Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

“Àlá Asán Láti Di Ọlọ́rọ̀”

Ìwé ìròyìn Times of Zambia sọ pé, bí wọ́n ṣe máa ń gbé tẹ́tẹ́ títa lárugẹ gan-an nínú ìpolówó ọjà ti tan ọ̀pọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù jẹ láti máa rò pé àwọ́n lè di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ tẹ́tẹ́ títa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣàṣà lẹni tó lè jẹ owó tó ní láárí nínú gbogbo àwọn tó ń ta á. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ṣe sọ, “pípolówó tẹ́tẹ́ lọ́tìrì máa ń mú káwọn èèyàn máa lá àlá asán láti di ọlọ́rọ̀, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n máa fọkàn yàwòrán ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì, kí wọ́n sì máa ronú pé ojú ẹsẹ̀ làwọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé tí kò ní ìṣòro rárá,” àmọ́ “wọn kì í sábà mẹ́nu kàn án pé iye àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ tẹ́tẹ́ ọ̀hún kéré jọjọ.” Ìwé ìròyìn náà wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kò sí àlàyé tí ẹnikẹ́ni lè ṣe o, olè ojúkorojú ni tẹ́tẹ́ títa jẹ́, ohun tó sì yẹ ká fòfin dè ní gbogbo àwùjọ ọmọlúwàbí ni.”

Ẹ̀rù Òkùnkùn Ń Bà Wọ́n

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London ṣe sọ, “àwọn ọmọdé máa ń bẹ̀rù òkùnkùn ju bí àwọn òbí wọn ṣe bẹ̀rù rẹ̀ lọ nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé. Ìdí rẹ̀ ni pé, bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń rí ìmọ́lẹ̀ àtọwọ́dá lálaalẹ́ kì í jẹ́ kí wọ́n fi bẹ́ẹ̀ wà nínú òkùnkùn biribiri.” Aric Sigman, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú àti òǹkọ̀wé, ṣe ìwádìí kan tó fi hàn pé nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò tíì pé ọdún mẹ́wàá ló máa ń takú pé àwọ́n fẹ́ rí ìmọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ sùn lálẹ́. Ó sọ pé àìkìíwà nínú òkùnkùn yìí, àní nígbà tí wọ́n bá lọ sùn pàápàá, kì í jẹ́ kí agbára ìfinúyàwòrán-nǹkan àwọn èwe gbòòrò. Ìròyìn náà sọ pé “ó yẹ ká fún agbára ìfinúyàwòrán-nǹkan àwọn ọmọdé láyè láti gbòòrò sí i. Bí wọ́n bá ń ṣeré ìdárayá nínú òkùnkùn, èyí lè ru ìmọ̀lára wọn sókè, nítorí pé gbogbo eré tí wọ́n bá ń ṣe á jẹ́ àtọkànwá.” Àmọ́ lónìí, “àwọn àwòrán àtọwọ́dá tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀, èyí tó máa ń wà nínú tẹlifíṣọ̀n, nínú eré sinimá àti nínú eré orí kọ̀ǹpútà ló máa ń wà lọ́kàn àwọn ọmọdé fún ìgbà pípẹ́,” ó sì máa ń dẹ́rù bà wọ́n. Ọ̀mọ̀wé Sigman tún sọ pé: “Bí ìmọ̀ràn ayé àtijọ́ ló ṣe máa ń rí tá a bá ń sọ pé káwọn ọmọ túbọ̀ máa kàwé kí wọ́n sì dín tẹlifíṣọ̀n wíwò kù, àmọ́ ó yẹ ká máa tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí gbọnmọgbọnmọ.”

Ohun Ìní Tí Kò Dọ́gba

Ìwé The State of World Population 2001 ròyìn pé, ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ayé ló ń dá lo ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ohun ìní àti nǹkan amáyédẹrùn ayé báyìí. Ìròyìn náà, èyí tí Àjọ Tó Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Iye Èèyàn Àgbáyé gbé jáde, kìlọ̀ pé “‘ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ’” ló wà láàárín àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà àtàwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà tó bá di ọ̀rọ̀ “ọjà rírà.” Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, “bí wọ́n bá bí ọmọ kan lónìí ní orílẹ̀-èdè kan tó ti gòkè àgbà, yóò ra ohun ìní púpọ̀ tí èyí yóò sì ṣokùnfà ìbàyíkájẹ́ púpọ̀ sí i ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ju èyí táwọn ọmọdé bí ọgbọ̀n sí àádọ́ta tí wọ́n bá bí ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà máa ṣe lọ. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ìdá kan nínú márùn-ún àwọn èèyàn ayé, tí wọ́n ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, ló ń ṣokùnfà ohun tó lé ní ìdajì gáàsì carbon dioxide tó ń tú sínú afẹ́fẹ́, nígbà tó jẹ́ pé ìdá mẹ́ta péré nínú ọgọ́rùn-ún gáàsì náà ló ń jẹ́ látọwọ́ ìdá kan nínú márùn-ún àwọn tó tòṣì jù lọ lágbàáyé. Kò tán síbẹ̀ o, àgbègbè ilẹ̀ tàbí agbami òkun tí ẹnì kan ṣoṣo tó wà láwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ nílò láti mú kí ìgbésí ayé dẹrùn fún un fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ìlọ́po mẹ́rin pọ̀ ju èyí ti ọ̀pọ̀ èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nílò lọ.

Ètò Gbalasa Òfuurufú Ilẹ̀ Ṣáínà

Ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC News ròyìn pé, ní April 1, 2002, ọkọ̀ àgbéresánmà [Shenzhou III] ti ilẹ̀ Ṣáínà, èyí tí kò sí èèyàn kankan nínú rẹ̀, balẹ̀ láìséwu ní àgbègbè Inner Mongolia lẹ́yìn ìrìn-àjò rẹ̀ ọlọ́sẹ̀ kan. Ọkọ̀ àgbéresánmà náà gbé “èèyàn àtọwọ́dá” kan dání fún ìwádìí náà—ìyẹn ni ọmọlangidi kan tí wọ́n di àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń wo nǹkan mọ́ lára, láti mọ bí ìwọ̀n afẹ́fẹ́ oxygen ṣe pọ̀ tó ní gbalasa òfuurufú àti láti díwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù rẹ̀. Èyí jẹ́ àwòkọ́ṣe láti fi mọ̀ bóyá á ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti lè gbé ní gbalasa òfuurufú bí wọ́n bá rán àwọn èèyàn lọ síbẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń bójú tó ètò gbalasa òfuurufú nílẹ̀ Ṣáínà ti kéde pé àwọ́n ń ṣètò láti rán ẹ̀dá èèyàn kan lọ sí gbalasa òfuurufú ní, ó pẹ́ tán ọdún 2005. Ìròyìn náà sọ pé “góńgó tí ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò gbalasa òfuurufú nílẹ̀ Ṣáínà ń lé ni pé, ó pẹ́ tán a ò rírú ẹ̀ rí, àwọ́n á rán èèyàn lọ sínú Òṣùpá títí ọdún 2010.”

Ipa Tí Lílo Egbòogi Ń Ní Lórí Àwọn Àgbàlagbà

Ìwé ìròyìn Der Spiegel ti ilẹ̀ Jámánì sọ pé “àwọn ẹni tó bá ti lé ní ọmọ ọgọ́ta ọdún máa ń lo oríṣi oògùn mẹ́ta ní ìpíndọ́gba, èyí sì jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta ti àwọn aláìsàn tó kéré sí wọn gan-an lọ́jọ́ orí. Àmọ́, ewu kí [oògùn] máa ṣiṣẹ́ gbòdì lára, látàrí àwọn àbájáde búburú tó lè jẹ yọ látinú oògùn lílo, máa ń lọ sókè gan-an ni bí iye oògùn téèyàn ń lò ṣe ń pọ̀ sí i.” Ìṣòro mìíràn tó ṣeé ṣe kó yọjú ni pé “àwọn dókítà ìdílé . . . kì í sábà ronú nípa bí kíndìnrín àwọn àgbàlagbà ṣe máa ń kọṣẹ́ díẹ̀díẹ̀ nítorí ọjọ́ ogbó.” Àbájáde èyí ni pé, àwọn oògùn tí wọ́n ń lò lè máa ṣẹ́ jọ sínú ara. Nípa bẹ́ẹ̀, “iye egbòogi tí kò lè ṣèpalára fún ẹnì kan tó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún lè jẹ́ májèlé fún ẹni tó jẹ́ ọmọ àádọ́rin ọdún,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Der Spiegel ṣe ṣàlàyé. “Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tiẹ̀ tún máa ń mú nǹkan le fún ara wọn nípa ṣíṣàì máa mu omi tó pọ̀ tó.” Ìròyìn náà fi kún un pé, ìpàdánù omi ara lásán lè ṣokùnfà àwọn ìṣòro tó fara jọ irú èyí téèyàn lè ní bó bá ń lo àwọn oògùn apàrora, oògùn amárarọni, àtàwọn oògùn tó ń ṣèdènà ẹ̀jẹ̀ ríru. Lára àwọn àmì ìṣòro yìí sì ni ìdàrú ọkàn, ṣíṣe ìràn-ǹ-rán, àti kí òòyì máa kọ́ni, èyí tí àwọn èèyàn wulẹ̀ máa ń pè ní àmì ọjọ́ ogbó.

Àwọn Kìnnìún Wà Nínú Ewu

Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé “ó ṣeé ṣe kí kìnnìún di ẹranko tó máa kú àkúrun ní ọ̀pọ̀ àgbègbè ilẹ̀ Áfíríkà.” Ó máa gbà tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìnnìún sí ẹgbẹ̀rún kan tí ẹ̀ya wọn yàtọ̀ síra láti lè rí ọgọ́rùn-ún kìnnìún tó jẹ́ akọ àti abo tó máa lè gun ara wọn—iye yìí ni kò ní jẹ́ kí àwọn kìnnìún tó jẹ́ ara ìdílé kan náà máa gun ara wọn. Níbàámu pẹ̀lú àkíyèsí tí Ẹgbẹ́ Tó Ń Dáàbò Bo Ìṣẹ̀dá Lágbàáyé ṣe, iye kìnnìún tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà àti Àárín Gbùngbùn Áfíríkà kéré gan-an ni sí iye tá a mẹ́nu kan lókè yìí. Hans Bauer tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Leiden ní orílẹ̀-èdè Netherlands sọ pé “ọ̀ràn ọ̀hún kì í ṣe ọ̀ràn kékeré rárá o. Kò sí ẹ̀ya kankan lára àwọn ẹranko wọ̀nyí tá a lè fọwọ́ sọ̀yà pé wọ́n á ṣì máa wà níbẹ̀ títí lọ gbére.” Lájorí ohun tó ń fa bí kìnnìún ṣe ń dín kù ni bí àwọn èèyàn ṣe ń gba ilẹ̀ tó jẹ́ ibùgbé wọn. Àwọn kìnnìún nílò àgbègbè ìṣọdẹ tó tóbi gan-an—èyí tó máa tó igba [200] kìlómítà níbùú lóròó fún akọ kìnnìún kan. Bauer kìlọ̀ pé: “Kìnnìún jẹ́ irú ọ̀wọ́ ẹranko kan tí àwọn ẹranko mìíràn fẹ̀yìn tì. Àmì ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ o—nítorí pé bá a ṣe ń fi àwọn kìnnìún sínú ewu nísinsìnyí lè túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe kí irú ọ̀wọ́ àwọn ẹranko mìíràn kú àkúrun bó bá fi máa di ogún ọdún sí ọgbọ̀n ọdún sí àkókò tá a wà yìí.”

Ṣíṣépè Níbi Iṣẹ́

Ìwé ìròyìn The Gazette ti ìlú Montreal nílẹ̀ Kánádà sọ pé, èpè ṣíṣẹ́ ti wá di ohun tó wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀ ibi iṣẹ́. Àwọn ògbógi kan gbà pé ṣíṣépè máa ń dá kún másùnmáwo níbi iṣẹ́. Karen Harlos, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìhùwàsí níbi iṣẹ́ ní Yunifásítì McGill, sọ pé: “Bí èpè ṣíṣẹ́ bá wà lára ọ̀nà tá a fi ń ṣàríwísí ẹnì kan, ó lè ní ipa búburú lórí bí ẹni tá a gbà ṣíṣẹ́ ṣe máa ṣiṣẹ́ tó pójú owó sí, lórí iyì ara ẹni rẹ̀, àti lórí ìlera rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ṣe sọ, “ọ̀gá ló sábà máa ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀” níbi iṣẹ́, èyí táwọn ọmọọṣẹ́ máa tẹ̀ lé. Bí èpè ṣíṣẹ́ níbi iṣẹ́ bá ń kó ìdààmú bá ọ, ìwé ìròyìn The Gazette dábàá pé kó o kọ́kọ́ lọ bá “ẹni tó o rò pé ó ń kọjá àyè rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ, kó o sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ fún onítọ̀hún pé kó yéé sọ ìsọkúsọ níbi tó o bá wà.”

“Àwọn Òkè Tó Lómi” Wà Nínú Ewu

Ìwé ìròyìn The Toronto Star ti ilẹ̀ Kánádà sọ pé, ìdajì lára àwọn olùgbé ayé ló jẹ́ pé omi tí kò ní iyọ̀ tó ń wá látinú àwọn òkè ńlá ni wọ́n gbára lé. Àwọn òkè ńlá wọ̀nyí, tí wọ́n pè ní “àwọn òkè olómi àgbáyé” wà nínú ewu ńlá gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kọ láti fi sàmì sí Ọdún Àwọn Òkè Ńlá ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Star ṣe sọ, àwọn ohun tó ń ṣàkóbá yìí ni “ìyípadà nínú ipò ojú ọjọ́, ìbàyíkájẹ́, ogun jíjà, ìṣòro àpọ̀jù èèyàn, pípa igbó run, àti bí àwọn ilé iṣẹ́ oníṣẹ́ àgbẹ̀, ilé iṣẹ́ ìwakùsà, àti ilé iṣẹ́ ìrìn-àjò afẹ́ ṣe ń lò wọ́n nílòkulò.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, ìkìlọ̀ tí wọ́n ṣe nínú ìròyìn ọ̀hún ni pé, “bí wọ́n ṣe ń dín àwọn òkè tó lómi kù yìí yóò yọrí sí ọ̀pọ̀ omíyalé, ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀ ilẹ̀, àti ìyàn ńlá.”

Sísọ Ọtí Líle Di Bárakú

Ìwé ìròyìn The Independent ti ìlú London sọ pé, èèyàn kan nínú mẹ́tàlá nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ti sọ ọtí líle di bárakú, tí èyí sì mú kí sísọ ọtí líle di bárakú di “ohun tó wọ́pọ̀ ní ìlọ́po méjì ju bí sísọ oògùn olóró tàbí egbòogi tí dókítà fúnni di bárakú ṣe wọ́pọ̀ lọ.” Látọdún 1994 sí 1999, ikú tí àmujù ọtí líle ṣokùnfà—títí kan àwọn ìṣòro bí àrùn ọkàn àyà, ìsúnkì ẹ̀dọ̀, àti májèlé inú ọtí líle—ti lọ sókè sí nǹkan bí ìdá mẹ́tàlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún. Jàǹbá ọkọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ látàrí mímu ọtí yó kéèyàn tó wakọ̀ ti lọ sókè láti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé ọgọ́rùn-ún [10,100] lọ́dún 1998 sí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá, ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́rin [11,780] lọ́dún 2000, èyí ló sì ṣokùnfà ìdá kan nínú méje ikú tó ń pa àwọn èèyàn lójú pópó. Ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn agbanisíṣẹ́ ló ń ní ìṣòro pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ wọn tó jẹ́ òkú ọ̀mùtí, ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó sì máa ń hu ìwà ọ̀daràn ló jẹ́ nítorí ọtí líle tí wọ́n ń mu. Eric Appleby, olùdarí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìmukúmu Ọtí Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Bí ìṣòro ọ̀hún ṣe rinlẹ̀ tó sì gbòde kan tó, bó ṣe máa ń nípa lórí ìlera àwọn èèyàn àti lórí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àti bó ṣe máa ń gbọ́n owó àpò wọn gbẹ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ipa tó ń ní lórí àwùjọ, . . . fi hàn pé ọ̀ràn yìí nílò ìgbésẹ̀ kánjúkánjú, èyí tó yẹ ká pawọ́ pọ̀ ṣe.”