Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Máa Mú Àlàáfíà Pípẹ́títí Wá?

Ta Ló Máa Mú Àlàáfíà Pípẹ́títí Wá?

Ta Ló Máa Mú Àlàáfíà Pípẹ́títí Wá?

KÍ LÓ dé tí Ọlọ́run ò ṣe tíì dáhùn àwọn àdúrà àlàáfíà táwọn tó jẹ́ aṣáájú nínú onírúurú ìsìn ayé ń gbà? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó fani lọ́kàn mọ́ra. Kì í ṣe pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà—kódà, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún àlàáfíà jinlẹ̀ gan-an ju ti àwọn àlùfáà tó ń gbàdúrà lọ. Àní, Ọlọ́run ti ṣe àwọn ètò gúnmọ́ kan láti mú kí àlàáfíà ayé ṣeé ṣe. Ó ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì láti ṣe èyí. Ó tún ti sọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé ní kedere. Àmọ́ ṣá, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ìsìn ayé kò kọbi ara sí ohun tí Ọlọ́run sọ rárá.

Nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, Ọlọ́run ṣèlérí “irú-ọmọ” kan, tí yóò jẹ́ alákòóso, ẹni tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé nípa pípèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni nípa ẹni tó máa jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:18; 49:10) Wòlíì Aísáyà, ẹni tó gbajúmọ̀ fún jíjẹ́ tó jẹ́ òǹkọ̀wé àwọn àkànṣe àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, kọ̀wé pé Aṣáájú tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ yìí yóò di “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” lórí ilẹ̀ ayé, àti pé lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, “àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7) Alákòóso tó máa ṣàkóso látòkè ọ̀run yìí yóò fòpin sí ìwà búburú, yóò sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè, níbi tí ìwà ìrẹ́nijẹ, àìsàn, ipò òṣì, àti ikú kì yóò ti sí mọ́. Àlàáfíà àti ìyè àìnípẹ̀kun ló máa gbayé kan. (Sáàmù 72:3, 7, 16; Aísáyà 33:24; 35:5, 6; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:4) Ìgbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀?

Àlàáfíà Ayé ti Sún Mọ́lé

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, ṣáájú kí òpin tó dé bá ètò àwọn nǹkan búburú yìí àti kí àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tuntun tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé orí ilẹ̀ ayé, onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà tó ń mi ayé tìtì yóò máa ṣẹlẹ̀, tí ìwọ̀nyí á sì máa ṣẹlẹ̀ pa pọ̀ lásìkò kan náà. (Mátíù 24:3, 7-13) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí—irú bí ogun, ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, ká kàn mẹ́nu kan díẹ̀ péré—ń wáyé lóòrèkóòrè ní gbogbo sànmánì, àmọ́ gbogbo wọn lápapọ̀ kò tíì ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà tàbí kí wọ́n máa wáyé jákèjádò ayé gẹ́gẹ́ bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ ní sànmánì tiwa yìí. Bákan náà, àbájáde irú àwọn ìṣòro kíkàmàmà bẹ́ẹ̀ máa ń burú gan-an ju bó ti ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ nítorí pé àwọn èèyàn tó ń gbé nínú ayé ti pọ̀ sí i.

Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni bí ẹ̀dá èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́, èyí tó ń bá a lọ láìdáwọ́dúró. (Ìṣípayá 11:18) Láfikún sí i, ṣáájú kí òpin tí a sọ tẹ́lẹ̀ yìí tó dé, a ní láti ṣe iṣẹ́ ìkìlọ̀ kan jákèjádò ayé, ìyẹn ni wíwàásù “ìhìn rere ìjọba” náà. Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe iṣẹ́ yìí jákèjádò ayé.—Mátíù 24:14.

Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn yóò jẹ́ ìhìn rere fún ìran èèyàn olùṣòtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni o, ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò ní ojúlówó àlàáfíà ti sún mọ́lé! Ìyẹn ni yóò fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ìkórìíra àti ìpániláyà yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá, tí a kò sì ní gbúròó wọn mọ́. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.

Irú Àdúrà tí Ọlọ́run Ń Gbọ́

Gbígbàdúrà sí Ọlọ́run kì í ṣe ohun téèyàn kàn ń ṣe ṣáá láìnítumọ̀ tàbí ààtò ìsìn onípẹ́pẹ́fúúrú kan lásán. Bíbélì pe Jèhófà ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Nítorí náà, ìgbàkigbà téèyàn ì báà gbàdúrà, Ọlọ́run ń fetí sí àìmọye àdúrà táwọn olóòótọ́ ọkàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń gbà sí i. Àmọ́ o, ǹjẹ́ àwọn ohun kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè fetí sí àdúrà wa? Bíbélì fi hàn pé àwọn olóòótọ́ ọkàn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ọlọ́run ní láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n kọ́, kí wọ́n sì di “olùjọsìn tòótọ́,” ìyẹn àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:23) Òun kì í dáhùn àdúrà àwọn tí kò bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ìyẹn ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń yí etí rẹ̀ kúrò nínú gbígbọ́ òfin [Ọlọ́run]—àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.”—Òwe 28:9.

Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn lónìí ni kì í fi ète Ọlọ́run láti mú àlàáfíà wá kọ́ àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gbàdúrà nípa ète náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìjọba ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n máa ń gbàdúrà fún láti yanjú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ní kedere pé “kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn ní sànmánì tiwa yìí, àwọn olùfẹ́ àlàáfíà yóò máa wọ́ tìrítìrí lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, èyí tó dúró fún ìjọsìn tòótọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ṣe ìyípadà tó kọyọyọ nínú ìgbésí ayé wọn: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:2-4.

Ǹjẹ́ àwùjọ àwọn olùjọsìn kan wà lónìí tó ń tiraka láti gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn? Àbí ńṣe ni gbogbo ìsìn wulẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà lásán nígbà tí wọ́n tún ń ṣagbátẹrù ogun lọ́wọ́ kan náà? Nígbà míì tó o bá tún bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, a rọ̀ ọ́ láti jíròrò ọ̀ràn nípa àlàáfíà pẹ̀lú wọn, kó o lè mọ ìsìn tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láti máa bá gbogbo èèyàn gbé ní àlàáfíà.