Ṣé Kì Í Ṣe Pé Pàbó ni Gbogbo Ìrètí Àlàáfíà Ń Já Sí?
Ṣé Kì Í Ṣe Pé Pàbó ni Gbogbo Ìrètí Àlàáfíà Ń Já Sí?
“Lónìí, ńṣe ló dà bíi pé inú ìjì líle kan la wà . . . nínú àjálù ńlá kan tí kò láfiwé rárá.”—Ìwé ìròyìn “La Repubblica,” ti ìlú Róòmù, lórílẹ̀-èdè Ítálì, ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.
LẸ́YÌN táwọn apániláyà ṣọṣẹ́ ní ìlú New York City àti ìlú Washington, D.C. lọ́dún tó kọjá, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ju ti ìgbàkigbà rí lọ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì lórí ọjọ́ iwájú ìran èèyàn. Àìmọye ìgbà làwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ti fi àwòrán bí àwọn Ilé Gogoro Méjì náà, ìyẹn Twin Towers, ṣe ń wó lulẹ̀ hàn. Wọ́n tún ń fi hàn bí àìnírètí àti ìbànújẹ́ ṣe bo àwọn tó yè bọ́. Àwọn ìran wọ̀nyí ń mú ọkàn àwọn èèyàn káàkiri ayé pòrúurùu. Yàtọ̀ sí ìpayà tó gbòde kan yìí, èrò tó tún wà lọ́kàn àwọn èèyàn báyìí ni pé àyípadà mánigbàgbé kan ti dé bá ayé. Ṣé òótọ́ ni?
Ogun bẹ́ sílẹ̀ kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó wáyé ní September 11, 2001. Láìpẹ́, àwọn orílẹ̀-èdè tó ti fìgbà kan jẹ́ ata-àtojú síra wọn lẹ̀dí àpò pọ̀ láti tẹ ìpániláyà rì. Bá a bá sọ ọ́ lọ tá a sọ ọ́ bọ̀, ẹ̀mí èèyàn àti dúkìá tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ kì í ṣe kékeré rárá. Àmọ́, ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn jákèjádò ayé kà sí àyípadà tó túbọ̀ pabanbarì ni ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ tí kò sí mọ́, ìyẹn ni pé, èrò tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ lọ́kàn tọmọdé tàgbà ni pé, kò sẹ́ni tó mórí bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ewu, láìka ibikíbi tí onítọ̀hún lè máa gbé sí.
Àwọn tó jẹ́ aṣáájú nínú ayé ń dojú kọ àìmọye ìṣòro. Àwọn akọ̀ròyìn àtàwọn abẹnugan lórí ọ̀ràn àjọṣe ẹ̀dá ń ṣàníyàn nípa bí a ṣe lè dáwọ́ ìpániláyà dúró kó tó gbèèràn bí iná ọyẹ́, níwọ̀n bó ti jọ pé ipò òṣì àti ìgbawèrèmẹ́sìn ló máa ń ṣokùnfà rẹ̀—àwọn ìṣòro tó jẹ́ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè rí ojútùú sí wọn. Ìwà ìrẹ́nijẹ ti tàn kálẹ̀ gan-an nínú ayé débi pé gbogbo nǹkan tó lè dá rògbòdìyàn tó burú jáì sílẹ̀ ló ti wà nílẹ̀. Àwọn èèyàn lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ló ń kọminú nípa bóyá àwọn ìṣòro tó wà lórí ilẹ̀ ayé á wábi gbà lọ́jọ́ kan. Ǹjẹ́ ogun—pẹ̀lú gbogbo ìnira, ikú, àti àdánù tó ń mú wá—máa dópin láé bí?
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń dara pọ̀ mọ́ onírúurú ètò ẹ̀sìn torí àtilè wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Àmọ́, àwọn ẹlòmíràn ń ṣiyèméjì gan-an. Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o rò pé àwọn aṣáájú ìsìn lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí? Àti pé, ǹjẹ́ àdúrà tí wọ́n ń gbà nípa pé kí àlàáfíà wà ha lè ṣẹ bí?