Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
“À ń kojú ìṣòro kan lọ́jọ́ òní tó lè fa ìparun yán-án yán-án.”
Ọ̀RỌ̀ tí ọ̀gbẹ́ni Stephen Lewis tó jẹ́ aṣojú pàtàkì fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lórí ọ̀rọ̀ àrùn éèdì nílẹ̀ Áfíríkà sọ yìí, fi ìbẹ̀rù tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn hàn nípa ìṣòro àrùn éèdì ní apá gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lẹ́yìn ríràn tí àrùn éèdì ń ràn. Àrùn éèdì sì tún ti wá mú kí àwọn ìṣòro kan tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ burú sí i. Láwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà àti láwọn apá ibòmíràn láyé níbi tí àrùn éèdì ti ń ràn láìdáwọ́dúró, àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ níbẹ̀ sábà máa ń jẹ mọ́ àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí.
Ìwà Rere. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ipasẹ̀ ìbálòpọ̀ làwọn èèyàn fi ń ní kòkòrò HIV tó lè
fa àrùn éèdì jù, àìsí àwọn ìlànà ìwà rere tó ṣe kedere lohun tó dájú pé ó túbọ̀ ń dá kún títàn tí àrùn náà ń tàn kálẹ̀. Àmọ́, èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, láti máa sọ pé kí àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó má ṣe ní ìbálòpọ̀ kò lè ṣiṣẹ́. Nínú ìwé ìròyìn The Star, ti ìlú Johannesburg, ní ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, Francois Dufour kọ̀wé pé: “Láti wulẹ̀ máa kìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́langba pé kí wọ́n yẹra fún ìbálòpọ̀ kò lè ṣiṣẹ́. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń rí àwọn ohun tó ní ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀, nípa irú ẹni tó yẹ kí wọ́n fara wé àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà.”Ó jọ pé báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń hùwà lóòótọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè kan fi hàn pé, nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá sí mẹ́tàdínlógún ló ti ní ìbálòpọ̀.
Ìfipá-báni-lòpọ̀ ni wọ́n sọ pé ó ti di ìṣòro ńlá kan tó ń fẹ́ àmójútó kíákíá lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà. Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Citizen ti ìlú Johannesburg sọ pé “àṣà náà wọ́pọ̀ débi pé, ó ti gborí lọ́wọ́ àwọn ìṣòro mìíràn tó ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn obìnrin ní orílẹ̀-èdè yìí, bí wọ́n ṣe ń hu ìwà yìí sáwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ibẹ̀ pàápàá sì tún ń peléke sí i ni.” Àpilẹ̀kọ yìí kan náà tún sọ pé: “Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, àṣà fífipá bá àwọn ọmọdé lòpọ̀ ti di ìlọ́po méjì ohun tó jẹ́ tẹ́lẹ̀ . . . Ohun tó mú kí wọ́n máa dá àṣà yìí kò tàsé èrò èké tí wọ́n fẹ́ kó máa bá a lọ náà pé, tí ẹni tó ti ní kòkòrò tó lè yọrí sí àrùn éèdì bá fipá bá wúńdíá kan lòpọ̀, ara rẹ̀ á yá.”
Àwọn àrùn tí wọ́n ń kó nípasẹ̀ ìṣekúṣe. Àwọn àrùn tí wọ́n ń kó nípasẹ̀ ìṣekúṣe ti wá di ohun tó wọ́pọ̀ gidi ní àgbègbè náà.
Ìwé ìròyìn South African Medical Journal sọ pé: “Tí ẹnì kan bá ti kó àrùn nípasẹ̀ ìṣekúṣe, ńṣe ni ewu níní kòkòrò tó lè fa àrùn éèdì á túbọ̀ ga sí i.”Ipò òṣì. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Áfíríkà ló wà nínú òṣì paraku, èyí sì ń jẹ́ kí àrùn éèdì túbọ̀ máa ráyè gbilẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ máa ń kà sí kòṣeémáàní nínú ìgbésí ayé ni kò sí ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ọ̀pọ̀ àwọn àgbègbè ńláńlá ni kò ní iná mànàmáná àti omi tó dára fún mímu. Àwọn ojú ọ̀nà tó wà láwọn ìgbèríko kò kúnjú ìwọ̀n tàbí kó máà tiẹ̀ sí rárá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni àìjẹun-re-kánú ń bá fínra, bẹ́ẹ̀ làwọn ilé ìwòsàn tó pójú owó kò tó nǹkan.
Àrùn éèdì tún ń ṣàkóbá fún iṣẹ́ ajé àtàwọn iléeṣẹ́. Bí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń kó àrùn yìí ṣe ń pọ̀ sí i, ohun táwọn iléeṣẹ́ ìwakùsà ń mú jáde ti dín kù jọjọ, àwọn iléeṣẹ́ ọ̀hún sì ti ń mọ̀ ọ́n lára. Láti wá nǹkan ṣe sí báwọn òṣìṣẹ́ ṣe ń dín kù, àwọn iléeṣẹ́ kan ti ń gbèrò láti ní àwọn ẹ̀rọ tó máa lè dáṣẹ́ ṣe fúnra wọn àtàwọn ẹ̀rọ mìíràn tó ń báná ṣiṣẹ́. Lọ́dún 2000, ní iléeṣẹ́ kan tó ń wa irin látinú ilẹ̀, wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ tó kó àrùn éèdì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì, nǹkan bí ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún sì ni àpapọ̀ gbogbo òṣìṣẹ́ tó lùgbàdì àrùn náà.
Àbájáde kan tó bani nínú jẹ́ nípa àrùn éèdì ni ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọdé tó ń di aláìlóbìí nígbà tí àrùn náà bá ti pa àwọn òbí wọn. Yàtọ̀ sí pípàdánù àwọn òbí wọn, tí kò sì sí ẹni tó máa gbọ́ bùkátà wọn, àwọn ọmọ wọ̀nyí tún ní láti máa fara da ìtìjú tó so mọ́ àrùn éèdì. Àwọn ìbátan tàbí àwọn aládùúgbò sì lè kúṣẹ̀ẹ́ débi pé, wọn ò ní lágbára láti ṣèrànwọ́ tàbí kí wọ́n máà fẹ́ ṣe é. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ aláìlóbìí ló máa ń fi iléèwé sílẹ̀. Igbá aṣẹ́wó làwọn kan máa ń gbé, tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ máa tan àrùn náà kálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ti dá ètò ìjọba tàbí ètò aládàáni sílẹ̀ láti lè máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ aláìlóbìí yìí.
Àìmọ̀kan. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ti kó kòkòrò tó lè fa àrùn éèdì ni kò mọ̀ pé àwọ́n ti kó o. Ọ̀pọ̀ kì í fẹ́ lọ fún àyẹ̀wò nítorí ẹ̀sín tó so mọ́ àrùn náà. Ìròyìn kan tí Ètò Àjùmọ̀ṣe ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Lórí Àrùn Éèdì àti Kòkòrò Tó Ń Fà Á gbé jáde sọ pé: “Wọ́n lè kọ̀ láti fún àwọn èèyàn tó ti kó àrùn éèdì tàbí tí wọ́n fura sí ní ìtọ́jú láwọn ilé ìwòsàn, àwọn èèyàn lè kọ̀ láti fún wọn nílé tàbí láti gbà wọ́n síṣẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lè pa wọ́n tì, àwọn iléeṣẹ́ abánigbófò lè sọ pé irú wọn kọ́ làwọ́n ń wá, tàbí kí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ òkèèrè má gbà wọ́n láyè láti wọ ilẹ̀ wọn.” Wọ́n tiẹ̀ ti pa àwọn kan nígbà tí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ti kó àrùn éèdì.
Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Nínú ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀dálẹ̀ Áfíríkà, àwọn obìnrin kì í sábà lẹ́nu láti bi àwọn ọkọ wọn nípa àwọn àlè tí wọ́n ní síta, wọn ò lè kọ̀ pé àwọn kò ní ìbálòpọ̀, tàbí kí wọ́n dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà ìbálòpọ̀ tó lè yọ wọ́n nínú ewu kíkó àrùn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àṣà ìbílẹ̀ kì í jẹ́ káwọn èèyàn lóye àrùn éèdì tàbí kí wọ́n kọ̀ láti gbà pé lóòótọ́ ni àrùn éèdì wà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé àwọn àjẹ́ ló wà nídìí àìsàn náà, tí wọ́n á sì máa tọ àwọn adáhunṣe lọ fún ìrànlọ́wọ́.
Àìsí àwọn ilé ìwòsàn tó péye. Àrùn éèdì ti túbọ̀ mú kí àwọn ilé ìwòsàn, èyí tí kò tó nǹkan tẹ́lẹ̀, máa kún àkúnya. Àwọn ọsibítù ńláńlá méjì ló sọ pé, ó ju ìlàjì lọ lára àwọn aláìsàn tó wà láwọn ọsibítù náà tí wọ́n ti kó kòkòrò tó lè fa àrùn éèdì. Ọ̀gá àgbà ọsibítù kan nílùú KwaZulu-Natal sọ pé, àwọn èèyàn tó ń wà nínú àwọn wọ́ọ̀dù òun máa ń fi ìlọ́po, ìlọ́po ju iye tí wọ́n ṣe wọ́n fún lọ. Nígbà míì, àwọn aláìsàn méjì ló jọ máa ń pín bẹ́ẹ̀dì kan lò, tí ẹnì kẹta á sì wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ lábẹ́ bẹ́ẹ̀dì náà!—Ìwé ìròyìn South African Medical Journal.
Pẹ̀lú bí ìṣòro yìí ṣe burú tó nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn ẹ̀rí ń fi hàn pé àfàìmọ̀ ni kò ní burú sí i. Peter Piot tó jẹ́ olùdarí Ètò Àjùmọ̀ṣe ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Lórí Àrùn Éèdì àti Kòkòrò Tó Ń Fà Á sọ pé: “Àrùn éèdì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣọṣẹ́ ni o, a ò tíì rí nǹkankan.”
Ẹ̀rí tó ṣe kedere wà pé, akitiyan ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan láti kojú àrùn náà. Bákan náà, fún ìgbà àkọ́kọ́, ní June 2001, Ẹgbẹ́ olùṣàkóso Gíga Jù Lọ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe ìpàdé pàtàkì kan láti jíròrò lórí kòkòrò tó lè yọrí sí àrùn éèdì àti àrùn éèdì fúnra rẹ̀. Ṣé akitiyan èèyàn á mú àṣeyọrí wá? Ìgbà wo gan-an ni àrùn éèdì tó ń pa àwọn èèyàn nípakúpa yìí máa dáwọ́ dúró pátápátá?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
OÒGÙN ÀÀRÙN ÉÈDÌ TÓ Ń JẸ́ NEVIRAPINE ÀTI ÌṢÒRO KÀǸKÀ TÓ Ń KOJÚ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ
Kí ló ń jẹ́ nevirapine? Gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn Nicole Itano ṣe sọ, ó jẹ́ “oògùn kan tí onírúurú àyẹ̀wò fi hàn pé ó lè dín ewu kí [ìyá] kó àrùn éèdì ran oyún inú kù sí ìlàjì.” Iléeṣẹ́ kan tó ń ṣe oògùn nílẹ̀ Jámánì sọ pé òún ṣe tán láti máa kó o fún orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà láìgba kọ́bọ̀ fún odindi ọdún márùn-ún. Síbẹ̀, títí oṣù August ọdún 2001, ìjọba orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà kò tíì tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn náà. Kí ló fà á?
Kò sí orílẹ̀-èdè mìíràn lágbàáyé táwọn alárùn éèdì pọ̀ sí tó ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, mílíọ̀nù mẹ́rin àti ọ̀kẹ́ márùndínlógójì èèyàn ló ti ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì náà níbẹ̀. Ìwé ìròyìn The Economist ti ìlú London sọ lóṣù February ọdún 2002 pé, Ààrẹ ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, Thabo Mbeki “kò gbà pé kòkòrò HIV ló ń fa àrùn éèdì gẹ́gẹ́ bí gbogbo èèyàn ṣe gbà,” bẹ́ẹ̀ “ló sì ń ṣiyèméjì nípa ìnáwó tó so mọ́ àwọn oògùn tí wọ́n sọ pé ó ń gbógun ti àrùn éèdì náà, ó tún ń ṣiyèméjì bóyá wọn ò léwu nínú àti pé bóyá wọ́n wúlò. Kò tíì fòfin dè wọ́n, àmọ́ wọn ò jẹ́ kí àwọn dókítà ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà lò wọ́n.” Kí ló dé tí èyí fi jẹ́ ọ̀ràn pàtàkì bẹ́ẹ̀? Nítorí pé lọ́dọọdún, nílẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ni wọ́n ń bí pẹ̀lú kòkòrò tó lè fa àrùn éèdì, ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn aboyún ló sì ní kòkòrò àrùn náà lára.
Nítorí àìgbọ́ra-ẹni-yé tó wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́ láti fipá mú ìjọba láti pín oògùn nevirapine. Oṣù April ọdún 2002 ni Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn nílẹ̀ Gúúsù Áfíríkà gbé ìdájọ́ rẹ̀ jáde. Gẹ́gẹ́ bí Ravi Nessman ti kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn The Washington Post, ó sọ pé, ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé “ìjọba gbọ́dọ̀ mú kí oògùn náà wà láwọn ilé ìwòsàn tó mọ bí wọ́n ṣe lè lò ó fún àwọn èèyàn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibùdó méjìdínlógún jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni ìjọba Gúúsù Áfíríkà ti ń pín oògùn náà láti kọ́kọ́ dán an wò ná, wọ́n sọ pé òfin tuntun náà ti ń fi àwọn aboyún tó ti ní kòkòrò tó lè fa àrùn éèdì ní orílẹ̀-èdè náà lọ́kàn balẹ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
KÒKÒRÒ ELÉTEKÉTE TÓ Ń TAN SẸ́Ẹ̀LÌ INÚ ARA JẸ
Dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀ ná kó o sì ronú nípa kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì, kó o sì fọkàn yàwòrán bó ṣe kéré bín-ń-tín tó. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé: “Lẹ́yìn àìmọye ọdún tí mo ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn egunrín kòkòrò nípa lílo awò amú-nǹkan-tóbi, orí mi ò tíì yé wú, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀lára mi ò sì tíì yé ru sókè nípa bí ohun tó kéré bín-ń-tín bẹ́ẹ̀, àní tó kéré gan-an, ṣe lè ní àwọn ètò pípé pérépéré tó sì tún díjú gan-an bẹ́ẹ̀.”
Kòkòrò bakitéríà kéré gan-an tá a bá fi wéra pẹ̀lú sẹ́ẹ̀lì inú ara ẹ̀dá èèyàn, síbẹ̀, kòkòrò tá à ń sọ yìí tún wá kéré gan-an lẹ́gbẹ̀ẹ́ kòkòrò bakitéríà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ti sọ, kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì kéré gan-an débi pé, “ọgbọ̀n lé rúgba [230] mílíọ̀nù [egunrín kòkòrò àrùn éèdì] á gba inú àmì ìdánudúró tó wà níparí gbólóhùn yìí.” Kòkòrò kan kò lè sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ àfi tó bá ráyè wọ inú sẹ́ẹ̀lì nínú ara tó sì gba agbára lọ́wọ́ sẹ́ẹ̀lì náà.
Nígbà tí kòkòrò tó ǹ fa àrùn éèdì bá dénú ara èèyàn, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ bá àwọn èròjà alágbára tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ètò ìdènà àrùn nínú ara wọ̀yá ìjà ná. a Mùdùnmúdùn inú egungun máa ń pèsè ètò ààbò kan tó ń gbógun ti àrùn, èyí tó ní àwọn sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ nínú. Àwọn sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ yìí ní àwọn èròjà méjì kan tí wọ́n ń pè ní T cell àti B cell. Àwọn sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ kan sì tún wà tó ń jẹ́ phagocytes, tàbí “àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń jẹ sẹ́ẹ̀lì inú ara.”
Onírúurú ìpele làwọn T cell yìí wà, iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ń ṣe. Àwọn sẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń pè ní helper T cell (sẹ́ẹ̀lì aṣèrànwọ́) máa ń ṣiṣẹ́ ribiribi láti gbógun ti àwọn ọ̀tá tó wọnú ara. Sẹ́ẹ̀lì yìí kan náà ló máa ń dá àwọn ohun tó jẹ́ àjèjì nínú ara mọ̀, tó sì máa pàṣẹ fún ara láti mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ sẹ́ẹ̀lì jáde sí i, èyí tó máa gbógun ti ọ̀tá náà tó sì máa pa á run. Àmọ́ tí kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì bá dénú ara èèyàn, àwọn sẹ́ẹ̀lì helper T cell to ń ṣèrànwọ́ yẹn gan-an ló máa ń dájú sọ. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan tó ń jẹ́ killer T cell (apá-sẹ́ẹ̀lì-run) náà á wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹrẹu, wọ́n á máa pa àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ọwọ́ ti tẹ̀ run. Àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń jẹ́ B cell ló ń mú àwọn èròjà agbógunti àrùn jáde, táwọn yẹn náà á sì dára pọ̀ mọ́ ọn ní bíbá àwọn kòkòrò tó ń fa àkóràn jà.
Ọgbọ́nkọ́gbọ́n Tí Kòkòrò Tí Ń Fa Àrùn Éèdì Ń Lò
Kòkòrò àrùn ni wọ́n ka kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì sí. Bí kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì ṣe ń ṣiṣẹ́ jọra pẹ̀lú bí àbùdá ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́. Kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì yìí jẹ́ ẹ̀ya kòkòrò àrùn kan tí wọ́n ń pè ní lentiviruses, torí pé kòkòrò yìí lè wà nínú ara fún àkókò gígùn kí àwọn àmì àrùn lílágbára tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa fara hàn.
Tí kòkòrò tó lè fa àrùn éèdì bá ti ráyè wọnú sẹ́ẹ̀lì kan, ó lè lo ọ̀nà tí sẹ́ẹ̀lì náà ń gbà ṣiṣẹ́ láti máa bá iṣẹ́ jàǹbá tirẹ̀ lọ. Á “yí ètò ìṣiṣẹ́ sẹ́ẹ̀lì náà padà” tíyẹn á sì wá máa mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ kòkòrò ti ń fa àrùn éèdì jáde. Àmọ́ kí kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì tó lè ṣe èyí, ó gbọ́dọ̀ lo “ọ̀nà” mìíràn tó yàtọ̀. Ó gbọ́dọ̀ yí ìlànà tirẹ̀ náà padà lọ́nà tó fi máa bá ti sẹ́ẹ̀lì inú ara náà mu, kí ìyẹn lè máa rò pé ara òun ni. Kí kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì lè ṣe èyí yọrí, ó máa ń lo èròjà kan tó ń jẹ́ transcriptase, èyí tó máa ń yí ìlànà padà. Bí àkókò ti ń lọ, sẹ́ẹ̀lì inú ara náà á kú, àmọ́ nígbà yẹn, á ti mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn egunrín kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì jáde. Àwọn egunrín tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí á wá máa lọ kéèràn ran àwọn sẹ́ẹ̀lì mìíràn nínú ara.
Gbàrà tí àwọn helper T cell aṣèrànwọ́ bá ti dín kù jọjọ, àwọn ọ̀tá mìíràn á wá ráyè gbéjà ko gbogbo ara láìsí ìbẹ̀rù pé sẹ́ẹ̀lì kankan ń gbógun tì wọ́n. Ni ará á bá juwọ́ sílẹ̀ fún onírúurú àìsàn àti àkóràn. Ẹni tó ní àkóràn náà ti di alárùn éèdì gidi nìyẹn. Kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì ti ṣàṣeyọrí, ó ti sọ gbogbo agbára ìdènà àrùn ara onítọ̀hún di aláìlágbára.
Ọ̀nà tó rọrùn tá a lè fi ṣàlàyé kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì nìyí. Àmọ́ a ò ní gbàgbé pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà táwọn olùṣèwádìí kò mọ̀ nípa agbára tó ń dènà àrùn nínú ara àti bí kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì ṣe ń ṣọṣẹ́.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún ọdún báyìí tí kòkòrò bín-ń-tín yìí ti ń fi àjùlọ han àwọn onímọ̀ ìṣègùn jàǹkànjàǹkàn tí wọ́n ń ṣèwádìí tọ̀sán-tòru lórí rẹ̀, èyí sì ti jẹ òbítíbitì owó. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ti tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì. Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, Sherwin B. Nuland, tó jẹ́ dókítà oníṣẹ́ abẹ sọ pé: “Ohun ìyàlẹ́nu gbáà ni gbogbo ìsọfúnni . . . tá a ti kó jọ pelemọ nípa kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì jẹ́, bákan náà ni ìtẹ̀síwájú tá a ti ṣe láti kojú ìkọlù rẹ̀ pabanbarì.”
Síbẹ̀, bí àrùn éèdì ṣe ń pa àwọn èèyàn nípakúpa yìí kò dáwọ́ dúró o, ó ṣì ń bá a lọ láti máa gbẹ̀mí àwọn èèyàn lọ́nà tó ń dáyà foni.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí! (Gẹ̀ẹ́sì) ti February 8, 2001, ojú ìwé 13 sí 15.
[Àwòrán]
Kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì máa ń gbéjà ko àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń dènà àrùn nínú ara tá á sì yí wọn padà láti máa mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì jáde
[Credit Line]
CDC, Atlanta, Ga.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ ló ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì