Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́

Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́

Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́

GẸ́GẸ́ BÍ LADISLAV ŠMEJKAL ṢE SỌ Ọ́

Lẹ́yìn tí wọ́n ti dá ẹjọ́ mi, wọ́n dá mi padà sínú yàrá ẹ̀wọ̀n mi. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí fàmì sọ̀rọ̀ sí ọ̀rẹ́ mi tó wà ní àjà kejì nípa títa ògiri pẹ́pẹ́. Ó ti ń dúró láti gbọ́ iye ọdún tí wọ́n dá fún mi.

Mo rọra fọwọ́ ta ògiri pẹ́pẹ́ pé: “Ọdún mẹ́rìnlá.”

Kò gbà mí gbọ́. Lòun náà bá ta ògiri pẹ́pẹ́ padà pé: “Ṣé oṣù mẹ́rìnlá lo pè é?”

Mo wá dá a lóhùn pé: “Rárá, àní ọdún mẹ́rìnlá.”

ỌDÚN 1953 lèyí ṣẹlẹ̀. Ibi tó ti ṣẹlẹ̀ ni ìlú Liberec, ní orílẹ̀-èdè Czechoslovakia (tó ti wá di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech báyìí). Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tó ti gbé ọ̀rọ̀ ìṣèlú karí ni mí nígbà náà, tí mò ń wá ìyípadà lójú méjèèjì nínú ìṣèlú. Àwa tí à ń wá ìyípadà nínú ìṣèlú máa ń polongo èrò ọkàn wa nípa pínpín àwọn ìwé pélébé tó ń tàbùkù Ìjọba Kọ́múníìsì, èyí tó ń ṣàkóso nígbà náà. Ẹ̀sùn pé a fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ wa dé ni wọ́n fi kàn wá fún ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ wa—èyí ló mú kí wọn ní kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ bẹ́ẹ̀.

Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún kan látìmọ́lé kí wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ẹjọ́ mi. Kí wọ́n tó dá ẹjọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, méjì-méjì ni wọ́n máa ń tì wọ́n mọ́ ibì kan náà, wọ́n sì máa ń mú wọn jáde lóòrèkóòrè pẹ̀lú ojú wọn tí wọ́n fi aṣọ dì láti lọ fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Wọn ò gbà wá láyè láti sọ̀rọ̀ tá a bá wà nínú ibi tí wọ́n tì wá mọ́, nítorí náà ńṣe la máa ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ tàbí ká máa fi àmì bá ara wa sọ̀rọ̀ nípa títa ògiri pẹ́pẹ́.

Kò pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wá sí, wọ́n máa ń pààrọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó jọ wà nínú yàrá kan náà lóṣooṣù tàbí lóṣù méjìméjì. Níwọ̀n bí mo ti nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, inú mi dùn nígbà tí wọ́n fi mí sínú yàrá kan náà pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí kan lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kò pẹ́ sígbà náà tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo rò pé kò lòdì láti pe àwọn ìjíròrò wa ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní Bíbélì tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí. Àní, ní gbogbo àsìkò yẹn, mi ò tíì fojú ba Bíbélì rí láyé mi. Àmọ́ a jọ máa ń sọ̀rọ̀—Ẹlẹ́rìí náà máa ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì fún mi láìmú ìwé kankan dání—mo sì máa ń ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń sọ. Ká tó lè ṣe gbogbo èyí, ńṣe la máa jókòó sún mọ́ra wa pẹ́kípẹ́kí tí àá sì rọra máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

Gbogbo ohun tá a ní kò ju bébà anùdọ̀tí àti kóòmù lọ. Kóòmù yìí ni mo máa ń fi kọ ọ̀rọ̀ sórí bébà anùdọ̀tí. Mo há ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a jíròrò náà sórí. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ tún kọ́ mi láwọn orin Ìjọba Ọlọ́run. Ẹlẹ́rìí kan sọ fún mi pé: “Báyìí, ò ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí pé o jẹ́ arúfin nídìí ọ̀ràn ìṣèlú, àmọ́ ó lè dọ̀la kó o tún bára ẹ lẹ́wọ̀n nítorí pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò láìmọye ìgbà, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún mi, wọ́n sì gbé mi lọ sí àgọ́ iṣẹ́ àṣekú kan tó wà nítòsí ìlú Jáchymov. Nígbà yẹn, ó ti dá mi lójú pé lọ́jọ́ kan, mo máa di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo Ṣe Ọ̀pọ̀ Ọdún Nínú Ẹ̀wọ̀n

Nígbà tí mo dé sí àgọ́ náà, níbi tí wọ́n ti ń wa èròjà uranium jáde látinú ilẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn Ẹlẹ́rìí kiri. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo gbọ́ pé wọ́n ti kó wọn lọ síbòmíràn. Àmọ́, ó ṣẹ́ ku Ẹlẹ́rìí kan, nítorí pé ó máa ń se oúnjẹ fún wọn níbẹ̀. Ó yá mi ní Bíbélì kan tó ti gbó, èyí tí wọ́n ti fi pa mọ́ sí oríṣiríṣi ibi. Èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo ti há ságbárí. Bí mo bá ti ń kà á ni màá máa sọ fún ara mi pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, báwọn arákùnrin yẹn ṣe kọ́ mi gẹ́lẹ́ ló rí.’

Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbé mi lọ sí àgọ́ kan tí wọ́n ń pè ní Bytiz, nítòsí ìlú Příbram. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn. Ní àgọ́ Bytiz yìí, a máa ń rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà déédéé, èyí táwọn kan ń yọ́ mú wọlé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alábòójútó àgọ́ náà gbìyànjú láti mọ bó ṣe ń tẹ̀ wá lọ́wọ́, wọn ò rídìí rẹ̀. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n tó mẹ́rìnlá máa ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn nígbà gbogbo. Ìdajì lára àwọn wọ̀nyí jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe batisí, àwọn ìdajì tó kù kò sì yàtọ̀ sí mi, ìyẹn àwa tó jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n la ti ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ẹ̀sìn àwọn Ajẹ́rìí.

Ọ̀pọ̀ lára wa ló wù láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. Àmọ́ nítorí pé kò sí omi, tàbí kí n kúkú sọ pé kò sí nǹkan tó lè gba omi téèyàn lè fi ṣèrìbọmi, èyí kò jẹ́ kí ìrìbọmi rọrùn rárá láti ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, láwọn àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ ní láti dúró títí dìgbà tí wọ́n máa tó jáde lẹ́wọ̀n kí wọ́n tó lè ṣe batisí. Àmọ́ nínú àgọ́ Bytiz, àwọn ilé gogoro kan wà tó ní omi nínú, èyí tí wọ́n ń lò fún ẹ̀rọ tó ń mú kí afẹ́fẹ́ tútù ní iléeṣẹ́ ìwakùsà náà. Láàárín àwọn ọdún 1955 sí 1959, wọ́n batisí àwa bíi mélòó kan nínú táǹkì kan tí omi ń ro sí látinú ọ̀kan lára àwọn ilé gogoro náà.

Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní March 1960, ọ̀gá ọlọ́pàá kan tó ń ṣe kòkáárí ọ̀rọ̀ àwọn tó bá ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ní kí n wá rí òun. Ó ní tí n bá lè sọ nípa ìgbòkègbodò àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù fún òun, òún á ṣètò bí iye ọdún tó yẹ kí n lò lẹ́wọ̀n ṣe máa dín kù. Nígbà tí mo kọ̀ láti sọ fún un, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò èébú lé mi lórí. Ó pariwo lé mi pé: “O kàn sọ ìfà tó o ní láti gbòmìnira nù ni. Màá rí i pé o ò padà sí ilé rẹ mọ́! Ibi tó o máa kú sí lo wà yìí.” Àmọ́, oṣù méjì lẹ́yìn náà, wọ́n fún mi ní ìdáríjì tó tọ́ sí mi látọ̀dọ̀ ìjọba, mo sì padà sílé lẹ́yìn tí mo ti lo àpapọ̀ ọdún mẹ́jọ lẹ́wọ̀n.

Àkókò Òmìnira Díẹ̀

Láti oṣù April ọdún 1949 ni wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Czechoslovakia, kò sì pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé díẹ̀ ni òmìnira tí mo ṣì ń rò pé mo ní láti sin Ọlọ́run fi sàn ju ìgbà tí mo wà lẹ́wọ̀n lọ. Nísìnyí tí wọ́n ti wá dá mi sílẹ̀, mo tún dojú kọ ìṣòro mìíràn. Lásìkò yẹn, ìjọba sọ ọ́ di dandan fún gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà lórílẹ̀-èdè náà láti ṣiṣẹ́ ológun fún ọdún méjì.

Wọ́n máa ń yọ̀ọ̀da àwọn ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ láwọn iléeṣẹ́ Ìjọba kan láti má ṣe wọṣẹ́ ológun. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa èédú nírú òmìnira bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bí mo ti ṣiṣẹ́ ìwakùsà rí, mo wáṣẹ́ lọ sí ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Nígbà tí mo débẹ̀, wọ́n gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Wọ́n sì sọ fún mi pé: “Má ṣèyọnu nípa iṣẹ́ ológun o. Àá rí sí i pé wọn ò mú ẹ wọ̀ ọ́.”

Oṣù méjì lẹ́yìn ìgbà náà, nígbà tí mo gba ìwé kan tó sọ pé mo gbọ́dọ̀ wá wọ iṣẹ́ ológun, àwọn aláṣẹ ibi ìwakùsà náà tún dá mi lọ́kàn le, wọ́n ní: “Fọkàn rẹ balẹ̀, bóyá wọ́n ṣàṣìṣe ni. Àá rí i pé a kọ̀wé sí iléeṣẹ́ àwọn ológun, ọ̀ràn ọ̀hún á sì yanjú.” Àmọ́ kò yanjú o. Kò pẹ́ kò jìnnà, ọ̀gá kan níbẹ̀ wá bá mi ó sì bẹ̀ mí, ó ní: “Irú nǹkan báyìí kò ṣẹlẹ̀ rí, ó jọ pé o níláti lọ fún iṣẹ́ ológun o.” Nígbà ti mo kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ológun nítorí pé ẹ̀rí ọkàn mi kò yọ̀ọ̀da fún mi, wọ́n fàṣẹ ọba mú mi wọ́n sì gbé mi lọ sí ẹ̀ka àwọn ológun kan tó wà nítòsí.—Aísáyà 2:4.

Mo Fojú Ba Ilé Ẹjọ́

Lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ mí sẹ́wọ̀n nílùú Kladno ní January ọdún 1961, àwọn ológun ta oríṣiríṣi ọgbọ́n láti rí i pé àwọ́n yí mi lọ́kàn padà kí n lè di sójà. Ọ̀gá ológun kan tó ń bójú tó ẹ̀wọ̀n náà ṣètò ìpàdé kan. Wọ́n mú mi lọ sí yàrá àpérò kan tí tábìlì ńlá kan wà, èyí tí wọ́n to àwọn àga dẹ̀ǹkù-dẹ̀ǹkù yí ká. Láìpẹ́, àwọn lọ́gàá-lọ́gàá nínú iṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ sí í dé tí wọ́n sì ń jókòó yí tábìlì náà ká. Ni alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n hàn mí lọ́kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà ló wá jókòó tó sì sọ pé: “Ó yá, a fẹ́ kó o ṣàlàyé ìsìn rẹ yìí fún wa ká gbọ́.”

Lẹ́yìn tí mo ti yára gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwùjọ tó tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa náà sọ̀rọ̀. Kò pẹ́ tí ìjíròrò náà fi yí padà tó di ti ẹfolúṣọ̀n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé sáyẹ́ǹsì jẹ́rìí sí ẹfolúṣọ̀n. Mo ti ka ìwé kékeré náà, Evolution Versus the New World a nínú àgọ́ iṣẹ́ àṣekú kan tí mo ti kọ́kọ́ wà rí. Nípa bẹ́ẹ̀, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ọ̀gá ológun náà láti rí i pé mo lè pèsè àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àbá èrò orí lásánlàsàn tí kò ṣeé ṣàlàyé ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n jẹ́.

Lẹ́yìn náà ni ọ̀gá sójà kan tó hàn gbangba pé ìdílé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló ti wá dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó béèrè pé: “Irú ẹni wo lẹ ka Màríà Wúńdíá sí? Kí sì ni èrò yín nípa Máàsì mímọ́?” Lẹ́yìn tí mo ti dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀, mo wá fi kún un pé: “Ọ̀gá, mo rí i pé ẹ ní láti jẹ́ onígbàgbọ́, nítorí pé àwọn ìbéèrè yín yàtọ̀ sí tàwọn yòókù.”

Ló bá yarí tó sì pariwo pé: “Rárá o! Rárá àti rárá! Èmi kì í ṣe onígbàgbọ́ o!” Lábẹ́ Ìjọba Kọ́múníìsì, wọn kì í fojú ẹni gidi wo àwọn tó bá pera wọn ní Kristẹni bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ fún wọn ní ẹrù iṣẹ́, ìyẹn tí wọ́n bá tiẹ̀ fún wọn rárá nìyẹn. Nítorí náà, lẹ́yìn ìbéèrè tó bi mí yẹn tí mo sì fún un ní ìdáhùn, ọkùnrin ológun náà kò dá sí ìjíròrò náà mọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ọkàn mi kún fún ọpẹ́ gan-an fún àǹfààní tí mo ní yìí láti ṣàlàyé ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn.

Àwọn Àǹfààní Mìíràn Láti Jẹ́rìí Tún Yọjú

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbé mi lọ sílé àwọn ológun kan tó wà nílùú Prague, wọ́n sì fi àwọn sójà síbẹ̀ láti máa ṣọ́ mi. Ẹnu ya sójà tó dìhámọ́ra tí wọ́n kọ́kọ́ yàn pé kó wá ṣọ́ mi náà nígbà tó rí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti máa ṣọ́ èmi nìkan. Ó sọ fún mi pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí wọ́n máa ní ká wá dúró ti ẹnì kan ká sì máa ṣọ́ ọ.” Ni mo bá ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi jù mí sẹ́wọ̀n fún un. Ọ̀rọ̀ yìí mú un lọ́kàn débi pé, ńṣe ló fìdí kalẹ̀—ó gbé ìbọn rẹ̀ sáàárín itan rẹ̀—ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí gbọ́ mi. Lẹ́yìn wákàtí méjì, sójà mìíràn wá gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ìyẹn náà sì tún béèrè irú ìbéèrè kan náà, ìjíròrò Bíbélì sì tún tẹ̀ lé e.

Láwọn ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, mo ní àǹfààní láti jẹ́rìí fún àwọn tó ń ṣọ́ mi àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà bá fàyè sílẹ̀. Kódà àwọn ẹ̀ṣọ́ yẹn máa ń ṣí àwọn yàrá ẹ̀wọ̀n sílẹ̀, tí wọ́n á sì fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n láyè láti péjọ fún ìjíròrò Bíbélì! Nígbà tó yá, ẹrù bẹ̀rẹ̀ sí í bà mí pé òmìnira tí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà fún mi láti máa bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn sọ̀rọ̀ lè lọ hàn síta, wàhálà ńlá sì lèyí máa kó mi sí. Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kò hàn síta rárá.

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n gbé mi lọ sílé ẹjọ́, àwọn tí mo ti bá sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi ló sì tún wá ń fún mi níṣìírí. Wọ́n ní kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì, wọ́n sì fi ọdún mẹ́fà tí mi ò lò nígbà tí ìjọba fún mi ní ìdáríjì nígbà ìdájọ́ mi àkọ́kọ́ kún un. Èyí túmọ̀ sí pé, ẹ̀wọ̀n tó ń lọ sí bí ọdún mẹ́jọ ló ń dúró dè mí.

Mo Rí Ọwọ́ Ọlọ́run Lára Mi

Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń rí i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi bí wọ́n ti ń gbé mi láti àgọ́ kan lọ sí òmíràn, àti látinú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan lọ dé òmíràn nílẹ̀ Czechoslovakia. Nígbà tí mo dé sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ti Valdice, ẹni tó jẹ́ aláṣẹ ibẹ̀ béèrè ohun tó gbé mi débẹ̀. Mo dá a lóhùn pé: “Nítorí pé mo kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun ni. Ìgbàgbọ́ mi kò gbà mí láyè láti lọ́wọ́ sí ogun jíjà.”

Pẹ̀lú ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn ló fi fèsì pé: “Ì bá dára gan-an ká ní gbogbo èèyàn ló lè ní irú ẹ̀mí yẹn.” Àmọ́ lẹ́yìn tó ti ronú nípa rẹ̀ fún bí ìṣẹ́jú díẹ̀, ló bá sọ pé: “Ṣùgbọ́n ṣá o, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn lónìí kò ti ronú lọ́nà yẹn, a gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ọ́—àá sì fi jẹ ọ́ dáadáa!”

Ẹ̀ka tó ń ṣiṣẹ́ ọnà gíláàsì ni wọ́n fi mí sí, èyí tó jẹ́ ẹ̀ka tí wọ́n ti ń fìyà jẹni. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé torí pé mo kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n, ẹlẹ́wọ̀n olóṣèlú ni wọ́n ṣì kà mí sí, nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tó nira gan-an ni wọ́n fún mi ṣe. Iṣẹ́ gbígbẹ́ gíláàsì fún ṣíṣe àwọn fìtílà alásorọ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀ṣọ́ ilé àtàwọn nǹkan olówó gọbọi mìíràn jẹ́ iṣẹ́ tó nira gan-an, nítorí pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe wọ́n lọ́nà tí wọn ò fi ní í ní àbùkù kankan lára. Àmọ́, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ni pé, tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n bá lọ kó iṣẹ́ tí wọ́n ti parí sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n á kàn rí i pé lọ́jọ́ kejì, ìlàjì rẹ̀ ni wọ́n dá padà fún àtúnṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣòro gan-an láti lè ṣe iye tí wọ́n ní kí wọ́n máa mú jáde.

Lọ́jọ́ tí mo dé sí ẹ̀ka tí wọ́n ti ń gbẹ́ gíláàsì náà, mo ní láti kọ́kọ́ dúró de ẹni tó jẹ́ ọ̀gá níbẹ̀. Nígbà tó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo lé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, torí pé lójú rẹ̀, wọn ò ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Bó ṣe kúrò lọ́dọ̀ wọn ló wá sọ́dọ̀ mi, tó sì bi mí pé: “Ìwọ ńkọ́? Kí ló dé tóò ṣiṣẹ́?”

Mo ṣàlàyé fún un pé ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ yàn síbẹ̀ ni mí. Ló bá mú mi lọ sínú ọ́fíìsì rẹ̀ ó sì bi mí ní ìbéèrè kan náà tí wọ́n ti máa ń béèrè lọ́wọ́ mi nípa ohun tó gbé mi dẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí mo ti ṣàlàyé ara mi fún un, ó sọ pé: “Lọ́rọ̀ kan, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́?”

Mo dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”

Ni ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí mi bá yí padà. Ó wá sọ pé: “Fọkàn rẹ balẹ̀. A ti ní ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa níbí rí. Gbogbo wọn la bọ̀wọ̀ fún, nítorí pé wọn kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ rárá, ọmọlúwàbí èèyàn sì ni wọ́n. Màá rí i pé ìwọ̀nba iṣẹ́ tó o máa lè ṣe ni wọ́n á fún ẹ.”

Ìyàlẹ́nu gbáà ni bí ìwà ọ̀gá náà ṣe yí padà sí mi jẹ́ fún mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an, mo sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi tí mi ò mọ̀ náà tí wọ́n mú kó ṣeé ṣe fún àwa Ẹlẹ́rìí láti ní orúkọ rere nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, mo rí ọwọ́ onífẹ̀ẹ́ Jèhófà lára mi ní gbogbo àkókò tí mo fi wà nínú ẹ̀wọ̀n.

Bó ti wù kí nǹkan le fún mi tó, ńṣe ni ọkàn mi máa ń balẹ̀ nígbà gbogbo pé, bópẹ́bóyá, màá pàdé àwọn Kristẹni arákùnrin mi. Nígbà yẹn, màá rí ẹ̀rín músẹ́ wọn tó ń tuni lára, màá sì rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ wọn. Ká ní wọn ò sí ni, ì bá nira fún mi gan-an láti máa fara da jíjù tí wọ́n ń jù mí sẹ́wọ̀n náà.

Ó dà bíi pé kò sí ohun mìíràn tí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ń finú rò ju bí wọ́n ṣe máa gbẹ̀san ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n lọ. Àmọ́ mi ò ronú bẹ́ẹ̀ rí. Mo mọ̀ pé torí ìgbọràn mi sí àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run ni mo ṣe ń jìyà. Nípa bẹ́ẹ̀, mo mọ̀ pé, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí mo lò nínú ẹ̀wọ̀n, Jèhófà lè fún mi ní àìmọye ọjọ́ ìgbésí ayé alárinrin nínú Párádísè ayé tuntun rẹ̀.—Sáàmù 37:29; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.

Mo Ṣọpẹ́ fún Àwọn Ìbùkún Ọjọ́ Òní

Ní oṣù May ọdún 1968, lẹ́yìn tí mo ti lo ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n dá mi sílẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Lákọ̀ọ́kọ́, ó máa ń nira fún mi láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Èyí wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó bá ti lo púpọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn tàbí pẹ̀lú àwọn wọ́dà. Àmọ́ kò pẹ́ tí àwọn Kristẹni arákùnrin mi fi ràn mí lọ́wọ́ láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, èyí tó jẹ́ pé abẹ́ ìfòfindè ni wọ́n ṣì ń ṣe é nígbà yẹn.

Kò ju ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lọ lẹ́yìn tí mo jáde lẹ́wọ̀n tí mo pàdé Eva. Láìka inúnibíni lílekoko látọ̀dọ̀ ìdílé rẹ̀ sí, òun, pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, ti fi ìgboyà dúró ṣinṣin ti òtítọ́ Bíbélì ní ọdún mẹ́ta ṣáájú ìgbà náà. Kò pẹ́ tá a fi jọ bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù pa pọ̀. A tún jọ ṣiṣẹ́ láti mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde. Inú àjàalẹ̀, níbi tá a gbé àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé pa mọ́ sí, la ti ń tẹ àwọn ìwé yìí. Nígbà tó wá di November 1969, a ṣègbéyàwó.

Lọ́dún 1970, a bí Jana, ọmọ wa àkọ́kọ́. Bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sin àwọn ìjọ lópin ọ̀sẹ̀ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí mò ń bẹ̀ wọ́n wò láti fún wọn ní ìṣírí tẹ̀mí. Ẹnu iṣẹ́ yìí ni mo wà lọ́dún 1975 tí wọ́n fi mú mi tí wọ́n sì tún sọ mí sẹ́wọ̀n padà. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mi ò lò ju ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ lọ níbẹ̀. Nígbà tó sì di ọdún 1977, a bí Štěpán, ọmọ wa ọkùnrin.

Níkẹyìn, ní September 1, 1993, ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech jẹ́ kó di mímọ̀ pé wọ́n ti fọwọ́ sí ìsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Jana, ọmọbìnrin wa, fẹ́ Dalibor Dražan tó jẹ́ Kristẹni alàgbà. Lẹ́yìn náà lọ́dún 1999, Štěpán, ọmọkùnrin wa, tí òún jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣègbéyàwó pẹ̀lú Blanka tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Gbogbo wa là ń dara pọ̀ báyìí pẹ̀lú àwọn ìjọ tó wà nílùú Prague. Gbogbo wa ń fojú sọ́nà de ìgbà tí ayé tuntun máa wọlé dé—àmọ́, èmi bí ẹnì kan ń wọ̀nà lójú méjèèjì fún àkókò náà nígbà tí kò ní sí ọgbà ẹ̀wọ̀n mọ́ níbì kankan.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde lọ́dún 1950.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mò ń fi kóòmù kọ ẹsẹ Bíbélì sílẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àgọ́ Bytiz, níbi tí mo ti ṣẹ̀wọ̀n tí mo sì ti ṣe batisí lẹ́yìn náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Eva, pẹ̀lú Štěpán àti Blanka lápá òsì àti Jana àti Dalibor lápá ọ̀tún