Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 20. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Nínú àlá tí Nebukadinésárì Ọba lá, kí ni áńgẹ́lì náà sọ pé a óò fún arabaríbí igi tí a gé lulẹ̀ náà, kí ni èyí sì túmọ̀ sí? (Dáníẹ́lì 4:16)

2. Kí ni Sámúsìnì ṣe lọ́dọ̀ àwọn Filísínì lákòókò àsè ìgbéyàwó rẹ̀, èyí tó wá yọrí sí pípa tó pa ọgbọ̀n ọkùnrin lára àwọn Filísínì ní Áṣíkẹ́lónì? (Àwọn Onídàájọ́ 14:12-19)

D3. Nítorí òfin kan tí kò ṣeé yí padà, ọba Bábílónì wo ló di ọ̀ràn-anyàn fún láti mú kí a sọ Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún? (Dáníẹ́lì 6:9)

4. Àwọn òṣìṣẹ́ ààfin mélòó ni Ahasuwérúsì Ọba rán láti lọ mú Fáṣítì Ayaba wá síwájú rẹ̀ kó lè ṣàfihàn ẹwà obìnrin náà? (Ẹ́sítérì 1:8-10)

5. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti sọ, nǹkan méjì wo ni Ọlọ́run fẹ́ nínú “ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin”? (Jákọ́bù 1:27)

6. Bí ẹrú kan tó jẹ́ Hébérù kò bá fẹ́ gbòmìnira kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, kí la béèrè pé kí ọ̀gá náà ṣe? (Ẹ́kísódù 21:6)

7. Àwọn ọmọkùnrin Elíábù tó jẹ́ ẹ̀yà Rúbẹ́nì méjì wo ló ti Kórà lẹ́yìn nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ sí Mósè àti Áárónì? (Númérì 16:1-3)

8. Àṣà bíba awọ ara jẹ́ wo ni a kà léèwọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Léfítíkù 19:28)

9. Ta ni ìyá Hesekáyà Ọba? (2 Àwọn Ọba 18:2; 2 Kíróníkà 29:1)

10. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti sọ, kí ni “gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run” ní? (Oníwàásù 3:1)

11. Kí ni Jèhófà pàṣẹ fún Jeremáyà láti ṣe nígbà tí Jèhóákímù Ọba sun àkájọ ìwé náà nínú iná, lẹ́yìn tó ti gbọ́ díẹ̀ lára àwọn ègún tó wà nínú rẹ̀? (Jeremáyà 36:27-32)

12. Ta la mọ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àti ọ̀jáfáfá adàwékọ? (Nehemáyà 8:9)

13. Kí ló dé tí àwọn ọmọkùnrin Jákọ́bù fi kọ̀ nígbà tí bàbá wọn ní kí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì láti lọ ra oúnjẹ sí i wá lákòókò tí ìyàn mú? (Jẹ́nẹ́sísì 43:1-5)

14. Ọ̀nà wo la gbà dá Ádámù “ní ìrí Ọlọ́run”? (Jẹ́nẹ́sísì 5:1)

15. Ewé tó lóòórùn gan-an wo ni Jésù dárúkọ nígbà tó ń sọ nípa bí àwọn Farisí ṣe ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra san ìdámẹ́wàá ewé náà, àmọ́ tí wọ́n ṣàìka “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí”? (Mátíù 23:23)

16. Báwo ni Jeremáyà ṣe dán ìgbọràn àwọn ọmọ Rékábù wò? (Jeremáyà 35:3-6)

17. Ọ̀nà wo ni àwọn arákùnrin Jósẹ́fù mẹ́wàá gbà tan Jákọ́bù tó fi rò pé ẹranko ẹhànnà kan ti pa Jósẹ́fù jẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 37:31-33)

18. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn lè wà tó tóbi jù ú lọ, ta ni òmìrán tó lókìkí jù lọ tá a dárúkọ rẹ̀ nínú Bíbélì? (1 Sámúẹ́lì 17:4)

19. Orí òkè wo ni Mósè kú sí, lẹ́yìn tó ti wo bí Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí láti ọ̀ọ́kán? (Diutarónómì 32:49, 50)

20. Ìhà ibo ni àgọ́ ìjọsìn àtàwọn tẹ́ńpìlì tá a kọ́ lẹ́yìn ìgbà náà kọjú sí? (Númérì 3:38)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. “Ọkàn-àyà ẹranko.” Pé orí Nebukadinésárì á dàrú á sì máa ṣe bí ẹranko

2. Ó pa àlọ́

3. Dáríúsì

4. Méje

5. “Láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé”

6. Kí ó mú un wá síbi ilẹ̀kùn tàbí òpó ilẹ̀kùn kí ó sì “fi òòlu lu etí rẹ̀”

7. Dátánì àti Ábírámù

8. Fínfín àmì sí ara

9. Ábíjà tàbí Ábì ní ìkékúrú

10. “Ìgbà tí a yàn kalẹ̀”

11. Pé kí ó kọ tuntun mìíràn tó tún gùn ju ti àkọ́kọ́ lọ

12. Ẹ́sírà

13. Olùṣàkóso ní ilẹ̀ Íjíbítì ti sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ padà wá láìjẹ́ pé wọ́n mú ọmọkùnrin tó kéré jù lọ dání, ìyẹn Bẹ́ńjámínì

14. Ó ní òye àti àwọn ànímọ́ tó ju ti gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn lọ fíìfíì, irú bí àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní àti agbára láti hùwà rere

15. Efinrin

16. Ó gbé wáìnì síwájú wọn ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n mu ún, èyí tó lòdì sí ohun tí baba ńlá wọn ti pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe

17. Wọ́n ti ẹ̀wù Jósẹ́fù gígùn abilà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Jákọ́bù

18. Gòláyátì

19. Nébò

20. Ìlà Oòrùn