Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Burú Jù Lọ Táráyé Ò Rírú Ẹ̀ Rí”

“Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Burú Jù Lọ Táráyé Ò Rírú Ẹ̀ Rí”

“Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Burú Jù Lọ Táráyé Ò Rírú Ẹ̀ Rí”

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

“Kò tíì sí ogun tí wọ́n jà lórí ilẹ̀ ayé tó tíì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí tó àjàkálẹ̀ àrùn éèdì.”—COLIN POWELL, AṢOJÚ ÌJỌBA AMẸ́RÍKÀ FÚN Ọ̀RÀN ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ, LÓ SỌ BẸ́Ẹ̀.

OṢÙ June ọdún 1981 ni ìgbà àkọ́kọ́ pàá tí ọ̀rọ̀ nípa àrùn éèdì jáde nínú ìròyìn. Peter Piot, olùdarí àgbà fún Ètò Àjùmọ̀ṣe ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Lórí Àrùn Éèdì àti Kòkòrò Tó Ń Fà Á, sọ pé: “Kò sí ọ̀kankan lára àwa tí a kópa nínú wíwá ojútùú sí àrùn yìí níbẹ̀rẹ̀ tó lè ronú pé ó máa wá di àjàkálẹ̀ àrùn bó ṣe dà yìí.” Láàárín ogún ọdún péré, ó ti tàn ká gbogbo ayé lọ́nà tí kò sírú rẹ̀ rí, àwọn ẹ̀rí sì fi hàn pé ńṣe ni yóò máa burú sí i.

Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógójì [36,000,000] èèyàn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n ti ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì, mílíọ̀nù méjìlélógún [22,000,000] ló sì ti gbẹ́mìí mì nítorí ohun tí àrùn yìí dá sí wọn lára. a Lọ́dún 2000, mílíọ̀nù mẹ́ta [3,000,000] èèyàn làrùn éèdì pa jákèjádò ayé, iye yìí ló sì pọ̀ jù lọ tí àrùn náà pa láàárín ọdún kan látìgbà tó ti bẹ́ sílẹ̀. Èyí rí bẹ́ẹ̀ láìka onírúurú oògùn táwọn èèyàn ń lò láti bá àrùn náà jà sí, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ gidi.

Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan

Apá gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà ni àrùn éèdì pọ̀ sí jù lọ torí pé àwọn tí wọ́n fojú bù níbẹ̀ pé wọ́n ní àrùn náà tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [25,300,000]. Ní àgbègbè yìí nìkan, mílíọ̀nù méjì ó lé ogún ọ̀kẹ́ [2,400,000] èèyàn làwọn ìṣòro tó so mọ́ àrùn éèdì pa lọ́dún 2000, èyí sì jẹ́ ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn tí àrùn éèdì pa jákèjádò ayé lọ́dún 2000. Àrùn éèdì ni olórí ohun tó ń ṣokùnfà ikú àwọn èèyàn ní àgbègbè yẹn. b

Nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé, Gúúsù Áfíríkà làwọn tó ní àrùn éèdì pọ̀ sí jù lọ torí pé àwọn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n ní àrùn náà níbẹ̀ ń lọ sí bíi mílíọ̀nù márùn-ún [5,000,000]. Ní orílẹ̀-èdè náà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìkókó ni wọ́n ń bí lóṣooṣù pẹ̀lú kòkòrò tó lè yọrí sí àrùn yìí. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi Àpérò Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá Lórí Àrùn Éèdì tí wọ́n ṣe nílùú Durban ní July 2000, Nelson Mandela tó jẹ́ ààrẹ ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà nígbà kan rí sọ pé: “Kàyéfì gbáà ló jẹ́ fún wa láti gbọ́ pé ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà níbí, ọ̀kan nínú méjì, ìyẹn ìdajì gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa, ni àrùn éèdì máa pa. Ohun tó wá kó jìnnìjìnnì bá wa jù lọ ni pé, gbogbo àkóràn yìí, èyí tí ìròyìn ń fi tó wa létí, àtàwọn ìnira tó ń bá a rìn . . . la lè ti dènà rẹ̀ àti pé wọ́n ṣeé dènà.”

Àrùn Éèdì Ń Ràn Bí Iná Ọyẹ́ Láwọn Orílẹ̀-èdè Míì Náà

Bí àrùn yìí ṣe ń ran àwọn èèyàn lápá Ìlà Oòrùn Yúróòpù, Éṣíà, àti àgbègbè Caribbean náà kò dáwọ́ dúró o. Ní ìparí ọdún 1999, ọ̀kẹ́ mọ́kànlélógún [420,000] èèyàn ló ti lùgbàdì àrùn náà lápá Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Nígbà tó fi máa di ìparí ọdún 2000, iye àwọn tí wọ́n fi tìṣọ́ratìṣọ́ra fojú bù pé wọ́n ti lùgbàdì àrùn náà ti ròkè tó ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000].

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní àwọn ìlú ńláńlá mẹ́fà ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi hàn pé, bí kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì ṣe ń ràn láàárín àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ ti lọ sókè dé ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún, ó tún lé. Yàtọ̀ síyẹn, kìkì ìdá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ní àrùn éèdì ló mọ̀ pé àwọn ní in. Ẹnì kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa àrùn tó ń ṣe aráàlú tó ṣáájú ìwádìí náà sọ pé: “Ó bà wá lọ́kàn jẹ́ gidi láti rí i pé kìkì ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin tó ti kó kòkòrò tó lè fa àrùn náà ló mọ̀. Èyí túmọ̀ sí pé ńṣe làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kó kòkòrò àrùn náà ń kó o ran àwọn mìíràn láìmọ̀ rárá.”

Níbi ìpàdé kan tí àwọn tó jẹ́ ògbógi onímọ̀ nípa àrùn éèdì ṣe ní orílẹ̀-èdè Switzerland ní May 2001, wọ́n pe àrùn yìí ní “àjàkálẹ̀ àrùn tó burú jù lọ táráyé ò rírú ẹ̀ rí.” Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà ni ríràn tí àrùn éèdì ń ràn bí iná ọyẹ́ ti légbá kan. Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e á sọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Iye tá a gbé jáde níbí jẹ́ iye tí Ètò Àjùmọ̀ṣe ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Lórí Àrùn Éèdì àti Kòkòrò Tó Ń Fà Á fojú bù.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

“Ohun tó wá kó jìnnìjìnnì bá wa jù lọ ni pé gbogbo àkóràn yìí . . . àtàwọn . . . ìnira tó ń bá a rìn . . . la lè ti dènà rẹ̀ àti pé wọ́n ṣeé dènà.”—NELSON MANDELA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti ní kòkòrò tó lè yọrí sí àrùn éèdì ni kò mọ̀ rárá

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò UN/DPI 198594C/Greg Kinch