Ilẹ̀ Gíríìsì Ti Fàyè Gba Òmìnira Ẹ̀sìn
Ilẹ̀ Gíríìsì Ti Fàyè Gba Òmìnira Ẹ̀sìn
FÚN ÌGBÀ ÀKỌ́KỌ́, ìjọba orílẹ̀-èdè Gíríìsì fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní láti lo ọ̀kan lára àwọn ibi ìṣeré rẹ̀ tó dára jù lọ fún àpéjọ ńlá kan lọ́dún tó kọjá. Òun ni gbọ̀ngàn ìṣeré Olympic Sportshall, èyí tó lè gba ọ̀kẹ́ kan [20,000] èèyàn. Gbọ̀ngàn ìṣeré tí ó ní ẹ̀rọ amúlétutù nínú yìí wà lára àwọn ibi tí wọ́n fẹ́ lò fún Eré Ìdárayá Olympic ti ọdún 2004 nílùú Áténì.
Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ní ọdún 1963 àti ọdún 1988, àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣètò láti lo àwọn ibi ìṣeré ńlá tó wà nílùú Áténì fún àwọn àpéjọ wọn. Àmọ́, nígbà méjèèjì, àwọn aláṣẹ ibẹ̀ jẹ́ kí ìhalẹ̀mọ́ni látọ̀dọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì dẹ́rù bà wọ́n, wọ́n sì kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí lò wọ́n.
Ohun Tó Jẹ́ Àbájáde Lọ́tẹ̀ Yìí Yàtọ̀
Ní oṣù February ọdún 2001, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí sọ pé àwọ́n fẹ́ láti lo gbọ̀ngàn ìṣeré Olympic Sportshall—èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn gbọ̀ngàn ìṣeré ńlá bíi mélòó kan tí ó tóbi tó láti gba ọ̀pọ̀ èèyàn—ńṣe ni ominú ń kọ wọ́n bóyá bí ọ̀ràn ṣe ń rí látẹ̀yìnwá náà ló tún ṣe máa rí. Bí wọ́n ti ń retí, ńṣe làwọn aláṣẹ kọ́kọ́ fárígá.
Àmọ́, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò láti lọ bá àwọn lọ́gàá-lọ́gàá tí wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí, tí wọn kò sì ní ẹ̀tanú. Ṣé wọ́n á múra tán láti gbé ẹ̀tọ́ tí olúkúlùkù ní lábẹ́ òfin láti ṣe ìjọsìn lómìnira àti láti ṣe àpéjọ wọ́ọ́rọ́wọ́ lárugẹ? Ṣé wọ́n á fìgboyà kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn onísìn fipá mú wọn láti ṣe ohun tí wọn kò fẹ́ ṣe? Wọ́n kúkú kọ̀ jálẹ̀, ìdájọ́ tuntun kan ló sì dojú bí wọ́n ṣe kọ̀ jálẹ̀ níṣàájú dé. Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti ṣètò àpéjọ wọn ní gbọ̀ngàn ìṣeré Sportshall sí July 27 sí 29, 2001.
Lásìkò kan náà, àwọn aláṣẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti lo gbọ̀ngàn ìṣeré mìíràn tí ìjọba ń mójú tó, ìyẹn ni gbọ̀ngàn ìṣeré Palais de Sport, tó wà nílùú Thessalonica.
Ìsapá Ṣọ́ọ̀ṣì Láti Fínná Mọ́ Àwọn Aláṣẹ Já sí Pàbó
Bí ọjọ́ tí wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ àpéjọ ti ìlú Áténì náà ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ìbéèrè tó ń kóni láyà sókè ló ń jà gùdù lọ́kàn àwọn Ẹlẹ́rìí: Ǹjẹ́ àwọn aláṣẹ á dúró lórí àdéhùn wọn láìka bí àwùjọ àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ṣe ń fínná mọ́ wọn? Àti pé, ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí á lè gbádùn àpéjọ wọn tẹ́rùn láìsí pé àwọn kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá kan ń dà wọ́n láàmú?
Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kò tíì gbàgbé ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí wọ́n máa ń dá látọjọ́ pípẹ́, ìyẹn ni lílo agbára wọn láti fi da àpéjọ rú. Àwọn iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n sọ pé àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ní kí àwọn má ṣe polongo àpéjọ tó ń bọ̀ lọ́nà náà fáyé gbọ́. Àmọ́ ṣá o, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, pàbó ni gbogbo ìsapá ṣọ́ọ̀ṣì já sí.
Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí pé ìsìn wọn jẹ́ ètò ìmùlẹ̀ kan. Àmọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún gan-an ló tún wá ń gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ káwọn aráàlú mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú gbọ̀ngàn ìṣeré Sportshall. Ó dùn mọ́ni nínú pé, àwọn akọ̀ròyìn tó jẹ́ onígboyà kò jẹ́ kí ìhalẹ̀mọ́ni àwọn àlùfáà mú wọn láyà pami. Wọ́n ṣe ìkéde àpéjọ ọ̀hún lọ́nà gbígbòòrò gan-an, tí kò sì ní ẹ̀tanú nínú rárá.
Síwájú sí i, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó fẹ́ lọ sí àpéjọ náà ló tún ń sọ fún àwọn èèyàn nípa àpéjọ wọn nígbà tí wọ́n bá ń wàásù fún wọn nípa ìgbàgbọ́ wọn. Níbikíbi tí wọ́n bá lọ, káàdì àlẹ̀máyà aláwọ̀ yẹ́lò tó jẹ́ ti àpéjọ náà làwọn èèyàn fi ń dá wọn mọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n pè wá sí àpéjọ náà ló pésẹ̀, tí èyí sì mú kí iye àwọn tó pé jọ sí gbọ̀ngàn ìṣeré Sportshall lọ́jọ́ tó gbẹ̀yìn àpéjọ náà jẹ́ egbèjìdínlẹ́gbàájọ ó lé ọgọ́jọ [15,760] èèyàn. Ní òpin ọ̀sẹ̀ méjì tó kẹ́yìn oṣù July, àpapọ̀ iye èèyàn tó lọ sí àwọn àpéjọ tó wáyé ní gbọ̀ngàn ìṣeré Palais de Sport nílùú Thessalonica jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje ó lé ẹ̀tàléláàádọ́sàn-án [13,173] èèyàn.
Àpéjọ Náà Wú Àwọn Èèyàn Lórí
Nígbà tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé mẹ́rin [2,604]—tí gbogbo wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà—ya bo gbọ̀ngàn ìṣeré Sportshall, tí wọ́n ń tún un ṣe, tí wọ́n ń kùn ún lọ́dà, tí wọ́n sì ń múra ibẹ̀ sílẹ̀ fún àpéjọ náà, àwọn tó jẹ́ máníjà gbọ̀ngàn ìṣeré náà sọ pé: “A wá síbí láti wá fojú ara wa rí ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí ní ibí yìí.” Ẹnì kan sọ pé: “Ẹ̀yin ni kẹ́ ẹ máa lo ibi ìṣeré yìí lọ́dọọdún kẹ́ ẹ lè máa tún tinú-tòde rẹ̀ ṣe dáadáa.”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wú Andreas Vardakis, tó jẹ́ ọ̀gá alukoro fún ibi ìṣeré Sportshall, lórí gan-an. Ó sọ pé: Ẹ̀yin èèyàn wọ̀nyí ti ṣe ibi ìṣeré yìí lóge. Kì í ṣe pé a ò láwọn òṣìṣẹ́ tó lè máa tún un ṣe. Àmọ́ ìsapá yín láti tún un ṣe gan-an lohun tó jẹ́ kí àpéjọ yín kẹ́sẹ járí.”
Nígbà tí àpéjọ náà ń lọ lọ́wọ́, tí ọ̀gá ọlọ́pàá kan sì rí i pé òun kò ní láti rán àwọn ọlọ́pàá láti lọ kápá àwọn èrò tó wà létòlétò náà, ó sọ pé: “Mi ò tíì rí irú ìwà ọmọlúwàbí àti ìwàlétòlétò bẹ́ẹ̀ rí.”
Ìròyìn Ayọ̀ Tó Wáyé ní Àpéjọ Náà
Nínú àsọyé tó kẹ́yìn àpéjọ náà, wọ́n ṣèfilọ̀ pé Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀kọ́ àti Ẹ̀sìn nílẹ̀ Gíríìsì ti ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí “ẹ̀sìn táyé mọ̀.” Síwájú sí i, Àjọ náà ti fọwọ́ sí orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Áténì lábẹ́ òfin. Ìwé àkọsílẹ̀ tí ìjọba fi fìdí ẹ̀rí èyí múlẹ̀ sọ lápá kan pé:
“Àjọ yìí ti ka àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà [náà] sí ẹ̀sìn táyé mọ̀ . . . wọ́n sì lẹ́tọ̀ọ́ láti jàǹfààní nínú gbogbo ọ̀ràn òfin tó jẹ mọ́ ìfọwọ́sí ìjọba yìí. Ìwé àkọsílẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè tá a mẹ́nu kan lẹ́ẹ̀kan fàyè gba òmìnira ìjọsìn, ṣíṣe ìsìn ẹni lọ́nà tó wu kálukú àti lílo ohun ìní láti fi gbé ìsìn ẹni lárugẹ lọ́nà tó wu kálukú, àti bíbójú tó àwọn àlámọ̀rí ìsìn lọ́nà tó wu ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ìpàdé ìsìn kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe kedere pé ìfọwọ́sí tí ìjọba fún ètò àjọ náà tún [ka] iléeṣẹ́ wọn tó wà ní àgbègbè Marousi [ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] sí ibi ọ̀wọ̀, tí a ti yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run. Orúkọ tí wọ́n máa ń pe irú àwọn iléeṣẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ ni Bẹ́tẹ́lì, èyí tó túmọ̀ sí ‘Ilé Ọlọ́run.’”
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti ti gbogbo ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí òmìnira ẹ̀sìn, dùn sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun wọ̀nyí. Àdúrà wọn ni pé, gẹ́gẹ́ bí àbájáde èyí, àwọn èèyàn yóò lè máa gbé ìgbésí ayé Kristẹni tí wọ́n ń gbé lọ ‘lọ́nà píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́, pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.’—1 Tímótì 2:1, 2.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn Ẹlẹ́rìí péjọ sí gbọ̀ngàn ìṣeré Olympic
[Credit Line]
Harry Bilios