Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ, àmọ́ Tí Kò Dá Wà

Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ, àmọ́ Tí Kò Dá Wà

Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ, àmọ́ Tí Kò Dá Wà

“Nígbà táwọn ọmọ mi bá padà dé sílé, tí wọ́n bá fò mọ́ mi, tí wọ́n sì sọ fún mi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi, ohun tó dùn jù lọ nínú jíjẹ́ abiyamọ nìyẹn.”DORIS, ÌYÁ KAN TÓ Ń NÌKAN TỌ́ ỌMỌ MÉJÌ.

Ọ̀RỌ̀ kan wà nínú Bíbélì tó lè fi àwọn ìyá tó ń nìkan tọ́mọ lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn ni pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Sáàmù 127:3) Pé inú ìdílé olóbìí kan ni wọ́n ti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà kò sọ pé kí wọ́n má ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí àwọn ìdílé olóbìí kan ṣàṣeyọrí. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó ni ó ń mú ìtura bá.” (Sáàmù 146:9) Kí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ lọ fọkàn balẹ̀ o, Ọlọ́run ṣe tán láti tì wọ́n lẹ́yìn.

Ẹ̀tọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan ni pé kí a tọ́ ọ dàgbà lọ́nà onífẹ̀ẹ́, láìséwu àti ní àyíká kan tí ààbò wà, èyí tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti dàgbà bó ṣe yẹ—nípa tara, nípa ti ìmí ẹ̀dùn, àti nípa tẹ̀mí. Ẹrù iṣẹ́ òbí kọ̀ọ̀kan ni, àǹfààní ńlá ló sì tún jẹ́ fún wọn pẹ̀lú pé Ọlọ́run ń lò wọ́n láti kọ́ ọmọ kan.

Ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó ń nìkan tọ́mọ ti rí i pé, láti ṣàṣeyọrí, ó ń béèrè fífi tọkàntọkàn gbàdúrà, fífi ìlànà Bíbélì sílò nígbà gbogbo, àti gbígbáralé Jèhófà pátápátá. Èyí wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú tá a rí nínú Sáàmù 55:22 tó sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn òbí àgbà, àwọn alàgbà nínú ìjọ, àtàwọn òbí tó nírìírí nínú ìjọ Kristẹni lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèrànwọ́ fún ìdílé olóbìí kan láti kojú àwọn ipò lílekoko. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wa lè ṣe láti kọ́wọ́ tí akitiyan àwọn òbí tó ń nìkan tọ́mọ, àmọ́ òbí ni Ọlọ́run dìídì gbé ẹrù iṣẹ́ títọ́ ọmọ wọn lé lọ́wọ́. a

Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó ń nìkan tọ́mọ, tí wọ́n ń kojú àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ tí ipò wọn ń mú wá ti ṣàṣeyọrí, wọ́n sì ti tọ́ àwọn ọmọ tó wúlò, tí wọ́n mọ̀wàáhù, tí wọ́n sì bẹ̀rù Ọlọ́run. Àwọn òǹṣèwé Jí! bá àwọn kan lára wọn sọ̀rọ̀. Díẹ̀ rèé lára àwọn nǹkan tí irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ fi jọra:

• Ètò inú ilé tó mọ́yán lórí. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí wọ́n ṣàṣeyọrí máa ń gbìyànjú láti ṣe nǹkan létòlétò wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kára láti rí i pé àwọ́n bójú tó àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ìwéwèé tó bójú mu àti ètò tó yẹ ṣe pàtàkì. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”—Òwe 21:5.

• Jíjẹ́ kí ire ìdílé jẹni lógún. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí wọ́n ṣàṣeyọrí máa ń jẹ́ kí ire ìdílé wọn jẹ wọ́n lọ́kàn gan-an. Wọ́n máa ń fi àwọn ohun tó kan àwọn ọmọ wọn gbọ̀ngbọ̀n ṣáájú ti ara wọn.—1 Tímótì 5:8.

• Níní ojú ìwòye tó dára nípa àwọn ipò nǹkan. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí wọ́n ṣàṣeyọrí kì í fojú kéré ìṣòro tàbí kí wọ́n sọ ọ́ di bàbàrà; bí wọ́n ṣe máa rí ojútùú sí i ni wọ́n máa ń wá. Wọ́n máa ń kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti borí wọn láìsí pé wọ́n ń káàánú ara wọn tàbí pé wọ́n ń banú jẹ́.

• Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó jíire. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí wọ́n ṣàṣeyọrí máa ń rí sí i pé gbogbo ìdílé náà jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa. Wọ́n máa ń fún kálukú láyè láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tàbí bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Bàbá kan tó ń dá tọ́mọ sọ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ti ṣí sílẹ̀ ni mo máa ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ìgbà tá a bá ń gbọ́únjẹ alẹ́ ni a jọ máa ń ‘gbádùn ara wa’ jù. Ìgbà yẹn gan-an ni wọ́n máa ń sọ tinú wọn fún mi.”

• Bíbójútó ara ẹni. Láìka ti àkókò tí wọn kì í sábà ní sí, àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí wọ́n ṣàṣeyọrí mọ̀ pé, bíbójútó ara wọn nípa tẹ̀mí, ní ti ìmí ẹ̀dùn, àti nípa tara ṣe pàtàkì. Ethel, ìyá kan tó ń nìkan tọ́ ọmọ méjì, tóun àti ọkọ rẹ̀ ti tú ká, ṣàlàyé pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti wá àyè díẹ̀ gbọ́ ti ara mi. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀rẹ́ kan bá ń kọ́ àwọn ọmọ mi lórin, èyí máa ń jẹ́ kí n rí wákàtí kan lò fún ara mi. Màá fìdí kalẹ̀, mi ò sì ní tan tẹlifíṣọ̀n rárá.”

• Níní ẹ̀mí pé nǹkan á dára. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí wọ́n ṣàṣeyọrí máa ń fi ojú tó dára wo iṣẹ́ ọmọ títọ́ àti ìgbésí ayé lódindi. Wọ́n máa ń wo ire tó lè jẹ yọ látinú ìṣòro wọn. Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ sọ pé: “Mo ti wá rí i pé kò sóhun tójú ò rí rí nínú pé èèyàn ń dá tọ́mọ.”

Ìrírí Àwọn Tó Ti Ṣàṣeyọrí

Ǹjẹ́ àwọn ìlànà wọ̀nyí gbéṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn látinú ọ̀pọ̀ ìrírí àwọn òbí tó ti nìkan tọ́mọ tí wọ́n sì ṣe é láṣeyọrí. Gloria, ìyá kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tóun àti ọkọ rẹ̀ ti tú ká, tó ń dá tọ́mọ tó sì tún ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, tọ́ ọmọkùnrin méjì àti obìnrin kan dàgbà. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dàgbà di Kristẹni òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, wọ́n sì ń lo ìgbésí ayé wọn fún kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí a béèrè lọ́wọ́ Gloria pé ọ̀nà wo ló gbé e gbà, ó ṣàlàyé pé: “Ìpèníjà àkọ́kọ́ jẹ́ láti rí i pé à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tó gbádùn mọ́ni tó sì ṣe déédéé. Mo fẹ́ kí àwọn ọmọ náà láyọ̀, kí ọkàn wọn balẹ̀, kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn, kí wọ́n má sì jìn sínú ọ̀fìn. Mo rí iṣẹ́ alẹ́ kan tí mò ń ṣe. Ìdí tí mo fi ṣe èyí ni láti máa rí i pé àwọn ọmọ náà wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe fún mi. Kí n tó lọ síbi iṣẹ́, àá jọ gbàdúrà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, lẹ́yìn náà màá rí i pé wọ́n lọ sùn. Àbúrò màmá mi obìnrin ló máa ń wà pẹ̀lú wọn nílé nígbà tí mo bá lọ sí ibi iṣẹ́.”

Báwo ni Gloria ṣe ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n fi sí ipò àkọ́kọ́? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Fífi àwọn ohun tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́ ló jẹ mí lọ́kàn jù. A ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, mi ò sì ń fi èyí bò fún àwọn ọmọ náà rárá. Ohunkóhun tí mo bá ní kí wọ́n ṣe lèmi náà máa ń ṣe, gbogbo wọn ló sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀.” Nígbà tó ń ronú padà sí ọgbọ́n tó dá sí i tí ìdílé rẹ̀ fi wà pa pọ̀ tímọ́tímọ́, Gloria sọ pé: “Àṣírí ibẹ̀ ni jíjọ ṣe nǹkan pa pọ̀. Kò sẹ́ni tó ń lọ dérí mọ́nú yàrá. Ńṣe la jọ máa ń se oúnjẹ, tá a jọ ń tọ́jú ilé, tá a sì jọ ń ṣe inú ilé lọ́ṣọ̀ọ́. A ò jẹ́ kí ìgbòkègbodò wa kan pa òmíràn lára. Mo máa ń rí i dájú nígbà gbogbo pé a máa ń ṣe eré ìtura.”

Ńṣe ni inú Carolyn, ìyá ọmọdékùnrin kan tó ń jẹ́ Joseph, máa ń dùn fún bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà. Kí ni àṣírí ìdùnnú rẹ̀? Obìnrin náà sọ pé: “A máa ń ka Bíbélì pa pọ̀ ká tó lọ sùn, mo sì máa ń bi í ní ìbéèrè nípa àwọn ohun tó ti kọ́. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún máa ń jíròrò àwọn ìpínrọ̀ tá a pilẹ̀ yàn nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, tá a sì máa ń fi wọ́n sílò bó ṣe kan kálukú wa. Èyí máa ń ran Joseph lọ́wọ́ nígbà tó bá dojú kọ ìṣòro, bíi kíkojú àwọn ìpáǹle ọmọ nílé ìwé.” Carolyn kò sẹ́ pé ìgbésí ayé òun kò níṣòro, ṣùgbọ́n kò mọ̀ ọ́n lára pé ńṣe ni òun dá wà. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà kọ́ ni nǹkan máa ń rọrùn o, àmọ́ mo gbà pé Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Mo tún máa ń rí ọ̀pọ̀ ìṣírí gbà nínú ìjọ Kristẹni.”

Àwọn ìrírí nípa àṣeyọrí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òbí tó ń nìkan tọ́mọ, irú bíi Gloria àti Carolyn, jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn òbí òde oní lè gbára lé àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì láti tọ́ àwọn ọmọ tó máa yàn, tó máa yanjú, tí wọ́n á sì dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. (Òwe 22:6) Àṣeyọrí ṣeé ṣe o! Dídá tọ́mọ ń mú ọ̀pọ̀ ìpèníjà wá, èyí tó lè mú kí òye ẹni túbọ̀ pọ̀ sí i kó sì kọ́ni láti túbọ̀ mọ bá a ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Gbígbáralé Ọlọ́run pátápátá, àti níní ìdánilójú pé yóò pèsè ìrànwọ́, jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti kojú àwọn pákáǹleke tó wà nínú dídá tọ́mọ.—Sáàmù 121:1-3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àfikún ìsọfúnni lórí bí àwọn ìdílé olóbìí kan ṣe lè ṣàṣeyọrí, wo orí 9 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé ti ran àwọn ọmọ Gloria mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ́wọ́ láti di Kristẹni òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àwọn nìyí tí wọ́n ń wo lẹ́tà kan àti fọ́tò kan tí ẹ̀gbọ́n wọn àgbà, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì báyìí, fi ránṣẹ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Carolyn àti ọmọ rẹ̀, Joseph