Ṣé Bẹ́ẹ̀ Lẹ̀míi Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Lágbára Tó Ni?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ṣé Bẹ́ẹ̀ Lẹ̀míi Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Lágbára Tó Ni?
“Mi ò rò pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ń nípa lórí mi.”—Pamela, akẹ́kọ̀ọ́ kan nílé ẹ̀kọ́ gíga, ló sọ bẹ́ẹ̀.
“Mi ò rò pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tún fi bẹ́ẹ̀ lágbára lórí mi bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ohun tó wù mí ni mò ń ṣe.”—Ọ̀dọ́langba kan tó ń jẹ́ Robbie ló sọ bẹ́ẹ̀.
ǸJẸ́ irú èrò báyìí ti sọ sí ọ lọ́kàn rí bí? Lóòótọ́, o lè ti mọ̀ nípa ohun tí Bíbélì wí pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àmọ́, o tún lè máa wò ó pé, ‘Ǹjẹ́ àsọdùn kọ́ ni ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe yìí báyìí—bóyá kò tiẹ̀ lágbára tó bí àwọn òbí mi àtàwọn àgbàlagbà mìíràn ṣe máa ń sọ ọ́?’
Bí irú iyèméjì bẹ́ẹ̀ bá ń jà gùdù lọ́kàn rẹ látìgbàdégbà, ìwọ kọ́ ni ẹni àkọ́kọ́ tí irú rẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí. Ṣùgbọ́n a fẹ́ kó o ronú lórí kókó kan ná. Ipa tí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ń ní há lè ju bó o ṣe rò lọ bí? Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láti rí bí ẹ̀mí yìí ṣe lágbára tó. Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Angie sọ pé, ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ ìgbà lòún máa ń ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe láwùjọ dípò kí òun ṣe ohun tó wá látọkàn òun. Ó sọ pé: “Nígbà míì, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe máa ń lágbára débi pé o ò ní mọ̀ pé òun ló ń nípa lórí rẹ. Wàá bẹ̀rẹ̀ sí rò pé ohun tó wá látinú rẹ lò ń ṣe.”
Bákan náà, Robbie tá a mẹ́nu kàn lókè sọ pé inú ọkàn òun ni agbára tó ń sún òun ṣe nǹkan ti ń wá. Síbẹ̀, ó gbà pé kò rọrùn láti máa gbé ní ìlú ńlá. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwùjọ táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì bẹ́ẹ̀ máa ń nípa lórí ẹni. Ó sọ pé: “Rírí towó ṣe ló máa ń wà lórí ẹ̀mí àwọn èèyàn.” Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe jẹ́ ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lé lórí. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi máa ń rò pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe kò nípa lórí àwọn?
Ó Máa Ń Tanni Jẹ
Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè máa darí ẹni láìmọ̀—kódà, a lè má ṣàkíyèsí rẹ̀ rárá. Afẹ́fẹ́ lè lo agbára díẹ̀ lórí nǹkan, òun ló fi jẹ́ pé, bí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́, ó lè mú kí ewé jábọ́ lára igi, ó sì lè mú kí ìgbì òkun máa bì. Ẹ̀fúùfù tó bá le gan-an tiẹ̀ lè wó ilé lulẹ̀. Ojoojúmọ́ là ń rí àmì pé afẹ́fẹ́ ń fẹ́, àmọ́ a lè máà kíyè sí i. Kí nìdí? Torí pé ó ti mọ́ wa lára.
Òótọ́ ni pé, agbára tí afẹ́fẹ́ tó wà láyìíká wa ní Róòmù 12:2, The New Testament in Modern English) Àmọ́, báwo lèyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?
kò fi dandan léwu. Ṣùgbọ́n, nígbà táwọn èèyàn bá ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo agbára lórí wa, wọ́n lè mú ká máa yí padà díẹ̀díẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lóye agbára tí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ní. Ó kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ayé tó yí yín ká mú yín bá bátànì rẹ̀ mu.” (Bó Ṣe Máa Ń Nípa Lórí Ẹni
Ǹjẹ́ o máa ń fẹ́ káwọn ẹlòmíràn gba tìẹ? Ọ̀pọ̀ lára wa ló máa fẹ́ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní yìí lè ṣiṣẹ́ fún ète rere tàbí búburú. Báwo la ṣe máa ń forí ṣe fọrùn ṣe tó káwọn èèyàn lè gba tiwa? Kódà bí a bá tiẹ̀ dá ara wa lójú pé a ò ní jẹ́ kí ohun búburú nípa lórí wa, àwọn tó wà láyìíká wa ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn náà máa ń gbìyànjú láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, àbí ńṣe ni wọ́n ń jẹ́ kó yí wọn padà sí nǹkan mìíràn?
Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lónìí máa ń rò pé àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì kò bóde mu mọ́ tàbí pé wọn kò wúlò nínú ayé òde òní. Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa gbà jọ́sìn òun. (Jòhánù 4:24) Kí ló ń mú wọn rò bẹ́ẹ̀? Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó fà á. Ní Éfésù 2:2, Pọ́ọ̀lù sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí ní “ẹ̀mí” kan tàbí ìṣarasíhùwà kan, èyí tó gbòde kan. Ẹ̀mí yẹn máa ń lo agbára lórí àwọn èèyàn láti mú kí wọ́n máa ronú bíi ti ayé tí kò mọ Jèhófà. Báwo lèyí ṣe lè nípa lórí wá?
Àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́ bíi, lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ tàbí kíka ìwé, ṣíṣe ojúṣe wa nínú ìdílé, àti ṣíṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ sábà máa ń béèrè pé ká ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn tí kò tẹ̀ lé gbogbo ìlànà tí àwa Kristẹni ní. Bí àpẹẹrẹ, ní ilé ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ lè wà tí wọ́n ń lépa àtidi gbajúmọ̀ lọ́nàkọnà, tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ takọtabo, tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ń lo oògùn olóró àti ọtí líle pàápàá. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bá a bá lọ yan ọ̀rẹ́ kòríkòsùn láàárín àwọn tó ń hu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ tàbí láàárín àwọn tí kò gbà pé ó lòdì, kódà tí wọ́n tún ń pọ́n ọn lé pàápàá? Ó ṣeé ṣe ká bẹ̀rẹ̀ sí káṣà wọn—èyí sì lè kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. “Ẹ̀mí,” tàbí “afẹ́fẹ́” ayé yóò lo agbára lórí wa, yóò sì sọ wá da bí ayé ṣe dà.
Lọ́nà tó gbádùn mọ́ni, àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ti ṣe àwọn àṣeyẹ̀wò kan tó kín àwọn ìlànà Bíbélì wọ̀nyí lẹ́yìn. Ìwọ wo àṣeyẹ̀wò kan tó gbàfiyèsí, èyí tí Ọ̀mọ̀wé Asch ṣe. Ó sọ pé kí ẹnì kan wá dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn èèyàn kan tí wọ́n jókòó síbì kan náà. Ọ̀mọ̀wé Asch wá fi káàdì ńlá tí wọ́n fa ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ kan tó wà lóòró sí han àwọn tó jókòó náà, lẹ́yìn náà ó fi káàdì mìíràn hàn wọ́n, èyí tó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ mẹ́ta tó wà lóòró àmọ́ tí wọn ò gùn dọ́gba. Lẹ́yìn èyí, ó sọ pé kí àwọn tó wà nínú àwùjọ náà sọ èyí tí wọ́n rò pé ó bá ìlà àkọ́kọ́ dọ́gba nínú ìlà mẹ́ta náà. Ìdáhùn yẹn kò ṣòro láti mọ̀. Nígbà àkọ́kọ́ àti lẹ́ẹ̀kejì, gbogbo wọn fohùn ṣọ̀kan. Àmọ́ nígbà tó di ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ìyàtọ̀ wà nínú ìdáhùn wọn.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣẹlẹ̀ níṣàájú, ó rọrùn láti sọ àwọn ìlà tó bára dọ́gba. Àmọ́ láìhàn sí ẹni tí wọ́n ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ńṣe ni wọ́n sanwó fún àwọn tó kù nínú àwùjọ náà láti kópa nínú àṣeyẹ̀wò náà. Gbogbo wọ́n fohùn ṣọ̀kan láti mú ìdáhùn tí kò tọ̀nà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Kìkì ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn tí wọ́n ṣe àṣeyẹ̀wò náà fún ni kò yí èrò wọn padà lórí ohun tó jẹ́ òtítọ́. Àmọ́ gbogbo àwọn yòókù gbà pẹ̀lú àwùjọ náà, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan—bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí túmọ̀ sí pé ńṣe ni wọ́n ń sẹ́ ohun tí wọ́n fojú ara wọn rí kòrókòró!
Ó ṣe kedere pé, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti ṣe bí àwọn tó wà láyìíká wọn ṣe ń ṣe—débi pé ọ̀pọ̀ ló máa sẹ́ ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ òótọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ti fúnra wọn mọ bí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe yìí ṣe máa ń lo agbára lórí ẹni. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó ń jẹ́ Daniel sọ pé: “Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè mú kó o yí padà. Àti pé, báwọn èèyàn bá ṣe ń pọ̀ sí i ni ìfẹ́ láti ṣe bíi tiwọn á máa jinlẹ̀ sí i. O tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí rò pé ohun tí wọ́n ń ṣe bójú mu.”
Angie tá a mẹ́nu kàn lókè sọ àpẹẹrẹ bí ẹ̀mí yìí ṣe lè nípa lórí ẹni nílé ẹ̀kọ́, ó ní: “Nígbà tó o bá wà ní ìpele ọlọ́dún mẹ́ta àkọ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga, irú aṣọ tí ò ń wọ̀ ṣe pàtàkì. O gbọ́dọ̀ máa wọ aṣọ tí orúkọ rẹ̀ gbayì gan-an. Ó lè má wù ọ́ látọkànwá láti ná
àádọ́ta dọ́là sórí ẹyọ ṣẹ́ẹ̀tì kan—kí ló máa sún ẹnì kan láti fẹ́ ná owó tó tó bẹ́ẹ̀ sórí ṣẹ́ẹ̀tì kan ṣoṣo?” Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Angie, èèyàn lè má tètè rí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe síbẹ̀ kó máa nípa lórí ẹni. Àmọ́, ǹjẹ́ ẹ̀mí yìí lè nípa lórí wa nínú àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì gan-an?Ìdí Tó Fi Léwu Gan-an
Fojú inú wò ó pé ò ń lúwẹ̀ẹ́ nínú òkun. Bó o ti ń lúwẹ̀ẹ́ síwájú, àwọn nǹkan mìíràn lè máa nípa lórí rẹ láìhàn sí ọ rárá. Ìgbì omi lè máa tì ọ́ lọ sí etídò, àmọ́ ìgbì mìíràn tún lè wà nísàlẹ̀ tó lè máa nípa lórí rẹ nígbà kan náà. Díẹ̀díẹ̀, á máa tì ọ́ lọ sẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ̀ẹ́. Nígbà tó o bá fi máa wo etídò, wàá rí i pé o ò rí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń lúwẹ̀ẹ́ mọ́, torí pé o ti jìnnà síbi tí wọ́n wà. O ò mọ̀ rárá pé ìgbì náà ti tì ọ́ jìnnà gan-an! Bákan náà, bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan lójoojúmọ́, ìgbà gbogbo làwọn nǹkan kan ń nípa lórí èrò wa àti ìmọ̀lára wa. Ká tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, àwọn ohun tó ń nípa lórí ẹni wọ̀nyí lè ti tì wá lọ jìnnà kúrò nídìí àwọn ìlànà tá a ti ń rọ̀ mọ́ ṣinṣin.
Bí àpẹẹrẹ, onígboyà ọkùnrin ni àpọ́sítélì Pétérù. Ó lo idà láìbẹ̀rù láti gbéjà ko àwọn èèyànkéèyàn kan lóru ọjọ́ tí wọ́n fàṣẹ ọba mú Jésù. (Máàkù 14:43-47; Jòhánù 18:10) Síbẹ̀, ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó jẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe sún òun láti fi ojúsàájú hàn gbangba-gbàǹgbà. Ó yẹra fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí—bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ti fi ìran kan hàn án níṣàájú, èyí tó fi sọ fún un láti má ṣe fi ojú aláìmọ́ wo àwọn Kèfèrí. (Ìṣe 10:10-15, 28, 29) Pétérù lè rí i pé ó rọrùn fún òun láti kojú idà ju pé kí òun gba ìdálẹ́bi àwọn èèyàn lọ! (Gálátíà 2:11, 12) Láìsí àní-àní, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe léwu.
Ó Dáa Láti Gbà Pé Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Lágbára
Àpẹẹrẹ Pétérù lè kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ìyẹn ni pé, jíjẹ́ tí ẹnì kan jẹ́ onígboyà láwọn ọ̀nà kan kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ onígboyà ní gbogbo ọ̀nà. Pétérù ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú gbogbo wa. Irú ẹni yòówù ká jẹ́, ó pọn dandan pé ká mọ ibi tí kùdìẹ̀-kudiẹ wa wà. A lè fi òótọ́ inú béèrè lọ́wọ́ ara wa pé: ‘Apá ibo ni mo kù sí? Ǹjẹ́ mò ń yán hànhàn fún ìgbésí ayé oníyọ̀tọ̀mì? Ǹjẹ́ fífi ìrísí mi tàbí àwọn àṣeyọrí tí mo ṣe yangàn ha ti ń nípa lórí ọkàn mi bí? Ǹjẹ́ n kì í forí ṣe fọrùn ṣe káwọn èèyàn lè kan sáárá sí mi, tàbí kí n fi lè dépò ọlá, tàbí kí n di gbajúmọ̀?’
Tóò, a lè máà dìídì fi ara wa sínú ewu nípa bíbá àwọn oníwàkiwà tó ń lo oògùn olóró tàbí àwọn èèyàn tó jẹ́ oníṣekúṣe kẹ́gbẹ́. Àmọ́, kí la máa ṣe sí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa mìíràn tí wọ́n túbọ̀ fara sin? Bó bá jẹ́ pé àwọn tó máa nípa tí kò dára lórí wa ní àwọn ibi tá a ní kùdìẹ̀-kudiẹ sí la jọ ń ṣe wọléwọ̀de, nígbà náà, ńṣe là ń gba ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe láyè láti darí wa, èyí sì lè já sí ìpalára wa ayérayé pàápàá.
Àmọ́ ṣá o, ó dáa láti máa fi sọ́kàn pé, kì í ṣe gbogbo ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ló burú. Ǹjẹ́ a lè darí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe—àní ká tiẹ̀ mú kó ṣe wá láǹfààní pàápàá? Báwo la sì ṣe lè dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè pa wá lára? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwùjọ táwọn èèyàn ti jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè mú kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe nípa lórí rẹ lọ́nà lílágbára