Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe?

“Kò síbi tí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ò sí.”—Jesse, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ló sọ bẹ́ẹ̀.

“Fífẹ́ láti ṣe ohun táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ mi ń ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó nira jù lọ tí mo ní láti kojú bí mo ṣe ń dàgbà.”—Johnathan, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ló sọ bẹ́ẹ̀.

DÁJÚDÁJÚ, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe jẹ́ ohun tó yẹ kéèyàn ronú lé lórí dáadáa. Àmọ́, jẹ́ kó dá ọ lójú pé, o dènà rẹ̀. Àní, o lè darí rẹ̀, kó o sì tún jẹ́ kó ṣe ọ́ láǹfààní pàápàá. Ṣùgbọ́n, báwo lo ṣe lè ṣe èyí?

Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú lórí kókó yìí, a jíròrò ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé: Mọ̀ pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lágbára, àti pé ó lè nípa lórí ìwọ fúnra rẹ. a Àwọn ìgbésẹ̀ dáradára wo lo tún lè gbé láfikún sí i? Ìtọ́sọ́nà tó o nílò wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òwe 24:5 sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ . . . ń mú kí agbára túbọ̀ pọ̀ sí i.” Ìmọ̀ wo ló lè túbọ̀ fún ọ lágbára láti kojú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ìṣòro kan tó lè mú kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lo agbára lórí rẹ.

Àìdára-Ẹni-Lójú Léwu

Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rí i pé, nígbà míì, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe jẹ́ ìṣòro ńlá kan fún wọn nítorí pé wíwàásù nípa ìgbàgbọ́ wọn fún àwọn ẹlòmíràn pọn dandan nínú ìgbésí ayé wọn. (Mátíù 28:19, 20) Ǹjẹ́ o máa ń rí i pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń ṣòro fún ọ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tó o bá pàdé? Kì í ṣe ìwọ nìkan lèyí ń ṣẹlẹ̀ sí o. Ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún kan tó ń jẹ́ Melanie sọ pé: “Tó bá di pé kí n sọ fún àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ mi pé Ẹlẹ́rìí ni mí, ó máa ń nira ju bí mo ṣe rò lọ.” Ó fi kún un pé: “Bí mo bá ti pinnu lọ́kàn mi tán báyìí láti sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí ni mí, ńṣe ni màá tún di ojo padà.” Ó jọ pé, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè pani lára ló ń fà á sẹ́yìn tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Bíbélì mú un dá wa lójú pé kódà àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ títayọ pàápàá ti lọ́ tìkọ̀ láti sọ nípa Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Jeremáyà ọ̀dọ́ mọ̀ pé òún á dojú kọ ìfiṣẹ̀sín àti inúnibíni bí òún bá ṣègbọràn sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé kí òun wàásù láìṣojo. Yàtọ̀ síyẹn, Jeremáyà kò dá ara rẹ̀ lójú. Kí nìdí? Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” Ǹjẹ́ Ọlọ́run gbà pé jíjẹ́ tí Jeremáyà jẹ́ ọ̀dọ́ ni kò jẹ́ kó tóótun láti sọ̀rọ̀? Rárá o. Jèhófà fi wòlíì náà lọ́kàn balẹ̀ pé: “Má ṣe wí pé, ‘ọmọdé lásán ni mí.’” Jèhófà kò fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, dípò ìyẹn ńṣe ló gbé iṣẹ́ pàtàkì tó fẹ́ rán ọ̀dọ́kùnrin tó ń lọ́ tìkọ̀ náà lé e lọ́wọ́.—Jeremáyà 1:6, 7.

Bí a ò bá dá ara wa lójú, tí à ń rò pé a kò tóótun, ó lè ṣòro gan-an fún wa láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Àwọn ìwádìí táwọn ògbógi ṣe fi hàn pé lóòótọ́ ni èyí máa ń ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn—ìyẹn lọ́dún 1937, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ Muzafer Sherif ṣe àṣeyẹ̀wò kan tó gbajúmọ̀. Ó ní káwọn èèyàn dúró sínú iyàrá kan tó ṣókùnkùn, ó wá mú kí ìtànṣán iná kan tàn nínú iyàrá náà lójú wọn, lẹ́yìn náà ló wá béèrè lọ́wọ́ wọn bí ìtànṣán iná náà ṣe rìn jìnnà tó.

Ní ti gidi, ìtànṣán iná náà kò kúrò lójú kan rárá; ńṣe ló kàn rí bẹ́ẹ̀ lójú. Nígbà tó dán àwọn èèyàn náà wò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sọ ohun tó wá látọkàn kálukú wọn nípa ìtànṣán iná tó hàn gbangba pé kò kúrò lójú kan yìí. Àmọ́, nígbà tí wọ́n wà ní àwùjọ-àwùjọ, ó ní kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n rò sókè ketekete. Kí ló ṣẹlẹ̀? Nítorí pé wọn kò dá ara wọn lójú nípa ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ òtítọ́, àwùjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí ara wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe àṣeyẹ̀wò náà fún wọn léraléra, ìdáhùn wọn bẹ̀rẹ̀ sí dọ́gba títí tí gbogbo wọn fi ní “ojú ìwòye kan náà.” Kódà nígbà tí wọ́n tún dán kálukú wọn wò lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan ṣì ń jẹ́ kí ohun tí gbogbo àwùjọ náà lápapọ̀ sọ darí àwọn.

Àṣeyẹ̀wò yẹn fi kókó pàtàkì kan hàn. Àìdára-ẹni-lójú máa ń jẹ́ káwọn èèyàn tètè juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Ọ̀rọ̀ yìí gbàrònú gidi, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó ṣe tán, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè nípa lórí àwọn èèyàn nínú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì gan-an pàápàá, irú bí ojú tí wọ́n fi ń wo ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, lílo oògùn olóró, àti ohun tí wọ́n fẹ́ lépa nínú ìgbésí ayé wọn. Bá a bá jẹ́ kí ‘ojú ìwòye àwùjọ’ nípa lórí wa nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, a lè fúnra wa ṣàkóbá fún ọjọ́ iwájú wa. (Ẹ́kísódù 23:2) Kí la lè ṣe?

Tóò, báwo lo ṣe rò pé wàá ṣe dáhùn ìbéèrè inú àṣeyẹ̀wò yẹn ná bó o bá mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìtànṣán iná kò kúrò lójú kan? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, o kò ní jẹ́ kí àwùjọ náà nípa lórí rẹ. Dájúdájú, a ní láti dá ara wa lójú, ká sì ní ìgbọ́kànlé nínú ara wa. Ṣùgbọ́n, irú ìdára-ẹni-lójú wo la nílò, báwo la sì ṣe lè ní in?

Fi Jèhófà Ṣe Ìgbọ́kànlé Rẹ

O lè máa gbọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ nípa dídá ara ẹni lójú, tàbí níní ìgbọ́kànlé nínú ara ẹni. Àmọ́ bó bá wá di pé kí ìwọ fúnra rẹ ní in—àti bó ṣe yẹ kó o dá ara rẹ lójú tó—èrò oríṣiríṣi ló máa wá sí ọ lọ́kàn. Ìmọ̀ràn kan tó wà déédéé wà nínú Bíbélì, ìyẹn ni pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.” (Róòmù 12:3) Nínú ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn, ẹsẹ yìí kà pé: “Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù yín láti má ṣe fojú díwọ̀n ara rẹ̀ ju bó ti jẹ́ gan-an ní tòótọ́ lọ, àmọ́ kí ó ṣe ìdíyelé ara rẹ̀ pẹ̀lú ìrònújinlẹ̀.”—Charles B. Williams.

‘Fífi ìrònújinlẹ̀ díye lé ara rẹ’ láti mọ ‘bó o ṣe jẹ́ gan-an ní tòótọ́’ kì yóò jẹ́ kó o di ajọra-ẹni-lójú tàbí kó o jẹ́ agbéraga. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, irú ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o ní ìdánilójú nínú agbára tó o ní láti máa fúnra rẹ ronú jinlẹ̀ àti láti máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ẹlẹ́dàá rẹ ti fún ọ ní “agbára ìmọnúúrò,” èyí tó jẹ́ ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye kan. (Róòmù 12:1) Fífi èyí sọ́kàn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dènà jíjẹ́ kí àwọn tó wà nítòsí rẹ máa ṣèpinnu fún ọ. Àmọ́ ṣá o, irú ìdára-ẹni-lójú kan wà tó máa ṣèrànwọ́ gan-an láti dáàbò bò ọ́.

Ọlọ́run mí sí Dáfídì Ọba láti kọ̀wé pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá.” (Sáàmù 71:5) Dájúdájú, Dáfídì ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Baba rẹ̀ ọ̀run, àtìgbà tó sì ti wà ní ọ̀dọ́ ló ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ bọ̀. “Ọmọdékùnrin lásán-làsàn” ni—ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọ̀dọ́langba—nígbà tí òmìrán ilẹ̀ Filísínì tó ń jẹ́ Gòláyátì sọ pe kí ọmọ ogun Ísírẹ́lì èyíkéyìí tó bá tó bẹ́ẹ̀ wá bá òun fìjà pẹẹ́ta. Ìpeniníjà yìí da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ọmọ ogun náà. (1 Sámúẹ́lì 17:11, 33) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ló mú kí gbogbo wọn máa rò pé àwọn ò lè kojú òmìrán náà láé. Kò sí àní-àní pé, ńṣe ni wọ́n á máa fi ìbẹ̀rùbojo sọ bí Gòláyátì ṣe ṣe gìrìwò tó àti bó ṣe jẹ́ alágbára tó, tí wọ́n á sì máa sọ pé àfi wèrè èèyàn nìkan ló lè gbà láti lọ bá a jà lóun nìkan. Dáfídì kò jẹ́ kí irú ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́-ń-ṣe bẹ́ẹ̀ mú òun láyà pami rárá. Kí nìdí?

Wo ohun tí Dáfídì sọ fún Gòláyátì: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá.” (1 Sámúẹ́lì 17:45) Kì í ṣe pé Dáfídì kò mọ bí Gòláyátì ṣe tóbi fìrìgbọ̀n tó, bó ṣe lágbára tó, tàbí bí gbogbo nǹkan ìjà tó kó mọ́ra ṣe pọ̀ tó. Ṣùgbọ́n ó mọ ohun kan, ohun náà sì dá a lójú dáadáa. Ìyẹn ni pé, Gòláyátì kò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Bí Jèhófà bá wà pẹ̀lú Dáfídì, kí ló máa wá mú kó bẹ̀rù Gòláyátì? Ìgbọ́kànlé tí Dáfídì ní nínú Ọlọ́run ló fi í lọ́kàn balẹ̀. Kò sí bí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ọ̀hún ṣe lè lágbára tó tí yóò mú kí Dáfídì mikàn.

Ǹjẹ́ ìwọ náà ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà? Kò tíì yí padà látìgbà ayé Dáfídì. (Málákì 3:6; Jákọ́bù 1:17) Bó o bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tó ni wàá ṣe máa rí i pé òótọ́ ni gbogbo ohun tó sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Jòhánù 17:17) Níbẹ̀, wàá rí àwọn ìlànà tí kì í yí padà, tó sì ṣeé gbára lé, èyí tó lè ṣamọ̀nà rẹ nínú ìgbésí ayé, tó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Láfikún sí fífi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé rẹ, ohun kan ṣì wà tó o lè ṣe.

Yan Àwọn Agbaninímọ̀ràn Rere

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti wá ìtọ́sọ́nà rere. Òwe 1:5 sọ pé: “Ẹni òye . . . ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” Àwọn òbí rẹ, tí wọ́n fẹ́ pé kó dára fún ọ, lè jẹ́ orísun ìtọ́sọ́nà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Indira mọ̀ pé òótọ́ lèyí. Ó sọ pé: “Bí àwọn òbí mi ṣe máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti fi bá mi fọ̀rọ̀ wérọ̀ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì tún mú kí Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí mi nínú ìgbésí ayé mi, ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́ nísinsìnyí.” Ohun tó jẹ́ èrò ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ náà nìyẹn.

Bó o bá wà nínú ìjọ Kristẹni, o ní orísun ìtìlẹyìn kan níbẹ̀—ìyẹn ni àwọn alábòójútó tí a yàn sípò, tàbí àwọn alàgbà, àtàwọn Kristẹni mìíràn tó dàgbà dénú. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Nadia sọ pé: “Mo mọrírì àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ mi gidigidi. Mo rántí àsọyé kan tí alábòójútó olùṣalága sọ, èyí tó dá lórí ọ̀rọ̀ àwa ọ̀dọ́. Lẹ́yìn ìpàdé, inú èmi àti ọ̀rẹ́ mi dùn gan-an nítorí pé ìṣòro tí à ń dojú kọ gan-an ló sọ̀rọ̀ lé lórí.”

Ohun mìíràn tó o lè fi gbéjà ko ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè pani lára ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè gbéni ró. Bó o bá fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa lépa àwọn ohun tó bójú mu àti láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà títọ́. Báwo la ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ rere? Máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Nadia fara balẹ̀ yan àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ilé ẹ̀kọ́—ìyẹn àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere kan náà. Ó sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin ilé ẹ̀kọ́ wa bá sọ pé àwọ́n fẹ́ bá wa ‘sọ̀rọ̀,’ ńṣe làwa akẹ́kọ̀ọ́ tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń ṣètìlẹ́yìn fún ara wa.” Àwọn ọ̀rẹ́ rere lè sún wa láti fi àwọn ànímọ́ wa tó dára gan-an hàn. Wọ́n yẹ lẹ́ni téèyàn ń sapá láti wá rí.

Nítorí náà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé, bó o bá fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé rẹ, tó o wá ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú, tó o sì fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, yóò lè ṣeé ṣe fún ọ láti kojú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Àní sẹ́, o lè ni ipa tí ń gbéni ró lórí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kó o sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ kí gbogbo yín lè jọ máa rìn ní ọ̀nà ìyè láìyẹsẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bẹ́ẹ̀ Lẹ̀míi Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Lágbára Tó Ni?”, èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti December 8, 2002.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]

Wá àwọn ọ̀rẹ́ rere, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ bíi tìrẹ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

“Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33

“Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20