojú ọjọ́ bá ṣe nípa lórí rẹ̀ sí ló máa ń pinnu bóyá wọ́n á lágbára láti ṣọṣẹ́. Síwájú sí i, àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ronú pé bí orílẹ̀-èdè kan bá lo ohun ìjà oníkòkòrò àrùn láti fi gbógun ti òmíràn, orílẹ̀-èdè tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí náà á fẹ́ láti gbẹ̀san nípa fífi ohun ìjà oníkòkòrò àrùn ránṣẹ́ padà tìrìgàngàn tàbí kó lo àwọn ohun ìjà runlérùnnà tirẹ̀. Níkẹyìn, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìwà wèrè gbáà ló jẹ́ láti máa mọ̀ọ́mọ̀ lo àwọn èròjà kòkòrò àrùn láti fi sọ ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ ẹni di aláàbọ̀ ara tàbí láti fi ṣekú pa á.

Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìdí wọ̀nyí tó jọ pé yóò ṣèdíwọ́ fún àwọn èèyàn tí ìkórìíra ń ru gùdù nínú wọn, tí wọ́n sì ti múra tán láti ṣe ohun tí a kò retí pé kí ọmọlúwàbí ṣe. Àwọn ẹni ibi tó ti pinnu láti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn láìbìkítà ti rí i pé ohun ìjà oníkòkòrò àrùn wúlò gan-an láti fi ṣọṣẹ́. Wọ́n lè ṣe àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn ní bòókẹ́lẹ́, kí wọ́n sì fi wọ́n ránṣẹ́ síbi tí wọ́n á ti ṣe àwọn èèyàn ní jàǹbá. Ó lè máà ṣeé ṣe láti mọ ẹni tó fi ohun ìjà ọ̀hún ránṣẹ́, bí wọ́n bá tiẹ̀ mọ̀ ọ́n, kò rọrùn láti gbẹ̀san lára àjọ ìpàǹpá àwọn apániláyà kan tó ní ọmọ ẹgbẹ́ káàkiri orílẹ̀-èdè tó pọ̀. Kò tán síbẹ̀ o, lílo ohun ìjà oníkòkòrò àrùn tó jẹ́ ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́, tí kò ṣeé fojú rí, tó sì jẹ́ aṣekúpani ti tó láti kó ìpayà àti ṣìbáṣìbo bá àwọn aráàlú. Fífi kòkòrò àrùn kọ lu irè oko tàbí ẹran ọ̀sìn lè fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ àti ìwólulẹ̀ ọrọ̀ ajé.

Ohun mìíràn tó tún lè mú kí lílo àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn yá àwọn ẹni ibi lára ni pé owó pọ́ọ́kú ni wọ́n fi ń ṣe é. Àwọn olùṣèwádìí ṣe ìfiwéra iye tí onírúurú ohun ìjà lè náni láti pa àwọn aráàlú tí kò lè gbèjà ara wọn, ní àgbègbè kan tó fẹ̀ ní kìlómítà kan níbùú lóròó. Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ohun ìjà alábọ́ọ́dé á náni ní ẹgbẹ̀rún méjì dọ́là, àwọn ohun ìjà runlérùnnà á náni ní ẹgbẹ̀rin dọ́là, àwọn ohun ìjà tó jẹ́ gáàsì aséniléèémí á náni ní ẹgbẹ̀ta dọ́là, àmọ́ àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn kò lè náni ju dọ́là kan péré lọ.

Onírúurú Ọgbọ́n Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Tó Lè Ṣèdíwọ́ fún Àwọn Apániláyà

Onírúurú ìròyìn tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ apániláyà kan ti ń ṣèwádìí lórí àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn. Síbẹ̀ ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín ṣíṣèwádìí lórí àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn àti fífi wọ́n ṣọṣẹ́.

Kí apániláyà kan tàbí ẹgbẹ́ àwọn apániláyà tó lè ṣe iṣẹ́ ibi wọn yọrí, àwọn ìpèníjà kan wà tí wọ́n ní láti kojú nídìí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, apániláyà ọ̀hún ní láti wá èròjà kòkòrò àrùn aṣekúpani tó máa pọ̀ tó láti lò fún iṣẹ́ ibi rẹ̀. Èkejì, ó gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe máa bójú tó kòkòrò àrùn náà lọ́nà yíyẹ àti bó ṣe máa tọ́jú rẹ̀ láìséwu. Ẹ̀kẹta, ó gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe lè mú un jáde ní ọ̀pọ̀ yanturu. Ká ní wọ́n fi kòkòrò àrùn díẹ̀ kín-ún ránṣẹ́ síbi kan, tó sì dé ọ̀gangan ibi tó yẹ kó lọ ní tààràtà, ìwọ̀nba rẹ̀ yìí léwu gan-an débi pé ó lè ba oko ọ̀gbìn jẹ́ ráúráú, ó lè pa agbo ẹran run ráúráú, ó sì lè pa gbogbo àwọn aráàlú kan run pátápátá. Bó ti wù kó rí, àwọn èròjà kòkòrò àrùn kì í fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mú wọn kúrò níbi ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kìkì ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn èròjà kòkòrò àrùn ọ̀hún ló máa dé ibi tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí, látàrí èyí, wọ́n ní láti ṣe èyí tó pọ̀ gan-an tí wọ́n bá fẹ́ kí àjálù tó bùáyà gan-an wáyé.

Àwọn ohun mìíràn tún wà tó tún lè dá wọn lọ́wọ́ kọ́. Apániláyà náà gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe máa ṣe é tí kòkòrò àrùn náà á ṣì lágbára, tí èròjà aṣenilọ́ṣẹ́ inú rẹ̀ kò fi ní kú ní gbogbo ìgbà tó bá ń gbé e kúrò láti ibi tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ sí lọ síbi tó ti máa fi ṣọṣẹ́. Níkẹyìn, ó tún gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe máa fọ́n kòkòrò àrùn náà káàkiri lọ́nà gbígbéṣẹ́. Èyí ń béèrè pé kó rí i dájú pé kòkòrò àrùn náà dé ọ̀gangan ibi tó yẹ kó lọ àti pé kò tóbi ju bó ṣe yẹ kí ó rí lọ, pé yóò tó láti lò fún àgbègbè kan, àti pé àpòpọ̀ èròjà rẹ̀ lágbára tó láti kéèràn ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà. Nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ó gba àwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan tí wọ́n jẹ́ ògbógi nínú fífi kòkòrò àrùn ṣe ohun ìjà, ní ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá láti hùmọ̀ ètò kan tó ṣe é gbára lé, láti fi kòkòrò àrùn ránṣẹ́ síbi tí wọ́n ti fẹ́ fi ṣọṣẹ́. Gbàrà tí wọ́n bá ti tú èròjà kòkòrò àrùn kan sínú afẹ́fẹ́ ni oòrùn àti bí ojú ọjọ́ ṣe gbóná sí tàbí tutù sí á ti máa nípa lórí rẹ̀, èyí sì lè mú kí kòkòrò àrùn ọ̀hún kú. Látàrí èyí, fífi àwọn èròjà ohun alààyè tíntìntín ṣe ohun ìjà oníkòkòrò àrùn ń béèrè fún mímọ gbogbo àpadé-àludé tó jẹ mọ́ ipa tí afẹ́fẹ́ ń kó lórí àwọn ohun alààyè tíntìntín.

Tá a bá gbé onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ tó lè ṣèdíwọ́ fún àwọn apániláyà yìí yẹ̀ wò, kò yani lẹ́nu pé ọṣẹ́ tí wọ́n ti fi kòkòrò àrùn ṣe kò tó nǹkan. Láfikún sí i, àwọn èèyàn díẹ̀ ló kú nínú irú àwọn jàǹbá wọ̀nyẹn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èèyàn márùn-ún ni àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi kòkòrò àrùn anthrax sínú wọn ṣekú pa nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Èyí bani nínú jẹ́, àmọ́ iye àwọn tó ṣòfò ẹ̀mí ì bá pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ ká ní ohun abúgbàù kékeré kan tàbí ìbọn ìléwọ́ kan ni wọ́n lò. Àwọn olùṣèwádìí ṣírò rẹ̀ pé láti ọdún 1975, nínú ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọṣẹ́ tí wọ́n fi ohun ìjà oníkẹ́míkà tàbí ti oníkòkòrò àrùn ṣe káàkiri àgbáyé, àwọn èèyàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣekú pa tàbí tó ṣèpalára fún kò ju mẹ́ta lọ.

Níwọ̀n bí Àjọ Tó Ń Rí sí Ìsọfúnni Lórí Ọ̀ràn Ààbò fún Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti mọ onírúurú ìṣòro tó wà nínú lílo kòkòrò àrùn láti fi ṣe jàǹbá, wọ́n sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìjọba dojú kọ àìlóǹkà ewu látọ̀dọ̀ àwọn apániláyà tí wọ́n ń halẹ̀ láti lo ohun ìjà oníkẹ́míkà tàbí oníkòkòrò àrùn, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀ràn ló gbà gbọ́ pé àwọn àjálù tó lè ṣekú pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ṣeé ṣe lóòótọ́, àmọ́ kò dájú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè wáyé.” Ṣùgbọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ dájú pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè wáyé, àwọn ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ á burú jáì tó bá lọ rí bẹ́ẹ̀.

Ìròyìn Búburú

Títí débi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, gbogbo ohun tá a ṣì sọ ló fini lọ́kàn balẹ̀: Ìyẹn ni pé, àwọn ìṣòro ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá nínú ìtàn fi hàn pé kò dájú pé àwọn ẹni ibi á lè fi kòkòrò àrùn ṣọṣẹ́. Àmọ́, ní kúkúrú, ìròyìn búburú ibẹ̀ ni pé: Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá nínú ìtàn kò lè fún wa ní ìtọ́sọ́nà pípéye nípa bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lílo àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn ti já sí òtúbáńtẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà sẹ́yìn, síbẹ̀, wọ́n lè lọ kẹ́sẹ járí lọ́jọ́ iwájú.

Ọ̀ràn ọ̀hún ń kọni lóminú. Ó jọ pé àwọn apániláyà tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ti múra tán láti ṣekú pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn. Kì í ṣe pé àwọn apániláyà ń tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lọ́nà tó kàmàmà nìkan ni, àmọ́ àwọn ẹgbẹ́ apániláyà kan ní òbítíbitì owó lọ́wọ́ láti lò, wọ́n sì tún mọ ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ oríṣiríṣi tí wọ́n lè lò ní ìfiwéra pẹ̀lú èyí tí àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan ní.

Ó dà bíi pé àwọn ògbógi kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn nípa bóyá àwọn orílẹ̀-èdè kan lè kó àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn fún àwọn ẹgbẹ́ apániláyà láti lò. Ọ̀mọ̀ràn kan sọ pé: “Kò sí bí ìjọba orílẹ̀-èdè kan ṣe lè ya òǹrorò tó, tàbí kó máa lépa àṣeyọrí lójú méjèèjì tó, tàbí kó ya abẹ́gbẹ́yodì tó, tí yóò wá kó àwọn ohun ìjà tó léwu gan-an fún àwọn ẹgbẹ́ apániláyà tí wọn kò lè ṣàkóso wọn; àwọn ìjọba lè gbìyànjú láti kọ́kọ́ lo irú àwọn ohun ìjà bẹ́ẹ̀ láti fi gbéjà ko orílẹ̀-èdè mìíràn, ṣùgbọ́n àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa fi wọ́n halẹ̀ lásán dípò tí wọ́n á fi fi wọ́n jagun.” Ohun tó ń kọ àwọn ògbógi lóminú ni pé àwọn ògbóǹkangí kan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè lọ lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ apániláyà láti máa bá wọn ṣiṣẹ́, táwọn yẹn bá fi owó gegere fà wọ́n mọ́ra.

Ṣíṣẹ̀dá Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn

Ohun mìíràn tó tún ń fa ìpayà ni onírúurú ìtẹ̀síwájú tó ń wáyé nínú lílo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ láti fi mú ohun alààyè jáde lọ́pọ̀ yanturu. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ gbogbo àpadé-àludé yíyí àwọn èròjà kòkòrò àrùn tó wà báyìí padà kí wọ́n lè di olóró gan-an, láìjẹ́ pé wọ́n á ṣèpalára fún àwọn tó máa fi wọ́n ṣọṣẹ́. Wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè yí àwọn ohun tó pilẹ̀ àbùdá àwọn kòkòrò àrùn tíntìntín tí kò lè pani lára dà lọ́nà tí wọ́n á fi ní májèlé. Wọ́n tún lè ṣe àyípadà sí àwọn ohun alààyè tíntìntín lọ́nà tí àwọn ẹ̀rọ tó ń tú ohun ọṣẹ́ fó kò fi ní lè tú wọn fó. Síwájú sí i, wọ́n lè dọ́gbọ́n sí àwọn kòkòrò àrùn lọ́nà tí àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn, àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára gbogbo-ǹ-ṣe, àtàwọn egbòogi ajẹ́bíidán ò fi ní lè ràn wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó yapa kúrò nílẹ̀ Soviet Union àtijọ́ sọ pé àwọ́n ti mú oríṣi kòkòrò àrùn plague kan jáde, èyí tí oògùn agbógunti kòkòrò àrùn mẹ́rìndínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kò lè ràn rárá.

Àwọn ògbógi retí pé ìtẹ̀síwájú ọjọ́ iwájú nínú lílo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ láti fi mú ohun alààyè jáde lọ́pọ̀ yanturu, àti ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ nípa yíyí àwọn ohun tó pilẹ̀ àbùdá padà, lè túbọ̀ fún àwọn ẹni ibi níṣìírí láti lo àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣe àwọn àyípadà kan nínú àwọn ohun tó pilẹ̀ àbùdá láti ṣàtúnṣe sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn tàbí kí wọ́n ṣe wọ́n lákọ̀tun kí wọ́n bàa túbọ̀ léwu sí i, kí wọ́n rọ́kú sí i, kó sì lè rọrùn láti mú wọn jáde àti láti fi wọ́n ṣọṣẹ́ láìsí pé wọ́n ń tàsé ibi tí wọ́n rán wọn lọ. Wọ́n lè ṣe wọ́n lọ́nà tó fi máa rọrùn fún wọn láti mọ bí wọ́n á ṣe ṣọṣẹ́ tó àti bí wọ́n á ṣe lè darí wọn. Wọ́n lè ṣe irú àwọn èròjà kòkòrò àrùn kan tó jẹ́ pé lẹ́yìn tó bá ti pín ara rẹ̀ sí àìmọye sẹ́ẹ̀lì kéékèèké ló máa tó di aláìlágbára—ìyẹn ni pé ẹyin tí wọ́n bá ti ṣeni lọ́ṣẹ́ tán ni wọn máa tó pòórá.

Wọ́n sì tún lè mú àwọn àràmérìíyìírí ohun ìjà ayọ́kẹ́lẹ́-ṣọṣẹ́ jáde lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àkànṣe ohun ìjà olóró kan wà tó lè sọ agbára ìdènà àrùn ara di aláìlágbára—ìyẹn ni pé, dípò tí wọn ì bá fi fi àrùn kan ṣoṣo kanni, ara ẹni tó bá kàgbákò rẹ̀ kò ní í lè dènà àrùn kankan mọ́. Bí irú àwọn kòkòrò àrùn aṣekúpani bíi ti àrùn AIDS wọ̀nyí bá lọ di ohun tó tàn kálẹ̀, ta ló máa mọ̀ bóyá àyípadà nínú apilẹ̀ àbùdá tó ṣàdédé wáyé nínú ara ló ṣokùnfà rẹ̀, tàbí pé àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan ló ṣe àyípadà ọ̀hún látinú ibi ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ kan?

Ìtẹ̀síwájú lónírúurú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti yí ojú ìwòye àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ológun padà. Ọ̀gágun kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé: “Àwọn tó ń ṣe ohun ìjà jáde ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwárí ọ̀nà tí wọ́n fi lè lo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè láti fi ṣe jàǹbá ni o. Ọ̀ràn tó gbàrònú gan-an lèyí jẹ́ o, torí pé ìtẹ̀síwájú tí wọ́n máa ní lọ́jọ́ iwájú máa pọ̀ gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú èyí tí wọ́n ti ní sẹ́yìn.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Kí Ló Ń Jẹ́ Fífi Kòkòrò Àrùn Jagun?

Ọ̀rọ̀ náà “fífi kòkòrò àrùn jagun” túmọ̀ sí mímọ̀ọ́mọ̀ tan àrùn kálẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀dá èèyàn, ẹranko, tàbí ewéko. Àrùn á kọ lu èyíkéyìí lára wọn nígbà tí àwọn kòkòrò àrùn bá kéèràn ràn wọ́n. Àwọn ohun alààyè tíntìntín wọ̀nyí á wá máa gbèrú sí i (tí àwọn kan lára wọn á tiẹ̀ máa mú májèlé jáde), bí àkókò ti ń lọ, àwọn àmì àrùn náà á wá fara hàn kedere. Àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn kan lè sọ èèyàn di aláàbọ̀ ara, àwọn mìíràn sì lè pa èèyàn kú fin-ín fin-ín. Síbẹ̀, wọ́n lè lo àwọn mìíràn láti fi ba irè oko jẹ́.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ìsọfúnni Nípa Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn

Àrùn Anthrax: Àrùn yìí máa ń ràn, kòkòrò bakitéríà kan tó ń mú èròjà spore jáde ló sì máa ń ṣokùnfà rẹ̀. Lára àwọn àmì téèyàn á rí tó bá fa kòkòrò àrùn anthrax ságbárí lè fara jọ ti ọ̀fìnkìn. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó máa ṣòro gan-an fún onítọ̀hún láti mí, àwọn kòkòrò àrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣàn dáadáa. Irú àrùn anthrax báyìí sábà máa ń ṣekú pani.

Àwọn tí kòkòrò àrùn anthrax bá kọlù lè lo àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn kó má bàa gbèèràn. Títọ́jú rẹ̀ ní kíá mọ́sá ṣe kókó; fífi jáfara lè yọrí sí ikú.

Kì í sábà ṣẹlẹ̀ pé kí ẹnì kan kó o látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn nípa ìfarakanra, èyí tiẹ̀ lè máà wáyé rárá.

Ní apá ìparí ọ̀rúndún ogún, àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan bẹ̀rẹ̀ sí lo kòkòrò àrùn anthrax gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà oníkòkòrò àrùn, lára wọn sì ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́. Iye àwọn orílẹ̀-èdè táwọn olùṣèwádìí ronú pé, àfàìmọ̀ ni wọn kò fi ń ṣètò láti mú àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn jáde ti ròkè látorí mẹ́wàá lọ́dún 1989 sí mẹ́tàdínlógún lọ́dún 1995. Kò sẹ́ni tó lè sọ ni pàtó bí iye tó ń lo kòkòrò àrùn anthrax lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ti pọ̀ tó. Níbàámu pẹ̀lú àyẹ̀wò kan tí ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe, títú kòkòrò àrùn anthrax tí ó tó ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún kìlógíráàmù sórí ìlú ńlá kan lè léwu gan-an, kò yàtọ̀ sígbà tí bọ́ǹbù eléròjà hydrogen bá bú.

Àrùn Botulin: Àrùn yìí máa ń sọ iṣu ẹran ara di ahẹrẹpẹ, ohun tó sì máa ń ṣokùnfà rẹ̀ ni kòkòrò bakitéríà kan tó máa ń mú májèlé jáde. Lára àwọn àmì àrùn yìí, èyí téèyàn lè kó nínú oúnjẹ ni kí ojú ẹni máa rí nǹkan kan ṣoṣo lọ́nà méjì tàbí kéèyàn máa ríran bàìbàì, kí ìpéǹpéjú ẹni rọ wálẹ̀ jọbọlọ, kí ọ̀rọ̀ máa fà lẹ́nu ẹni, kéèyàn máa gbé oúnjẹ mì pẹ̀lú ìnira, àti kí ẹnu èèyàn máa gbẹ fúrúfúrú. Àwọn iṣu ẹran ara á bẹ̀rẹ̀ sí di ahẹrẹpẹ láti èjìká wálẹ̀. Bí àwọn iṣu ẹran ara tó ń jẹ́ kí mímí èémí ṣeé ṣe bá sì ti rọ jọwọrọ, àfàìmọ̀ kí onítọ̀hún máà gbẹ́mìí mì. Àrùn botulin kì í ràn.

Bí wọ́n bá tètè lo aporó tó ń pa májèlé kó tó pẹ́ jù, èyí á dín bí àwọn àmì àrùn náà ṣe lágbára kù, ó sì lè dènà ikú tí ì bá pa onítọ̀hún.

Májèlé botulinum, èyí tí àrùn botulin máa ń ṣokùnfà rẹ̀, jẹ́ èròjà kan tí wọ́n máa ń lò jù gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà oníkòkòrò àrùn, kì í ṣe torí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èròjà tó lóró jù lọ nìkan ni, àmọ́ torí pé ó rọrùn gan-an láti mú jáde àti láti gbé kiri. Bákan náà, àwọn tó bá ràn gbọ́dọ̀ máa gba ìtọ́jú àkànṣe fún àkókò pípẹ́. Àwọn olùṣèwádìí ronú pé àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ti ń mú májèlé botulinum jáde gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà oníkòkòrò àrùn.

Àrùn Plague: Àrùn yìí máa ń ràn gan-an, kòkòrò bakitéríà kan ló sì máa ń ṣokùnfà rẹ̀. Àwọn àmì tó máa ń kọ́kọ́ fara hàn lára ẹni tó bá kó àrùn plague aṣekúpani, tó máa ń fi òtútù àyà ṣeni ni ibà, ẹ̀fọ́rí, àárẹ̀ ara, àti ikọ́. Ohun tó máa tẹ̀ lé e ni pé àwọn kòkòrò àrùn á máa ṣèdíwọ́ fún ẹ̀jẹ̀ onítọ̀hún láti má ṣàn dáadáa. Bí ẹni tó kọlù kò bá tètè tọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ikú ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀.

Itọ́ tó bá ta síni lára látọ̀dọ̀ aláìsàn náà ló máa ń jẹ́ kí àrùn náà tàn látọ̀dọ̀ ẹnì kan sí ẹlòmíràn.

Ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, láàárín ọdún márùn-ún péré, àrùn plague ṣekú pa àwọn èèyàn tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́tàlá ní Ṣáínà àti nǹkan bí ogún sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn ní Yúróòpù.

Láàárín àwọn ọdún 1950 sí 1960, ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ jágbọ́n ọ̀nà láti tan àrùn plague tó ń fi òtútù àyà ṣeni kálẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì làwọn olùṣèwádìí gbà gbọ́ pé wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lórí lílo kòkòrò bakitéríà tó ń fa plague láti fi ṣe ohun ìjà oníkòkòrò àrùn.

Àrùn Ìgbóná: Àrùn yìí máa ń ràn gan-an, kòkòrò fáírọ́ọ̀sì kan ló sì máa ń ṣokùnfà rẹ̀. Lára àwọn àmì tó máa kọ́kọ́ fara hàn ni akọ ibà, àárẹ̀, ẹ̀fọ́rí, àti ẹ̀yìn ríro. Lẹ́yìn náà, àwọn ọgbẹ́ tó ní ọyún nínú, tó ń roni gan-an á wá máa fara hàn káàkiri awọ ara. Ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn tí àrùn ìgbóná bá kọ lù ló máa ń kú.

Wọ́n ṣẹ́gun àrùn ìgbóná jákèjádò ayé lọ́dún 1977. Fífún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára látìgbàdégbà láti dènà àrùn ìgbóná dópin láàárín ọdún 1975 sí 1976. Kò dá ẹnikẹ́ni lójú bóyá ó ṣeé ṣe kí àwọn tó gba abẹ́rẹ́ àjẹsára ọ̀hún ṣáájú ìgbà náà tún kó àrùn náà. Kò sí oògùn ajẹ́bíidán kankan tí ẹ̀rí wà pé ó lè wo ìgbóná.

Àrùn náà máa ń ràn látọ̀dọ̀ ẹnì kan sí ẹlòmíràn tí itọ́ aláìsàn náà bá ta síni lára. Fífara kan aṣọ alárùn náà tàbí aṣọ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ tún lè tan àrùn náà kálẹ̀.

Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1980, ilẹ̀ Soviet Union ti dáwọ́ lé ètò kan tó kẹ́sẹ járí, wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ kòkòrò àrùn ìgbóná jáde, wọ́n sì ṣe é pé kí àwọn bọ́ǹbù olóró atamátàsé tó ń lọ jìnnà máa fọ́n ọn káàkiri. Wọ́n tún ti ṣakitiyan láti mú onírúurú kòkòrò àrùn ìgbóná tó lóró gan-an tó sì ń yára gbèèràn jáde.

[Àwòrán]

Kòkòrò àrùn “anthrax” àti èròjà “spore” tó rí rógódó

[Àwọn Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Ibùdó Tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àti Ibùdó Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Tó Jẹ Mọ́ Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn ní Yunifásítì John Hopkins.

Ẹni tí kòkòrò àrùn anthrax kéèràn ràn: CDC, Atlanta, Ga.; kòkòrò àrùn anthrax: ©Dr. Gary Gaugler, Photo Researchers; kòkòrò tó ń fa àrùn botulin: CDC/Courtesy of Larry Stauffer, Oregon State Public Health Laboratory

Kòkòrò àrùn plague: Copyright Dennis Kunkel Microscopy, Inc.; kòkòrò àrùn ìgbóná: ©Meckes, Gelderblom, Eye of Science, Photo Researchers; Ẹni tí kòkòrò àrùn ìgbóná kéèràn ràn: CDC/NIP/Barbara Rice

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi kòkòrò àrùn “anthrax” sínú wọn ṣẹ̀rù ba tọmọdé tàgbà

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Axel Seidemann

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn bọ́ǹbù oníkẹ́míkà àti bọ́ǹbù oníkòkòrò àrùn tí wọ́n máa ń jù látojú òfuurufú, èyí tí wọ́n pa run lẹ́yìn Ogun Gulf

[Credit Line]

Fọ́tò AP/MOD