Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Mo Nílò Tẹlifóònù Alágbèérìn?

Ǹjẹ́ Mo Nílò Tẹlifóònù Alágbèérìn?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Mo Nílò Tẹlifóònù Alágbèérìn?

“Ọkàn mi kì í balẹ̀ rárá, ńṣe ni inú sì máa ń bí mi bí kò bá sí tẹlifóònù alágbèérìn lọ́wọ́ mi.”—Akiko. a

TẸLIFÓÒNÙ alágbèérìn ti di ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò báyìí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Tẹlifóònù yìí rọrùn láti lò. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn òbí rẹ lè fi pè ọ́ kí wọ́n sì fi bá ọ sọ̀rọ̀ nígbàkigbà àti níbikíbi tó o bá wà—ìwọ náà sì lè fi bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n ṣe àwọn kan lọ́nà tó máa fi ṣeé ṣe fún ẹni tó ń lò ó láti tẹ ọ̀rọ̀ ṣókí ránṣẹ́ sí ẹlòmíràn lórí rè, ni ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London fi pè é ní “ọ̀nà tuntun tí àwọn ọ̀dọ́ ń lò láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀.” Àwọn tẹlifóònù alágbèérìn kan tiẹ̀ wà tí wọ́n lè bá Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣiṣẹ́, èyí ṣeé lò fún wíwá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti fún kíkọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà (E-mail).

Bóyá o ti ní, tàbí kó o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ẹ́ ní, èyí ó wù ó jẹ́, máa rántí pé, kò sí ohun tí ọmọ èèyàn ṣe tí kò ní àléébù tirẹ̀. Tẹlifóònù alágbèérìn láwọn àǹfààní àti àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó yẹ kéèyàn ronú lé béèyàn bá ní in, torí pé mímọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ìṣòro tó lè yọjú á jẹ́ kéèyàn ó lè fọgbọ́n lò ó.

“Gbéṣirò Lé Ìnáwó Náà”

Jésù fi ìlànà ọlọgbọ́n kan lélẹ̀, pé ó yẹ kéèyàn “gbéṣirò lé ìnáwó náà” kó tó bẹ̀rẹ̀ ìdáwọ́lé pàtàkì kan. (Lúùkù 14:28) Ǹjẹ́ o lè fi irú ìlànà yẹn sílò bó bá dọ̀ràn lílo tẹlifóònù alágbèérìn? Dájúdájú. Òótọ́ ni pé, ó ṣeé ṣe kí owó tó o fi gba tẹlifóònù náà kéré tàbí kó jẹ́ pé ẹnì kan ló gbà á fún ọ lọ́fẹ̀ẹ́. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Henna tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ṣe mọ̀ látinú ìrírí tiẹ̀, ó sọ pé, “owó tí wàá máa san lórí àwọn ibi tó o fi pè lè fò sókè lójijì.” O tún lè máa fìgbà gbogbo ṣàníyàn nípa fífi àwọn nǹkan tí kò ní tẹ́lẹ̀ kún un kó lè túbọ̀ lágbára sí i. Ó sì lè máa wù ọ́ láti ra àwọn oríṣi mìíràn tó túbọ̀ gbówó lórí. Látàrí èyí, Hiroshi sọ pé: “Mò ń ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́, mo sì máa ń fowó pa mọ́ kí n lè máa ra oríṣi tuntun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí àtẹ lọ́dọọdún.” Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. b

Báwọn òbí rẹ bá tiẹ̀ gbà láti máa bá ọ sanwó ibi tó o fi tẹlifóònù náà pè, síbẹ̀, ó ṣì ṣe pàtàkì láti ronú nípa iye tó ò ń ná. Kristẹni alábòójútó arìnrìn-àjò kan ní Japan sọ pé: “Àwọn ìyá kan ń ṣe àfikún iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ torí kí wọ́n lè san owó ibi tí àwọn ọmọ wọn fi tẹlifóònù alágbèérìn wọn pè, èyí táwọn ọmọ náà tiẹ̀ lè máà nílò rárá.” Ó dájú pé o ò ní fẹ́ gbé irú ìnira bẹ́ẹ̀ ka àwọn òbí rẹ lórí!

“Ohun Kan Tó Máa Ń Fi Àkókò Ṣòfò”

Ọ̀pọ̀ tó ń lo tẹlifóònù alágbèérìn ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ lè wá rí i pé ó ń jẹ àkókò àwọn ju bí àwọ́n ti retí lọ—àní ó tún ń gba àkókò tí wọn ì bá fi ṣe àwọn nǹkan pàtàkì. Tẹ́lẹ̀ rí, Mika ti máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹun alẹ́ tán. Ó sọ pé: “Ní báyìí, tá a bá ti jẹun tán, ńṣe ni kálukú á gba iyàrá rẹ̀ lọ pẹ̀lú [tẹlifóònù alágbèérìn] tirẹ̀.”

Ìwé ìròyìn The Guardian ti ìlú London sọ pé, “ìdámẹ́ta àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sí ogún ọdún ló fẹ́ràn títẹ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ sórí tẹlifóònù alágbèérìn ju lílo àwọn ọ̀nà mìíràn tó wà fún kíkọ ìsọfúnni ránṣẹ́ lọ.” Títẹ ọ̀rọ̀ sórí tẹlifóònù alágbèérìn lè máà fi bẹ́ẹ̀ náni lówó tó fífi ohùn bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀, àmọ́ ó máa ń gba àkókò tó pọ̀ gán-an. Mieko sọ pé: “Bí ẹnì kan bá tẹ ọ̀rọ̀ náà, ‘ó dàárọ̀’ sórí tẹlifóònù tó sì fi ránṣẹ́ sí mi, èmi náà á fèsì nípa títẹ ‘ó dàárọ̀’ padà sí onítọ̀hún. Lẹ́yìn náà, a óò wá máa fi ìsọfúnni ránṣẹ́ síra wa fún bíi wákàtí kan. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ tó ní láárí o.”

Bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lo tẹlifóònù alágbèérìn bá fara balẹ̀ ṣàròpọ̀ gbogbo àkókò tí wọ́n fi ń lo tẹlifóònù wọn ní oṣù kan, á yà wọ́n lẹ́nu gidigidi. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún kan tó ń jẹ́ Teija sọ pé: “Fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ohun kan tó máa ń fi àkókò ṣòfò ni tẹlifóònù alágbèérìn jẹ́ kàkà tí ì bá fi jẹ́ ohun tó ń pa àkókò mọ́.” Kódà, bí ipò rẹ bá mú kó pọn dandan fún ọ láti ní in, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa kíyè sí àkókò tó o fi ń lò ó.

Kristẹni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Marja sọ pé: “Láwọn àpéjọ Kristẹni, ńṣe ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa ń fi ìsọfúnni tí kò ṣe pàtàkì ránṣẹ́ sí àwọn mìíràn. Àṣà yìí wọ́pọ̀ gan-an ni!” A ti ṣàkíyèsí irú ìwà yìí kan náà láàárín àwọn ọ̀dọ́ nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Bíbélì gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn láti máa ra àkókò padà fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. (Éfésù 5:16) Ẹ ò rí i pé kì í ṣe ohun tí ó dára pé ìjíròrò orí tẹlifóònù ń gba irú àkókò ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀!

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Bòókẹ́lẹ́

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Marie tún sọ̀rọ̀ lórí àléébù mìíràn tó wà nínú lílo tẹlifóònù alágbèérìn, ó ní: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé tààràtà ni ẹni tó gbé tẹlifóònù dání máa gba ìpè náà, tí kò kọ́kọ́ lọ sórí tẹlifóònù tó wà nínú ilé ná, ewu wà níbẹ̀, torí pé àwọn òbí ò ní mọ ẹni tí àwọn ọmọ wọn ń bá sọ̀rọ̀ tàbí bóyá wọ́n tiẹ̀ ń lo tẹlifóònù alágbèérìn náà lọ́wọ́ tàbí wọn kò lò ó.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń lo tẹlifóònù alágbèérìn láti bẹ̀rẹ̀ àjọṣe oníbòókẹ́lẹ́ pẹ̀lú ẹ̀yà òdìkejì. Àwọn kan kì í kíyè sára mọ́ tí wọ́n bá ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ orí tẹlifóònù pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ńṣe ni wọ́n máa ń hu ìwà tí wọn kì í hù nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Báwo lèyí ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti ìlú London sọ pé: “Títẹ ìsọfúnni ránṣẹ́ nípasẹ̀ tẹlifóònù alágbèérìn túmọ̀ sí pé ẹnì kankan kò ní máa mójú tó ohun tí [àwọn ọ̀dọ́] ń ṣe.” Bí o kò bá fojú rí tàbí kí o gbọ́ ohùn ẹni tó ń kàn sí ọ, èyí lè nípa lórí rẹ. Timo sọ pé: “Àwọn kan máa ń rò pé títẹ ìsọfúnni ránṣẹ́ nípasẹ̀ tẹlifóònù alágbèérìn jẹ́ ọ̀nà kan láti sọ ohunkóhun tó bá wù wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Àwọn kan lè kọ àwọn ohun tí wọn ò jẹ́ sọ ní gbangba bó bá jẹ́ ojúkojú ni wọ́n ń bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀.”

Nígbà tí Kristẹni ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Keiko bẹ̀rẹ̀ sí lo tẹlifóònù alágbèérìn, ó sọ nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lójoojúmọ́ sí ọmọkùnrin kan tó wà nínú ìjọ rẹ̀, ìyẹn náà sì ń dá èsì padà. Keiko sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ tó ń lọ nìkan la máa ń sọ, àmọ́ nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí bára wa sọ ẹ̀dùn ọkàn kálukú wa. Bí àjọṣe àwa méjèèjì ṣe di tímọ́tímọ́ lórí tẹlifóònù alágbèérìn nìyẹn.”

Ọpẹ́lọpẹ́ pé ó tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn alàgbà Kristẹni. Ọ̀ràn náà ì bá di ńlá. Ó wá sọ báyìí pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣáájú kí àwọn òbí mi tó fún mi ní tẹlifóònù alágbèérìn, wọ́n ti kìlọ̀ fún mi gan-an nípa ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ìsọfúnni pẹ̀lú ẹ̀yà òdìkejì, síbẹ̀ ojoojúmọ́ ni mò ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí i. Èyí kì í ṣe ọ̀nà tó dára rárá láti gbà máa lo tẹlifóònù náà.” c

Bíbélì gbà wá níyànjú láti “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.” (1 Pétérù 3:16) Ṣíṣe èyí ń béèrè pé tó o bá ń lo tẹlifóònù alágbèérìn gẹ́gẹ́ bí ohun tí Koichi sọ, o ní láti rí i dájú pé, “kò sí ohun kankan tó lè tì ọ́ lójú,” kódà bí ẹlòmíràn bá ṣèèṣì rí ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ sínú tẹlifóònù rẹ̀ tàbí tó fetí kọ́ ohun tó ò ń sọ lórí tẹlifóònù. Máa rántí nígbà gbogbo pé, kò sí àṣírí tí Baba wa ọ̀run kò mọ̀. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Kò . . . sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú [Ọlọ́run], ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tó o fi ń gbìyànjú láti ní àjọṣe kan ní bòókẹ́lẹ́ pẹ̀lú ẹnì kan?

Fi Ààlà sí Bí Wàá Ṣe Máa Lò Ó

Bó o bá ń ronú láti ní tẹlifóònù alágbèérìn, o ò ṣe kọ́kọ́ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ipò rẹ ná kó o lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo nílò rẹ̀? Jíròrò ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Àwọn kan wò ó lọ́nà tí ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jenna gbà wò ó, ó sọ pé: “Lílo tẹlifóònù alágbèérìn jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ńlá kan tó wúwo jù fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ láti bójú tó.”

Kódà bó o bá pinnu pé wàá ní tẹlifóònù alágbèérìn, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Lọ́nà wo? Nípa fífi ààlà tó mọ́gbọ́n dání sí bí wàá ṣe máa lò ó ni. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ kí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rẹ̀ tí wàá máa lò tàbí iye àkókò àti owó tí wàá máa ná sórí tẹlifóònù náà mọ níba. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ tẹlifóònù ti máa ń pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa béèyàn ṣe lò ó, o lè máa bá àwọn òbí rẹ jíròrò lórí iye tó o ní láti san lórí tẹlifóònù náà látìgbàdégbà. Àwọn kan rí i pé ó rọ àwọn lọ́rùn láti máa lo tẹlifóònù alágbèérìn tí wọ́n ti sanwó lílò rẹ̀ sílẹ̀ fún àkókò pàtó kan, láti dín bí wọ́n á ti máa lò ó kù.

Tún ronú dáadáa lórí ìgbà tí wàá máa fèsì padà bí ẹnì kan bá tẹ̀ ọ́ láago tàbí tó fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ọ, àti ọ̀nà tí wàá máa gbà fèsì padà. Gbé àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu tó o fẹ́ máa fúnra rẹ tẹ̀ lé kalẹ̀. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Shinji sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́ ni mo máa ń wo ibi tí ìsọfúnni máa ń wà nínú tẹlifóònù mi, ìgbà tí àwọn ìsọfúnni bá sì ṣe pàtàkì gan-an nìkan ni mo sábà máa ń fèsì padà. Látàrí èyí, àwọn ọ̀rẹ́ mi kì í fi àwọn ìsọfúnni tí kò ní láárí ránṣẹ́ sí mi mọ́. Bí ìṣòro pàjáwìrì bá wà, wọ́n á wá ọ̀nàkọnà láti tẹ̀ mí láago.” Ní pàtàkì jù lọ, mọ irú àwọn ẹni tí wàá máa bá ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Ṣọ́ra fún sísọ nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ fún tajá-tẹran. Máa lo irú ìlànà kan náà tó o máa ń tẹ̀ lé nípa yíyan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere.—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníwàásù 3:1, 7) Ó ṣe kedere pé, tẹlifóònù alágbèérìn náà gbọ́dọ̀ ní “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́.” Àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa jẹ́ “ìgbà tí a yàn kalẹ̀” fún jíjọ́sìn Ọlọ́run, kì í ṣe fún lílo tẹlifóònù. Àwọn máníjà ilé àrójẹ àti gbọ̀ngàn ìwòran sábà máa ń sọ fún àwọn oníbàárà wọn láti má ṣe lo tẹlifóònù alágbèérìn. A máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tẹ̀ lé irú ìlànà bẹ́ẹ̀. Láìsí àní-àní, ó yẹ ká fún Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run náà ní irú ọ̀wọ̀ yíyẹ bẹ́ẹ̀!

Ọ̀pọ̀ máa ń pa tẹlifóònù wọn ni àyàfi bí wọ́n bá ń retí ìkésíni pàtàkì kan, tàbí kẹ̀, wọ́n á yí i wálẹ̀ lọ́nà tí kò fi ní pariwo nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì lọ́wọ́. Àwọn kan kì í fi tẹlifóònù alágbèérìn wọn sí àrọ́wọ́tó. Ó ṣe tán ọ̀pọ̀ lára àwọn ìkésíni wọ̀nyẹn la lè bójú tó nígbà tó bá yá.

Bó o bá pinnu láti ní tẹlifóònù alágbèérìn, rí i pé ìwọ lò ń darí rẹ̀, má ṣe jẹ́ kó darí rẹ. Ó dájú pé o ní láti wà lójúfò, kó o sì rí i pé bó o ṣe ń lò ó kò ṣèdíwọ́ fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Bó o bá pinnu láti ní tẹlifóònù alágbèérìn, jọ̀wọ́ rí i dájú pé ò ń fi òye hàn nínú bó o ṣe ń lò ó.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Fún ìjíròrò lórí ṣíṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ lẹ́yìn àkókò ilé ẹ̀kọ́, jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà, “Awọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Kí Ló Burú Nínú Wíwá Owó?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! September 22, 1997.

c Bíbá ẹ̀yà òdìkejì sọ̀rọ̀ déédéé tàbí títẹ ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí tẹlifóònù lè jẹ́ oríṣi ọ̀nà kan láti dá ọjọ́ àjọròde. Jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà, “Awọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Ki Ni O Buru Ninu Bíbá Ẹnikinni Keji Sọ̀rọ̀?”, èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! August 22, 1992.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn ọ̀dọ́ kan ń ní àjọṣe bòókẹ́lẹ́ nípasẹ̀ tẹlifóònù alágbèérìn