Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Dáàbò Bo Oyún Rẹ

Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Dáàbò Bo Oyún Rẹ

Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Dáàbò Bo Oyún Rẹ

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ

GẸ́GẸ́ bí ohun tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Iye Ènìyàn sọ, lọ́dọọdún, ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù àwọn obìnrin tó ń kú nígbà tí wọ́n lóyún. Láfikún sí i, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ròyìn pé, lọ́dọọdún, ó ju ọgọ́ta mílíọ̀nù àwọn obìnrin lọ tí wọ́n máa ń ní ìṣòro líle koko nínú oyún. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máa ń tó ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn wọ̀nyí tí ìṣòro náà máa ń ṣàkóbá tó máa wà títí lọ fún tàbí kí wọ́n kó àrùn tí wọ́n á máa bá yí títí ọjọ́ ayé wọn nípasẹ̀ rẹ̀. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọ̀pọ̀ obìnrin ló jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń bímọ kan ni wọ́n tún ń lóyún òmíràn láìsí àbójútó tó yẹ́. Èyí kì í jẹ́ kí wọ́n ní ìmí nínú, wọ́n sì máa ń ṣàìsàn. Bẹ́ẹ̀ ni, oyún níní léwu—kódà ó lè gbẹ̀mí ẹni. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí obìnrin kan lè ṣe láti dín ewu ìgbà ìlóyún kù?

Ìtọ́jú Ṣáájú Ìlóyún

Àjọrò. Ó dára kí tọkọtaya kọ́kọ́ jókòó láti jíròrò iye ọmọ tí wọ́n máa bí. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kì í ṣe ohun àjèjì láti rí àwọn obìnrin tí wọ́n ṣì ń tọ́ ọmọ kékeré lọ́wọ́ síbẹ̀ tí oyún òmíràn ti wà níkùn wọn. Àjọrò tọkọtaya àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò tí ọkọ ní á jẹ́ kí wọ́n lè fi àyè tí ó tó sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bí ọmọ kan kí wọ́n tó lóyún òmíràn lé e. Èyí á jẹ́ kí obìnrin náà lè ní ìsinmi tí ó tó, á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti lókun nínú dáadáa lẹ́yìn tó bá bímọ kan tán.

Oúnjẹ aṣaralóore. Níbàámu pẹ̀lú ìsọfúnni kan látọ̀dọ̀ Àwùjọ Àwọn Ẹgbẹ́ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Aláboyún, wọ́n sọ pé kí obìnrin kan tó lóyún, ó yẹ kó fi oṣù mẹ́rin ó kéré tán sílẹ̀, láti mú kí àwọn nǹkan eléwu bí oríṣiríṣi oògùn tó ti lò, sìgá, ọtí líle àtàwọn nǹkan tó ní èròjà kaféènì nínú bíi kọfí àti obì tó ti jẹ, pa rẹ́ kúrò nínú àgọ́ ara rẹ̀, kó sì ti máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore nítorí ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lóyún rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ewu kí ògóóró ẹ̀yìn là (spina bifida), èyí tó máa ń wáyé nígbà tí egungun ẹ̀yìn kò bá dí dáadáa, máa ń dín kù jọjọ tí aláboyún kan bá ní èròjà folic acid tó pọ̀ tó nínú ara. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́rin tí obìnrin bá lóyún ni egungun ẹ̀yìn ọmọ inú ti máa ń pa dé—kí ọ̀pọ̀ tiẹ̀ tó mọ̀ rárá pé àwọ́n fẹ́ra kù—àwọn obìnrin kan tí wọ́n mọ̀ pé àwọ́n fẹ́ẹ́ lóyún máa ń lo àwọn egbòogi tó ní èròjà folic acid nínú.

Nǹkan aṣaralóore mìíràn tó tún ṣe kókó ni èròjà iron. Ní ti gidi, ìlọ́po méjì ni èròjà iron tí ara obìnrin kan nílò nígbà tó bá lóyún. Bí èròjà yìí kò bá tó nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà—ó lè yọrí sí àìsàn. Ìṣòro yìí á tún le koko sí i bí obìnrin náà bá ń lóyún léraléra, níwọ̀n bí àkókò tó ń fi sílẹ̀ kó tó ní oyún mìíràn ti kéré jù láti mú kí ara rẹ̀ ní èròjà iron tó pọ̀ tó. a

Ọjọ́ orí. Ewu ikú àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n lóyún kí wọ́n tó pé ọdún mẹ́rìndínlógún fi ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ju ti àwọn tó ti lé lọ́mọ ogún ọdún lọ. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó rọrùn gan-an fún àwọn obìnrin tó ti lé lẹ́ni ọdún márùndínlógójì láti bí àwọn ọmọ tó ní àrùn Down’s syndrome (ìyẹn ni àwọn dìndìnrìn ọmọ). Àwọn ìyá tó kéré gan-an lọ́jọ́ orí tàbí àwọn tó ti dàgbà kọjá ọjọ́ orí ọmọ bíbí sábà máa ń ní ìṣòro kan tó ń jẹ́ preeclampsia, èyí tó máa ń yọjú bí àkókò ìbímọ bá ti ń tó. Àìsàn yìí, tó máa ń fara hàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ̀ ríru tí oyún bá ti wọ oṣù márùn-ún, pa pọ̀ pẹ̀lú kí ara máa wú gùdùgbẹ̀ àti kí àpọ̀jù èròjà protein wà nínú ìtọ̀, máa ń mú kí ewu ikú ìyá àti ti ọmọ pọ̀ sí i.

Àkóràn. Àkóràn nínú àpò ìtọ̀, ní ojú ara, àti nínú ìfun lè burú sí i lákòókò tí obìnrin bá lóyún, èyí sì lè mú kí ewu bíbí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé tàbí níní àrùn preeclampsia pọ̀ sí i. Ó dára gan-an láti kọ́kọ́ wo àkóràn èyíkéyìí tó lè wà nínú ara sàn ṣáájú kéèyàn tó lóyún.

Ìtọ́jú Nígbà Oyún

Ìtọ́jú aláboyún. Lílọ rí dókítà déédéé nínú oyún máa ń gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá là. Kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti máa lọ sí ilé ìgbàtọ́jú tàbí ilé ìwòsàn déédéé, àwọn agbẹ̀bí tó mọṣẹ́ dáadáa lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó.

Lílọ fún ìtọ́jú lè jẹ́ kí àwọn olùtọ́jú aláboyún tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ tètè rí àwọn ìṣòro tó lè fi hàn pé aboyún kan máa nílò ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ọmọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló wà níkùn ẹni náà, ó lè ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ọkàn tàbí ti kíndìnrín, àti àrùn àtọ̀gbẹ. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, aláboyún kan lè rí abẹ́rẹ́ àjẹsára gbà láti dáàbò bo ọmọ inú rẹ̀ lọ́wọ́ àrùn ipá. Nígbà tí oyún rẹ̀ bá wọ oṣù mẹ́fà ààbọ̀ sí méje, wọ́n tún lè yẹ̀ ẹ́ wò bóyá ó ní àrùn tó ń jẹ́ streptococcus, èyí tó máa ń ba sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ jẹ́. Tí àrùn yìí bá lọ wà nínú ìfun ìyá náà, ó lè ran ọmọ nígbà ìbí.

Aboyún náà tún gbọ́dọ̀ múra tán láti sọ gbogbo ohun tó bá lè sọ fún àwọn olùtọ́jú, títí kan bí ìlera rẹ̀ ṣe máa ń rí látẹ̀yìnwá. Ó tún gbọ́dọ̀ máa béèrè ìbéèrè fàlàlà lọ́wọ́ àwọn olùtọ́jú. Ó ní láti lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera láìjáfara bó bá rí i tí ẹ̀jẹ̀ ń jáde lójú ara rẹ̀, bí ojú rẹ̀ bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í wú, bí orí bá ń fọ́ ọ wàá wàá láìdáwọ́ dúró tàbí tí ọmọ ìka bá ń ro ó ṣáá, tí ojú rẹ̀ sì ń ṣàdédé ṣe bàìbàì, bí ikùn bá ń dùn ún gan-an, bó bá ń bì ṣáá, bí òtútù bá ń mú un tàbí tí ara rẹ̀ bá ń gbóná kọjá ààlà, bí iye ìgbà tí ọmọ inú rẹ̀ ń yíra padà bá ń dín kù sí i tàbí tó ń ṣe lemọ́lemọ́ sí i, bí omi bá ń dà jáde lójú ara rẹ̀, bó bá ń ní ìrora nígbà tó bá ń tọ̀ tàbí tí kò tọ̀ tó bó ṣe yẹ.

Ọtí líle àti oògùn olóró. Ńṣe ni aláboyún tó bá ń mu ọtí líle tàbí tó ń lo oògùn olóró (títí kan sìgá mímu) túbọ̀ fi ọmọ rẹ̀ sínú ewu yíya dìndìnrìn, níní àbùkù ara, tàbí kó tiẹ̀ máa hùwà lódìlódì. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti fi hàn pé, àwọn ọmọ ọwọ́ tí ìyá wọn jẹ́ ajoògùnyó máa ń ní àwọn àìlera kan tó dà bíi tàwọn tó ń lo oògùn olóró àmọ́ tí wọn ò lò ó mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbà pé kò sóhun tó burú nínú mímu ife wáìnì kan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ògbóǹkangí sábà máa ń dámọ̀ràn pé kí àwọn aláboyún yẹra fún un pátápátá ló dára jù. Àwọn tó lóyún tún gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún wíwà nítòsí àwọn tó ń mu sìgá.

Egbòogi. Aláboyún kò gbọ́dọ̀ lo oògùn kankan àyàfi tó bá jẹ́ dókítà tó mọ̀ nípa oyún náà ló kọ ọ́ fún un tó sì ti gbé àwọn ewu tó lè tìdí rẹ̀ yọ yẹ̀ wò. Àwọn egbòogi kan tó ń ṣàlékún èròjà fítámì pàápàá lè ṣèpalára. Bí àpẹẹrẹ, àpọ̀jù èròjà vitamin A, lè sọ ọmọ inú di aláàbọ̀ ara.

Sísanra jọ̀kọ̀tọ̀. Aláboyún gbọ́dọ̀ yẹra fún dídi ẹni tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Krause’s Food, Nutrition and Diet Therapy ṣe sọ, ewu kí ọmọ tí ìwọ̀n rẹ̀ kéré gan-an kú fi ìgbà ogójì ju ti ọmọ tuntun tí ìwọ̀n rẹ̀ wà déédéé lọ. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí aláboyún bá ń jẹ oúnjẹ èèyàn méjì lẹ́ẹ̀kan, èyí yóò yọrí sí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀. Sísanra lọ́nà tó bójú mu—èyí tó máa ń hàn kedere nígbà tí oyún bá wọ oṣù kẹrin—fi hàn pé aláboyún náà ń jẹun bó ṣe yẹ, èyí tó nílò lásìkò yìí. b

Ìmọ́tótó àtàwọn nǹkan mìíràn tó yẹ fún àgbéyẹ̀wò. Aláboyún lè máa wẹ̀ bó ṣe ń wẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ máa rọ omi ọṣẹ tàbí oògùn sí ojú ara. Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí ẹnikẹ́ni tó bá ní àrùn tó lè ràn, irú bí àrùn rubella, tí a mọ̀ sí èèyi. Síwájú sí i, láti yàgò fún kíkó àìsàn toxoplasmosis, èyí tó máa ń mú kí oyún bà jẹ́ tàbí tó lè ṣàkóbá fún ọmọ inú, ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi fún jíjẹ ẹran tí wọn ò sè jinná dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ibi tí ìgbẹ́ ológbò bá wà. Àwọn ìlànà ìmọ́tótó pàtàkì, irú bíi fífọ ọwọ́ àti fífọ àwọn oúnjẹ téèyàn kì í sè kó tó jẹ wọ́n, ṣe kókó. Níní ìbálòpọ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ léwu àyàfi tí àkókò ìbímọ bá ti ń sún mọ́ tàbí tí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára aláboyún náà, tó ń ní pajápajá, tàbí tí oyún bá ti bà jẹ́ lára rẹ̀ rí.

Bíbí Wẹ́rẹ́

Obìnrin tó bá bójú tó ara rẹ̀ dáadáa nígbà tó wà nínú oyún kò ní fi bẹ́ẹ̀ níṣòro lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀. Ó yẹ kó ti ṣètò ṣáájú, bóyá ilé ló máa bímọ sí àbí ọsibítù. Ó tún yẹ kó mọ̀ nípa àwọn ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí obìnrin bá ń bímọ àti bó ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọ̀jáfáfá agbẹ̀bí tàbí dókítà tó máa gbẹ̀bí fún un. Ẹni yìí náà yóò sì ti gbọ́ látẹnu obìnrin náà ṣáájú nípa ohun tó fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́—bó bá jẹ́ ibi téèyàn ti lè yan ohun tó fẹ́—lórí àwọn kókó bí irú ipò tó fẹ́ wà lásìkò ìbímọ, bóyá kí wọ́n la abẹ́ rẹ̀ láti mú kí ìbímọ náà yá, lílo ẹ̀mú tí wọ́n fi ń fa ọmọ jáde, lílo oògùn apàrora, tàbí lílo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń wo ọmọ nínú ikùn ìyá. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn kókó mìíràn: Ọsibítù wo ni wọ́n máa lọ bí ìṣòro líle koko bá dìde nígbà tó ń bímọ lọ́wọ́ nínú ilé? Kí lohun náà gan-an tí wọ́n máa ṣe bí ẹ̀jẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí dà láìdáwọ́ dúró? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé pípàdánù ẹ̀jẹ̀ ló máa ń fa ikú ọ̀pọ̀ àwọn ìyá tó ń bímọ lọ́wọ́, àwọn àfirọ́pò ẹ̀jẹ̀ gbọ́dọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn aláboyún tí kì í gba ẹ̀jẹ̀. Bákan náà, ìmúrasílẹ̀ ṣáájú ti gbọ́dọ̀ wà nípa ohun tí wọn yóò ṣe bó bá di pé iṣẹ́ abẹ ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi gbé ọmọ náà jáde.

Bíbélì sọ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọmọ jẹ́, ìyẹn ni pé “ogún” ni wọ́n. (Sáàmù 127:3) Bí òye tí obìnrin kan ní nípa oyún rẹ̀ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ṣàṣeyọrí tó nígbà oyún àti nígbà tó bá fẹ́ bímọ. Nípa bíbójútó ara rẹ̀ dáadáa kó tó lóyún àti nígbà tó wà nínú oyún, àti nípa fífarabalẹ̀ ronú ṣáájú nípa oríṣiríṣi ohun tó wé mọ́ ìbímọ yóò fi hàn pé obìnrin kan ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti túbọ̀ dáàbò bo oyún rẹ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ohun tó lè fún ara ní èròjà folic acid àti èròjà iron ni ẹ̀dọ̀ ẹran, onírúurú ẹ̀wà, ewébẹ̀ tí ewé rẹ̀ dúdú dáadáa, onírúurú ẹ̀pà, àtàwọn oúnjẹ oníhóró tí wọ́n fi àwọn oúnjẹ aṣaralóore mìíràn lú. Kí àwọn oúnjẹ tó ní èròjà iron nínú lè ṣiṣẹ́ dáadáa lára, ó dára láti jẹ wọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn nǹkan mìíràn tó ń fún ara ní èròjà vitamin C, irú bí oríṣiríṣi èso.

b Àwọn ògbógi dámọ̀ràn pé kí obìnrin kan tó sanra níwọ̀nba nígbà tó kọ́kọ́ lóyún fi kìlógíráàmù mẹ́sàn-án sí méjìlá sanra sí i nígbà tó bá fi máa tó àkókò ìbímọ. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà àtàwọn obìnrin tí kò jẹun-re-kánú ní láti fi kìlógíráàmù méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sanra sí i, nígbà tí àwọn tó ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀ tẹ́lẹ̀ kò nílò ju kìlógíráàmù méje sí mẹ́sàn-án lọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

ÌMỌ̀RÀN FÚN ÀWỌN ALÁBOYÚN

● Lára àwọn oúnjẹ tó yẹ kí aláboyún máa jẹ lójoojúmọ́ ni èso, ẹ̀fọ́ àti ewébẹ̀ lóríṣiríṣi, onírúurú ẹ̀wà (irú bí ẹ̀wà pupa àti funfun, ẹ̀wà sóyà, lẹ́ńtìlì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ), àwọn oúnjẹ oníhóró (irú bí àlìkámà, ọkà, oats, àti ọkà báálì—wọ́n lè jẹ wọ́n bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n lú àwọn oúnjẹ mìíràn mọ́ wọn), àwọn oúnjẹ tó wá láti ara ẹran (ẹja, ẹran adìyẹ, ẹran màlúù, ẹyin, wàràkàṣì, àti mílíìkì, ó dára kó jẹ́ mílíìkì tí kò ní ọ̀rá nínú). Ohun tó dára jù ni pé kí jíjẹ oúnjẹ tó ní ọ̀rá, ṣúgà àti iyọ̀ mọ níwọ̀nba. Máa mu omi púpọ̀. Yẹra fún àwọn ohun mímu tó ní èròjà caffeine nínú àtàwọn oúnjẹ tí wọ́n ti lú nǹkan tí kì í jẹ́ kí oúnjẹ tètè bà jẹ́ mọ́ tàbí tí wọ́n ti fi àwọn nǹkan amú-oúnjẹ-ta-sánsán sí. Má ṣe jẹ táàṣì tí wọ́n ń fi sí aṣọ, amọ̀, àtàwọn nǹkan mìíràn tí kò wà fún jíjẹ, torí wọ́n lè fa àìsàn àìjẹunre-kánú tàbí kí wọ́n jẹ́ májèlé.

● Ṣọ́ra fún àwọn nǹkan eléwu mìíràn tó lè wà láyìíká, irú bíi wíwà níbi ìtànṣán X-ray tàbí nítòsí àwọn kẹ́míkà tó léwu. Dín bó o ṣe ń lo àwọn nǹkan fínfín àtàwọn kẹ́míkà mìíràn nínú ilé kù. Má ṣe jẹ́ kí ooru máa mú ọ jù nípa dídúró sí ibi tó gbóná gan-an tàbí ṣíṣe eré ìmárale kọjá ààlà. Má ṣe máa wà lórí ìdúró fún àkókò gígùn tàbí kó o máa lo ara rẹ kọjá ààlà. Máa de bẹ́líìtì ọkọ̀ lọ́nà tó bá ipò tí ara rẹ wà mu.