Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbójú Fo Àwọn Kùdìẹ̀-kudiẹ Wa?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Á Gbójú Fo Àwọn Kùdìẹ̀-kudiẹ Wa?
‘Mi ò kì í ṣe ẹni búburú! Gbogbo ipá mi ni mo ń sà láti pa àwọn ìwà tí ò dáa tì, àmọ́, bí mo ṣe ń gbìyànjú tó, agbára mi ò gbé e!’
ǸJẸ́ gbólóhùn òkè yìí fi bí nǹkan ṣe rí lára rẹ tàbí lára ẹnì kan tó o mọ̀ hàn? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò ṣeé ṣe rárá láti ṣẹ́gun àwọn ìwàkiwà tó ti jingíri mọ́ wọn lára. Ọtí làwọn kan dara dé, àwọn mìíràn sì rèé, tábà tàbí oògùn olóró ni tiwọn. Ìwà ìwọra ló ń darí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Àwọn kan sì wà tí wọ́n ti juwọ́ sílẹ̀ fún ìṣekúṣe, tí wọ́n á máa sọ pé àwọn ò rò pé àwọ́n lè jáwọ́ níbẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Mátíù 26:41 ti fi hàn, tàánútàánú ni Jésù fi jẹ́ ká mọ̀ pé òún lóye àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ẹ̀dá èèyàn. a Kódà, gbogbo àkọsílẹ̀ inú Bíbélì látòkèdélẹ̀ ló fi hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù láàánú ẹ̀dá èèyàn lójú gan-an. (Sáàmù 103:8, 9) Àmọ́ ǹjẹ́ a lè retí pé kí Ọlọ́run gbójú fo gbogbo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa?
Mósè àti Dáfídì
Gbé àkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè yẹ̀ wò. Bíbélì fi hàn pé Mósè “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀,” ó sì ṣe gudugudu méje láti máa pa ànímọ́ yìí mọ́. (Númérì 12:3) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń rìn la aginjù já, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń hu àwọn ìwà tí kò mọ́gbọ́n dání, wọn kì í sì í bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run àtàwọn aṣojú rẹ̀. Ní gbogbo àkókò yìí, ńṣe ni Mósè máa ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.—Númérì 16:12-14, 28-30.
Àmọ́, bí ìrìn àjò gígùn tí ń tánni lókun náà ti ń parí lọ, Mósè fara ya níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè náà, kò sì ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run. Ọlọ́run dárí jì í, àmọ́ ǹjẹ́ Ó gbójú fo ohun tó ṣe yẹn dá? Rárá o. Ó sọ fún Mósè pé: “Nítorí tí [o] kò fi ìgbàgbọ́ hàn nínú mi . . . , [ìwọ] kì yóò mú ìjọ yìí wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn dájúdájú.” Númérì 20:7-12.
Ìyẹn túmọ̀ sí pé Mósè kò ní wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Lẹ́yìn ogójì ọdún tó ti ń làkàkà pé kọ́wọ́ òun lè tẹ àǹfààní àgbàyanu yẹn, ìkùdíẹ̀-káàtó kan tó lágbára mú kó pàdánù ẹ̀bùn náà.—Ọba Dáfídì tún ni ẹlòmíràn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tóun náà ní kùdìẹ̀-kudiẹ kan. Ní àkókò kan, ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ó sì lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó-oníyàwó. Ó wá gbìyànjú láti bo ohun tó ṣe mọ́lẹ̀ nípa pípa ọkọ obìnrin náà. (2 Sámúẹ́lì 11:2-27) Lẹ́yìn náà, ó kábàámọ̀ gan-an fún ìwà ọ̀daràn tó hù, Ọlọ́run sì dárí jì í. Àmọ́ Dáfídì ti pa ìdílé kan run, Jèhófà kò sì dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ àwọn ìyọnu tí ń kó ìbànújẹ́ báni tó dé bá a lẹ́yìn náà. Ọmọkùnrin tí Dáfídì bí ṣàìsàn gidigidi, Jèhófà kò sì wò ó sàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì gbàdúrà gan-an nítorí ọmọ rẹ̀ yìí. Ọmọ náà kú, ẹ̀yìn náà ni oríṣiríṣi àjálù tún wá ń tẹ̀ léra wọn nínú agbo ilé Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 12:13-18; 18:33) Ohun tí Dáfídì fojú winá rẹ̀ kì í ṣe kékeré nítorí pé ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìwàkiwà.
Àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé Ọlọ́run máa ń mú kí àwọn èèyàn dáhùn fún ìwà tí wọ́n bá hù. Àwọn tó fẹ́ láti sìn ín gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti ṣàtúnṣe láwọn ibi tí wọ́n kù sí nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì di Kristẹni tó sunwọ̀n sí i. Ọ̀pọ̀ ló ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní.
Ìjàkadì Láti Jára Ẹni Gbà Lọ́wọ́ Àwọn Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tá a lè kà sí àpẹẹrẹ rere fún gbígbé ìgbésí ayé Kristẹni. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìgbà gbogbo ló ń bá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀ wọ̀yá ìjà? Róòmù 7:18-25 ṣàlàyé kínníkínní nípa ìjàkadì yìí, tàbí, ‘ogun’ yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 23 ti pè é. Pọ́ọ̀lù bá ẹ̀ṣẹ̀ jà láìkáàárẹ̀, torí ó mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í fini lọ́rùn sílẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.
Àwọn kan tó jẹ́ ara ìjọ Kristẹni ní ìlú Kọ́ríńtì ìjímìjí pàápàá ti jẹ́ oníwàkiwà paraku rí. Bíbélì sọ pé, ‘alágbèrè, panṣágà, àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, olè, oníwọra àti ọ̀mùtípara’ ni wọ́n tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ó tún sọ pé a “ti wẹ̀ [wọ́n] mọ́.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Lọ́nà wo? Ìmọ̀ pípéye, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni àti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló fún wọn lókun láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà búburú wọn. Níkẹyìn, Ọlọ́run polongo wọn ní olódodo ní orúkọ Kristi. Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run nawọ́ ìdáríjì sí wọn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn ní ẹ̀rí ọkàn rere.—Ìṣe 2:38; 3:19.
Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì kò fojú kéré àwọn ìtẹ̀sí wọn fún ẹ̀ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bá a wọ̀yá ìjà, wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Àwọn olùjọsìn ọ̀rúndún kìíní yìí wá di ẹni tá a gbóríyìn fún látàrí ìwà rere wọn, láìka àyíká tí wọ́n ń gbé àti àìpé ẹ̀dá tó ń fẹ́ tì wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí. Àwa náà ńkọ́?
Ọlọ́run Retí Pé Ká Ṣiṣẹ́ Lórí Àwọn Kùdìẹ̀-Kudiẹ Wá
Bíbá kùdìẹ̀-kudiẹ kan tá a ní wọ̀yá ìjà lè máà mú un kúrò pátápátá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún àìpé wa, kò ṣeé ṣe fún wa láti pa á run. Àìpé ló máa ń fa àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ìgbà gbogbo. Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa yìí. (Sáàmù 119:11) Kí ló mú kí èyí ṣe pàtàkì gan-an?
Ìdí ni pé Ọlọ́run kò gbà ká máa lo àìpé gẹ́gẹ́ bí àwíjàre nígbà gbogbo fún ìwà burúkú. (Júúdà 4) Jèhófà fẹ́ kí àwọn ẹ̀dá èèyàn fọ ara wọn mọ́ tónítóní, kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé ìwà rere. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” (Róòmù 12:9) Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi fọwọ́ kékeré mú ọ̀ràn yìí?
Ìdí kan ni pé jíjuwọ́sílẹ̀ fún kùdìẹ̀-kudiẹ wa léwu. Gálátíà 6:7 sọ pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Àwọn tí wọ́n ń juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn àṣà bárakú, ìwà ìwọra àti ìṣekúṣe sábà máa ń kárúgbìn àwọn ohun tó ń fa ìbànújẹ́ bá wọn nígbèésí ayé. Àmọ́ ìdí kan wà tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ.
Ọlọ́run kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ gan-an. Ó ń dá “ìpínyà” sílẹ̀ láàárín àwa àti Jèhófà. (Aísáyà 59:2) Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe fún àwọn tó ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà láti rí ojú rere rẹ̀, ó gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ wẹ̀; ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́; . . . ẹ ṣíwọ́ ṣíṣe búburú.”—Aísáyà 1:16.
Aláàánú àti onífẹ̀ẹ́ ni Ẹlẹ́dàá wa. “Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Jíjuwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ nígbà gbogbo kò ní jẹ́ ká rí ojú rere Ọlọ́run. Níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti ń gbójú fo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, àwa náà kò gbọ́dọ̀ gbójú fò wọ́n.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jésù sọ pé: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”