Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Kérésìmesì
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Kérésìmesì
Ọ̀ KẸ́ àìmọye èèyàn yíká ayé ti ń palẹ̀ mọ́ báyìí láti gbádùn àjọ̀dún Kérésìmesì ti ọdún 2002. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà wà lára wọn. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó lè máà jẹ́ àṣà tìrẹ láti máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ náà láti lọ ṣe ayẹyẹ tó gbajúmọ̀ yìí. Èyí ó wù kó jẹ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ò ní lè yẹra pátápátá fún àwọn ohun tó so mọ́ Kérésìmesì. Àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ayẹyẹ Kérésìmesì máa ń fara hàn gbangba nínú káràkátà àti nínú eré ìnàjú, kódà láwọn ilẹ̀ tí kì í ṣe ti ẹlẹ́sìn Kristi pàápàá.
Kí lo mọ̀ nípa Kérésìmesì? Ǹjẹ́ ibì kankan wà nínú Bíbélì tó ti ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Kristi lẹ́yìn? Ibo ni ayẹyẹ tó gbajúmọ̀ tí wọ́n ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún yìí tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ gan-an?
Wọ́n Fòfin De Kérésìmesì
Bó o bá lè fi àkókò díẹ̀ ṣèwádìí nípa kókó tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, wàá rí i pé kì í ṣe látinú ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ni Kérésìmesì ti ṣẹ̀ wá. Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ látinú onírúurú ẹ̀ya ìsìn jẹ́rìí sí èyí. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, kò yẹ kó yà ọ́ lẹ́nu pé, ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Cromwell ṣòfin lọ́dún 1647 pé, kí wọ́n máa fi ọjọ́ Kérésìmesì ṣe ọjọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tó sì di ọdún 1652, ni wọ́n bá kúkú fòfin dè é pátápátá. Èyí ló mú kí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà máa pàdé ní gbogbo ọjọ́ tó bá bọ́ sí December 25, láti ọdún 1644 sí ọdún 1656. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Penne L. Restad ti sọ, “ńṣe làwọn òjíṣẹ́ tó bá wàásù nípa ọjọ́ Ìbí Kristi ń fẹ̀wọ̀n ṣeré. Àwọn ọmọ ìjọ tó bá lọ fi àwọn nǹkan Kérésìmesì ṣe ṣọ́ọ̀ṣì lọ́ṣọ̀ọ́ yóò san owó ìtanràn. Òfin tún sọ pé, wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣí àwọn ṣọ́ọ̀bù lọ́jọ́ Kérésìmesì bí wọ́n ṣe máa ń ṣí i láwọn ọjọ́ tó kù.” Kí ló dé tí wọ́n fi gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó lágbára yìí? Àwọn Aláfọ̀mọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbà gbọ́ pé, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì ló máa dá àwọn àṣà tí kò sí nínú Ìwé Mímọ́ sílẹ̀. Wọ́n máa ń wàásù kíkankíkan láti bẹnu àtẹ́ lu àwọn ayẹyẹ tó so mọ́ àjọ̀dún Kérésìmesì wọ́n sì máa ń pín àwọn ìwé kiri lórí èyí.
Irú ohun tó jọ èyí náà ṣẹlẹ̀ ní Àríwá Amẹ́ríkà. Láàárín ọdún 1659 sí ọdún 1681, wọ́n fòfin de Kérésìmesì ní àgbègbè Massachusetts Bay Colony. a Gẹ́gẹ́ bí òfin tí wọ́n ṣe nígbà náà ti wí, wọn ò gbọ́dọ̀ ṣayẹyẹ Kérésìmesì lọ́nàkọnà. Àwọn tó bá tàpá sí òfin yìí máa ń san owó ìtanràn. Kì í ṣe àwọn Aláfọ̀mọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ti àgbègbè New England nìkan ni kò fara mọ́ ṣíṣayẹyẹ Kérésìmesì, àwọn àwùjọ kan tó ń gbé ní àárín gbùngbùn àgbègbè náà pẹ̀lú kò fara mọ́ ọn. Àwọn onísìn kan tó ń jẹ́ Quakers ní ìlú Pennsylvania náà kò jẹ́ lọ́wọ́ sí ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì bíi tàwọn Aláfọ̀mọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ìwé kan sọ pé, “kò pẹ́ lẹ́yìn táwọn ará Amẹ́ríkà gba òmìnira wọn, Elizabeth Drinker, tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́sìn Quaker, pín àwọn olùgbé Philadelphia sí ọ̀nà mẹ́ta. Àwọn kan jẹ́ ẹlẹ́sìn Quakers, tí wọn ‘ò ka ọjọ́ [Kérésìmesì] sí ọjọ́ tó ṣe pàtàkì ju òmíràn lọ,’ àwọn mìíràn jẹ́ àwọn tó kà á sí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe nínú ẹ̀sìn, àtàwọn yòókù tó jẹ́ pé ‘àríyá ẹhànnà àti mímu ọtí àmuyíràá ni wọ́n máa ń lo ọjọ́ náà fún.’”
Henry Ward Beecher, oníwàásù kan tó gbajúmọ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà, tí wọ́n tọ́ dàgbà ní ilé àwọn ẹlẹ́sìn Calvin àtayébáyé kò fi bẹ́ẹ̀ mọ nǹkan kan rárá nípa ohun tó ń jẹ́ Kérésìmesì títí tó fi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún. Beecher kọ̀wé lọ́dún 1874 pé: “Nǹkan àjèjì pátápátá ni Kérésìmesì jẹ́ sí mi.”
Àwọn Ìjọ Onítẹ̀bọmi àtàwọn ọmọ Ìjọ Congregational ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà kò rí ìpìlẹ̀
Ìwé Mímọ́ kankan fún ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Kristi. Ìwé kan sọ pé, December 25, ọdún 1772 ni Ìjọ Onítẹ̀bọmi ti ìlú Newport [Rhode Island] nílẹ̀ Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì fún ìgbà àkọ́kọ́. Èyí sì jẹ́ nǹkan bí àádóje [130] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti dá Ìjọ Onítẹ̀bọmi sílẹ̀ ní àgbègbè New England.Ibi Tí Kérésìmesì Ti Ṣẹ̀ Wá
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia là á mọ́lẹ̀ pé: “Kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ ìbí Kristi. Àwọn ìwé ìhìn rere kò sọ ọjọ́ tàbí oṣù náà ní pàtó . . . Gẹ́gẹ́ bí èròǹgbà ọ̀mọ̀wé H. Usener . . . èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní fara mọ́, ọjọ́ tí wọ́n pè ní ọjọ́ ìbí Kristi yìí ni wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ọjọ́ tó gùn jù lọ nínú ọdún, èyí tó jẹ́ ìgbà òtútù (December 25 nínú Kàlẹ́ńdà àwọn ará Róòmù, January 6 lórí Kàlẹ́ńdà àwọn ará Íjíbítì). Ìdí ni pé, bí oòrùn bá ti ń padà sí apá Àríwá Ìlàjì Ilẹ̀ Ayé làwọn kèfèrí tó jẹ́ olùfọkànsìn ọlọ́run oòrùn tí wọ́n ń pè ní Mithra máa ń ṣe ayẹyẹ ọdún wọn tí wọ́n ń pè ní dies natalis Solis Invicti, (ọjọ́ ìbí oòrùn tí kò ṣeé ṣẹ́gun). Ṣáájú àkókò yìí, ní December 25, ọdún 274 Sànmánì Tiwa, Aurelian tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù, ti polongo pé ọlọ́run oòrùn ni olùdáàbòbò ilẹ̀ ọba náà, ó sì ya tẹ́ńpìlì kan sọ́tọ̀ fún un ní àgbègbè Campus Martius. Kérésìmesì bẹ̀rẹ̀ ní àkókò kan tí ìjọsìn oòrùn lágbára gan-an nílẹ̀ Róòmù.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ M’Clintock àti Strong sọ pé: “Ṣíṣayẹyẹ Kérésìmesì kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì pilẹ̀ṣẹ̀ látinú Májẹ̀mú Tuntun. Kò sí ẹ̀rí kankan látinú Májẹ̀mú Tuntun tá a lè tọ́ka sí pẹ̀lú ìdánilójú pé ọjọ́ kan báyìí ni a bí Kristi.”
“Ẹ̀tàn Òfìfo” Lásán
Níbàámu pẹ̀lú àwọn àlàyé tá a ṣé lókè yìí, ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ sí ayẹyẹ Kérésìmesì? Ǹjẹ́ inú Ọlọ́run á dùn láti rí i ká máa da ìjọsìn rẹ̀ pọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àti àṣà àwọn èèyàn tí kò jọ́sìn rẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ìkìlọ̀ nínú Kólósè 2:8 pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”
Àpọ́sítélì náà tún kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì [Sátánì]? Tàbí ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?”—2 Kọ́ríńtì 6:14, 15.
Lójú àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé sẹ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ Kérésìmesì. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ wí, wọ́n ń làkàkà láti ṣe “ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run,” nípa pípa ara wọn mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọdún 1628 làwọn Aláfọ̀mọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dá Massachusetts Bay Colony sílẹ̀, òun ló sì tóbi jù lọ tó tún rọ́wọ́ mú jù lọ nínú àwọn àgbègbè tí wọ́n dá sílẹ̀ láyé ọjọ́un ní New England.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]
Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fòfin de àjọ̀dún Kérésìmesì lọ́dún 1652
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]
“Nǹkan àjèjì pátápátá ni Kérésìmesì jẹ́ sí mi”—HENRY WARD BEECHER, ÀLÙFÁÀ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ KAN NÍLẸ̀ AMẸ́RÍKÀ LÓ SỌ BẸ́Ẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn kèfèrí olùfọkànsin ọlọ́run Mithras àti ọlọ́run oòrùn (tá a fi hàn nínú ère gbígbẹ́) ṣayẹyẹ December 25
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris