Ìṣòro Tí Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Ń Kojú Kò Níye
Ìṣòro Tí Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Ń Kojú Kò Níye
“Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tí mo máa ń ní kò ṣeé fẹnu sọ. Ọ̀pọ̀ alẹ́ ni mo fi máa ń wà nínú ilé ìwẹ̀ tí màá máa sunkún. Ìnira ọ̀hún pọ̀.”—JANET, ÌYÁ KAN TÓ Ń DÁ TỌ́ ỌMỌ MẸ́TA.
ÀWỌN ohun tó ń sọ òbí kan di ẹni tó ń dá nìkan tọ́mọ pọ̀. Ogun, àjálù, tàbí àìsàn ló máa ń sọ ẹrù ẹni méjì di ti ẹnì kan nínú àwọn ìdílé kan.
Ńṣe làwọn òbí àwọn ọmọ kan sì kọ̀ láti fẹ́ra wọn. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Sweden, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì gbogbo ọmọ tí wọ́n ń bí níbẹ̀ làwọn òbí wọn ò ṣègbéyàwó. Ìkọ̀sílẹ̀ tún wà lára ohun tó máa ń sọ ìdílé di olóbìí kan. Ìwádìí fi hàn pé, ó ju ìdajì lọ lára àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó máa gbé inú ilé olóbìí kan fún àkókò díẹ̀ nígbà ọmọdé wọn.
Lílóye Àwọn Ìṣòro Náà
Àwọn ìyá tí wọ́n di opó lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ láti kojú ní tiwọn. Ó di dandan fún wọn láti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé bùkátà ìdílé lẹ́sẹ̀ kan náà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ọkọ wọn tó kú. Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù kí ipò yìí tó mọ́ wọn lára, ó tiẹ̀ lè gba ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá, bí wọ́n ti ń bá ìṣòro ìṣúnná owó yí, tí wọ́n sì tún ń tu àwọn ọmọ wọn nínú. Ó lè nira gan-an fún opó tó lọ́mọ yìí láti bójú tó gbogbo àwọn ẹrù iṣẹ́ yìí. Èyí lè jẹ́ kí ọmọ kan ṣàìrí àbójútó tó yẹ látọ̀dọ̀ òbí, ní àkókò kan tó yẹ kí àwọn òbí máa fọkàn rẹ̀ balẹ̀ kí wọ́n sì máa fún un ní àfiyèsí lójú méjèèjì.
Nígbà mìíràn, àwọn tó ń di ìyá tó ń dá tọ́mọ, tí wọ́n bímọ láìsí nílé ọkọ, sábà máa ń jẹ́ ọmọdé pátápátá tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́n. Ó lè má ṣeé ṣe fún wọn láti parí ẹ̀kọ́ wọn. Nígbà tí wọn ò bá sì ní iṣẹ́ gidi lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ya akúùṣẹ́, kó jẹ́ pé iṣẹ́ tí kò ní láárí ni wọ́n á máa ṣe. Láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí, irú bí àwọn òbí wọn, ẹrù iṣẹ́ rírí ẹni tó máa bá wọn tọ́jú ọmọ tún lè kún ìṣòro wọn. Ẹni tí ó di ìyá láìlọ́kọ náà tún lè máa ní ẹ̀dùn ọkàn, bóyá kí ojú máa tì í tàbí kó máa nímọ̀lára pé òún nìkan wà. Ẹ̀rù lè máa ba àwọn kan pé ọmọ tí àwọ́n bí náà kò ní jẹ́ káwọn rí ọkọ gidi láé. Bí àwọn ọmọ tó wà nínú irú agbo ilé bẹ́ẹ̀ bá sì ṣe ń dàgbà, àwọn ìbéèrè tó ń dìde lọ́kàn wọn nípa ìdílé wọn, èyí tí wọn ò rí ìdáhùn sí, àti ìfẹ́ pé kí òbí wọn kejì tí kò sí nítòsí máa ṣe ojúṣe òbí fún àwọn, lè máa kó ìdààmú bá ọkàn àwọn náà.
Bákan náà, àwọn òbí tí ìgbéyàwó wọn tú ká máa ń ní másùnmáwo tó kọjá sísọ. Inú lè máa bí àwọn òbí kan gan-an nítorí ìkọ̀sílẹ̀ náà. Ìmọ̀lára àìjámọ́-nǹkankan àti ìrora ọkàn pé wọ́n pa àwọn tì tún lè máà jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn òbí mìíràn láti rójú ráyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn. Ó lè nira fún àwọn ìyá tó di dandan fún láti wá iṣẹ́ ṣe fún ìgbà àkọ́kọ́ láti kojú ẹrù iṣẹ́ bíbójútó ìdílé. Wọ́n lè máa ronú pé àwọn ò ní àkókò tàbí okun tó láti gbọ́ tàwọn ọmọ wọn,
ìyẹn àwọn ọmọ tí àwọn pẹ̀lú ń kojú ìyípadà ńlá tó dé bá wọn láìròtẹ́lẹ̀ lẹ́yìn táwọn òbí wọn tú ká.Àwọn Ìṣòro Bíbùáyà Tí Àwọn Obí Tó Kọra Wọn Sílẹ̀ Ń Kojú
Àwọn òbí tó ń dá nìkan tọ́mọ mọ̀ pé àwọn ohun tí ọmọ wọn kọ̀ọ̀kan nílò yàtọ̀ síra, kíákíá làwọn nǹkan wọ̀nyí sì máa ń yí padà. Ní ti òbí tó ń dá tọ́mọ nítorí ìkọ̀sílẹ̀, rírí àyè láti pèsè ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí bó ṣe yẹ tún lè jẹ́ ìṣòro líle koko mìíràn.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan tí ìgbéyàwó wọn ti tú ká, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lè máà ní àǹfààní láti mú àwọn ọmọ wọn sọ́dọ̀. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ti gbìyànjú láti fi àkókò tí àwọn ọmọ wọn ń wá sọ́dọ̀ wọn sígbà tó máa ṣeé ṣe fún wọn láti lè lọ sí ìpàdé Kristẹni. Ètò ìbẹ̀wò yìí á fún ọmọ náà láǹfààní láti lè máa lọ sí ìjọ Kristẹni lóòrèkóòrè, èyí tó máa ń ṣe ọmọ àwọn òbí tó ti kọra wọn sílẹ̀ láǹfààní ńlá.
Òbí kan tí ẹnì kejì ti kọ̀ sílẹ̀, tí kì í fi bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní láti máa rí àwọn ọmọ rẹ̀ déédéé ní láti máa wá àwọn ọ̀nà láti fi dá àwọn ọmọ náà lójú pé òún nífẹ̀ẹ́ wọn, àti pé òun ò pa wọ́n tì. Bí irú òbí bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, ó gbọ́dọ̀ máa ṣàkíyèsí àwọn ohun tó ń jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún ọmọ náà kó sì máa ṣiṣẹ́ lé wọn lórí. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì tí ọmọ náà bá ti di ọ̀dọ́langba, tó ti ń nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tó ń lọ láwùjọ, tó sì ti ń ní àwọn ọ̀rẹ́ tirẹ̀.
Òbí tó fẹ́ ṣàṣeyọrí á tún lóye ibi tí agbára ọmọ náà mọ, ìwà rẹ̀, àti bí ọmọ náà ṣe ń ronú. (Jẹ́nẹ́sísì 33:13) Àtòbí àtọmọ á máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó gbádùn mọ́ni láìfi nǹkan kan pa mọ́ fúnra wọn, wọ́n á sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn. Àtibá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà kò ní í máa jẹ́ ìṣòro. Ọmọ náà kò ní máa dágunlá sí àwọn ohun tó ń lọ nínú ìgbésí ayé òbí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òbí kò ní dágunlá sí ti ọmọ rẹ̀.
Ìdí Tó Fi Pọn Dandan Láti Lo Òye
Tí ìkọ̀sílẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn ọmọ á jàǹfààní tí wọ́n bá ń rí àwọn òbí méjèèjì déédéé. Ká ní ìsìn àwọn òbí méjèèjì yàtọ̀ síra ńkọ́, tí ọ̀kan jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí èkejì kì í sì ṣe Ẹlẹ́rìí? Ìjíròrò déédéé tó sì sojú abẹ níkòó máa ń jẹ́ kí gbọ́nmi-si omi–ò-to tí kò nídìí má lè wáyé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí àwọn òbí méjèèjì ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wu kálukú wọn.
Òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà lè fi dandan lé e pé ọmọ náà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé òun lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Kí ni òbí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà lè ṣe? Òun náà lè máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ nínú ẹ̀sìn rẹ̀ kọ́ ọmọ náà. Bí àkókò ti ń lọ, ọmọ náà lè ṣe ìpinnu fúnra rẹ̀ nípa irú ìsìn tó fẹ́ ṣe, bíi ti 2 Tímótì 3:14, 15) Bí ọkàn ọmọ náà kò bá balẹ̀ nítorí bó ṣe ń lọ sí ibi ètò ìsìn mìíràn, ó lè gbé àpẹẹrẹ Náámánì tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì yẹ̀ wò, ẹni tó jẹ́ pé lẹ́yìn tó ti di olùjọsìn tòótọ́, ó ṣì ń ṣe ojúṣe rẹ̀ láti máa bá ọba lọ sílé òrìṣà Rímónì tó ń jọ́sìn. Àkọsílẹ̀ yìí lè fi ọmọ náà lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ó mọ ohun tó fà á tó fi ń lọ síbi ètò ìsìn tí kò mọ́ ọn lára náà.—2 Ọba 5:17-19.
Tímótì ọ̀dọ́, ẹni tí ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ kọ́ ní àwọn ìlànà Bíbélì. (Òbí tó fẹ́ ṣàṣeyọrí lórí ọmọ títọ́ á lè tọ́ ìrònú ọmọ rẹ̀ tàbí àwọn ọmọ rẹ̀, á sì lóye ìmọ̀lára wọn. (Diutarónómì 6:7) Lóòótọ́, ojú lè máa ti òbí tí kò ṣègbéyàwó rí nítorí irú ìgbésí ayé tó ti gbé sẹ́yìn. Àmọ́, ó yẹ kí irú òbí bẹ́ẹ̀ máa rántí pé òbí méjì lọ́mọ máa ń ní. Àwọn ọmọ á fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn òbí méjèèjì, ó sì yẹ kí wọ́n máa rí i lára àwọn òbí náà pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn, pé kì í ṣe pé ńṣe làwọ́n kàn wá forí kó wàhálà tí kì í ṣe ẹ̀bi àwọn. Nípa rírí i pé òun kò sọ̀rọ̀ òbí tí kò sí níbẹ̀ náà láìdáa, àti fífún ọmọ náà láwọn ìdáhùn tí ọjọ́ orí rẹ̀ gbé, tàbí tó pọn dandan pé kó mọ̀, á ṣeé ṣe fún òbí náà láti pèsè ìdánilójú onífẹ̀ẹ́ fún ọmọ náà.
Àwọn òbí gbọ́dọ̀ rántí pé, òye tí ọmọ máa ń kọ́kọ́ ní nípa ìfẹ́, ọlá àṣẹ, àti agbára sinmi lórí irú àjọṣe tí ọmọ náà ní pẹ̀lú òbí rẹ̀. Nípa lílo ọlá àṣẹ àti agbára lọ́nà onífẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni òbí tó jẹ́ Kristẹni náà á lè ṣe láti múra ọmọ náà sílẹ̀ kó lè ní àjọṣe onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà, kó sì lè ní ọ̀wọ̀ fún àwọn ìṣètò inú ìjọ.—Jẹ́nẹ́sísì 18:19.
Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àwọn Ọmọ Ṣe Pàtàkì
Ó yẹ kí àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé olóbìí kan mọ̀ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tiwọn náà ṣe pàtàkì fún àṣeyọrí ìdílé náà. (Éfésù 6:1-3) Ṣíṣègbọràn sí àṣẹ òbí wọn fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òbí náà àti pé wọ́n mọrírì àfikún ìsapá tí òbí náà ń ṣe kí wọ́n lè ní agbo ilé tó ní ààbò àti ayọ̀. Níwọ̀n bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ kì í ti í ṣe ohun tí ẹnì kan ń dá ṣe, ó yẹ káwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé olóbìí kan máa rántí pé àwọn gbọ́dọ̀ múra tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú òbí náà kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó jíire lè máa wà nínú ìdílé náà.—Òwe 1:8; 4:1-4.
Ipò tí àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé olóbìí kan bá ara wọn sábà máa ń mú kó pọn dandan pé kí wọ́n tètè tẹ́rí gba ẹrù iṣẹ́ ìdílé ju àwọn ọmọ tí bàbá àti ìyá wọn ń gbé pọ̀ lọ. Pẹ̀lú ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ tá a fi sùúrù ṣe, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin á lè dá ara wọn lójú, wọn ò sì ní máa wo ara wọn bí ẹni tí kò ní láárí, bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí láti ìgbà ọmọdé. Bákan náà, òbí náà tún lè yan àwọn iṣẹ́ ilé kan fún àwọn ọmọ láti máa ṣe, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ nínú mímú kí nǹkan máa lọ létòlétò nínú ìdílé náà.
Èyí ò túmọ̀ sí pé ète tó máa wà lọ́kàn òbí tó ń nìkan tọ́mọ náà ni láti sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di àgbàlagbà kéékèèké sínú ilé, bí ẹni pé wọ́n ti tó ó bójú tó ara wọn, débi tí wọn ò ní nílò ìtọ́sọ́nà òbí mọ́. Ó dájú pé kò ní bọ́gbọ́n mu rárá láti fi ọmọ kékeré sílẹ̀ lóun nìkan tàbí láìní àbójútó.
Àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ sábà máa ń fi àṣìṣe ronú pé àwọn lè sọ àwọn ọmọ wọn di ojúgbà àwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọṣe tímọ́tímọ́ ṣe pàtàkì, ó yẹ kí òbí tó ń nìkan tọ́mọ máa rántí pé àwọn ọmọ nílò òbí, àti pé ọmọ kan kò lè gbọ́n débi tí òbí náà á fi sọ ọ́ di agbọ̀ràndùn tàbí tí yóò fi máa wò ó bí ojúgbà. Àwọn ọmọ rẹ á retí pé kó o máa ṣe bí òbí sí àwọn.
Àwọn òbí anìkàntọ́mọ àtàwọn ọmọ tí wọ́n jọ fìfẹ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lè mú kí ìdílé wọn ṣàṣeyọrí. Bí àwọn ọmọ tí wọ́n ń tọ́ nínú àwọn ìdílé olóbìí kan ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí í, ó yẹ kí gbogbo wa mọ̀ pé àwọn òbí anìkàntọ́mọ àtàwọn ọmọ wọn ní àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń kojú, ó sì yẹ ká múra tán láti pèsè ìṣírí onífẹ̀ẹ́ àti ìtìlẹ́yìn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ipa Tó Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
Àwọn òbí anìkàntọ́mọ lọ́pọ̀ ìgbà kì í ní àkókò tó fún ọmọ kọ̀ọ̀kan bíi tàwọn tó jẹ́ òbí méjì. Nígbà míì, òbí kan tó ń nìkan tọ́mọ lè máa gbé pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tàbí obìnrin mìíràn tí kì í ṣe ọkọ rẹ̀ tàbí aya rẹ̀. Àmọ́, bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ gbé pọ̀ kì í ṣe àjọṣe kan tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ bíi pé kí ẹ jẹ́ tọkọtaya. Bí àwọn ọmọ tó ń gbé nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀ ṣe ń dàgbà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bá onírúurú àgbàlagbà ọkùnrin tàbí obìnrin gbé, tí àwọn yẹn á sì máa nípa lórí ìgbésí ayé wọn.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwádìí kan ti fi hàn, “ní ìpíndọ́gba, kò dájú pé àwọn ọmọ tó ń gbé nínú ìdílé olóbìí kan lè gbé ìgbé ayé tó yàn tó yanjú tó àwọn ọmọ tí òbí wọn méjèèjì jọ ń gbé pọ̀.” Àmọ́ ṣá o, nígbà tí wọ́n tún àwọn ìwádìí yìí gbé yẹ̀ wò dáadáa, wọ́n rí i pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀dá owó jẹ́ “kókó pàtàkì tó ń fa ìyàtọ̀ tó ń wáyé nínú ìdàgbàsókè àti ìwà àwọn ọmọ tó wá láti onírúurú ìdílé.” Ṣùgbọ́n èyí ò wá túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ tó ń gbé nínú ìdílé olóbìí kan kò lè ṣàṣeyọrí o. Tí wọ́n bá rí ìtọ́sọ́nà àti ẹ̀kọ́ gidi gbà, wọ́n lè borí ìtẹ̀sí búburú.