Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Àrùn Éèdì Máa Dópin? Bó Bá Rí Bẹ́ẹ̀, Lọ́nà Wo?

Ṣé Àrùn Éèdì Máa Dópin? Bó Bá Rí Bẹ́ẹ̀, Lọ́nà Wo?

Ṣé Àrùn Éèdì Máa Dópin? Bó Bá Rí Bẹ́ẹ̀, Lọ́nà Wo?

Ó ṢE díẹ̀ tí ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Áfíríkà kò ti gbà pé lóòótọ́ ni àjàkálẹ̀ àrùn éèdì wà. Àwọn èèyàn kan kò tiẹ̀ ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rárá ni. Àmọ́ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ akitiyan ló ti wáyé láti jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì mọ̀ nípa àrùn yìí, àti láti fún àwọn èèyàn níṣìírí láti máa sọ̀ ohun tí wọ́n bá rí nípa rẹ̀. Gbogbo ìsapá yìí kò fi bẹ́ẹ̀ mú àṣeyọrí gidi kan wá. Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gbé ìgbésí ayé àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ wọn ti mọ́ wọn lára gan-an, èyí kì í sì í jẹ́ kó rọrùn láti yí èrò wọn padà.

Ìtẹ̀síwájú Nínú Ìmọ̀ Ìṣègùn

Lágbo ìmọ̀ ìṣègùn, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ púpọ̀ nípa kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì, wọ́n sì ti mú oríṣiríṣi oògùn jáde, èyí tó ti mú ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn gùn sí i. Lílo àpapọ̀ àwọn oògùn mẹ́ta kan tó ń gbógun ti àrùn náà, èyí tí wọ́n pè ní ajẹ́bíidán, ti ṣe bẹbẹ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe pé àwọn oògùn yìí ń mú àrùn éèdì kúrò, wọ́n ti ṣe bẹbẹ láti mú kí iye àwọn tó ń kú nítorí pe wọ́n ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì lára dín kù, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa kó àwọn oògùn yìí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àmọ́, àwọn oògùn yìí gbówó lórí, agbára ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè yẹn kò sì lè ká a.

Èyí ti wá gbé ìbéèrè kàǹkà kan dìde, ìyẹn ni pé: Ṣé owó ló ṣe pàtàkì ju ẹ̀mí èèyàn lọ ni? Dókítà Paulo Teixeira, ẹni tó jẹ́ olùdarí ètò tí ilẹ̀ Brazil ṣe lórí kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì gbà pé òótọ́ ni ìṣòro yìí, ó sọ pé: “A ò lè máa wo ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn níran pé kí wọ́n lọ máa wá ọ̀nà àbáyọ fúnra wọn nítorí àìsí oògùn tí wọ́n lè lò láti bọ́ lọ́wọ́ ikú, kìkì nítorí èrè gọbọi tá a fẹ́ jẹ, èyí tó ju iye tó yẹ kó máa wọlé fún wa lọ fíìfíì.” Ó fi kún un pé: “Ohun tó jẹ èmi lógún jù lọ ni pé, a ò gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ owó ṣáájú ohun tá a mọ̀ pé ó tọ́ tàbí ká fi ṣáájú níní ìgbatẹnirò fún ẹ̀dá èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa.”

Àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ ti wá pinnu láti má ṣe ka ẹ̀tọ́ oní-ǹkan tí àwọn iléeṣẹ́ apoògùn ńláńlá ní sí, dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n kúkú lọ fúnra wọn ṣe ẹ̀ya àwọn oògùn tí kò ní orúkọ iléeṣẹ́ kankan lára tàbí kí wọ́n kó irú oògùn bẹ́ẹ̀ wọ̀lú lówó pọ́ọ́kú. a Ìwádìí kan tí ìwé ìròyìn South African Medical Journal gbé jáde fi hàn pé, “iye owó tó wálẹ̀ jù lọ tí wọ́n ń ta [àwọn oògùn tí wọ́n ṣe ẹ̀ya wọn] fi ìdá méjìlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún dín sí iye tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bù lé e.”

Àwọn Ohun Tó Ń Dènà Ìtọ́jú

Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn iléeṣẹ́ apoògùn ńláńlá náà bẹ̀rẹ̀ sí ta àwọn oògùn àrùn éèdì wọn ní iye owó tó kéré gan-an fún àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà tí wọ́n nílò àwọn oògùn náà. Wọ́n ronú pé, lọ́nà yìí, á túbọ̀ ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti rí àwọn oògùn náà lò. Síbẹ̀, àwọn ìṣòro ńlá kan ṣì wà láti ṣẹ́pá kí àwọn oògùn yìí tó lè máa tẹ àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lọ́wọ́. Ọ̀kan lára irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ni iye tí wọ́n ń ta àwọn oògùn náà. Kódà, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe dín iye tí wọ́n ń ta àwọn oògùn náà kù tó, owó gọbọi ló ṣì jẹ́ fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tó nílò wọn.

Ìṣòro mìíràn ni pé, kò rọrùn láti lo àwọn oògùn náà fún àwọn aláìsàn. Ọ̀pọ̀ egbòogi oníhóró ni wọ́n ní láti lò lójúmọ́ ọjọ́ kan, ó sì ní àkókò tí wọ́n gbọ́dọ̀ lò wọ́n. Bí wọn ò bá lò wọ́n bó ti yẹ, tàbí bí wọ́n bá ń lò wọ́n ní ìdákúrekú, èyí lè fa irú kòkòrò àrùn éèdì kan tí kì í gbóògùn. Ó ṣòro láti rí i dájú pé àwọn aláìsàn náà ń lo iye oògùn tó yẹ kí wọ́n lò nítorí bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí ní ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tó jẹ́ pé oúnjẹ lè máà tó nǹkan, tí omi tó dára fún mímu lè máà fi bẹ́ẹ̀ sí, tó sì jẹ́ pé àwọn ilé ìwòsàn tó wà kò pọ̀ tó.

Síwájú sí i, wọ́n gbọ́dọ̀ máa mójú tó àwọn tó ń lo àwọn oògùn yìí dáadáa. Táwọn oògùn náà kò bá gbógun ti àìsàn náà mọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ yí wọn padà. Àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn tó mọṣẹ́ dunjú ló lè ṣe èyí, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n lè fi mọ̀ gbówó lórí gan-an. Bákan náà, àwọn oògùn náà ní àkóbá tiwọn tí wọ́n ń ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀ya kòkòrò tí kì í gbóògùn tún ti ń yọjú báyìí.

Ní oṣù June ọdún 2001, níbi ìpàdé pàtàkì kan tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe lórí ọ̀rọ̀ àrùn éèdì, wọ́n dábàá ètò kan tí wọ́n pè ní Àkànlò Owó fún Ìlera Àgbáyé, láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Wọ́n fojú bù ú pé, iye tí wọ́n nílò á tó bílíọ̀nù méje dọ́là sí bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là. Tí wọ́n bá pa gbogbo owó tí wọ́n ṣèlérí rẹ̀ pọ̀, kò tó nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ iye tí wọ́n nílò gan-an.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé àwọ́n lè rí abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn yìí, wọ́n sì ti ń dán oríṣiríṣi rẹ̀ wò ní onírúurú orílẹ̀-èdè. Ká tiẹ̀ wá sọ pé gbogbo akitiyan yìí yọrí sí rere, yóò gbà tó ọdún bíi mélòó kan kí wọ́n tó lè mú abẹ́rẹ́ àjẹsára kan jáde, kí wọ́n tó lè dán an wò, kí wọ́n sì rí i pé kò léwu láti lò fún gbogbo gbòò.

Àwọn orílẹ̀-èdè kan, bíi Brazil, Thailand àti Uganda ti ṣàṣeyọrí kíkàmàmà nínú àwọn ètò ìtọ́jú tí wọ́n dáwọ́ lé. Nípa lílo àwọn oògùn tí wọ́n mú jáde fúnra wọn, ó ti ṣeé ṣe fún ilẹ̀ Brazil láti dín ikú tí àrùn éèdì ń fà kù sí ìlàjì. Orílẹ̀-èdè Botswana tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi àmọ́ tó rí jájẹ náà ti ń sapá gan-an láti mú kí egbòogi àrùn éèdì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn tó nílò rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni akitiyan ṣì ń lọ láti pèsè àwọn ìtọ́jú tó pọn dandan.

Bí A Ṣe Máa Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì

Ohun pàtàkì kan wà tó mú àrùn èèdì yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn àjàkálẹ̀ àrùn yòókù: Ó ṣeé ṣe láti dènà rẹ̀. Bí àwọn èèyàn bá ṣe tán láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà pàtàkì tó wà nínú Bíbélì, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti yàgò fún kíkó àrùn náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, bí kì í bá ṣe ní gbogbo ọ̀nà.

Àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì kò díjú rárá. Àwọn tí kò ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ yàgò fún ìbálòpọ̀ takọtabo. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Àwọn ẹni tó bá ti ṣègbéyàwó ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí aya wọn tàbí ọkọ wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà. (Hébérù 13:4) Ṣíṣègbọràn sí ìṣílétí Bíbélì láti yẹra fún ẹ̀jẹ̀ tún ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò boni.—Ìṣe 15:28, 29.

Àwọn tó ti lùgbàdì àrùn yìí ṣì lè rí ayọ̀ àti ìtùnú ńlá nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé kan níbi tí kò ti ní sí àrùn kankan rárá, èyí ti Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò wọlé dé láìpẹ́, ìyẹn á sì ṣeé ṣe fún wọn nípa gbígbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè.

Bíbélì mú kó dá wa lójú pé, bópẹ́bóyá, gbogbo hílàhílo tó ń bá aráyé fínra pátá, títí kan àìsàn, ni yóò wá sópin. Ìlérí yìí wà nínú ìwé Ìṣípayá, èyí tó sọ pé: “Mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Kì í ṣe kìkì àwọn tó lágbára láti ra àwọn oògùn tó gbówó lórí nìkan ni ìdánilójú yìí wà fún o. Ìlérí tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí nínú ìwé Ìṣípayá orí 21 la fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú Aísáyà 33:24, èyí tó sọ pé: “Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Nígbà yẹn, gbogbo èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé ni yóò máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run, wọn yóò sì máa gbádùn ìlera pípé. Lọ́nà yìí, àrùn éèdì tó ń pa àwọn èèyàn nípakúpa—àti gbogbo àwọn àrùn yòókù pátá—ló máa di èyí tá a fòpin sí títí ayérayé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn oògùn tí wọ́n ṣe ẹ̀ya rẹ̀ làwọn oògùn tí àwọn iléeṣẹ́ apoògùn mìíràn ti mú jáde tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ oní-ǹkan lórí wọn àmọ́ táwọn mìíràn lọ ṣe jáde láìfi orúkọ iléeṣẹ́ kankan sí i lára. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ètò Ìṣòwò Lágbàáyé ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti má ṣe ka ẹ̀tọ́ oní-ǹkan sí tí ìṣòro pàjáwìrì bá yọjú.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9, 10]

IRÚ ÌWÒSÀN TÍ MÒ Ń WÁ GAN-AN RÈÉ

Apá ìhà gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà ni mò ń gbé, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún sì ni mí. Mo rántí ọjọ́ tí mo gbọ́ pé mo ti ní kòkòrò tí ń fa àrùn éèdì lára.

Èmi àti màmá mi la jọ wà lọ́dọ̀ dókítà nígbà tó já ìròyìn náà balẹ̀. Mi ò tíì gbọ́ ìròyìn tó bà mí nínú jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ rí nígbèésí ayé mi. Ńṣe lọkàn mi dàrú pátápátá. Ó ṣòro fún mi láti gbà á gbọ́. Mo ronú pé bóyá wọ́n ṣàṣìṣe níbi tí wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò náà ni. Mi ò mọ ohun tí ǹ bá sọ tàbí tí ǹ bá ṣe. Ó ṣe mí bíi kí n bú sẹ́kún, àmọ́ omi ò wá. Dókítà náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àwọn oògùn tó wà fún àrùn éèdì àtàwọn nǹkan mìíràn fún màmá mi, àmọ́ jìnnìjìnnì tó bá mi kò tiẹ̀ jẹ́ kí ọ̀kankan nínú ohun tó ń sọ yé mi.

Mo ronú pé, ó ní láti jẹ́ pé ọkùnrin kan ní yunifásítì tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ló kó o ràn mí. Ó ṣe mí bíi kí n rí ẹnì kan tí màá lè sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún tó sì máa lóye ìṣòro mi, àmọ́ mi ò mọ ẹnì kankan tí mo lè tọ̀ lọ. Ni mo bá kúkú gbà pé ó ti tán fún mi nìyẹn àti pé mi ò já mọ́ nǹkankan mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé mi dúró tì mí, mi ò nírètí kankan, ẹ̀rù á sì máa bà mí. Bó ti máa ń jẹ́ ìfẹ́ gbogbo ọ̀dọ́, èmi náà ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ ṣe nígbèésí ayé mi. Ọdún méjì péré ló kù kí n gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ní yunifásítì, àmọ́ ìrètí yẹn ti wọmi.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn egbòogi àrùn éèdì tí dókítà sọ, mo sì tún máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbani nímọ̀ràn lórí àrùn éèdì, síbẹ̀ ìbànújẹ́ ọkàn mi kò lọ. Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́, pé kó fi ìsìn Kristẹni tòótọ́ hàn mí kí n tó kú. Ọmọ ìjọ ṣọ́ọ̀ṣì Onígbàgbọ́ Wò-ó-sàn ni mí, àmọ́ ẹnì kan ṣoṣo báyìí láti ṣọ́ọ̀ṣì wa kò wá wò mí rárá. Mo fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ibi tí mo máa lọ lẹ́yìn tí mo bá kú.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, níbẹ̀rẹ̀ oṣù August ọdún 1999, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan ilẹ̀kùn mi. Mi ò lókun nínú rárá lọ́jọ́ náà, àmọ́ ó ṣeé ṣe fún mi láti dìde jókòó nínú pálọ̀. Àwọn obìnrin méjì náà sọ ẹni tí wọ́n jẹ́ wọ́n sì sọ pé àwọ́n ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìtura ńlá gbáà ló jẹ́ fún mi pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ọlọ́run gbọ́ àdúrà mi. Àmọ́ ní àkókò yẹn, mi ò ní ìmí kankan nínú rárá débi pé mi ò lè kàwé bẹ́ẹ̀ ni mi ò lè fọkàn sí ohun tí wọ́n ń sọ.

Síbẹ̀, mo sọ fún wọn pé mo fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì dá ọjọ́ tí wọ́n máa padà wá fún mi. Àmọ́ ó dùn mí pé, kí ọjọ́ yẹn tó pé, wọ́n ti gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn àwọn alárùn ọpọlọ nítorí ìdààmú ọkàn tí mò ń ní. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà náà ni mo padà sílé, inú mi sì dùn láti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò tíì gbàgbé mi. Mo rántí pé ọ̀kan lára wọn máa ń wá wò mi láti rí bí mo ṣe ń ṣe sí. Nígbà tó ṣe, ara mi yá díẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí ọdún yẹn ti ń lọ sí ìparí. Àmọ́ kò rọrùn fún mi o, nítorí ipò ìlera mi kò dúró sójú kan. Ṣùgbọ́n ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ náà ṣèèyàn gan-an, ó sì máa mú sùúrù fún mi.

Orí mi wú nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ nínú Bíbélì, tí mo sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó túmọ̀ sí ní ti gidi láti mọ̀ ọ́n àti láti máa wọ̀nà fún ìwàláàyè ayérayé. Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi, mo tún lóye ìdí tí ìran èèyàn fi ń jìyà. Ayọ̀ ńláǹlà ni mímọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó máa tó rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, mú bá mi. Èyí sún mi láti ṣàtúnṣe ìgbésí ayé mi látòkèdélẹ̀.

Irú ìwòsàn tí mò ń wá gan-an rèé. Ìtùnú ńlá ló mà jẹ́ fún mi o láti mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi àti pé kò pa mí tì! Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ńṣe ni mo ń rò pé Ọlọ́run kórìíra mi àti pé ìyẹn ló jẹ́ kí n lọ kó àrùn yìí. Ṣùgbọ́n mo kẹ́kọ̀ọ́ pé, Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣètò láti mú kí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ṣeé ṣe lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ ni pé Ọlọ́run bìkítà, gẹ́gẹ́ bí 1 Pétérù 5:7 ti sọ pé: ‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé e, nítorí ó bìkítà fún ọ.’

Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́ àti lílọ sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mò ń sapá gidigidi láti sún mọ́ Jèhófà bó bá ti lè ṣeé ṣe fún mi tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn, mo máa ń kó gbogbo àníyàn ọkàn mi lọ bá Jèhófà nínú àdúrà tí mo sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó fún mi ní okun àti ìtùnú. Àwọn ará ìjọ tí mo wà jẹ́ adúrótini lọ́jọ́ ìṣòro, èyí jẹ́ kí n láyọ̀.

Mo máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere déédéé pẹ̀lú ìjọ tí mò ń dara pọ̀ mọ́. Mo fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, pàápàá àwọn tí ipò wọn jọ tèmi. Oṣù December ọdún 2001 ni mo ṣèrìbọmi.

[Àwòrán]

Ayọ̀ ńláǹlà ni mímọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run mú bá mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ẹgbẹ́ kan tó ń fúnni nímọ̀ràn lórí àrùn éèdì nílẹ̀ Botswana

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lórí ilẹ̀ ayé tó ti di Párádísè, gbogbo èèyàn pátá ló máa gbádùn ìlera pípé