Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́—Àwọn Agbẹjọ́rò Rojọ́ Níwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́—Àwọn Agbẹjọ́rò Rojọ́ Níwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
FEBRUARY 26, 2002 ni ọjọ́ tí wọ́n dá, tí àwọn agbẹjọ́rò yóò ro ẹjọ́ náà níwájú Adájọ́ Àgbà, William Rehnquist àtàwọn adájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́jọ mìíràn. Àwọn agbẹjọ́rò mẹ́rin ló ṣojú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ẹni tó jẹ́ aṣáájú àwọn agbẹjọ́rò ti àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn kan tó gba àfiyèsí gbogbo àwọn tó wà nínú ilé ẹjọ́ náà, ó sọ pé: “Déédéé aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ni lọ́jọ́ Sátidé ní Abúlé Stratton. [Lẹ́yìn náà, ó fọwọ́ lu tábìlì iwájú rẹ̀ ko, ko, ko.] ‘Ẹ káàárọ̀ o. Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, mo ti sapá gidigidi láti wá sí ẹnu ọ̀nà yín láti wá bá yín sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Wòlíì Aísáyà tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ohun kan tó sàn ju àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí lọ. Ìyẹn ni ìhìn rere tí Kristi Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.’”
Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní Abúlé Stratton, ìwà ọ̀daràn ni wọ́n kà á sí pé kí ẹnì kan máa lọ láti ẹnu ọ̀nà kan dé òmíràn láti sọ ìhìn yẹn fún àwọn èèyàn láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ abúlé náà kó tó ṣe bẹ́ẹ̀.”
‘Ṣé Ẹ Kì Í Béèrè Owó?’
Adájọ́ Stephen G. Breyer béèrè àwọn ìbéèrè kan tó sojú abẹ níkòó lọ́wọ́ agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí. Ó béèrè pé: “Ṣé òótọ́ ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí kì í béèrè owó kankan, ì báà má ju táṣẹ́rẹ́ lọ, àti [pé] ṣé wọn kì í ta Bíbélì, ṣé wọn kì í sì í ta ohunkóhun? Ṣé gbogbo ohun tí wọ́n kàn máa ń sọ kò ju, ‘Mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa ìsìn’?”
Agbejọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí dá a lóhùn pé: “Olúwa Mi, kò sẹ́ni tí kò mọ̀ ní gbogbo Abúlé Stratton pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í béèrè owó. Bákan náà ló jẹ́ pé láwọn àgbègbè mìíràn, òtítọ́ tó ṣe kedere ni pé nígbà míì, wọ́n máa ń sọ fún àwọn èèyàn pé bí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè ṣe ìdáwó . . . . Kì í ṣe pé ńṣe là ń lọ láti tọrọ owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Ńṣe la kàn ń gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.”
Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Láti Gba Ìyọ̀ǹda Ìjọba?
Adájọ́ Antonin Scalia wá béèrè ìbéèrè olóye kan pé: “Ìyẹn ni pé, lójú tìrẹ, ko pọn dandan kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sọ́dọ̀ baálẹ̀ láti lọ gba àṣẹ kó tó lè bá aládùúgbò rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan kan tó ṣe pàtàkì?” Agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí wá dá a lóhùn pé: “A ò rò pé ó yẹ kí Ilé Ẹjọ́ yìí fọwọ́ sí òfin Ìjọba kan tó máa sọ pé aráàlú kan ní láti lọ gba ìwé àṣẹ kó tó lè bá aráàlú ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nínú ilé ẹni náà.”
Ọ̀rọ̀ Yí Padà, Ìmọ̀lára Yí Padà
Àwọn agbẹjọ́rò Abúlé Stratton lọ̀rọ̀ kàn báyìí láti sọ tẹnu wọn. Ẹni tó jẹ́ aṣáájú àwọn agbẹjọ́rò náà ṣàlàyé ìdí tí Abúlé náà fi ṣe òfin náà, ó sọ pé: “Ńṣe ni Abúlé Stratton ń lo agbára tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ kí àwọn kan má bàa máa yọ wọ́n lẹ́nu, ó sì ń gbìyànjú
láti dènà ìwà ọ̀daràn. Òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ jíròrò nǹkan kan tàbí lọ tọrọ nǹkan lọ́wọ́ àwọn èèyàn nínú ilé wọn wulẹ̀ ń béèrè pé kí àwọn èèyàn kọ́kọ́ lọ forúkọ sílẹ̀ ni, kí wọ́n sì máa mú ìwé tí wọ́n fi fún wọn láṣẹ dání nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ lílọ láti ilé dé ilé.”Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Adájọ Scalia lọ sórí ohun tó pilẹ̀ ẹjọ́ náà nípa bíbéèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin adájọ́ yòókù mọ̀ bóyá ẹjọ́ kankan tiẹ̀ wà tó jọ èyí tí a [ìyẹn Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ yìí] ti bójú tó rí, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú lílọ bá èèyàn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan kan, kì í ṣe láti lọ tọrọ owó o, kì í ṣe láti lọ ta ọjà o, àní sẹ́, bí àpẹẹrẹ, bíi kéèyàn sọ pé, ‘Mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi,’ tàbí ‘Mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè dáàbò bo àyíká wa?’ Ǹjẹ́ a ti ní irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ rí?”
Adájọ́ Scalia wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mi ò rò pé wọ́n gbé irú ẹjọ́ tó jọ bẹ́ẹ̀ wá láti ohun tó lé ní igba ọdún sẹ́yìn.” Èyí mú kí Adájọ́ Àgbà, Rehnquist dápàárá pé: “O ò tíì dáyé ní gbogbo ìgbà yẹn kẹ̀.” Ni gbogbo àwọn tó wà nínú ilé ẹjọ́ náà bá kú sẹ́rìn-ín. Adájọ́ Scalia ò dákẹ́ o, àmọ́ ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ohun tuntun gbáà lèyí jẹ́ sí mi.”
Ṣé Èrò Yẹn Bọ́gbọ́n Mu?
Adájọ́ Anthony M. Kennedy ni tiẹ̀ béèrè ìbéèrè kan tó sojú abẹ níkòó, o sọ pé: “Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí n kọ́kọ́ lọ gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ Ìjọba kí n tó lè lọ sí ilé kan ládùúgbò mi, níbi tí mi ò ti mọ gbogbo ẹni tó ń gbébẹ̀, kí n [sì] sọ pé, Mo fẹ́ bá ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń gbé níbí yìí sọ̀rọ̀ nípa gbígbé àwọn pàǹtírí tẹ́ ẹ dá jọ, tàbí pé, mo fẹ́ bá yín sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin wa, tàbí irú ohun kan tó jọ bẹ́ẹ̀? Ṣé mo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ sọ fún Ìjọba kí n tó lè ṣe ìyẹn ni?” Ó wá fi kún un pé, “Ìyàlẹ́nu gbáà lèyí jẹ́ sí mi.”
Lẹ́yìn èyí ni Adájọ́ Sandra Day O’Connor dá sí ìjiyàn náà, ó béèrè pé: “Ó dáa, àwọn ọmọ tó máa ń lọ sílé àwọn èèyàn lásìkò ọdún láti lọ tọrọ nǹkan ńkọ́? Ṣé wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ gba àṣẹ?” Adájọ́ O’Connor àti Adájọ́ Scalia tún ń bá àlàyé wọn lọ lórí kókó yìí. Adájọ́ O’Connor bá tún gba ibòmíràn yọ, ó sọ pé: “Ká sọ pé èèyàn fẹ́ lọ yá ṣúgà kọ́ọ̀bù kan lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀ ńkọ́? Ṣé mo ní láti lọ gba àṣẹ kí n tó lè lọ yá ṣúgà kọ́ọ̀bù kan lọ́wọ́ aládùúgbò mi?”
Ṣé Ẹni Tó Ń Wá Ìtìlẹyìn Àwọn Èèyàn Kiri Làwọn Ẹlẹ́rìí Ni?
Adájọ́ David H. Souter béèrè pé: “Kí ló dé tó jẹ́ pé orí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ̀rọ̀ yìí dá lé ná? Ṣé ẹni tó ń lọ bẹ̀bẹ̀ fún ìtìlẹyìn àwọn èèyàn ni wọ́n ni, àbí nǹkan ni wọ́n ń tọrọ kiri, àbí ọjà ni wọ́n ń kiri, àbí ó ní iṣẹ́ tí wọ́n ń lọ ṣe fáwọn èèyàn nílé wọn ni? Wọn kì í ṣe ọ̀kankan lára èyí, àbí?” Lọ́yà tó ń ṣojú Abúlé Stratton náà wá ka púpọ̀ lára ohun tí òfin náà sọ, ó sì wá fi kún un pé ilé ẹjọ́ kékeré ti sọ pé ẹni tó ń wá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn kiri làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí ló mú kí Adájọ́ Souter dá a lóhùn pé: “A jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtumọ̀ lo ní fún lílọ wá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn kiri, tó o bá ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”
Adájọ́ Breyer bá ka ìtumọ̀ tó wà fún lílọ wá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn jáde látinú ìwé atúmọ̀ èdè láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà kò bá àwọn Ẹlẹ́rìí mu. Ó tún fi kún un pé: “Mi ò tíì rí nǹkan kan nínú ìwé ẹjọ́ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ síbí tó ṣàlàyé ète tẹ́ ẹ fi ṣòfin pé kí àwọn èèyàn yìí [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] máa lọ sí gbọ̀ngàn ìlú láti lọ forúkọ sílẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé kì í ṣe pé torí owó ni wọ́n ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, tí kì í ṣe torí àtilọ tajà, tí kì í sì ṣe pé wọ́n ń lọ polongo ìbò. Kí nìdí tí ìlú náà fi ṣòfin yìí gan-an ná?”
Ìyẹn Ni Pé “Àǹfààní” Ló Jẹ́ Láti Báni Sọ̀rọ̀
Lọ́yà Abúlé náà wá sọ pé, “ìdí tí ìlú yìí fi ṣe òfin náà ni pé wọn ò fẹ́ ohun tó máa fa ìbínú àwọn onílé.” Ó tún ṣàlàyé síwájú sí i pé, wọ́n ṣòfin náà torí àtilè dáàbò bo àwọn tó ń gbébẹ̀ lọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀ àtàwọn ọ̀daràn. Adájọ́ Scalia fa ọ̀rọ̀ kan yọ nínú òfin náà láti fi hàn pé baálẹ̀ náà tún lè béèrè ìsọfúnni síwájú sí i lẹ́nu ẹni tó wá forúkọ sílẹ̀ náà àti ète tó fi wá, kó bàa lè “ṣeé ṣe láti mọ ohun tó fẹ́ lo àǹfààní náà fún.” Ó wá là á mọ́lẹ̀ pé: “Ìyẹn ni pé, níbàámu
pẹ̀lú òfin yín, àǹfààní lẹ̀yín kà á sí fún ẹnì kan láti lọ bá aráàlú ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan—èmi ò tiẹ̀ rò pé ìyẹn bọ́gbọ́n mu rárá.”Adájọ́ Scalia tún béèrè pé: “Ṣé pé gbogbo ẹni tó bá fẹ́ tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé kan gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ tẹ̀ka ní ọ́fíìsì ìjọba [kó] tó ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé ìbẹ̀rù pé kí ìwà ọ̀daràn má ṣẹlẹ̀ tó ohun téèyàn á fi sọ pé kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé kan lọ máa forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò tóyẹn.”
Ṣé Lóòótọ́ Ni Òfin Yẹn Dáàbò Bo Àwọn Aráàlú?
Nígbà tí ogún ìṣẹ́jú tí wọ́n fún agbẹjọ́rò Abúlé náà láti sọ̀rọ̀ pé, ó fa ọ̀rọ̀ lé amòfin àgbà fún ìpínlẹ̀ Ohio lọ́wọ́. Amòfin àgbà náà sọ pé, òfin máà-lọ-tọrọ-nǹkan-nílé-èèyàn yìí dáàbò bo àwọn ará abúlé náà lọ́wọ́ ìbẹ̀wò àwọn àjèjì, “dájúdájú, àjèjì ni èèyàn kan tí mi ò ké sí, [ẹni] tó wá sí ilé mi . . . látàrí èyí, mo rò pé abúlé náà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé, ‘Irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ kò fi wá lọ́kàn balẹ̀.’”
Adájọ́ Scalia wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Ìyẹn ni pé ohun tí abúlé náà ń sọ ni pé, ká tiẹ̀ ní àwọn èèyàn tí wọ́n á fẹ́ tẹ́wọ́ gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wà nínú ilé wọn láìrẹ́ni bá sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì fẹ́ kẹ́nì kan wá bá àwọn sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun, síbẹ̀, dandan ni kí àwọn èèyàn yìí [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] lọ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ baálẹ̀ kí wọ́n tó lè ní àǹfààní láti lọ tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.”
“Ìkálọ́wọ́kò Yẹn Kò Le Jù Rárá”
Láàárín àkókò tí àríyànjiyàn yẹn ń lọ lọ́wọ́, Adájọ́ Scalia, sọ kókó kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó sọ pé: “Gbogbo wa la gbà pé àwọn àgbègbè tó bọ́ lọ́wọ́ ewu jù lọ láyé làwọn ibi tí ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ ti ń ṣàkóso. Ìwà ọ̀daràn kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nírú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ bẹ́ẹ̀, àti pé, lára àwọn ìṣòro tí òmìnira máa ń dá sílẹ̀, dé ìwọ̀n àyè kan, ni ìwàkiwà tó máa ń pọ̀ gan-an. Kókó tó wá wà níbẹ̀ ni pé, bóyá ìwà ọ̀daràn tí òfin yìí máa jẹ́ kó dín kù tó nǹkan téèyàn ń lọ fọwọ́ síwèé kó tó lè ní àǹfààní láti tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé ẹnì kan.” Amòfin àgbà dá a lóhùn pé “ìkálọ́wọ́kò yẹn kò le jù rárá.” Bẹ́ẹ̀ ni Adájọ́ Scalia fèsì padà pé, kò le jù rárá lóòótọ́, ìyẹn náà “la ò fi rí ẹyọ ẹjọ́ kan ṣoṣo tí wọ́n tíì gbé wá síbí tó fi hàn pé ìjọba ìbílẹ̀ kan ṣe irú òfin bẹ́ẹ̀ jáde rí. Èmi ò gbà pé ìkálọ́wọ́kò yẹn kò le jù rárá.”
Níkẹyìn, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn adájọ́ náà tún sọ irú ohun kan náà, ni amòfin àgbà bá juwọ́ sílẹ̀, ó sì sọ pé: “Mi ò jẹ́ fara mọ́ ọn pé kí ẹnì kan ṣe òfin tó máa sọ pé àwọn èèyàn kò gbọ́dọ̀ lọ tẹ aago ẹnu ọ̀nà tàbí kan ilẹ̀kùn ilé ẹlòmíràn.” Gbólóhùn tó sọ yìí ló fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Nígbà tí agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí ń ta ko ohun tí agbẹjọ́rò Abúlé Stratton náà sọ, ó sọ pé, òfin náà kò ní ohun tí wọ́n lè fi mọ̀ bóyá ohun tẹ́nì kan pe ara rẹ̀ ló jẹ́ lóòótọ́. Ó ní: “Mo lè lọ sí ọ́fíìsì àwọn aláṣẹ abúlé náà kí n sì sọ pé, ‘Orúkọ mi ni [báyìí-báyìí],’ kí wọ́n sì fún mi láṣẹ láti máa lọ láti ojúlé dé ojúlé.” Ó tún sọ pé baálẹ̀ náà lágbára láti kọ̀ láti fún ẹni tó bá sọ pé òun kì í ṣe ara ẹgbẹ́ kan ní ìyọ̀ǹda. Ó wá sọ pé: “A gbà pé èyí kò yàtọ̀ sí lílo agbára tó wà ní ìkáwọ́ ẹni láti pinnu ohun téèyàn fẹ́ fún ẹlòmíràn,” ó sì fi kún un pé: “Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni mo fi sọ pé, iṣẹ́ àwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà] bá ohun tí Àtúnṣe Òfin Kìíní sọ mú dáadáa.”
Kété lẹ́yìn èyí, Adájọ́ Àgbà Rehnquist fòpin sí atótónu àwọn agbẹjọ́rò náà, ó sì sọ pé: “Ọwọ́ [Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ] ni ẹjọ́ náà kù sí.” Gbogbo àkókò tí àríyànjiyàn náà gbà kò ju wákàtí kan ó lé díẹ̀ lọ. Àmọ́, ìdájọ́ tí wọ́n kéde rẹ̀ lóṣù June ló máa fi bí wákàtí kan yẹn ṣe ṣe pàtàkì tó hàn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Adájọ́ Àgbà Rehnquist
Adájọ́ Breyer
Adájọ́ Scalia
[Àwọn Credit Line]
Rehnquist: Collection, The Supreme Court Historical Society/Dane Penland; Breyer: Collection, The Supreme Court Historical Society/Richard Strauss; Scalia: Collection, The Supreme Court Historical Society/Joseph Lavenburg
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Adájọ́ Kennedy
Adájọ́ O’Connor
Adájọ́ Souter
[Àwọn Credit Line]
Kennedy: Collection, The Supreme Court Historical Society/Robin Reid; O’Connor: Collection, The Supreme Court Historical Society/Richard Strauss; Souter: Collection, The Supreme Court Historical Society/Joseph Bailey
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Inú yàrá ilé ẹjọ́ tí wọ́n ti dájọ́ náà
[Credit Line]
Photograph by Franz Jantzen, Collection of the Supreme Court of the United States