Bí Ojú Ẹyẹ Idì Ṣe Lágbára Tó
Bí Ojú Ẹyẹ Idì Ṣe Lágbára Tó
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ
ÀWỌN ará Sípéènì máa ń sọ pé onílàákàyè èèyàn ní ojú idì (vista de águila). Àwọn ará ilẹ̀ Jámánì náà ní gbólóhùn kan tó jọ ọ́ (Adlerauge). Ó nídìí tó fi jẹ́ pé láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún làwọn èèyàn ti ń lo ojú idì tó máa ń ríran kedere láti fi ṣe àfiwé ọ̀rọ̀. Ìwé Jóòbù, èyí tí a kọ ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, sọ nípa ẹyẹ idì pé: “Ojú rẹ̀ ń wo ọ̀nà jíjìn.”—Jóòbù 39:27, 29.
Báwo ni idì ṣe lè ríran jìnnà tó? Ìwé The Guinness Book of Animal Records sọ pé: “Àwọn ẹyẹ idì aláwọ̀ wúrà (Aquila chrysaetos) lè rí bí ehoro kan ṣe sún kẹ́rẹ́ kúrò níbi tó wà láti ohun tó lé ní kìlómítà méjì síbi tí wọ́n wà.” Àwọn kan ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé idì lè rí ohun tó wà ní ibi tó tiẹ̀ tún jìnnà ju ìyẹn lọ!
Kí ló mú kí ojú idì lágbára tó bẹ́ẹ̀ yẹn? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, idì aláwọ̀ wúrà ní ojú ńlá méjì, èyí tó gba àyè tó fẹ̀ gan-an ní orí rẹ̀. Ìwé Book of British Birds sọ pé, ní ti idì aláwọ̀ wúrà, àwọn ojú rẹ̀ méjèèjì “tóbi gan-an, àmọ́ wọn ò dí i lọ́wọ́ láti fò.”
Láfikún sí i, àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gba ìmọ́lẹ̀ wọlé sínú ojú idì fi nǹkan bí ìlọ́po márùn-ún pọ̀ ju tí èèyàn lọ—ìyẹn ni pé, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan sẹ́ẹ̀lì tó ń gba ìmọ́lẹ̀ títàn yòò sára ló wà nínú ojú idì ní ìfiwéra pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] tí àwa ẹ̀dá èèyàn ní. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gba ìmọ́lẹ̀ wọlé sínú ojú wọ̀nyí ló ń bá iṣan inú ọpọlọ kan ṣiṣẹ́. Látàrí èyí, àwọn fọ́nrán iṣan ojú tó ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ọpọlọ ti ẹyẹ idì fi ìlọ́po méjì ju ti èèyàn lọ. Abájọ tí kò fi yani lẹ́nu pé, àwọn ẹyẹ wọ̀nyí máa ń rí àwọ̀ dáadáa! Níkẹyìn, bíi tàwọn ẹyẹ mìíràn, ojú àwọn ẹyẹ apẹranjẹ ní awò amú-nǹkan-di-ńlá kan tó lágbára, èyí tó lè yára yí kúrò látọ̀dọ̀ ohun kan tó wà nítòsí sí ohun mìíràn tó wà ní ọ̀nà jíjìn ní ìṣẹ́jú àáyá. Ojú tiwọn tún lágbára ju tiwa lọ lọ́nà yìí pẹ̀lú.
Ojú idì máa ń ríran kedere lọ́sàn-án, àmọ́ tó bá di alẹ́, ojú òwìwí ta tiẹ̀ yọ. Àwọn ẹyẹ apẹranjẹ tó máa ń fi òru jẹ̀ wọ̀nyí ní ọ̀pọ̀ sẹ́ẹ̀lì tó ń gba ìmọ́lẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ tàn yòò wọlé sínú ojú, wọ́n sì tún ní awò amú-nǹkan-di-ńlá títóbi kan lójú wọn. Látàrí èyí, wọ́n lè ríran kedere lálẹ́ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún ju ti èèyàn lọ. Àmọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí òkùnkùn biribiri bá bolẹ̀, bí àwọn ẹyẹ òwìwí ṣe máa ń gbọ́ràn lọ́nà tó mú hánhán ni wọ́n gbára lé jù láti mọ ibi tí ẹran tí wọ́n fẹ́ pa jẹ wà.
Ta ló fún àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ní àwọn ànímọ́ yìí? Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ Jóòbù pé: “Ṣé nípa àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni idì fi ń fò lọ síhà òkè?” Ó ṣe kedere pé kò sí èèyàn èyíkéyìí tó lè sọ pé iṣẹ́ ọwọ́ òun ni ẹ̀dá àgbàyanu yìí. Jóòbù fúnra rẹ̀ fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé [Jèhófà] lè ṣe ohun gbogbo.” (Jóòbù 39:27; 42:1, 2) Ojú idì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń jẹ́rìí sí ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa ni.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Idì aláwọ̀ wúrà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Òwìwí tó ń gbé àgbègbè oníyìnyín