Kí Ló Dé Tí Ọ̀kan Nínú Àwọn Òbí Mi Kò Fi Nífẹ̀ẹ́ Mi Mọ́?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Dé Tí Ọ̀kan Nínú Àwọn Òbí Mi Kò Fi Nífẹ̀ẹ́ Mi Mọ́?
“Kí dádì mi tó kọ mọ́mì mi sílẹ̀, ó máa ń mú mi jáde lọ gbafẹ́ létíkun, a jọ máa ń lọ ṣe fàájì ni, a sì jọ máa ń rìnrìn-àjò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ ni. Àmọ́, ńṣe ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí dópin lójijì. Dádì mi wá yí padà pátápátá. Ńṣe ló tiẹ̀ dà bíi pé ó kúkú ti kọ èmi náà sílẹ̀.”—Karen. a
Ọ̀PỌ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọ̀dọ́ ni irú àwọn nǹkan báyìí máa ń dà lọ́kàn rú. Bíi ti Karen, wọ́n máa ń rò pé bàbá àwọn tàbí ìyá àwọn kò fẹ́ràn àwọn mọ́, tàbí pé kò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn rí. Ohun tá à ń sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí kì í ṣe bí ọ̀dọ́ kan ṣe máa ń di kùnrùngbùn fún ìgbà díẹ̀ nítorí àìgbọ́ra-ẹni-yé tó lè wáyé láàárín òun àtàwọn òbí rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe máa ń fapá jánú nítorí pé àwọn òbí wọn bá wọn wí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá à ń sọ ni pé, gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn kan, bí àwọn òbí kan ṣe máa ń dìídì ṣá àwọn ọmọ wọn tì, tí wọ́n á kùnà láti fún wọn ní àbójútó àti ìbáwí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn sì rèé, ńṣe làwọn òbí kan máa ń hùwà ìkà tàbí ìwà òǹrorò sáwọn ọmọ wọn, bóyá kí wọ́n máa sọ̀kò èébú lù wọ́n tàbí kí wọ́n máa lù wọ́n ní ìlùkulù.
Ṣàṣà ni ohun tó lè dun ọmọ kan wọra tó pé kí òbí rẹ̀ pa á tì. Karen sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé mi ò wúlò rárá, pé mi ò já mọ́ nǹkan kan.” Bó o bá ti ní irú ìṣòro yìí rí, ronú lórí àwọn ìdámọ̀ràn kan tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí èrò òdì tó o ní. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé, bí àwọn òbí rẹ kò bá tiẹ̀ bójú tó ọ, o lè ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé!
Lílóye Àwọn Òbí Rẹ
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kò lòdì láti retí pé kí àwọn òbí rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ó yẹ kí ìfẹ́ tí òbí ní sí ọmọ jẹ́ ohun àdánidá, ohun tí kì í yẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi yíyọ oòrùn tí kò fìgbà kan tàsé àkókò rẹ̀ rí. Ọlọ́run retí pé kí àwọn òbí máa fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn. (Kólósè 3:21; Títù 2:4) Nítorí náà, kí ló dé táwọn òbí kan fi máa ń pa àwọn ọmọ wọn tì, tí wọ́n máa ń ta wọ́n nù, tàbí tí wọ́n máa ń fìyà jẹ wọ́n?
Ohun kan tó lè ṣokùnfà èyí ni ohun tójú àwọn náà ti rí nígbèésí ayé. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ibo làwọn òbí mi ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe ń tọ́mọ?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, bí àwọn òbí tiwọn alára ṣe tọ́ wọn làwọn náà ṣe máa tọ́ ọmọ wọn. Nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ tó kún fún wàhálà tá a sì ń gbé lónìí, tí ọ̀pọ̀ jaburata èèyàn jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá,” irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ táwọn òbí wọn ti fún wọn yìí sábà máa ń lálèébù gan-an. (2 Tímótì 3:1-5) Nígbà míì, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé bí wọ́n bá ṣe tọ́ àwọn òbí ni àwọn pẹ̀lú á ṣe tọ́ ọmọ wọn.
Láfikún sí i, oríṣiríṣi nǹkan ló lè kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá àwọn òbí. Torí káwọn òbí kan lè bọ́ lọ́wọ́ ìrora ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sì tó bá wọn, ńṣe ni wọ́n máa ń fi gbogbo àkókò ṣiṣẹ́ ṣáá, tí wọ́n á máa mu ọtí àmupara, tàbí tí wọ́n á máa lo oògùn olóró ṣáá. Bí
àpẹẹrẹ, ọ̀dọ̀ bàbá wọn tó jẹ́ ọ̀mùtípara ni William àti Joan gbé dàgbà. Joan sọ pé: “Bàbá mi ò kan sáárá sí wa rí. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù lọ ni bó ṣe máa ń bínú rangbandan nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí mutí àmupara. Ariwo ṣáá ló máa ń fi gbogbo ìrọ̀lẹ́ pa lé ìyá mi lórí. Ńṣe lẹ̀rù máa ń bà mí.” Kódà, báwọn òbí kò bá ń hùwàkiwà lọ́nà tó fara hàn, ìṣarasíhùwà wọn lè mú kó nira fún wọn láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì bójú tó wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.William ronú pé òún mọ ohun tó fà á tí bàbá òun fi máa ń hùwà lódìlódì bẹ́ẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Ìlú Berlin lórílẹ̀-èdè Jámánì ni bàbá mi dàgbà sí, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tó wà lọ́mọdé, àwọn nǹkan burúkú tójú ẹ̀ rí kó ṣeé fẹnu sọ, àwọn èèyàn tó sì ṣojú rẹ̀ kú kì í ṣe kékeré. Iṣẹ́ àṣekúdórógbó ló máa ń ṣe lójoojúmọ́ ayé láti lè rí nǹkan jẹ. Mo ronú pé àwọn ohun tí ojú bàbá mi ti rí ló ń jẹ́ kó máa hùwà bó ṣe ń hùwà.” Ní ti gidi, Bíbélì pàápàá sọ pé àwọn èèyàn tó bá rí ìnira tó gàgaàrá lè hùwà bí ayírí.—Oníwàásù 7:7.
Ṣé William àti Joan wá ronú pé bàbá wọn kò jẹ̀bi ìyà tó fi ń jẹ wọ́n nítorí àwọn ohun tójú rẹ̀ ti rí ni? William sọ pé: “Rárá o, ìyà tó ti jẹ láyé rẹ̀ kò fún un láṣẹ láti máa mu ọtí àmupara kó sì máa hùwà tí kò mọ́gbọ́n dání. Ṣùgbọ́n, mímọ̀ tí mo mọ èyí ti ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ irú ẹ̀dá tí bàbá mi jẹ́.”
Gbígbà pé àwọn òbí rẹ jẹ́ aláìpé àti ṣíṣèwádìí nípa ìrírí wọn nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé yóò ṣèrànwọ́ gan-an fún ọ láti lè lóye wọn. Òwe 19:11 sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.”
Bíborí Èrò Òdì Tó O Ní
Àwọn èrò òdì mìíràn tún wà tó lè máa dà ọ́ láàmú nítorí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú agboolé yín. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn òbí Patricia méjèèjì kò ṣe kà á sí mú kó nímọ̀lára pé “òun kò já mọ́ nǹkan kan àti pé òun kò wúlò rárá.” Ó nira fún LaNeisha láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọkùnrin ní gbogbo gbòò látìgbà tí bàbá rẹ̀ ti fi ìdílé wọn sílẹ̀ nígbà tó ṣì wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ péré. Ṣùgbọ́n ní ti Shayla, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹni tó bá ti rí ló máa ń retí pé kí wọ́n ka òun sí, kó sáà lè gba àfiyèsí tí kò rí gbà látọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ẹni tí “oògùn olóró ti sọ dìdàkudà.”
Ìbínú àti owú tún lè jẹ́ àwọn ìṣòro mìíràn. Nígbà tí Karen rí bí bàbá rẹ̀ tó ti fẹ́ ìyàwó mìíràn ṣe ń fi irú ìfẹ́ tí òún ń yán hànhàn fún hàn sí ìdílé rẹ̀ tuntun, èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í “jowú lákòókò kan.” Nígbà míì, Leilani tiẹ̀ máa ń ronú pé òún kórìíra àwọn òbí òun. Ó ní: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń bá wọn ní gbólóhùn asọ̀.”
Bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyí kò yani lẹ́nu, tá a bá gbé àwọn ohun tó ń ṣokùnfà wọn yẹ̀ wò. Àmọ́, báwo lo ṣe lè borí àwọn èrò òdì bẹ́ẹ̀ lọ́nà títọ́? Ronú lórí àwọn ìdámọ̀ràn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí.
• Sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run. (Jákọ́bù 4:8) O lè ṣe èyí nípa dídá ka Bíbélì àti nípa pípéjọpọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀. Bó o bá ṣe ń mọ bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò ni wàá máa rí i pé ó jẹ́ adúróṣinṣin. O lè gbẹ́kẹ̀ lé e. Jèhófà béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀?” Ó wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.” (Aísáyà 49:15) Nítorí náà, máa gbàdúrà déédéé sí Ọlọ́run. Má máa dààmú nípa pé ọ̀rọ̀ tóò ń lò kò fi bẹ́ẹ̀ tọ̀nà. Ọlọ́run lóye rẹ. (Róòmù 8:26) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ kódà bó bá dà bíi pé kò sí ẹni tó fẹ́ràn rẹ.—Sáàmù 27:10.
• Finú han àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán. Bá àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí dọ́rẹ̀ẹ́. Sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ àti bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ fún wọn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Nínú ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè rí àwọn bàbá àti ìyá nípa tẹ̀mí. (Máàkù 10:29, 30) Àmọ́, àfi kí ìwọ fúnra rẹ lọ ṣí ohun tó ń dà ọ́ lọ́kàn rú payá fún wọn. Àwọn ẹlòmíràn kò lè mọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ àyàfi bó o bá sọ fún wọn. Bí ara ṣe máa tù ọ́ pẹ̀sẹ̀ bó o bá ti kó àníyàn kúrò lọ́kàn rẹ lè fún ọ ní ojúlówó ìtùnú.—1 Sámúẹ́lì 1:12-18.
• Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí nínú ṣíṣe nǹkan fún àwọn ẹlòmíràn. Láti lè yẹra fún ewu kíkáàánú ara rẹ, gbìyànjú láti má ṣe máa ronú ṣáá lórí àwọn apá ibi tí kò bára dé nínú ipò rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa kún fún ìmọrírì fún àwọn ohun tó o ní. Lo àwọn àǹfààní rẹpẹtẹ tó ṣí sílẹ̀ fún ọ nípa ṣíṣàì máa “mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [rẹ] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Gbé àwọn nǹkan tẹ̀mí tí wàá máa lépa kalẹ̀, kó o sì ṣiṣẹ́ kára kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ wọ́n nípa níní èrò tó dára. Ṣíṣiṣẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni jẹ́ ọ̀nà dídára kan láti máa fi ire ti àwọn ẹlòmíràn ṣáájú tìrẹ.
• Máa bá a nìṣó láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn òbí rẹ. Máa rántí láti fi àwọn ìlànà àti ìtọ́sọ́nà Bíbélì sílò nígbà gbogbo. Ìwọ̀nyí kan bíbọlá fún àwọn òbí rẹ. (Éfésù 6:1, 2) Bíbọlá fún wọn lọ́nà yìí ni kì yóò jẹ́ kó o lẹ́mìí ìgbẹ̀san àti ìforóyaró. Rántí o, kò sí bí àìdáa tó jọ pé òbí kan ń ṣe ti lè pọ̀ tó tí yóò fún ìwọ náà láṣẹ láti máa hùwà àìdáa. Nítorí náà fi gbogbo ọ̀ràn lé Jèhófà lọ́wọ́. (Róòmù 12:17-21) Ó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo,” kò sì fi ọ̀ràn ààbò àwọn ọmọdé ṣeré rárá. (Sáàmù 37:28; Ẹ́kísódù 22:22-24) Bó o ṣe ń bá a nìṣó láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí rẹ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, tún máa gbìyànjú láti fi àwọn èso ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwà hù—pàápàá jù lọ, ìfẹ́.—Gálátíà 5:22, 23.
O Lè Ṣàṣeyọrí
Kò sí àní-àní pé ó máa ń dunni wọra bí òbí kan bá kùnà láti fi ìfẹ́ hàn síni. Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ ìkùnà àwọn òbí rẹ ló máa pinnu irú ẹni tó o máa yà. O lè pinnu fúnra rẹ pé wàá ní ọjọ́ iwájú aláyọ̀ àti aláṣeyọrí, nípa fífi àwọn ìlànà Bíbélì tá a mẹ́nu kàn lókè yìí sílò nínú ìgbésí ayé rẹ.
William, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan, jẹ́ òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti sìn ní ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan jaburata tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ipò bíbaninínújẹ́ wọ̀nyí. Àǹfààní ńlá ló mà jẹ́ o láti ní Baba ọ̀run yìí, ẹni tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ tó sì bìkítà!” Arábìnrin rẹ̀ Joan jẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, ó sì ń sìn ní àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù ìhìn rere. Ó sọ pé: “Bá a ṣe ń dàgbà là ń rí ìyàtọ̀ ṣíṣe kedere tó wà ‘láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.’” (Málákì 3:18) “Àwọn ohun tí ojú wa ti rí ti jẹ́ ká pinnu láìyẹsẹ̀ pé a ó ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti mọ òtítọ́, a óò si sọ ọ́ di tiwa.”
Ìwọ náà lè ṣe irú àṣeyọrí bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a.” (Sáàmù 126:5) Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe bá ipò rẹ mu? Tóò, bó o bá ṣiṣẹ́ kára láti fi àwọn ìlànà títọ́ sílò lábẹ́ àwọn ipò tí kò fara rọ, omijé rẹ á yí padà di ayọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn bó o bá ṣe ń gba ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Nítorí náà máa fi tọkàntara sapá láti sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run. (Hébérù 6:10; 11:6) Kódà bó o bá ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ní àníyàn, ìjákulẹ̀, àti ẹ̀bi, àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí lè máa pòórá díẹ̀díẹ̀, tí ara yóò máa tù ọ́, wàá sì lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:6, 7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ O Máa Ń Rò . . .
• Pé o ò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan tàbí pé o ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò?
• Pé kò tọ̀nà tàbí pé kò bọ́gbọ́n mu láti fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn?
• Pé o nílò ẹni tí yóò máa fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ lemọ́lemọ́?
• Pé o ti lè bínú jù tàbí pé o ti lè jowú jù?
Bí o bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, yáa tètè lọ bá òbí rẹ tó o fọkàn tán, alàgbà kan, tàbí ọ̀rẹ́ kan tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, kó o sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gbé àwọn ìgbésẹ̀ yíyẹ láti borí àwọn èrò òdì tó o ní