Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹlẹ́sìn Tìtorí Àlàáfíà Pé Jọ sí Ìlú Assisi

Àwọn Ẹlẹ́sìn Tìtorí Àlàáfíà Pé Jọ sí Ìlú Assisi

Àwọn Ẹlẹ́sìn Tìtorí Àlàáfíà Pé Jọ sí Ìlú Assisi

“Kí ìwà ipá di ohun ìgbàgbé! Kógun máà tún gbérí mọ́ láé! Ká máà rí ìpániláyà mọ́! Lórúkọ Ọlọ́run, kí gbogbo ẹ̀sìn pawọ́ pọ̀ láti mú ìdájọ́ òdodo, àlàáfíà, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwàláàyè, àti ìfẹ́ wá sórí ilẹ̀ ayé o!”—Póòpù John Paul Kejì ló gbàdúrà bẹ́ẹ̀.

ÌLÚ Assisi, lórílẹ̀-èdè Ítálì, ni ìpàdé náà ti wáyé ní January 24, 2002. Lọ́jọ́ yẹn, àwọn aṣojú látinú àwọn ẹ̀sìn ayé lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan kóra jọ sí ìlú náà láti gbàdúrà fún àlàáfíà, níwọ̀n bí ìpániláyà, àìráragba-nǹkan-sí, àti ìwà ìrẹ́nijẹ ti ń fi àlàáfíà ayé sínú ewu. Póòpù ló pe ìpàdé ọ̀hún ní oṣù méjì lẹ́yìn tí àwọn Ilé Gogoro Méjì wó lulẹ̀ ní ìlú New York City. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ló fi tọkàntọkàn jẹ́ ìpè yìí tó wá láti ibùjókòó ìjọba póòpù tí a mọ̀ sí Vatican.

Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣáájú èyí, ìyẹn lọ́dún 1986 àti lọ́dún 1993, ni póòpù ti pe ìpàdé ọlọ́jọ́ kan láti fi gbàdúrà ní ìlú Assisi yìí kan náà. a Àwọn akọ̀ròyìn tó wá láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti wá wo bí ìpàdé ti ọdún 2002 yìí ṣe máa lọ sí lé ní ẹgbẹ̀rún kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsìn ló rán aṣojú wá síbi àdúrà fún àlàáfíà yìí—àwọn ìsìn tó jẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù (ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, àwọn ọmọlẹ́yìn Luther, àwọn onísìn Áńgílíkà, àwọn onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àwọn onísìn Mẹ́tọ́díìsì, àwọn Onítẹ̀bọmi, àwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn, àwọn Mennonite, àwọn Quaker, àtàwọn mìíràn). Àwọn aṣojú kò ṣàì tún wá látinú ẹ̀sìn Ìsìláàmù, Híńdù, Confucius, Sikh, Jain, Tenrikyo, Buddha, ìsìn àwọn Júù, àwọn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Áfíríkà, Shinto, àti Zoroaster. Àwọn aṣojú látinú àwọn ẹ̀sìn mìíràn, àti ẹnì kan tó ń ṣojú fún Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé, tún bá wọn pésẹ̀ síbi ìpàdé náà.

Ìrawọ́ Ẹ̀bẹ̀ Nítorí Kí Àlàáfíà Lè Wà

Ayẹyẹ ọjọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́sàn-án ku ogún ìṣẹ́jú ní òwúrọ̀, nígbà tí “ọkọ̀ ojú-irin àlàáfíà” kúrò ní ibùdókọ̀ ojú irin kékeré kan ní ìlú tí í ṣe Ibùjókòó Ìjọba Póòpù. Ọkọ̀ òfuurufú hẹlikóbítà méjì ló ń dáàbò bo ọkọ̀ ojú irin onílé méje náà bó ti ń lọ, èyí tí wọ́n ti ṣe inú rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ tó sì ní àwọn ohun ìdẹ̀ra. Póòpù àtàwọn aṣáájú ìsìn yòókù rìnrìn àjò fún wákàtí méjì kí wọ́n tó dé ìlú Assisi. Wọn kò fi ọ̀ràn ààbò ṣeré rárá, kódà nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọlọ́pàá ló wà ní sẹpẹ́ láti kápá ewu tàbí rúkèrúdò èyíkéyìí.

Àwọn aṣáájú ìsìn náà kóra jọ sí gbàgede ńlá kan tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́, èyí tí wọ́n fi ìbòrí fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ bò. Nínú gbàgede náà, gbogbo àwọn aṣojú ìsìn náà jókòó lọ lápátùn-ún àti lápásì pèpéle ńlá kan tí wọ́n kùn ní àwọ̀ pupa, tí àga póòpù sì wà láàárín. Igi ólífì kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pèpéle náà, èyí tó dúró fún àlàáfíà. Níwájú pèpéle náà làwọn àlejò, tí wọ́n ti fara balẹ̀ yàn, tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì jókòó sí. Díẹ̀ lára àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba lórílẹ̀-èdè Ítálì ló jókòó lọ́wọ́ iwájú. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ orin ìsìn tó dá lórí àlàáfíà bí ẹnì kan bá ti sọ̀rọ̀ tán kí ẹlòmíràn tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Láwọn àgbègbè mìíràn nínú ìlú náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ọ̀dọ́langba, ń gbé àwọn bébà tí wọ́n ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé wọ́n lòdì sí ogun kiri lóríṣiríṣi èdè, wọ́n sì tún ń kọrin nípa àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ mú ẹ̀ka igi ólífì dání.

Lẹ́yìn tí póòpù ti jókòó sáyè rẹ̀ lórí pèpéle náà, ó kí àwọn aṣojú tó wá látinú onírúurú ìsìn náà káàbọ̀. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi èdè Látìn kọ orin ìsìn kan tí wọ́n gbé ka Aísáyà 2:4—èyí tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àkókò tí “orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè”—àwọn aṣojú méjìlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wọ aṣọ ìsìn tó yàtọ̀ síra wọn gédégédé, wá ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tọkàntọkàn nítorí àlàáfíà. Díẹ̀ nìwọ̀nyí lára àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n ṣe.

“Ní àkókò mánigbàgbé yìí nínú ìtàn, ó yẹ kí aráyé rí àwọn àmì tó ń fi hàn pé a fẹ́ kí àlàáfíà jọba, kí wọ́n sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí.”—Kádínà François Xavier Nguyên Van Thuân.

Ọlọ́run “kì í ṣe Ọlọ́run ogun àti rúkèrúdò ṣùgbọ́n ó jẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà.”—Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Bartholomeus Kìíní.

“Kò yẹ kí àìfohùnṣọ̀kan ẹ̀sìn sún [àwọn èèyàn] láti máa ṣá àwọn tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí tiwọn tì, tàbí kí wọ́n máa kórìíra wọn.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Setri Nyomi, aṣojú fún Àjọ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe Lágbàáyé.

“Àìṣègbè àti ìfẹ́ ará jẹ́ nǹkan pàtàkì méjì tó lè mú kí ojúlówó àlàáfíà ṣeé ṣe láàárín àwọn èèyàn.”—Olóyè Amadou Gasseto, aṣojú fún àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Áfíríkà.

“Àlàáfíà nìkan ló jẹ́ mímọ́, ogun kì í ṣe ohun mímọ́ rárá!”—Andrea Riccardi, aṣojú fún Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Àwọn aṣojú kan gbà pé àwọn ìsìn jẹ̀bi tó pọ̀ gan-an fún bí wọ́n ṣe ń súnná sí ẹ̀tanú ìsìn àti ogun. Aṣojú Ẹ̀sìn Luther Lágbàáyé sọ pé ayé ti “mì tìtì nítorí ìwà ìkà bíburú jáì tí ìgbónára ẹ̀sìn ṣokùnfà rẹ̀.” Ẹni tó jẹ́ aṣojú fún ẹ̀sìn àwọn Júù sọ pé: “Ìsìn ti dá kún àìmọye ogun bíburú jáì tó ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” Aṣojú ẹ̀sìn Híńdù sọ ní tirẹ̀ pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn léraléra pé, àwọn kan tó ń pariwo pé olùgbèjà ẹ̀sìn làwọn ti lo ìsìn láti fi darí àwọn èèyàn àti láti fi dá ìyapa sílẹ̀.”

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi taratara bẹnu àtẹ́ lu ìpániláyà àti ogun, àwọn aṣojú náà padà lọ jókòó sí àyè tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, kí kálukú lè gbàdúrà sí ọlọ́run tirẹ̀ fún àlàáfíà.

Àdúrà fún Àlàáfíà

Àwọn aṣojú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù gbàdúrà pa pọ̀ ní apá ìsàlẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Basilica ti St. Francis, nítòsí sàréè tí wọ́n fi sọ ṣọ́ọ̀ṣì náà lórúkọ. Àdúrà wọn bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí póòpù àtàwọn aṣojú mẹ́ta mìíràn ti ṣe “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Mẹ́talọ́kan.” Wọ́n ń kọ orin ìsìn, wọ́n sì ń ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà láàárín àdúrà náà, bákan náà ni Bíbélì kíkà lórí ọ̀ràn àlàáfíà náà tún ń wáyé lásìkò kan náà. Nínú àdúrà kan, wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run pé kó ṣe ìdásílẹ̀ “ẹ̀sìn kan tí kò ní ìyapa nínú.” Láti kádìí ayẹyẹ náà, àwọn tí wọ́n kópa nínú àdúrà náà fi èdè Látìn kọ orin Àdúrà Olúwa, èyí tí wọ́n gbé ka ìwé Mátíù orí 6, ẹsẹ 9 sí 13.

Lásìkò kan náà, àwọn aṣojú látinú àwọn ẹ̀sìn yòókù náà ń gbàdúrà tiwọn láwọn àgbègbè mìíràn. Nínú gbọ̀ngàn kan tí wọ́n yíjú rẹ̀ sí ìhà tí ìlú Mẹ́kà wà, àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n kúnlẹ̀ sórí kápẹ́ẹ̀tì ń ké pe Allah. Àwọn ẹlẹ́sìn Zoroaster, tí wọ́n ń gbàdúrà tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn Jain àtàwọn ẹlẹ́sìn Confucius, tan iná mímọ́ kan tí ń jó. Àwọn tó ń ṣojú fún àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Áfíríkà gbàdúrà sí ẹ̀mí àwọn babańlá wọn. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà látọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́run wọn. Gbogbo wọn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọlọ́run wọn níbàámu pẹ̀lú ààtò ìjọsìn kálukú wọn.

Wọ́n Jọ Ṣe Àdéhùn Láti Lépa Àlàáfíà

Àwọn aṣojú náà tún péjọ pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i lábẹ́ àtíbàbà náà láti mú ayẹyẹ náà wá sí òpin. Àwọn àtùpà tó ń jó—èyí tó ń ṣojú fún ìrètí àlàáfíà—ni àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn aṣojú náà. Ìran ọ̀hún dùn ún wò. Lẹ́yìn náà ni àwọn kọ̀ọ̀kan lára àwọn aṣojú náà ka àwọn àkọsílẹ̀ wọn lórí àdéhùn tí wọ́n jọ ṣe láti lépa àlàáfíà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń ṣe ìpolongo ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

“Mímú kí àlàáfíà wà ń béèrè pé kí olúkúlùkù nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀.”—Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Bartholomeus Kìíní.

“Ìwà ipá àti ìpániláyà forí gbárí pẹ̀lú ohun tí ìsìn túmọ̀ sí ní ti gidi.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Konrad Raiser, aṣojú fún Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé.

“A ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa fi ọ̀wọ̀ àti iyì tọ̀túntòsì kọ́ àwọn èèyàn.”—Bhai Sahibji Mohinder Singh, aṣojú fún ẹ̀sìn Sikh.

i“Àlàáfíà tó bá ti ní ojúsàájú nínú kì í ṣe ojúlówó àlàáfíà.”—Bíṣọ́ọ̀bù Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Vasilios.

Níkẹyìn, póòpù ka ọ̀rọ̀ tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sókè. Nígbà tí ìpàdé alámùúlùmálà ìgbàgbọ́ yìí parí, àwọn aṣojú tó pésẹ̀ náà fọwọ́ gbá ara wọn mọ́ra gẹ́gẹ́ bí àmì àlàáfíà. Wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in tí wọ́n ti fara balẹ̀ múra rẹ̀ sílẹ̀, ṣekárími àti afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ìpàdé ọ̀hún sì kúrò ní kékeré. Àmọ́, ojú wo làwọn èèyàn fi wo ayẹyẹ tó fakíki yìí?

‘Bí Wọ́n Bá Máa Jẹ́ Ṣe Ohun Tí Wọ́n Jẹ́Jẹ̀ẹ́ Rẹ̀’

Àwọn ìwé ìròyìn àti tẹlifíṣọ̀n kan sáárá sí ìgbésẹ̀ tí póòpù gbé yìí. Kódà àwọn kan pe póòpù ní “agbẹnusọ fún gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Kristi.” Ìwé ìròyìn Ibùjókòó Ìjọba Póòpù tí ń jẹ́ L’Osservatore Romano sọ pé, ayẹyẹ tí wọ́n ṣe ní ìlú Assisi lọ́jọ́ náà jẹ́ “ìgbésẹ̀ pàtàkì kan tó máa ṣamọ̀nà sí jíjẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbé ní àlàáfíà.” Àkọlé gàdàgbà tó wà nínú ìwé ìròyìn Corriere dell’Umbria sọ pé: “Assisi Tan Ìmọ́lẹ̀ sí Àlàáfíà.”

Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tó fara balẹ̀ kíyè sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wú lórí. Ìpàdé náà ń kọ àwọn kan lóminú torí pé, láìka bí wọ́n ṣe gbàdúrà láwọn ọjọ́ àdúrà fún àlàáfíà lọ́dún 1986 àti 1993 sí, àwọn ogun táwọn èèyàn ń jà látàrí ọ̀ràn ẹ̀sìn kò yé dààmú aráyé. Ìkórìíra tí ẹ̀sìn dá sílẹ̀ ti súnná sí ìpakúpa ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀ ní ilẹ̀ Uganda, Yugoslavia àtijọ́, Indonesia, Pakistan, Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, àti Àríwá Ireland.

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ítálì kan tó ń jẹ́ La Repubblica sọ pé, àwọn kan tó ń ṣe lámèyítọ́ ìpàdé náà bẹnu àtẹ́ lù ú nípa sísọ pé “afẹfẹyẹ̀yẹ̀ lásán-làsàn” ni. Ẹnì kan tó jẹ́ ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé, kí àlàáfíà tó lè wà, àwọn ẹlẹ́sìn gbọ́dọ̀ “fi ohun tí Ìhìn Rere sọ ṣèwà hù”—ìyẹn ni pé, kí wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì sí wọn.” Ó sọ pé lójú tòun, “kò sẹ́ni tó ń ṣe” bẹ́ẹ̀.

Alága Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́sìn Júù nílẹ̀ Ítálì sọ pé “ká máa wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ló kù báyìí, bí wọ́n bá máa ṣe ohun tí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe, tí wọ́n á sì mú kí àyípadà gidi wà.” Aṣojú fún àwọn Ẹlẹ́sìn Buddha nílẹ̀ Ítálì náà sọ kókó kan tó jọra nípa sísọ pé kálukú gbọ́dọ̀ “rí i dájú pé àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà so èso rere, kì í ṣe pé ká kàn máa rò ó lọ́kàn lásán.” Akọ̀ròyìn kan tó ń kọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn L’Espresso ti ilẹ̀ Ítálì sọ pé, ìpàdé tó wáyé ní ìlú Assisi tún ṣiṣẹ́ fún ète mìíràn yàtọ̀ sí ti ọ̀ràn àlàáfíà tí àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù torí rẹ̀ rán aṣojú lọ síbẹ̀. Ó pè é ní “ìgbáríjọ àwọn ẹlẹ́sìn láti kọjúùjà sí àìfẹ́-ṣẹ̀sìn, àìmọ̀wàáhù, àti àìnígbàgbọ́.” Bákan náà ló tún jẹ́ ìsapá láti gbógun ti “ìdágunlá sí ẹ̀sìn lọ́nà tó lékenkà,” èyí tó ń wáyé ní ilẹ̀ Yúróòpù láìka “bí ìtàn ti fi hàn pé ẹlẹ́sìn Kristi ni látilẹ̀wá” sí.

Lára àwọn tó ṣe àríwísí púpọ̀ jù sí ìpàdé náà ni àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tí kò fẹ̀sìn ṣeré, tí wọ́n ń kọminú pé ó lè sọ àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì di yẹpẹrẹ. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan lórí tẹlifíṣọ̀n, gbajúgbajà òǹkọ̀wé ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Vittorio Messori sọ pé, ayẹyẹ tó wáyé ní ìlú Assisi lè máà jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀sìn mọ́. Ká sòótọ́, àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan ṣáájú kó má bàa dà bíi pé wọ́n ń ṣe àmúlùmálà ẹ̀sìn. Póòpù gan-an fúnra rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ kan láti fi já irú ìfẹ̀sùnkanni bẹ́ẹ̀ ní koro. Síbẹ̀síbẹ̀, lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, ó dà bíi pé ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ayẹyẹ náà fi hàn pé àwọn onírúurú ìsìn wọ̀nyẹn wulẹ̀ ń ṣojú fún oríṣiríṣi ọ̀nà láti fi ké pe Ọlọ́run kan náà ni.

Ìsìn àti Àlàáfíà

Àmọ́, kí wá ni àwọn ètò ẹ̀sìn ayé lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan lè ṣe láti fi mú kí àlàáfíà wà? Ìbéèrè yẹn ń kọ àwọn èèyàn kan lóminú, nítorí pé ó dà bíi pé ohun táwọn ìsìn ń ṣe láti fi ṣokùnfà ogun ju ohun tí wọ́n ń ṣe láti fi dènà rẹ̀ lọ. Àwọn òpìtàn ti kọ̀wé nípa ọ̀nà tí àwọn ìjọba ayé ti gbà lo ìsìn láti fi súnná sí ogun. Bó ti wù kó rí, ìbéèrè kan tó dìde ni pé: Kí ló dé táwọn ìsìn fi ń jẹ́ kí wọ́n lo àwọn?

Ó kéré tán, àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ní òfin àtọ̀runwá kan níkàáwọ́ wọn, èyí tí ì bá ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹ̀bi tí ogun jíjà ń mú wá. Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kì yóò jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:16) Ká ní àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílò ni, wọn ì bá má dara wọn pọ̀ mọ́ àwọn ìjọba olóṣèlú, nípa fífi ojúure wo àwọn ológun àti ogun, àti nípa gbígbàdúrà fún wọn.

Ní tòótọ́, tí wọ́n bá fẹ́ hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ dídùn tí wọ́n sọ ní ìlú Assisi, àwọn aṣáájú ìsìn gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún àwọn ìjọba olóṣèlú. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n ní láti fi ọ̀nà àlàáfíà kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn òpìtàn ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn tó gba Ọlọ́run gbọ́—tàbí tí wọ́n ń sọ ọ́ lẹ́nu pé àwọ́n gbà á gbọ́—ló ń hu ìwà ipá inú ayé. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀rọ̀ olóòtú inú ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Kò pẹ́ lẹ́yìn Sept. 11, ẹnì kan kọ àwọn ọ̀rọ̀ amúnironújinlẹ̀ wọ̀nyí sára ògiri kan nílùú Washington, D.C.: ‘Ọlọ́run wa ò, mà jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ àwọn tó gbà ọ́ gbọ́.’”

Gbogbo ṣekárími àti afẹfẹyẹ̀yẹ̀ tó wáyé ní ìlú Assisi fi àwọn ìbéèrè kan tó ta kókó sílẹ̀ láìdáhùn. Àmọ́, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù—tàbí tó ta kókó jù—tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi tọkàntọkàn ṣẹ̀sìn ń wá ìdáhùn sí ni pé: Kí ló dé tí Ọlọ́run kò fi tíì dáhùn àwọn àdúrà fún àlàáfíà táwọn ìsìn ayé ń gbà sí i látọjọ́ yìí wá?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ọjọ́ àdúrà fún àlàáfíà ti ọdún 1986, jọ̀wọ́ wo Jí! December 8, 1987.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn aṣojú ìsìn ń gba àtùpà tí ń jó—èyí tó ń ṣojú fún ìrètí àlàáfíà

[Credit Line]

AP Photo/Pier Paolo Cito

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

AP Photo/Pier Paolo Cito