Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia

Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia

Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia

GẸ́GẸ́ BÍ JÁN BALI ṢE SỌ Ọ́

WỌ́N bí mi ní December 24, 1910, ní abúlé Záhor, tó wà ní ìhà ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Slovakia báyìí. Nígbà yẹn, abúlé wa jẹ́ apá kan Ilẹ̀ Ọba Austria òun Hungary. Lọ́dún 1913, màmá mi mú mi lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dọ̀ bàbá mi, ẹni tó ti kúrò ní Záhor ṣáájú àkókò yẹn. Ọdún méjì lẹ́yìn tí èmi àti màmá mi dé sí ìlú Gary, ní ìpínlẹ̀ Indiana, ni wọ́n bí àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Anna. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni Bàbá bẹ̀rẹ̀ àìsàn tó sì kú lọ́dún 1917.

Mo di akẹ́kọ̀ọ́ onítara, mo sì wá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn gidigidi. Ní Ṣọ́ọ̀ṣì Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin tí mo ti máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, olùkọ́ wa kíyè sí i pé mo nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Kí n lè túbọ̀ mọ púpọ̀ sí i nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn, ó fún mi ní Ẹ̀dà Ìtumọ̀ Bíbélì ti Holman, èyí tó ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ìbéèrè àti ìdáhùn nínú. Èyí fún èmi tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá péré ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti máa ronú lé lórí.

‘Èyí Ni Òtítọ́’

Láwọn ọdún wọ̀nyẹn, lára àwọn tó ṣí wọ̀lú láti orílẹ̀-èdè Slovakia, tí wọ́n ń gbé ní àdúgbò tá à ń gbé, di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Ọ̀kan lára wọn ni arákùnrin bàbá mi kan tó ń jẹ́ Michal Bali, ẹni tó fi àwọn òtítọ́ Bíbélì kọ́ wa. Àmọ́, lọ́dún 1922, Màmá mú èmi àti arábìnrin mi padà lọ sí Záhor, tó ti di apá kan ìhà ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Czechoslovakia lásìkò náà.

Kété lẹ́yìn ìgbà náà, Arákùnrin Michal fi gbogbo ìdìpọ̀ ìwé Studies in the Scriptures, èyí tí Charles Taze Russell kọ, ránṣẹ́ sí mi, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àtúntẹ̀ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó ti kọjá, títí kan ìtẹ̀jáde July 1, 1879, tí ó jẹ́ ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àkọ́kọ́. Mo ka gbogbo wọn tán látòkèdélẹ̀, mo tiẹ̀ ka àwọn apá kan lára wọn léraléra, ó sì wá dá mi lójú gbangba pé mo ti rí òtítọ́ Bíbélì tí mò ń wá kiri.

Láàárín àkókò yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Slovakia fi Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sílẹ̀, wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn. Àwọn ni wọ́n di àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè Slovak lórílẹ̀-èdè Czechoslovakia. Èmi àti màmá mi máa ń lọ sí àwọn ìpàdé tá à ń ṣe láyé ọjọ́un ní abúlé wa ní Záhor, àti láwọn ibòmíràn nítòsí ibẹ̀.

Àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn jọ irú àwọn ìpàdé Kristẹni tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. A sábà máa ń pàdé nínú ilé ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, níbi tí a óò ti jókòó yí tábìlì kan ká, èyí tí wọ́n gbé àtùpà kan tó ń lo epo bẹtiróò lé lórí. Torí pé èmi ni mo kéré jù lọ láàárín wọn, màá rọra jókòó lọ́wọ́ ẹ̀yìn, màá sì máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú òkùnkùn tí mo wà. Àmọ́ nígbà míì, wọ́n máa ń sọ pé kí n dá sí ìjíròrò náà. Nígbà tí ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n kà lédè Slovak kò bá yé wọn, wọ́n á ní: “Tóò, Ján, kí ni èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí ná?” Mo máa ń hára gàgà láti wá síbi tí àtùpà náà wà, tí màá sì túmọ̀ ohun tó wà nínú ìtẹ̀jáde Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Slovak.

Lára àwọn tó di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n sì padà wá sí orílẹ̀-èdè tó ti di Czechoslovakia lásìkò náà ni Michal Šalata. Ó padà sí abúlé Sečovce tó wà nítòsí wa, níbi tó ń gbé tẹ́lẹ̀, ó sì ṣèrànwọ́ láti ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ní Czechoslovakia. Arákùnrin Šalata máa ń mú mi dání tó bá ń rìnrìn-àjò lọ fún iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tó di ọdún 1924, tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, mo sọ fún un pé kó ṣe ìrìbọmi fún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé màmá mi ń wò ó pé mo ṣì kéré jù láti gbé irú ìgbésẹ̀ tó gba ìrònújinlẹ̀ bẹ́ẹ̀, mo jẹ́ kó dá a lójú pé ìpinnu mi nìyẹn, mi ò sì lè yẹ̀ ẹ́. Nítorí náà, ní oṣù July ọdún yẹn, nígbà àpéjọ ọlọ́jọ́ kan tá a ṣe nítòsí Odò Ondava, mo fi àmì ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi nínú odò yẹn.

Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tí Mo Ṣìkẹ́ Gidigidi

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo gbọ́ pé wọ́n fẹ́ ṣe ètò ìsìnkú kan ní kìlómítà bíi mélòó kan sí abúlé tí mo ti ń wàásù. Ìyẹn ni ètò ìsìnkú àkọ́kọ́ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ṣe ní àgbègbè yẹn. Nígbà tí mo débẹ̀, mo la àárín àwọn ará abúlé tó ti ń fojú sọ́nà láti wo bí a ṣe fẹ́ ṣe ètò náà kọjá, mo sì lọ bá olùbánisọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó yíjú sí mi, ó sì sọ pé: “Èmi ni màá kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, ìwọ ni wàá sì máa sọ ìyókù lọ.”

Mo gbé ọ̀rọ̀ mi ka àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú 1 Pétérù 4:7, èyí tó kà pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” Mo fi hàn látinú Ìwé Mímọ́ pé òpin máa tó dé bá ìnira àti ikú, mo sì ṣàlàyé ìrètí àjíǹde. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Láìka ti pé mo kéré ju ọjọ́ orí mi gan-an lọ—tàbí bóyá torí pé mo sì jẹ́ ọ̀dọ́ ló fà á—gbogbo àwọn olùgbọ́ ló tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ mi.

Àwọn ìròyìn tí ń mórí ẹni wú jáde nínú ìtẹ̀jáde llé Ìṣọ́ ti September 15, 1931, èyí tó ṣàlàyé pé a ò fẹ́ káwọn èèyàn máa pè wá ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí irú àwọn orúkọ bẹ́ẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n a fẹ́ kí wọ́n máa pè wá ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn tí mo ti ka ìsọfúnni yìí tán, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà lágbègbè wa ṣètò fún ìpàdé àkànṣe kan. Àwa Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí iye wa tó ọgọ́rùn-ún la pàdé ní abúlé Pozdišovce. Níbẹ̀, mo láǹfààní láti sọ àsọyé kan tó ní àkòrí náà, “Orúkọ Tuntun Náà,” èyí tá a gbé ka llé Ìṣọ́ tí mo mẹ́nu kàn lókè.

Pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà ni gbogbo àwọn tó wà lórí ìjókòó fi nawọ́ wọn sókè nígbà tí a ní kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan náà tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ti tẹ́wọ́ gba láwọn ibòmíràn lágbàáyé. Lẹ́yìn èyí, a tẹ wáyà ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, èyí tó kà pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a péjọ lónìí ní Pozdišovce gbà pẹ̀lú àlàyé inú llé Ìṣọ́ tó sọ nípa orúkọ tuntun náà, a sì ń tẹ́wọ́ gba orúkọ tuntun yìí, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Àgbègbè Slovakia àti Transcarpathia tó gbòòrò gan-an, tí wọ́n jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Czechoslovakia ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì, wá di ilẹ̀ ọlọ́ràá fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa. Láti wàásù káàkiri ìpínlẹ̀ títóbi yìí, ẹsẹ̀ la fi máa ń rìn, a sì tún máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin tàbí ká wọ bọ́ọ̀sì, tàbí ká gun kẹ̀kẹ́. Lákòókò yẹn, a fi “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú, ìyẹn ni sinimá tó ní àwọn àwòrán ara ògiri nínú pa pọ̀ pẹ̀lú ìró ohùn tí ń ṣàlàyé àwọn àwòrán náà. Lẹ́yìn ṣíṣe àfihàn kọ̀ọ̀kan, a máa ń gba àdírẹ́sì àwọn olùfìfẹ́hàn. Wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdírẹ́sì yìí fún mi, wọ́n sì ní kí n ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí tó máa lọ bẹ àwọn olùfìfẹ́hàn wò. Láwọn ìlú kan, a máa ń háyà àwọn gbọ̀ngàn ìpàdé níbi tí mo ti máa ń sọ àkànṣe àsọyé lẹ́yìn tí a bá ti fi àwọn àwòrán náà han àwọn aráàlú.

Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1939, mo láǹfààní láti lọ sí àwọn àpéjọ ńlá tá a ṣe ní ìlú Prague tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè wa. Lọ́dún 1932, Society ṣètò àpéjọ àgbáyé àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Czechoslovakia. A péjọ sí Gbọ̀ngàn Ìṣeré Varieté. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo èèyàn tá a kéde láti sọ ni, “Yúróòpù Ṣáájú Ìparun.” Èyí gba àfiyèsí àwọn aráàlú, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ èèyàn ló sì pésẹ̀. A ṣe àpéjọ àgbáyé mìíràn ní ìlú Prague lọ́dún 1937, mo sì láǹfààní láti sọ ọ̀kan lára àwọn àsọyé àpéjọ náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá sí àpéjọ yìí láti ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù, gbogbo wa la sì gba ìṣírí tá a nílò láti lè fara da àwọn àdánwò tó wáyé kété lẹ́yìn náà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

Ìgbéyàwó, àti Àwọn Ìdánwò Bíburú Jáì

Lẹ́yìn tá a padà sí Czechoslovakia, èmi àti Màmá ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹlẹgbẹ́ wa láti abúlé Pozdišovce tó wà nítòsí. Ibẹ̀ ni mo ti wá rí ọmọbìnrin olójú rèǹtèrente kan tó ń jẹ́ Anna Rohálová. Nígbà tá a dàgbà díẹ̀ sí i la wá rí i pé ìfẹ́ tá a ní sí ara wa ju èyí tó kàn máa ń wà láàárín Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin lọ. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1937. Látìgbà yẹn ni Anna ti jẹ́ alátìlẹyìn mi, kódà láwọn “àsìkò tó kún fún ìdààmú” tó máa tó wọlé dé.—2 Tímótì 4:2.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó ló wá ṣe kedere pé ilẹ̀ Yúróòpù ti ń gbara dì fún Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tó fi máa di November 1938, orílẹ̀-èdè Hungary, tó ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Násì ti Jámánì, gba àwọn àgbègbè tó wà ní apá ìhà gúúsù Transcarpathia àti Slovakia. Àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Hungary sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ìpàdé mọ́, wọ́n sì sọ pé a gbọ́dọ̀ máa fara hàn déédéé ní àgọ́ ọlọ́pàá.

Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní September 1939, àwọn agbófinró fàṣẹ ọba mú àwa Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan, àtọkùnrin àtobìnrin, wọ́n sì kó wa lọ sí ilé ńlá àtijọ́ kan tó wà nítòsí ìlú Mukacheve, tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè Ukraine báyìí. A bá ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa láti àwọn ìjọ tó wà ní Transcarpathia pàdé níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò tí wọ́n sì ń lù wá ṣáá fún bí oṣù mẹ́ta tàbí mẹ́rin, kóòtù àkànṣe kan tó jẹ́ tàwọn ológun gbé ẹjọ́ wa yẹ̀ wò. Ìbéèrè kan ṣoṣo ni wọ́n béèrè lọ́wọ́ gbogbo wa: “Ṣé ẹ múra tán láti ran ilẹ̀ Hungary lọ́wọ́ láti gbógun ti ilẹ̀ Soviet Union?” Nítorí pé a kọ̀ láti dá sí tọ̀tún-tòsì, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún wa, wọ́n sì rán wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó wà ní, Nọnba 85, Òpópónà Margit Boulevard, ní ìlú Budapest, lórílẹ̀-èdè Hungary.

Oúnjẹ ò ká gbogbo àwa ẹlẹ́wọ̀n lẹ́nu rárá. Láìpẹ́, àrùn bẹ̀rẹ̀ sí í gbèèràn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì bẹ̀rẹ̀ sí kú. Ìdùnnú ńlá ló jẹ́ fún mi láti rí i tí ìyàwó mi rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn láti abúlé wa ní Záhor láti wá wò mi! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ́jú márùn-ún péré ni mo fi ráyè bá a sọ̀rọ̀ látinú galagálá irin inú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi ní irú aya adúró-tini-lọ́jọ́-ìṣòro bẹ́ẹ̀.

Láti Ọgbà Ẹ̀wọ̀n sí Àgọ́ Iṣẹ́ Àṣekú

Láti ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí ni wọ́n ti gbé mi tààràtà lọ sí ìlú Jászberény, lórílẹ̀-èdè Hungary, níbi tí wọ́n ti kó àwọn Ẹlẹ́rìí bí ọgọ́jọ lọ. Nígbà tá a wà níbẹ̀, ọ̀gágun ilẹ̀ Hungary kan fún wa ní àǹfààní ìkẹyìn látọ̀dọ̀ ìjọba orílẹ̀-èdè Hungary: “Bó o bá ṣe tán láti ṣiṣẹ́ ológun, bọ́ síta níbí.” Kò sẹ́ni tó jáde síta. Ọ̀gágun náà wá sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe ò bá mi lára mu, ìpinnu yín láti jẹ́ olùṣòtítọ́ wú mi lórí gan-an ni.”

Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n fi ọkọ̀ òkun kan tó ń rìnrìn-àjò lórí Odò Danube kó wa lọ sí àgọ́ iṣẹ́ àṣekú kan nítòsí ìlú Bor tó wà lórílẹ̀-èdè Yugoslavia. Nígbà tá a wà nínú ọkọ̀ òkun náà, àìmọye ìgbà làwọn ọmọ ogun náà àti ọ̀gá wọn gbìyànjú láti mú ká juwọ́ sílẹ̀, ká sì sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Ọ̀gá náà ní káwọn ọmọ ogun rẹ̀ máa fi ìbọn wọn lù wá, kí wọ́n máa fi bàtà wọn ta wá nípàá, kí wọ́n sì máa jẹ wá níyà láwọn ọ̀nà mìíràn.

Nígbà tí wọ́n fà wá lé Ọ̀gágun András Balogh tó jẹ́ alábòójútó àgọ́ iṣẹ́ àṣekú ti ìlú Bor, lọ́wọ́, ó sọ fún wa pé: “Bó bá fi jẹ́ pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ fún mi nípa yín, á jẹ́ pé ẹ ò ní pẹ́ kú nìyẹn.” Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ti ka ìsọfúnni kan táwọn aláṣẹ ìjọba ti fi èdìdì dí kí wọ́n tó fi ránṣẹ́ sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá wa lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Balogh fún wa ní òmìnira díẹ̀ láti máa rìn fàlàlà, kódà ó tún gbà wá láyè láti kọ́ ibùgbé mọ́ńbé kan fún ara wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ wọ́n bí ojú, a ní ilé ìdáná tiwa, nípa bẹ́ẹ̀ oúnjẹ máa ń kárí gbogbo wa láìsí ojúsàájú.

Ní March ọdún 1944, orílẹ̀-èdè Jámánì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn àgbègbè tó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Hungary tẹ́lẹ̀. Lásìkò yẹn, ọ̀gágun Ede Marányi, tó jẹ́ alátìlẹyìn ìjọba Násì, bọ́ sípò Balogh. Ó gbé òfin líle koko kalẹ̀, èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sáwọn òfin tí wọ́n ń lò ní àgọ́ iṣẹ́ àṣekú. Àmọ́, kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Russia bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ tòsí, ni wọ́n bá kó gbogbo ẹni tó wà nínú àgọ́ ìlú Bor kúrò. Lẹ́yìn náà, nígbà tá à ń fẹsẹ̀ rìn lọ, a fojú ara wa rí bí wọ́n ṣe pa àwọn Júù nípakúpa ní ìlú Cservenka. Bí wọn ò ṣe pa wá lọ́jọ́ náà kàn ń dà bí iṣẹ́ ìyanu ni.

Nígbà tó kù díẹ̀ ká dé ààlà orílẹ̀-èdè Hungary àti orílẹ̀-èdè Austria, wọ́n pàṣẹ fún wa láti gbẹ́ ilẹ̀ ibi tí wọ́n máa ri àwọn ìbọn arọ̀jò-ọta wọn sí. A ṣàlàyé pé ohun tó fà á gan-an tí wọ́n fi sọ wá sẹ́wọ̀n ni pé a kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé apá iwájú ni mo wà, ọ̀gágun ọmọ ilẹ̀ Hungary kan wọ́ mi mọ́ra, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lù mí. Bẹ́ẹ̀ ló ń pariwo pé: “Màá rí i pé mo pa ẹ! Torí bí ìwọ ò bá ṣiṣẹ́, àpẹẹrẹ burúkú tìẹ ni gbogbo àwọn yòókù máa tẹ̀ lé!” Ọpẹ́lọpẹ́ pé arákùnrin András Bartha, àgbàlagbà Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aṣáájú wa nínú iṣẹ́ ìwàásù, fi tìgboyàtìgboyà dá sí ọ̀ràn náà lákòókò yẹn, ọ̀gágun náà ì bá pa mi. a

Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà ni ogun náà parí, tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí padà sílé. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn, tí wọ́n ti dá sílẹ̀ níṣàájú lágọ̀ọ́ tó wà ní ìlú Bor, ti lọ sọ fáwọn èèyàn wa pé gbogbo àwa tí wọ́n kó lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Cservenka làwọn ológun ti pa. Torí èyí, fún bí oṣù mẹ́fà ni ìyàwó mi fi ka ara rẹ̀ sí opó. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un lọ́jọ́ kan láti rí mi lẹ́nu ọ̀nà! Ńṣe ni omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú wa pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ bá a ṣe dì mọ́ ara wa lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tá a ti pínyà.

Ṣíṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù

Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n da ilẹ̀ Slovakia pọ̀ mọ́ ilẹ̀ Czechia láti di orílẹ̀-èdè Czechoslovakia. Àmọ́, àgbègbè Transcarpathia, tí ọ̀pọ̀ lára rẹ̀ ti jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Czechoslovakia kí ogun náà tó bẹ̀rẹ̀, wá di apá kan orílẹ̀-èdè Ukraine tó wà lára Soviet Union. Lọ́dún 1945, èmi àti Michal Moskal lọ sí ìlú Bratislava, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Slovakia nísinsìnyí, níbi tá a ti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti ṣètò iṣẹ́ ìwàásù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ò lókun mọ́ nípa tara àti ní ti ìmí ẹ̀dùn, à ń hára gàgà láti máa bá iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù pa láṣẹ fún wa lọ.—Mátíù 24:14; 28:18-20.

Lẹ́yìn ogun náà, àwọn àpéjọ tá a ṣe fún wa ní ìṣírí gan-an láti jára mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Ní September 1946, a ṣe àpéjọ àkọ́kọ́ tó wà fún gbogbo orílẹ̀-èdè ní ìlú Brno. Mo láǹfààní láti sọ àsọyé kan tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Òpin Ayé Ni Ìkórè Náà.”

Lọ́dún 1947, a ṣe àpéjọ mìíràn tó tún jẹ́ ti gbogbo orílẹ̀-èdè ní ìlú Brno. Níbẹ̀, Nathan H. Knorr, Milton G. Henschel, àti Hayden C. Covington, tí wọ́n ń ṣèbẹ̀wò láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, sọ àwọn àsọyé tí ń gbéni ró. Mo láǹfààní láti ṣe ògbufọ̀ fún wọn bí wọ́n ti ń sọ àwọn àsọyé ọ̀hún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí egbèje [1,400] olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ló wà ní orílẹ̀-èdè Czechoslovakia lásìkò náà, àwọn èèyàn bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ló pésẹ̀ láti gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn.

Inúnibíni Lábẹ́ Ìṣàkóso Kọ́múníìsì

Lọ́dún 1948, ìjọba Kọ́múníìsì gorí àlééfà, láìpẹ́ sígbà náà ni wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, èyí tó ń bá a lọ fún ogójì ọdún. Lọ́dún 1952, ọ̀pọ̀ lára àwa Ẹlẹ́rìí táwọn aláṣẹ kà sí aṣáájú ni wọ́n sọ sẹ́wọ̀n. Wọ́n fẹ̀sùn ìdojú-ìjọba-dé kan ọ̀pọ̀ lára wa, ṣùgbọ́n ẹ̀sùn ìdìtẹ̀-gbàjọba ni wọ́n fi kan àwa kan. Wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò fún ọdún kan ààbọ̀. Nígbà tí mo béèrè lọ́wọ́ adájọ́ náà pé, ọ̀nà wo ni mo gbà jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, ó sọ pé: “Ò ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. O sì sọ pé Ìjọba náà ni yóò máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé. Èyí sì kan orílẹ̀-èdè Czechoslovakia pẹ̀lú.”

Mo wá fèsì pé: “Bó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ẹ̀sùn ọ̀dàlẹ̀ lẹ máa fi kan gbogbo ẹni tó bá ń gba Àdúrà Olúwa, tó sì ń gbàdúrà pé ‘Kí Ìjọba Ọlọ́run dé.’” Síbẹ̀, wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún ààbọ̀, wọ́n sì mú mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba Kọ́múníìsì kan tó burú jáì, èyí tó wà ní ìlú Jáchymov, lórílẹ̀-èdè Czechoslovakia.

Lẹ́yìn tí mo ti lo ọ̀pọ̀ lára ọdún tí wọ́n dá fún mi, wọ́n dá mi sílẹ̀ lómìnira. Anna aya mi, dúró tì mí gbágbáágbá, bó ṣe ń kọ lẹ́tà sí mi ló tún ń ṣèbẹ̀wò, tó sì tún ń tọ́jú Mária, ọmọbìnrin wa. Níkẹyìn, gbogbo ìdílé wa tún wà pa pọ̀, a sì tún bẹ̀rẹ̀ àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni wa, èyí tá à ń bá lọ lábẹ́lẹ̀.

Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Láti ohun tó lé ní àádọ́rin ọdún sẹ́yìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè wa ti ń sin Ọlọ́run lábẹ́ onírúurú ipò, tí ọ̀pọ̀ jù lọ èyí sì jẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso Kọ́múníìsì. Lóòótọ́, mo ti darúgbó mi ò sì lókun nínú mọ́, àmọ́ ó ṣì ṣeé ṣe fún mi láti sìn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni alàgbà ní Záhor, pẹ̀lú àwọn olùṣòtítọ́ bí arákùnrin Ján Korpa-Ondo, ẹni tó ṣì wà láàyè ní ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún. b Aya mi àtàtà, tí ó jẹ́ ojúlówó ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà, kú lọ́dún 1996.

Kedere kèdèrè ni mo ṣì máa ń rántí ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò kan tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ojú ìwé 228 sí 231 nínú ìwé The Way to Paradise, èyí tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 1924. Níbẹ̀, a sọ pé kí ẹni tó ń ka ìwé náà fojú inú wò ó pé òún wà nínú Párádísè, tí ó ń gbọ́ tí àwọn ẹni méjì tí a jí dìde ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n ń ṣe kàyéfì nípa ibi tí àwọ́n wà. Nígbà náà ni ẹnì kan tó ti la Amágẹ́dọ́nì já láǹfààní láti ṣàlàyé fún àwọn ẹni méjì náà pé a ti jí wọn dìde sí Párádísè. (Lúùkù 23:43) Bí mo bá la Amágẹ́dọ́nì já, màá fẹ́ láti ṣàlàyé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún aya mi, ìyá mi, àtàwọn ojúlùmọ̀ mi mìíràn nígbà tí a bá jí wọn dìde. Àmọ́ bí mo bá kú ṣáájú Amágẹ́dọ́nì, mò ń fojú sọ́nà de àkókò náà tí ẹnì kan nínú ayé tuntun yóò sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí mo kú fún mi.

Ní báyìí, mo ṣì ń gbádùn àǹfààní àgbàyanu àti aláìlẹ́gbẹ́ tí mo ní láti máa bá Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run sọ̀rọ̀, àti àǹfààní tí mo ní láti sún mọ́ ọn. Ìpinnu mi ni láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 14:8, pé: “Bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà, bí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà. Nítorí náà, bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, ti July 15, 1993, ojú ìwé 11, fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa András Bartha.

b Wo ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti September 1, 1998, ojú ìwé 24 sí 28.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi pẹ̀lú Anna, ọdún kan lẹ́yìn ìgbéyàwó wa

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi pẹ̀lú Nathan H. Knorr ní àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1947 ní ìlú Brno