Nígbà Tí Àṣìṣe Tí Kò Tó Nǹkan Bá Di Àjálù Ńlá
Nígbà Tí Àṣìṣe Tí Kò Tó Nǹkan Bá Di Àjálù Ńlá
NÍ July 6, 1988, àwọn òṣìṣẹ́ kan ń ṣe àtúnṣe pọ́ǹpù kan lára ẹ̀rọ Piper Alpha gìrìwò tí wọ́n fi ń wa epo rọ̀bì látinú Òkun Àríwá, ṣùgbọ́n wọn kò parí iṣẹ́ náà. Nítorí àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán láàárín àwọn òṣìṣẹ́ náà lórí ibi tí wọ́n bá iṣẹ́ dé, ńṣe làwọn tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí fi pọ́ǹpù náà ṣiṣẹ́ láìmọ̀ pé kò ì tíì dára. Bí iná ṣe là nìyẹn. Orí òkè téńté nínú agbami òkun làwọn òṣìṣẹ́ tí iná ká mọ́ náà wà, nípa bẹ́ẹ̀ kò ṣeé ṣe fún wọn láti rí ọ̀nà sá àsálà, èyí sì ṣekú pa èèyàn mẹ́tàdínláàádọ́sàn-án [167].
Ọdún méjìlá lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ní July 25, 2000, ọkọ̀ òfuurufú Concorde ayára-bí-àṣá kan ń sáré geerege lórí ilẹ̀ kó tó gbéra ní Pápákọ̀ Òfuurufú Charles de Gaulle ní ìlú Paris, lórílẹ̀-èdè Faransé. Bí ọkọ̀ òfuurufú náà ti ń múra àtigbéra nílẹ̀, pàǹtírí titanium kékeré kan tó wà lórí títì náà fọ́ ọ̀kan lára àwọn táyà rẹ̀, tí èyí sì mú kí táǹkì epo tó wà níbi ọ̀kan lára àwọn apá ọkọ̀ náà bẹ́. Epo ọkọ̀ tó ṣàn lọ sí ibi tí àwọn ẹ́ńjìnnì apá òsì ọkọ̀ òfuurufú náà wà paná mọ́ ọn lẹ́nu, ó sì ṣokùnfà iná kan tó ń jó làlà fún bí ọgọ́ta mítà. Lẹ́yìn nǹkan bí ìṣẹ́jú méjì, ọkọ̀ òfuurufú náà forí sọ òtẹ́ẹ̀lì kan, ó sì ṣekú pa gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀, àtàwọn èèyàn kan tó wà lórí ilẹ̀.
Nígbà tí James Chiles ń sọ̀rọ̀ lórí irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ nínú ìwé rẹ̀, Inviting Disaster—Lessons From the Edge of Technology ni pé: “Nínú sànmánì tuntun tá à ń gbé yìí, tí oríṣiríṣi ẹ̀rọ tó máa ń ṣàdédé yarí mọ́ni lọ́wọ́ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lè ṣokùnfà àwọn jàǹbá tó burú jáì.” Nígbà tí ìwé ìròyìn Science ń ṣàgbéyẹ̀wò ìwé tí Chiles kọ náà, ó sọ pé: “Ọ̀nà aṣeniníkàyéfì tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbà ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìyárakánkán láti àwọn ọ̀rúndún bíi mélòó kan sẹ́yìn kàn ń jọni lójú ṣáá ni. Ńṣe ló ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tí ẹ̀dá èèyàn ò lè ṣe bó bá dọ̀ràn lílóye ilẹ̀ ayé wa yìí àti ṣíṣe àyípadà sí i. [Àmọ́] kò sídìí láti máa ronú pé a ò lè ṣàṣìṣe mọ́ láyé òde òní bíi ti àtijọ́.”
Nígbà tí ìwé ìròyìn Science ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó túbọ̀ léwu gan-an, ó sọ pé: “Kódà, [àṣìṣe] tó kéré bíńtín pàápàá léwu gan-an. Ní ti irú àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ tiraka láti ṣiṣẹ́ dé ojú àmì kí wọ́n lè wà ní ipò pípé pérépéré.” Àmọ́, ṣe àwọn ohun tí aráyé ti ṣe sẹ́yìn fi hàn pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe nǹkan lọ́nà tó pé pérépéré? Rárá o! Látàrí èyí, kò sí àní-àní pé àwọn jàǹbá oríṣiríṣi tí àṣìṣe ń ṣokùnfà yóò máa bá a lọ láti ṣẹlẹ̀.
Àmọ́ wọn ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí ayé. Àwọn èèyàn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la kan nígbà tí àṣìṣe ẹ̀dá èèyàn tàbí àìpé ẹ̀dá kò ní ké ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn kúrú lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́ mọ́. Kí nìdí? Ó jẹ́ torí pé Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ ọ̀run, yóò fòpin sí gbogbo ohun tó ń ṣokùnfà ikú, ìbànújẹ́, àti ìrora.—Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
AP Photo/Toshihiko Sato