Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ọkàn Rẹ Ṣe Lè Balẹ̀ Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú

Bí Ọkàn Rẹ Ṣe Lè Balẹ̀ Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú

Bí Ọkàn Rẹ Ṣe Lè Balẹ̀ Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú

NÍ Ọ̀SẸ̀ díẹ̀ péré ṣáájú àjálù tó wáyé ní September 11, 2001, Alex gbà pé òun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ borí ìbẹ̀rù tí òun máa ń ní tí òun bá wọkọ̀ òfuurufú. Ọmọ ọdún méjìlélógójì ni, ọ̀gá sì ni ní ẹ̀ka ìpolongo iléeṣẹ́ kan. Bí ọkọ̀ òfuurufú tí Alex wọ ti ń gbéra láti ìlú Áténì lọ sí ìlú Boston, ojora bẹ̀rẹ̀ sí í mú un—ó ń mí gúlegúle, omi ń sun ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ó sì ń làágùn níwájú orí

Àmọ́ ó mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Olùkọ́ tó ń ràn án lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù tó ń ní tó bá wọ ọkọ̀ òfuurufú ti sọ fún un pé kó máa mí kanlẹ̀, kó máa fọkàn yàwòrán àgbègbè ẹlẹ́wà kan, kó sì máa di apá àga tó jókòó lé mú pinpin, kó wá máa jù ú sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹrin ní ìṣẹ́jú kan. Nígbà tí ìmìjìgìjìgì ọkọ̀ òfuurufú náà àti ariwo rẹ̀ tí ń dáyà foni fẹ́ kọjá ohun tí Alex lè mú mọ́ra, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara rẹ̀ bíi pé òun wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún odò píparọ́rọ́ kan. Alex sọ pé: “Ó dà bíi pé mo ti tẹ̀ síwájú gan-an torí pé ìbẹ̀rù mi ti dín kù jọjọ.”

Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó máa ń rìnrìn àjò nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú lẹ̀rù máa ń bà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ti ń lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ni nípa béèyàn ṣe lè borí ìbẹ̀rù wíwọ ọkọ̀ òfuurufú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ pé àwọn ẹbí, àwọn ọ̀gá wọn níbi iṣẹ́, àtàwọn iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, tí wọ́n mọ àǹfààní tí wọ́n máa jẹ níbẹ̀, máa ń rọ̀ wọ́n láti lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí. Fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń wọkọ̀ òfuurufú, àǹfààní kékeré kọ́ làwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ti ṣe fún wọn; ọ̀pọ̀ àwọn tó sì ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ló sì máa ń yangàn pé, ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn èèyàn tí àwọ́n ti ràn lọ́wọ́ ni kò bẹ̀rù mọ́ láti wọkọ̀ òfuurufú.

Àmọ́ gbogbo ìyẹn yí padà nígbà tí àjálù September 11, 2001 wáyé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Alex ti pa ilé ẹ̀kọ́ tó ń lọ náà tì. Ìjákulẹ̀ ló sì jẹ́ fún iléeṣẹ́ rẹ̀ nígbà tí Alex tún pa gbogbo ètò tó ti ń ṣe tì, ìyẹn láti wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ pàdé ẹni pàtàkì kan tó ṣeé ṣe kó di oníbàárà iléeṣẹ́ náà. Alex sọ pé: “Kí ìbẹ̀rù àwọn apániláyà tún wá pẹ̀lú ìbẹ̀rù wíwọ ọkọ̀ òfuurufú tí mo ti ní tẹ́lẹ̀, irọ́, agbára mi ò gbé e. Ilé ẹ̀kọ́ tí mò ń lọ kò tíì kọ́ mi débẹ̀ yẹn.”

Ètò Ààbò Bọ́ Sábẹ́ Àyẹ̀wò Ńlá

Àwọn tó ń bẹ̀rù àtiwọ ọkọ̀ òfuurufú kò ṣàì tún fi ohun kan kún un o. Wọ́n ní ṣebí wọ́n bi àwọn apániláyà tó fa àjálù September 11 láwọn ìbéèrè tí wọ́n máa ń bi gbogbo arìnrìn-àjò. Àwọn ìbéèrè bíi: “Ǹjẹ́ ẹnì kankan tó ò mọ̀ rí sọ pé kó o bá òun gbé ẹrù lọ́wọ́ nínú ọkọ̀ òfuurufú yìí? Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára àwọn ẹrù tó ò ń gbé rìnrìn àjò yìí ti bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíràn látìgbà tó o ti dì í?” Ó dájú pé: “Rárá o!” làwọn apániláyà náà dáhùn, bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ṣe máa ń dáhùn. Àwọn ògbóǹkangí díẹ̀ nínú ètò ààbò pẹ̀lú gbà pé, ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ẹni ibi náà láti wọnú àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n já gbà náà jẹ́ ẹ̀rí pé ètò ààbò ọkọ̀ òfuurufú ti mẹ́hẹ. Jim McKenna, olùdarí tẹ́lẹ̀ rí fún Àjọ Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni Nípa Ààbò Ọkọ̀ Òfuurufú sọ pé: “Tí kì í bá ṣe ti àjálù tó ṣẹlẹ̀ yìí ni, kò sí ohun tí ì bá mú ìyípadà kankan wá nínú ètò ààbò. Bí ọkọ̀ òfuurufú mẹ́rin ṣe bọ́ sọ́wọ́ àwọn apániláyà, tí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì pa rẹ́ ráúráú, pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí tó ṣòfò, ti tó láti mú kí ìyípadà wà nínú ètò ààbò.”

Lẹ́yìn tí àwọn àjálù tó fẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣòfò yìí wáyé, gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ààbò pápákọ̀ òfuurufú àti ọkọ̀ òfuurufú fúnra rẹ̀ ló ti bọ́ sábẹ́ àyẹ̀wò gidi. Nígbà tí Kenneth M. Mead, ọ̀gá àgbà fún Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ètò Ìrìnnà Nílẹ̀ Amẹ́ríkà ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé kan tó bá Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe, ó sọ pé: “Láìka àwọn ìlànà tó ti wà nílẹ̀ àtàwọn tá a tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sí, àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń dáyà foni àtàwọn . . . ibi tó nílò àtúnṣe ṣì wà tí wọ́n ń fẹ́ àbójútó.” Kí ni wọ́n ń ṣe láti rí sáwọn ibi tó nílò àbójútó yìí?

Yíyẹ Àwọn Èèyàn Wò Láti Dènà Ìṣẹ̀lẹ̀ Láabi

Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀gá kan nínú ètò ààbò ní iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ńlá kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà, bóyá ẹ̀rù máa ń bà á láti wọ ọkọ̀ òfuurufú, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló dáhùn pé: “Rárá o.” Ó ṣàlàyé pé, ètò ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kan tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò àwọn arìnrìn-àjò fi òun lọ́kàn balẹ̀. Ní àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú tí ètò yìí bá wà, àkọsílẹ̀ máa ń wà fún gbogbo tíkẹ́ẹ̀tì tí wọ́n bá tà fún àwọn oníbàárà wọn. Ètò yìí ló máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá ọ́fíìsì iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà lẹnì kan ti ra tíkẹ́ẹ̀tì rẹ̀, bóyá ọ̀dọ̀ aṣojú wọn kan ni tàbí nípasẹ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì ni. Ó tún máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni mìíràn, irú bíi, bóyá ńṣe ni ẹni tó fẹ́ wọ ọkọ̀ òfuurufú náà ń dá nìkan rìnrìn àjò tàbí ó ń lọ pẹ̀lú àwọn kan nínú ìdílé rẹ̀, tàbí pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mìíràn. Ó tún máa ń ṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn, irú bíi, bóyá wọ́n ti mọ ẹnì kan mọ́ àwọn ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ rí, bóyá ẹnì kan ti hu ìwàkiwà kan rí ní iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà, tàbí tó hùwà àìdáa kan sí àwọn òṣìṣẹ́ wọn níbẹ̀, tàbí bóyá ó ti bà wọ́n ní nǹkan jẹ́ rí.

Gbogbo ìgbà tí arìnrìn-àjò kan bá wá sí pápákọ̀ òfuurufú kan ni wọ́n máa ń tún àwọn ìsọfúnni yìí gbé yẹ̀ wò tí wọ́n á sì mu un bá ipò tí ẹni náà wà ní lọ́wọ́lọ́wọ́ mu, títí kan bí ẹni náà ṣe dá wọn lóhùn nígbà tí wọ́n ń béèrè àwọn ìbéèrè àyẹ̀wò lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ṣíṣe kókó tí wọ́n gbà sílẹ̀, àtàwọn ìlànà ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí wọ́n ń lò láti mọ̀ bóyá ìṣesí ẹnì kan fi hàn pé o ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹni ibi, wà lára àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ àṣírí jù lọ ní iléeṣẹ́ náà. Oríṣiríṣi ètò tó jọ irú èyí tá a ṣàlàyé lókè yìí ni wọ́n ti ń lò káàkiri ayé. Àwọn kan ń ṣe é ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba àtàwọn àjọ ọlọ́pàá àgbáyé irú bí ọ̀kan tó ń jẹ́ Interpol. Ní ọ̀pọ̀ pápákọ̀ òfuurufú nílẹ̀ Yúróòpù, àwọn ètò tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò ìwé àṣẹ ìrìn-àjò lè ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ibi tí ẹnì kan ti wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ láyé rẹ̀, ìgbà tó wọ̀ ọ́, àti bó ṣe ń rìn láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn.

Ìdí tí wọ́n fi ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni yìí ni pé, wọ́n ronú pé àwọn ẹ̀dákẹ́dàá tó ní èrò ibi lọ́kàn léwu ju ẹrù táwọn èèyàn gbé dání àtàwọn báàjì tí wọ́n ti yẹ̀ wò lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, láti mú kí ètò ààbò ní pápákọ̀ òfuurufú túbọ̀ lágbára sí i, oríṣiríṣi àwọn ohun tó ń jẹ́ kí wọ́n dá èèyàn kọ̀ọ̀kan mọ̀, àtàwọn káàdì ìdánimọ̀ tó lè fi oríṣiríṣi nǹkan hàn ni wọ́n ti ń gbèrò àtimáa lò báyìí tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ti máa lò ó lọ́wọ́lọ́wọ́.

Yàtọ̀ fún níní ìsọfúnni àwọn arìnrìn-àjò lọ́wọ́, bí wọn ò ṣe ní í jẹ́ kí àwọn nǹkan eléwu ráyè wọnú ọkọ̀ òfuurufú tún jẹ́ kókó pàtàkì kan lára ètò ààbò pápákọ̀ òfuurufú. Ìwọ̀nba ni ibi tí agbára ẹ̀rọ onítànṣán tí wọ́n ń lò fún àyẹ̀wò mọ. Bákan náà, kì í rọrùn fún àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ní pápákọ̀ òfuurufú láti pọkàn pọ̀ fún àkókò gígùn, nítorí pé títẹjú mọ́ àwòrán àwọn ẹrù tí kì í hàn dáadáa tó ń kọjá nínú àwọn ẹ̀rọ onítànṣán náà máa ń sú wọn. Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ẹ̀rọ tó máa ń fi àwọn nǹkan onírin tó mú ìfura lọ́wọ́ hàn kàn máa ń pariwo ṣáá ni, torí pé àtohun tó léwu àtèyí tí kò léwu ló ń fi hàn, ìbáà jẹ́ kọ́kọ́rọ́ ilé, àwọn owó wẹ́wẹ́, tàbí àwọn irin bẹ́líìtì pàápàá.

Wọ́n Mú Òfin Ètò Ààbò Le Sí I

Láti lè wá nǹkan ṣe sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, àwọn ìjọba ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ṣe àwọn òfin kan tó mú ààbò pápákọ̀ òfuurufú lágbára sí i. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tó bá fi máa di ìparí ọdún 2002, wọn ò ní máa di ẹrù kankan sínú ọkọ̀ òfuurufú láìjẹ́ pé ẹni tó lẹrù ti wọlé, gbogbo ẹrù tó wà nínú ọkọ̀ òfuurufú ni wọ́n á máa yẹ̀ wò látòkèdélẹ̀, bákan náà ni wọ́n á máa ṣàyẹ̀wò fínnífínní láti mọ̀ bóyá àwọn ohun tó lè bú gbàù wà nínú ẹrù wọn. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí àwọn ilẹ̀kùn tó wà níbi tí awakọ̀ òfuurufú àtàwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ pọ̀ ń jókòó sí túbọ̀ lágbára sí i, kó sì tún láàbò sí i. Wọ́n tún ti ń ṣe àfikún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú nítorí ìgbà tí ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ bá máa ṣẹlẹ̀. Wọ́n sì ti ń fi àwọn ológun tó dìhámọ́ra sínú àwọn ọkọ̀ òfuurufú oníṣòwò báyìí láti kápá wàhálà èyíkéyìí tó lè ṣẹlẹ̀.

Láwọn ọ̀sẹ̀ àti oṣù tó tẹ̀ lé àjálù September 11, ńṣe ni wọ́n ń yẹ ara àwọn èrò wò tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ tú àwọn ẹrù wọn wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ ní ọ̀pọ̀ pápákọ̀ òfuurufú yíká ayé. Àwọn pápákọ̀ òfuurufú kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò àwọn èrò àtàwọn ẹrù wọn. Irú ìgbésẹ̀ ààbò yìí kò ṣàjèjì sáwọn arìnrìn àjò tó jẹ́ ará Yúróòpù, torí wọ́n ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dáadáa láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1979, nígbà tí jíjá ọkọ̀ òfuurufú gbòde kan. Wọ́n tún ti kà á léèwọ̀ fún àwọn èrò pé wọn ò gbọ́dọ̀ mú àwọn nǹkan tó ṣe ṣóńṣó wọnú ọkọ̀ òfuurufú, irú bíi sísọ́ọ̀sì tàbí ohun tí wọ́n fi ń fá èékánná. Kìkì àwọn arìnrìn-àjò tó bá mú ojúlówó tíkẹ́ẹ̀tì dání ni wọ́n ń gbà láyè láti kọjá níbi tí wọ́n ti ń yẹ èrò wò. Títò lórí ìlà tó gùn lọ rẹrẹẹrẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í mọ́ ọ̀pọ̀ èrò lára báyìí, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ológun tó dìhámọ́ra láwọn pápákọ̀ òfuurufú kò fi bẹ́ẹ̀ dẹ́rù bà wọ́n mọ́.

Fífọwọ́ Pàtàkì Mú Àbójútó Ọkọ̀ Òfuurufú

Fọkàn yàwòrán ohun kan tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ yìí ná: Lẹ́yìn tí arìnrìn-àjò kan ti kọjá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi àyẹ̀wò ní pápákọ̀ òfuurufú, ó jàjà bára rẹ̀ níbi táwọn èrò máa ń dúró sí láti wọnú ọkọ̀ òfuurufú, ó ń dúró de kí òun gbọ́ ìkéde tí wọ́n máa ń ṣe pé kí àwọn èrò wọlé sínú ọkọ̀ òfuurufú. Bẹ́ẹ̀ ni oníṣòwò kan tó wọ kóòtù aláwọ̀ eérú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ǹjẹ́ o gbọ́ ìkéde tí wọ́n ṣe yẹn? Wọ́n ní ọkọ̀ òfuurufú yìí kò ní gbéra mọ́ lákòókò tí wọ́n dá torí pé nǹkan kan bà jẹ́ nínú rẹ̀.” Ojú rẹ̀ kọ́rẹ́ lọ́wọ́, ó wá fi kún un pé: “Mo ṣáà rò pé wọ́n ò ní máa gbé wa lọ pẹ̀lú òkú ẹ́ńjìnnì!”

Ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn arìnrìn-àjò kò mọ̀ ni pé, àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣàbójútó ọkọ̀ òfuurufú máa ń ṣe àwọn àyẹ̀wò tó gbópọn, èyí tí wọ́n máa ń fẹ̀sọ̀ ṣe. Wọ́n máa ń mọ àwọn àtúnṣe tí ọkọ̀ òfuurufú kan máa nílò nípa fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ọkọ̀ náà látìgbà tó ti ń fò. Àní, àwọn iléeṣẹ́ yìí máa ń ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ṣíṣàyẹ̀wò àti ṣíṣàtúnṣe àwọn ọkọ̀ òfuurufú àtàwọn ẹ́ńjìnnì wọn látòkèdélẹ̀, wọ́n sì máa ń mú èyí ní dandan gbọ̀n fún àwọn tó ni iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú. Àbójútó yìí máa ń wáyé déédéé gan-an ju ti ọkọ̀ ìrìnnà èyíkéyìí téèyàn ń lò lọ, yálà ọkọ̀ òfuurufú náà ti ní ìṣòro rí látìgbà tó ti ń fò tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Ọ̀gá kan ní ẹ̀ka tó ń rí sí ṣíṣàbójútó ọkọ̀ òfuurufú ní iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ńlá kan jẹ́rìí sí èyí. Ó sọ pé: “Láti bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí mo ti wà ní iléeṣẹ́ yìí, mi ò tíì rí ẹnì kan, tàbí kí n bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, tàbí kí n ṣàkíyèsí ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń rí sí ṣíṣàbójútó ọkọ̀ òfuurufú tí kò mú ọ̀rọ̀ ààbò lọ́kùn-únkúndùn. Ó ṣe tán, àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ àwọn tó ń ṣàbójútó ọkọ̀ òfuurufú náà máa ń wọ̀ ọ́, nípa bẹ́ẹ̀, wọn kì í fojú kékeré wo ohunkóhun tó bá lè fa jàǹbá.”

Iṣẹ́ kékeré kọ́ ló wà lọ́rùn àwọn òṣìṣẹ́ tó mọ̀ nípa ọkọ̀ òfuurufú àtàwọn tó máa ń bójú tó o. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Mi ò jẹ́ gbàgbé òru ọjọ́ tí ọkọ̀ òfuurufú wa kan já lulẹ̀ ní Ìlú Sioux, ní ìpínlẹ̀ Iowa, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lákòókò yẹn, iṣẹ́ títún ọkọ̀ òfuurufú ṣe ni iṣẹ́ mi, mo sì ní láti ṣe àyẹ̀wò kan ní apá ẹ̀yìn ọkọ̀ òfuurufú kan tó jẹ́ irú èyí tó já lulẹ̀ yẹn, mo ní láti nù ún, kí n sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ lára rẹ̀. Ní gbogbo àkókò tí mò ń ṣe àyẹ̀wò náà, a ò tíì fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an sí ọkọ̀ òfuurufú tó já lulẹ̀ náà. Mo rántí bí mo ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe lálẹ́ ọjọ́ náà, tí mò ń bi ara mi pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀ sọ́kọ̀ òfuurufú yẹn ná? Àbí ẹni tó ṣiṣẹ́ lára ọkọ̀ òfuurufú náà kò rí ohun kan tó ṣeé ṣe kí èmi rí nísìnyí ni, kí n sì tipa bẹ́ẹ̀ dènà irú àjálù bẹ́ẹ̀ kó má ṣẹlẹ̀ mọ́? Ǹjẹ́ mò ń ṣe ohun gbogbo lọ́nà tó yẹ kí n gbà ṣè é?’ Àkókò kékeré kọ́ ni mo lò ní apá ẹ̀yìn ọkọ̀ òfuurufú náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, tí mò ń yẹ ohun gbogbo wò fínnífínní, tí mo sì ń ronú nípa wọn ṣáá.”

Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń fún àwọn tó mọ tinú-tòde ọkọ̀ òfuurufú ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí gbogbo ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn, látorí àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe déédéé dórí àwọn àyẹ̀wò tó gba ìrònújinlẹ̀ gan-an, títí kan ṣíṣàwárí àwọn ìṣòro àti ṣíṣàtúnṣe wọn. Ọdọọdún ni wọ́n máa ń fi àwọn ohun tuntun kún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe fún wọn, èyí tó ń dá lórí gbogbo ipò èyíkéyìí tí wọ́n ronú pé ó ṣeé ṣe kó yọjú, látorí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan dórí àwọn tó ṣe pàtàkì gan-an.

Tí jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú kan bá ṣẹlẹ̀, wọ́n máa ń yẹ gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n bá kó jọ nípa jàǹbá náà wò fínnífínní, wọ́n á sì ṣètò èyí sínú ẹ̀rọ àfidánrawò kan tí wọ́n ṣe bí ọkọ̀ òfuurufú gẹ́lẹ́. Àwọn awakọ̀ òfuurufú tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àtàwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ nípa ọkọ̀ òfuurufú á wá lo ẹ̀rọ àfidánrawò náà láti mọ ojútùú tí wọ́n lè wá sí ìṣòro náà, kó lè ṣeé ṣe fún àwọn tó mọ̀ nípa ọkọ̀ òfuurufú láti bójú tó irú àwọn ìṣòro yẹn dáadáa lọ́jọ́ iwájú. Lẹ́yìn náà, wọ́n á ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan fún àwọn òṣìṣẹ́ náà láti lè fún wọn ní ìtọni tó ṣe pàtó lórí iṣẹ́ wọn. Bíbójútó àwọn ìṣòro lọ́nà yìí tún máa ń yọrí sí ṣíṣe ìyípadà nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe àwọn ọkọ̀ òfuurufú àtàwọn ẹ̀ya ara wọn, pẹ̀lú ìrètí pé irú àwọn àṣìṣe tó ti wáyé bẹ́ẹ̀ á jẹ́ àríkọ́gbọ́n, kí wọ́n sì lè dín irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ kù.

Ẹnì kan tó máa ń ṣàbójútó ọkọ̀ òfuurufú sọ pé: “Gbogbo wa ni wọ́n máa ń sọ fún pé ‘ààbò kì í ṣàdéédéé wá—ńṣe lèèyàn máa ń múra sílẹ̀ fún un.’”

Ó Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wọ Ọkọ̀ Òfuurufú Padà

Lẹ́yìn tí Alex ti fi oṣù mẹ́rin ta kú, tó kọ̀ tí kò wọ ọkọ̀ òfuurufú mọ́, fúnra rẹ̀ ló pinnu pé àsìkò tó tí òún gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí ìbẹ̀rùbojo òun. Kò jọ pé àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ológun tó máa ń wà ní Pápákọ̀ Òfuurufú Ńlá ìlú Boston tún ń dáyà já a mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìlà àwọn èrò tí wọ́n ń yẹ̀ wò tó gùn lọ rẹrẹẹrẹ àti bí wọ́n ṣe máa ń fọwọ́ tú ẹ̀rù rẹ̀ wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ kò bí Alex nínú rárá.

Fún Alex, ẹ̀rí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ làwọn nǹkan wọ̀nyẹn jẹ́, pé òun lè wọ ọkọ̀ òfuurufú láìsí ìbẹ̀rù. Ìlàágùn akọ ṣì máa ń bò ó díẹ̀díẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àyà rẹ̀ ṣì máa ń já lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, bí Alex ti ń gbé ẹrù ọwọ́ rẹ̀ tí wọ́n ti yẹ̀ wò sínú ibi ìkẹ́rùsí tó wà lókè ibi tó jókòó sí, ó sọ pé: “Ara ti tù mí gan-an báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìsọfúnni Lórí Wíwọ Ọkọ̀ Òfuurufú

Níbàámu pẹ̀lú ohun táwọn olùṣèwádìí fojú bù, ìdá kan nínú márùn-ún àwọn tó ń wọ ọkọ̀ òfuurufú lẹ̀rù máa ń bà. Àmọ́ ṣá, gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyí kọ́ ló gbà pé ọkọ̀ òfuurufú léwu láti wọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀tọ̀ lohun tó máa ń já wọn láyà, irú bí ìbẹ̀rù wíwà lókè fíofío tàbí ti wíwà láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ibi kótópó kan.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 8]

BÁWO NI JÀǸBÁ ṢE LÈ ṢẸLẸ̀ LEMỌ́LEMỌ́ TÓ?

Lọ́dún, ó lè ṣẹlẹ̀ Nígbèésí ayé, ó lè

ní ẹ̀ẹ̀kan nínú ìgbà: ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan nínú ìgbà:

Jàǹbá mọ́tò 6,212 81

Kí ẹlòmíràn gbẹ̀mí ẹni 15,104 197

Kí ẹ̀rọ pani 265,000 3,500

Jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú 390,000 5,100

Kéèyàn kú sínú kùdu ìwẹ̀ 802,000 10,500

Kí ẹranko tàbí

ewéko olóró pani 4,200,000 55,900

Kí mànàmáná pani 4,300,000 56,000

[Credit Line]

Ibi tá a ti rí ìsọfúnni yìí: National Safety Council

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Wọ́n ti mú kí ètò ààbò pọ̀ sí i ní pápákọ̀ òfuurufú

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Joel Page

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Gbígba ìsọfúnni àwọn arìnrìn-àjò sílẹ̀ àti ṣíṣàyẹ̀wò wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Wọ́n ti mú kí ṣíṣe àbójútó ọkọ̀ òfuurufú gbé pẹ́ẹ́lí sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀, tí wọ́n sì ti mọṣẹ́ dáadáa ló ń wa ọkọ̀ òfuurufú