Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Fara Hàn Gbangba Níbi—Iṣẹ́ Àfiṣèrànwọ́ Kan Tó Fa Kíki

Ìfẹ́ Fara Hàn Gbangba Níbi—Iṣẹ́ Àfiṣèrànwọ́ Kan Tó Fa Kíki

Ìfẹ́ Fara Hàn Gbangba Níbi—Iṣẹ́ Àfiṣèrànwọ́ Kan Tó Fa Kíki

ṢÀṢÀ lohun tó máa ń wú Richard Vara tó jẹ́ olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn Houston Chronicle lórí, àmọ́ lọ́dún tó kọjá ohun kan ṣẹlẹ̀ tó ṣe é ní kàyéfì. Tọkàntọkàn ló fi sọ pé: “Mi ò rí irú eléyìí rí láyé mi o! Áà, ó ṣòro fún mi láti gbà gbọ́.” Ẹlòmíràn tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún tún wú lórí ni ọ̀gbẹ́ni Lee P. Brown, ẹni tó jẹ́ olórí ìlú Houston, ní ìpínlẹ̀ Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé: “Ì bá wù mí pé kí gbogbo aráàlú Houston rí ohun tẹ́ ẹ ṣe. Èyí wú mi lórí gidigidi.” Kí lohun tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lé lórí? Iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Houston ni olóòtú ìwé ìròyìn náà àti olórí ìlú náà ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Kí ni ohun tó wé mọ́ iṣẹ́ tí wọ́n ṣe yìí? Kí ló ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi ṣe é? Àti pé, kí ló mú kó máa wúni lórí tó bẹ́ẹ̀? Láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká tibi pẹlẹbẹ mọ́ọ̀lẹ̀ jẹ́.

Omíyalé Tó Burú Jù Lọ Tí Irú Ẹ̀ Ò Wáyé Rí Nílùú Houston

Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ oṣù June ọdún 2001, ìjì líle kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Allison kọ lu àgbègbè kan tó tẹ́jú ní gúúsù ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Texas. Nígbà tó máa fi di ọjọ́ Friday June 8, láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún péré, ìjì líle Allison ti mú kí òjò ọlọ́gbàrá tó ga ní mítà kan rọ̀ sórí ìlú Houston—ìlú ńlá tó tóbi ṣìkẹrin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. a Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, omi tó ń ga sókè sí i yìí ti ya wọnú àwọn ṣọ́ọ̀bù, ọ́fíìsì àti nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ [70,000] ilé. Àwọn títì márosẹ̀ tó wà káàkiri ìlú ti di alagbalúgbú odò, tí èyí sì ń bo àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtàwọn ọkọ̀ ńlá tí kò lè lọ mọ́. Omi tó ń ga sí i yìí kò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ọkọ̀ panápaná àtàwọn ọkọ̀ mìíràn tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là láti ráyè kọjá làwọn òpópónà tí omi ti kún fọ́fọ́. Èyí ló mú ki wọ́n ṣètò pé káwọn hẹlikóbítà àtàwọn ọkọ̀ ológun mìíràn tó jẹ́ arinkòtò-ringegele wá ṣèrànwọ́ láti yọ àwọn èèyàn nínú ewu.

Níkẹyìn, nígbà tí ojú sánmà mọ́ foo lọ́jọ́ Monday June 11, ó wá ṣe kedere pé ìjì líle Allison ti mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ, ó sì ti ba àìmọye dúkìá jẹ́. Èèyàn méjìlélógún ló ti ṣekú pa, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì: Jeffrey Green, Kristẹni alàgbà kan, àti àbúrò ìyàwó rẹ̀, Frieda Willis. b Láfikún sí i, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ [70,000] ilé ló ti bà jẹ́, tí èyí sì mú kí omíyalé yìí jẹ́ ìjábá tó burú jù lọ tó tíì wáyé ní ìlú ńlá kan. Ní ti gidi, ohun ìní tí ìjì líle Allison bà jẹ́ ń lọ sí bílíọ̀nù márùn-ún dọ́là, èyí mú kó jẹ́ ìjì líle tó tíì pani lára jù lọ nínú ìtàn ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Omilẹgbẹ Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Rọ́ Dé

Jìnnìjìnnì bo tọmọdé tàgbà látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ọ̀kan lára àwọn tó wá ṣèrànwọ́ sọ pé: “Ńṣe ni gbogbo bẹ́ẹ̀dì wọn rin gbingbin fún omi. Gbogbo kápẹ́ẹ̀tì ti mu omi yó. Gbogbo fọ́tò àwọn ọmọ wọn àtèyí táwọn náà yà nígbà ọmọdé ló bómi lọ.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] tó ń gbé ní àgbègbè Houston kò ṣàì fara gbá nínú àjálù náà. Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ àti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ló bà jẹ́. Omi tó wọnú àwọn ilé kan ga tó sẹ̀ǹtímítà bíi mélòó kan; omi sì mu àwọn ilé mìíràn dé òrùlé. Lápapọ̀, ó lé ní ọgọ́rin ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjábá náà kàn. Àmọ́, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ò dá wọn dá ìṣòro wọn. Láàárín ọjọ́ díẹ̀, omilẹgbẹ mìíràn tún ya dé—ṣùgbọ́n ti ọ̀tẹ̀ yìí yàtọ̀, ẹgbàágbèje èèyàn tó wá ṣèrànwọ́ ni. Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀?

Kódà kó tó di pé àkúnya omi náà bẹ̀rẹ̀ sí fà, àwọn Kristẹni alàgbà ní ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Houston ti bẹ̀rẹ̀ sí wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà láìjáfara. Alàgbà kan sọ pé: “A fóònù àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a sì bẹ̀ wọ́n wò. Ẹ̀yìn tá a ṣèyẹn tán la wá ṣírò iye àwọn ohun tó bà jẹ́, nígbà tó sì fi máa di ọjọ́ Monday June 11, a ti ṣàkójọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa gbogbo àwọn tó pàdánù ohun ìní wọn, iye ilé tó bà jẹ́, àti bí ohun tó bà jẹ́ ṣe pọ̀ tó. A wá fi ìròyìn náà ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, nílùú New York.” Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Amẹ́ríkà ṣètò ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ kan, àwọn Kristẹni alàgbà mẹ́jọ nílùú Houston ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ náà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà sì tún fi owó àkànlò ránṣẹ́ láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìjábá náà kàn. Kí ni iṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà? Ó jẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá kí wọ́n lè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn, àti láti ṣàtúnṣe ilé àwọn Ẹlẹ́rìí tó bà jẹ́—àwọn ilé ọ̀hún sì ju ọgọ́rùn-ún méje lọ!

Àwọn tó jẹ́ ara ìgbìmọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà, èyí tí wọ́n pè ní Ìgbìmọ̀ Aṣèrànwọ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Houston Lọ́dún 2001, bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn pé, ‘Báwo la ṣe fẹ́ gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí ṣe?’ Wọ́n ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, àní títí wọ ọ̀gànjọ́ òru pàápàá, níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwéwèé àkọ́kọ́ṣe lórí iṣẹ́ náà. Wọ́n wá ké sí àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ọgọ́jọ lágbègbè Houston láti wá ṣèrànwọ́. Alága ìgbìmọ̀ náà sọ pé: “Báwọn ará ṣe tú yááyáá tí wọ́n tú yààyàà láti wá jẹ́ ìpè wa kọ yọyọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [11,000], tí wọ́n fi àkókò wọn, okun wọn, àti òye tí wọ́n ní nídìí iṣẹ́ wọn ṣèrànwọ́ láìgba kọ́bọ̀.”

Bí Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ṣe Kojú Ìṣòro Ògiri Tó Ń Hu Olú

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ọ̀yamùúmùú òjò náà rọ̀, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn lọ ṣiṣẹ́ nílé àwọn tí ìjábá náà ba ilé wọn jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń palẹ̀ àwọn nǹkan tó ti bà jẹ́ mọ́ kúrò, irú bíi kápẹ́ẹ̀tì tó ti rin gbingbin fún omi, ilẹ̀ tó ti sán, ògiri tó ti lanu, àwọn kọ́bọ́ọ̀dù tó ti mu omi yó, ilẹ̀kùn tó ti bà jẹ́, àti gbogbo nǹkan mìíràn tí ọ̀gbàrá ẹlẹ́gbin náà ti bà jẹ́. Ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn náà sọ pé: “Kì í ṣe pé ká kàn ṣàtúnṣe ilé àwọn arákùnrin wa ló ń jẹ wá lọ́kàn, àmọ́ a tún ń ṣàníyàn nípa ìlera wọn.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ni àwọn olú onímájèlé máa ń yára sú yọ lára ògiri àti nínú kọ́bọ́ọ̀dù, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi oògùn apakòkòrò fọ àwọn ilé náà tinú-tòde.

Láti mọ bí wọ́n á ṣe ṣe iṣẹ́ náà lọ́nà tí kò ní mú ìpalára wá, àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ arákùnrin, sọ pé kí Ẹ̀ka Ìjọba Àpapọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàjáwìrì, ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn. Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Ẹlẹ́rìí tí Ẹ̀ka náà ti fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ké sí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni mẹ́wàá mìíràn láti bá wọn lọ ṣiṣẹ́ ní ilé kan tó ti bà jẹ́, níbi tí wọ́n ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè fi oògùn apakòkòrò fọ ilé lọ́nà yíyẹ. Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹni mẹ́wàá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá lẹ́kọ̀ọ́ náà tún mú àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni mẹ́wàá mìíràn pẹ̀lú ara wọn láti lọ kọ́ àwọn náà. Olùyọ̀ǹda ara ẹni kan sọ pé: “Láàárín ọjọ́ díẹ̀, iye àwọn tó mọ bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ yìí ti wọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn.” Àwọn ògiri tó ń hu olú ọ̀hún kò lè dúró rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń pọ̀ sí i náà! Àwọn tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ àtàwọn ọ̀dọ́langba tó wà lákòókò ìsinmi ilé ẹ̀kọ́ wá ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ọ̀sán. Tó bá sì di alẹ́, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni mìíràn á gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn, wọ́n á sì máa báṣẹ́ náà lọ. Nígbà tó fi máa di ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé náà, gbogbo ilé àwọn Ẹlẹ́rìí tí èròjà onímájèlé náà wà lára wọn ló ti mọ́ tónítóní, tí kò sì lè ṣe ìpalára kankan mọ́.

Ibùdó Ìṣekòkáárí Kan Àtàwọn Ibi Ìpèsè Ìrànwọ́ Méje

Láàárín àkókò náà, ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ pátákó ìkọ́lé tí wọ́n ń pè ní gypsum àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun èlò ìkọ́lé mìíràn. Àmọ́ ibo ni wọ́n máa kó wọn sí? Agbẹnusọ fún ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà sọ pé: “Nígbà tí máníjà ilé iṣẹ́ kan gbọ́ nípa ohun tá a nílò, ó fún wa ní ilé ìkẹ́rùsí kan lò—èyí tí àyè ilẹ̀ rẹ̀ fẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún mítà níbùú lóròó—láìgba kọ́bọ̀!” Yàtọ̀ sí pé wọ́n kó àwọn ohun èlò ìkọ́lé sínú ilé ìkẹ́rùsí náà, wọ́n tún lo apá kan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àyè ọ́fíìsì. Láìpẹ́, ilé ìkẹ́rùsí náà wá di ibùdó ìṣekòkáárí fún iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà, níbi tí nǹkan bí igba sí ọ̀ọ́dúnrún olùyọ̀ǹda ara ẹni ti ń ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án, lóru, àti lópin ọ̀sẹ̀.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àgbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ilé tó bà jẹ́ náà wà, wọ́n pinnu láti ṣètò àwọn ibi ìpèsè ìrànwọ́ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba méje. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, ńṣe ni ibi ìpèsè ìrànwọ́ kọ̀ọ̀kan máa ń kún fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó wá ṣiṣẹ́. (Wo àpótí “Ojúkò Ìgbòkègbodò.”) Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ló ti jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ rí níbi kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba lágbègbè náà. Kódà, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ní òye iṣẹ́ ìkọ́lé nínú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wá ṣèrànwọ́ láti ìpínlẹ̀ Arkansas, Louisiana, Oklahoma àti Texas. c Ní ibi ìpèsè ìrànwọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn káfíńtà, àwọn kunlékunlé, àwọn oníṣẹ́ omi ẹ̀rọ àtàwọn òṣìṣẹ́ mìíràn tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ló jẹ́ aṣáájú níbi iṣẹ́ náà, tí wọ́n sì ń dá àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́.—Wo àpótí “Ètò Ìdánilẹ́kọ̀ọ́.”

Ṣíṣètò Iṣẹ́ Náà àti Ṣíṣàkójọ Ìsọfúnni Sínú Kọ̀ǹpútà

Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà ṣètò ilé kíkọ́ náà sí ìpele méje. Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n kó àwọn ohun èlò ìkọ́lé lọ sí àwọn ilé tó bà jẹ́ náà, wọ́n sì ṣètò pé kí iṣẹ́ àtúnṣe lórí ilé kọ̀ọ̀kan má gbà ju òpin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lọ. Lọ́nà yìí, yóò lè ṣeé ṣe fún wa láti parí gbogbo iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà.

Kí ètò tí ìgbìmọ̀ náà ṣe lè kẹ́sẹ járí, wọ́n dá ẹ̀ka méjìlélógún sílẹ̀, lára ìwọ̀nyí sì ni ẹ̀ka tó ń bójú tó ṣíṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ ibi tí wọ́n bá iṣẹ́ dé, ẹ̀ka tó ń mójú tó ríra àwọn ohun èèlò, ẹ̀ka ilé gbígbé àti ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò ìrìnnà. Àwọn ìsọfúnni tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà ti ṣàkójọ sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ kọ̀ǹpútà gbígbòòrò náà ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn ẹ̀ka náà láti ṣe iṣẹ́ wọn lọ́nà gbígbéṣẹ́. Ṣáájú kí iṣẹ́ àtúnṣe náà tó bẹ̀rẹ̀, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ti lo ọjọ́ mẹ́wàá gbáko láti fi kó gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n rí jọ sínú kọ̀ǹpútà. Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Kíkó gbogbo ìsọfúnni náà jọ sínú ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá.” Ṣùgbọ́n lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́wàá tó fa kíki yẹn, wọ́n ti ní àkójọ ìsọfúnni tó wúlò níkàáwọ́ wọn. Láàárín ìṣẹ́jú àáyá, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n fi ṣàkójọ ìsọfúnni náà lè jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [11,000] náà lè ráyè wá ṣèrànwọ́, irú iṣẹ́ tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe, àti bí wọ́n ṣe lè kàn sí wọn. Bákan náà ló tún jẹ́ kó rọrùn láti tètè mọ irú àtúnṣe tí wọ́n máa ṣe, àwọn ìwé àṣẹ ilé kíkọ́ tí wọ́n máa nílò láti gbà, àtàwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé mìíràn nípa àwọn ilé tó bà jẹ́. Orúkọ tí wọ́n fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí kọ̀ǹpútà náà ni “àwọn ohun tó ṣe kókó jù lọ nínú iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà.”

Orí Wọn Wú, Wọ́n sì Fi Ìmoore Hàn

Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́ á kọ́kọ́ lọ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé tí wọ́n ti fi oògùn apakòkòrò pa èròjà onímájèlé ara wọn, tí wọ́n sì ti gbẹ dáadáa, láti bàa lè pinnu ohun tí wọ́n máa nílò láti ṣe àtúnṣe ohun tó bà jẹ́. Agbẹnusọ ìgbìmọ̀ náà sọ pé: “Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni wọ̀nyí ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣirò lórí iṣẹ́ àtúnṣe ilé kọ̀ọ̀kan débi pé, wọ́n tún mọ iye ìṣó tí ilé náà máa nílò. A ò fẹ́ fi owó tàbí ohun èlò ìkọ́lé táwọn èèyàn fi ta wá lọ́rẹ ṣòfò rárá.” Lọ́wọ́ kan náà, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni mìíràn á lọ gba àwọn ìwé àṣẹ ìkọ́lé látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ ìlú.

Lẹ́yìn náà, wọ́n á ké sí àwọn ìdílé tí omíyalé náà ba ilé wọn jẹ́ láti wá sí ilé ìkẹ́rùsí náà kí wọ́n lè wo irú àwọn ohun èlò ilé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, irú bíi kápẹ́ẹ̀tì, kọ́bọ́ọ̀dù, ohun èlò vinyl tí wọ́n ń tẹ́ sórí ilẹ̀, àtàwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n nílò láti fi dí ohun tí wọ́n ti pàdánù. Orí àwọn ẹni wọ̀nyí wú nígbà tí wọ́n rí gbogbo ẹ̀bùn tí wọ́n dá jọ fún wọn, ńṣe ni omijé ayọ̀ sì ń bọ́ lójú wọn. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó mọ̀ nípa ọ̀ràn ìbánigbófò àtàwọn ìlànà ìjọba mìíràn tún fún wọn nímọ̀ràn nípa àwọn ohun tí wọ́n tún lè ṣe nípa ọ̀ràn ilé wọn. Lẹ́yìn èyí, wọ́n ṣètò bí wọ́n á ṣe ṣàtúnṣe ilé kọ̀ọ̀kan, ọjọ́ tí agbo òṣìṣẹ́ tó máa ṣiṣẹ́ kan bá nílò àwọn ohun èlò ìkọ́lé náà gan-an sì ni àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni máa fi ọkọ̀ akẹ́rù kó wọn wá. Ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń bá tún ilé rẹ̀ ṣe lọ́wọ́ sọ fún ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé: “Àwọn arákùnrin rẹ yìí mà ń ṣe bẹbẹ o. Bí àwọn òṣìṣẹ́ kan ṣe ń lọ, làwọn mìíràn ń ya wọlé. Ńṣe ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ bí èèrà!”

Lájorí iṣẹ́ àtúnṣe lórí ilé kọ̀ọ̀kan máa ń gba nǹkan bí òpin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Alága ìgbìmọ̀ náà sọ pé: “Àmọ́ o, nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀sẹ̀ márùn-ún tàbí mẹ́jọ pàápàá.” Nígbà táwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni bá yọ ògiri àwọn ilé tọ́jọ́ wọn ti pẹ́, wọ́n sábà máa ń ṣàkíyèsí pé àwọn ibì kan ti bà jẹ́ tẹ́lẹ̀, wọn kì í sì í fẹ́ fi ògiri tuntun síbẹ̀ láìkọ́kọ́ tún àwọn apá ibi tí ìṣòro ti wà tẹ́lẹ̀ náà ṣe. Olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tó jẹ́ oníṣẹ́ ọwọ́, sọ pé: “Nígbà míì, a máa ń rí i pé ikán wà nínú àwọn òpó tó wà láàárín ògiri, a ó wá rí i dájú pé a kọ́kọ́ pa gbogbo ikán ọ̀hún ráúráú. A ṣiṣẹ́ gan-an lórí àwọn igi àjà kí àwọn nǹkan lè wà nípò tó bójú mu. A sì máa ń rí i dájú pé ilé kan ti dúró sán-ún ká tó fibẹ̀ sílẹ̀.” Ọ̀kan lára àwọn tí omíyalé náà bá ilé wọn jẹ́, fi bí iṣẹ́ àtúnṣe náà ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn hàn, nígbà tó fi tìdùnnú-tìdùnnú sọ fún àlejò kan pé: “Báyìí, ilé mi ti wá dára ju ìgbà tí mo ṣẹ̀sẹ̀ rà á lọ!”

Oúnjẹ Àyáragbọ́

Láti pèsè oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan sọ ibi ìkẹ́rùsí tó wà lẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan di ibùdó oúnjẹ sísè àti pínpín oúnjẹ kiri. Àwọn Ẹlẹ́rìí káàkiri orílẹ̀-èdè náà fi ọ̀pọ̀ nǹkan tọrẹ, irú bí ẹ̀rọ amú-ǹkan-tutù, ẹ̀rọ amú-ǹkan-dì, ẹ̀rọ tó ń fọ abọ́, sítóòfù àtàwọn ohun èlò ilé ìdáná mìíràn. Ní gbogbo ọjọ́ Saturday àti Sunday, àwọn agbọ́únjẹ mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àtàwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó jẹ́ igba [200] máa ń se oúnjẹ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn níbẹ̀. Olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tó jẹ́ alábòójútó ilé ìdáná náà sọ pé: “A ti ń se oúnjẹ fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba fún bí ọdún mọ́kàndínlógún, àmọ́ èyí tá a ṣe lọ́tẹ̀ yìí gọntíọ, ó ju bá a ṣe rò lọ.”

Wọ́n máa ń kọ́kọ́ to àwọn abọ́ tí wọ́n ti bu oúnjẹ sí sínú ọgọ́fà àpótí ńlá. Wọ́n á wá to àwọn àpótí wọ̀nyí sínú ọgọ́ta ọkọ̀ akẹ́rù tó ti wà ní sẹpẹ́, èyí tó máa kó àwọn oúnjẹ náà lọ sí àwọn ibi ìpèsè ìrànwọ́ méjèèje àti ibùdó ìṣekòkáárí náà. Láàárín àkókò náà, agbo òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé kan á rán olùyọ̀ǹda ara ẹni kan lọ sí ibi ìpèsè ìrànwọ́ tí a yàn wọ́n sí láti lọ gbé oúnjẹ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ náà wá. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà máa ń jẹ oúnjẹ wọn nínú ilé tí wọ́n ń tún ṣe lọ́wọ́, wọ́n á sì padà lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Wọ́n Ṣe Iṣẹ́ Àfiṣèrànwọ́ Náà Ní Àṣeyanjú!

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní oṣù April ọdún 2002, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [11,700] parí iṣẹ́ náà, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ tó gba àkókò gígùn jù lọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tíì ṣe rí. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà lo bílíọ̀nù kan wákàtí nídìí iṣẹ́ náà láti ṣàtúnṣe àti láti ṣàtúnkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́tàlélógún [723] ilé. Ẹnì kan tí omíyalé náà ba àwọn ohun ìní rẹ̀ jẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, nígbà tó fi omijé ayọ̀ àti ẹ̀mí ìmoore sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àtàwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà fún gbogbo ìrànwọ́ tí wọ́n ti ṣe. Ìtùnú ńlá gbáà ni jíjẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ ará onífẹ̀ẹ́ yìí jẹ́!”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìlú New York, Los Angeles àti Chicago ni èrò inú wọn pọ̀ ju ti ìlú Houston lọ. Àwọn tó ń gbé ní ìlú Houston tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ [3,500,000], ìlú yìí sì tóbi ju orílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé lọ.

b Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Jeffrey àti Frieda tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọ̀ọ́dúnrún [1,300] ló pésẹ̀ síbi ètò ìsìnkú wọn. Ìtùnú kékeré kọ́ ni báwọn èèyàn ṣe dúró tì wọ́n já sí fún Abigail, ìyàwó Jeffrey tó sì tún jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Frieda.

c Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn wọ̀nyí ló sábà máa ń bójú tó iṣẹ́ kíkọ́ ibi ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

IBI ÌGBÒKÈGBODÒ

Ọjọ́ Saturday ni, ní aago méje òwúrọ̀, ní Ibi Ìpèsè Ìrànwọ́ Kẹrin tó wà ní ìhà àríwá ìlà oòrùn ìlú Houston. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń dápàárá, wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n ń sé kọfí mu, wọ́n sì ń jẹ dónọ́ọ̀tì bí gbogbo wọn ti ń bára wọn sọ̀rọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Àwọn kan ti wakọ̀ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà láti ìlú tí wọ́n ń gbé kí wọ́n lè débẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó di aago méje ààbọ̀ òwúrọ̀, gbogbo ìfọ̀rọ̀wérọ̀ alárinrin wọn lọọlẹ̀, alábòójútó ibi ìpèsè ìrànwọ́ náà sì darí ìjíròrò ẹsẹ Bíbélì kan. Ó tún ṣèfilọ̀ pé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa wáyé lọ́jọ́ Sunday ní aago méje ààbọ̀ òwúrọ̀ ṣáájú kí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà tó lọ sẹ́nu iṣẹ́ kálukú wọn, ó sì rọ̀ wọ́n láti kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nípa dídáhùn ìbéèrè yálà lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí lédè Spanish. Ó ka ìkíni tí wọ́n fi ránṣẹ́ láti orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé sétí wọn, ńṣe ni àtẹ́wọ́ sì ń dún wàá-wàá-wàá.

Lẹ́yìn náà ni alábòójútó ibi ìpèsè ìrànwọ́ náà sọ ibi tí wọ́n bá iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà dé, ó sì fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà fún ẹ̀mí ìmúratán tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹnì kankan wà níbí tí kò mọ ohun tó máa ṣe tàbí ibi tó ti máa lọ ṣiṣẹ́ lónìí?” Kò sẹ́ni tó nawọ́ sókè. Ó wá béèrè pé: “Oúnjẹ ẹ̀ẹ̀melòó la nílò?” Kíá, gbogbo wọ́n nawọ́ sókè, tí ẹ̀rín sì ń bọ́ lẹ́nu wọn. Níkẹyìn, wọ́n gbàdúrà, àwọn àádọ́talérúgba [250] olùyọ̀ǹda ara ẹni náà—àtọkùnrin, àtobìnrin, àtọmọdé àtàgbà—sì gbọ̀nà ibi iṣẹ́ wọn, wọ́n ti wà ní sẹpẹ́ fún iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n máa ṣe lọ́jọ́ náà.

Báyìí ni nǹkan ṣe ń rí ní gbogbo àwọn ibi ìpèsè ìrànwọ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yòókù àti ní ilé ìkẹ́rùsí náà. Lákòókò kan náà, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìdáná ńlá kan ti bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ sísè ní tiwọn—ó ṣe tán, bó bá fi máa di aago méjìlá ọ̀sán, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì jákèjádò ìlú Houston, àwọn tí ebi ti ń pa, ló ti máa múra tán láti jẹ oúnjẹ tó ń gbóná fẹlifẹli!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

ÈTÒ ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́

Nígbà tí iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn tó mọ oríṣiríṣi iṣẹ́ ọwọ́, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láìgba kọ́bọ̀, ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí kò ní òye iṣẹ́ kan pàtó. Wọ́n dá àwọn kan lẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi oògùn apakòkòrò fọ ilé. Àwọn mìíràn kọ́ bí wọ́n ṣe lè kọ́ ògiri, kí wọ́n sì fi kọ́bọ́ọ̀dù sínú ilé. Àwọn mìíràn sì kọ́ bí wọ́n ṣe ń rẹ́ ilé àti bí wọ́n ṣe ń kun ilé lọ́dà. Wọ́n fídíò ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, èyí tí wọ́n pè ní Àpérò Àwọn Òṣìṣẹ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, wọ́n sì ṣe é sínú kásẹ́ẹ̀tì. Wọ́n wá lo àwọn fídíò tí wọ́n mú jáde náà láti fi dá ọ̀pọ̀ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ láfikún sí i làwọn ibi ìpèsè ìrànwọ́ mìíràn. Ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà sọ pé: “Nípasẹ̀ àwọn àpérò wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe fún wa láti rí i dájú pé àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ṣe iṣẹ́ àtúnṣe tó jẹ́ ojúlówó.”

[Àwòrán]

Àwọn oníṣẹ́ ọnà ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

‘ÈYÍ GAN-AN LA LÈ PÈ NÍ IṢẸ́ ỌWỌ́ ỌLỌ́RUN’

Ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà sọ pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò máa ń sọ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí omíyalé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó ṣiṣẹ́ níbí fún gbogbo oṣù wọ̀nyí gan-an la lè pè ní iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Àní sẹ́, ẹgbẹ́ àwọn ará wa ń ṣe bẹbẹ!” Nígbà tí iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ yìí ń lọ lọ́wọ́, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló máa ń wá ṣiṣẹ́ lópin ọ̀sẹ̀. Alága ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà sọ pé: “Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tá ò sanwó fún wọ̀nyẹn fagi lé àwọn ìrìn-àjò tí wọ́n ti ṣètò láti lọ, wọ́n ṣàtúntò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé wọn, wọ́n sì tún sún àwọn ọ̀ràn ara ẹni mìíràn síwájú torí àtilè ṣèrànwọ́ nínú ọ̀kan lára iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ tó tóbi jù lọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tíì dáwọ́ lé rí.”

Iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ tó gba àkókò gígùn yìí béèrè pé káwọn èèyàn fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn. Olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tó ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ọ̀hún látìbẹ̀rẹ̀ dópin ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kan tó máa ń gbà á ní àádọ́ta wákàtí lọ́sẹ̀. Síbẹ̀, ó ń lo ogójì wákàtí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ níbi iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà. Ó sọ pé: “Jèhófà ló fún mi lókun. Àwọn tó mọ̀ mí máa ń béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Ṣé ò ń gbowó nídìí iṣẹ́ ọ̀hún ni?’ Màá sì dá wọn lóhùn pé, ‘Kò sí iye owó tí mo lè gbà tó lè mú mi ṣe iṣẹ́ yìí.’” Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn tí ìdílé kan láti ìpínlẹ̀ Louisiana bá ti lo gbogbo àárín ọ̀sẹ̀ níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, wọ́n máa ń wakọ̀ ẹgbẹ̀rin kìlómítà tàlọ-tàbọ̀ láti wá ṣèrànwọ́ níbi iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn náà máa ń ṣiṣẹ́ láti òwúrọ̀ títí di alẹ́, wọ́n á sì tún wakọ̀ padà sílé. Àwùjọ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tí iye wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n, tí wọ́n máa ń wakọ̀ fún wákàtí méje sí mẹ́wàá ní ìrìn-àjò ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, sọ pé: “Ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Olùyọ̀ǹda ara ẹni mìíràn tó jẹ́ obìnrin máa ń kúrò níbi iṣẹ́ rẹ̀ ní aago mẹ́ta ààbọ̀ ọ̀sán, ó sì máa ń ṣèrànwọ́ ní ibùdó ìṣekòkáárí náà títí di aago mẹ́wàá alẹ́. Ó tún máa ń wá ṣiṣẹ́ lópin ọ̀sẹ̀. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ náà jẹ́ iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀.”

Láìsí àní-àní, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni wọ̀nyí àti gbogbo àwọn tó kù, múra tán láti ṣèrànwọ́ nítorí pé wọ́n ní ìfẹ́ ará—èyí tó jẹ́ àmì tí a fi ń dá àwọn tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni mọ̀. (Jòhánù 13:35) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wú olórí ìlú Houston lórí gan-an nígbà tó ṣèbẹ̀wò sí ibùdó ìṣekòkáárí tí wọ́n lò fún iṣẹ́ àfiṣèrànwọ́ náà, ó wá sọ fún àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan níbẹ̀ pé: “Ẹ̀yin lẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ká máa ṣe. Ẹ̀ ń fi ohun tí ìgbàgbọ́ yín sọ sílò.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Ọ̀gbàrá òjò ya bo ìlú Houston, June 9, 2001

[Credit Line]

© Ìwé ìròyìn Houston Chronicle

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn títì márosẹ̀ di odò ńlá tó ń ṣàn fún ọ̀gbàrá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Omi ya wọ ilé àwọn èèyàn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Díẹ̀ rèé lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tó ṣiṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìdáná ṣe oúnjẹ fún àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà!

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

NOAA