Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ

ỌJỌ́ ÌDÁJỌ́ NÁÀ pé ní June 17, 2002, ìyẹn ọjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbé ìpinnu rẹ̀ jáde. Ìdájọ́ wo ni wọ́n ṣe? Àkọlé àwọn ìwé ìròyìn sọ àbájáde rẹ̀. Ìwé ìròyìn The New York Times kéde pé: “Ilé Ẹjọ́ Mú Òfin Tí Wọ́n Fi De Ìbẹ̀wò Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Ṣe Kúrò.” Ìwé ìròyìn The Columbus Dispatch ti ìpínlẹ̀ Ohio sọ pé: “Ilé Ẹjọ́ Gíga Wọ́gi Lé Òfin Lílọ Gba Ìyọ̀ǹda.” Ìwé ìròyìn The Plain Dealer ti ìlú Cleveland, ìpínlẹ̀ Ohio, wulẹ̀ sọ ní tirẹ̀ pé: “Kò Pọn Dandan Káwọn Tó Ń Lọ Béèrè Nǹkan Nílé Àwọn Èèyàn Gba Ìyọ̀ǹda Ìjọba Ìbílẹ̀.” Àkọlé ìròyìn tó fara hàn lójú ewé tó dojú kọ ti ọ̀rọ̀ olóòtú nínú ìwé ìròyìn USA Today kéde pé: “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ Borí.”

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti wọ́gi lé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré dá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì wáyé látàrí bí àwọn adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án ṣe fọwọ́ sí ìpinnu náà! Adájọ́ John Paul Stevens ló kọ àkọsílẹ̀ olójú ewé méjìdínlógún tí Ilé Ẹjọ́ náà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kà. Ìdájọ́ náà túbọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nílé-lóko pé, Àtúnṣe Òfin Kìíní náà ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lẹ́yìn. Nínú àkọsílẹ̀ náà, Ilé Ẹjọ́ ṣàlàyé pé ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi lọ gba ìyọ̀ǹda náà ni pé, wọ́n ní “inú Ìwé Mímọ́ làwọ́n ti rí àṣẹ láti máa wàásù.” Lẹ́yìn èyí ni àwọn adájọ́ náà wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé tí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ àlàyé wọn sí, èyí tó kà báyìí pé: “Bí a bá ń lọ gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ká tó wàásù, bí ìgbà tí à ń tàbùkù sí Ọlọ́run ló rí.”

Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà kà pé: “Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí tí Ilé Ẹjọ́ yìí ti ń wọ́gi lé òfin táwọn kan ń fi de wíwá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn láti ojúlé dé ojúlé àti pípín ìwé kiri. Kì í ṣe ohun tó kàn ń ṣàdéédéé ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn pé, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹjọ́ yìí ló máa ń dá lórí ṣíṣàìka Àtúnṣe Òfin Kìíní sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì máa ń mú un wá síwájú ilé ẹjọ́ yìí, nítorí pé ìsìn wọn béèrè pé kí wọ́n máa lọ láti ojúlé dé ojúlé. Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Murdock àti Ìpínlẹ̀ Pennsylvania, . . . (1943), àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘sọ pé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù làwọ́n ń tẹ̀ lé, nípa kíkọ́ni “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” Ìṣe 20:20. Wọn ò fọwọ́ kékeré mú àṣẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé, “Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.” Máàkù 16:15. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà gbọ́ pé àṣẹ Ọlọ́run làwọ́n ń pa mọ́.’”

Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà tún fa ọ̀rọ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sí i látinú ẹjọ́ tó wáyé lọ́dún 1943 náà, ó sọ pé: “Lábẹ́ Àtúnṣe Òfin Kìíní, bí jíjọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti wíwàásù lórí àga ìwàásù ṣe ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìsìn yìí ṣe ṣe pàtàkì. Báwọn ìsìn tó ti wà tipẹ́ àtàwọn tó gbajúmọ̀ gan-an ṣe bófin mu lòun náà bófin mu.” Nígbà tí Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹjọ́ kan tó wáyé lọ́dún 1939, ó sọ pé: “Láti máa sọ pé káwọn èèyàn máa forúkọ sílẹ̀ nípa gbígba ìwé àṣẹ, èyí tí kò ní í jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti pín ìwé kiri ní fàlàlà láìsí ìdíwọ́, lòdì pátápátá sí ohun tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè yìí.”—Àwọn ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní lẹ́tà wínníwínní.

Ilé Ẹjọ́ náà wá sọ kókó kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ó sọ pé: “Àwọn ẹjọ́ wọ̀nyí fi hàn pé akitiyan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti má ṣe fara mọ́ òfin tó bá de ọ̀rọ̀ sísọ kì í ṣe ìjà tí wọ́n ń jà fún ẹ̀tọ́ tiwọn nìkan.” Àkọsílẹ̀ náà ṣàlàyé pé, àwọn Ẹlẹ́rìí “nìkan kọ́ làwọn ‘mẹ̀kúnnù’ tó ṣeé ṣe kí wọ́n di ẹni tí a fi òfin pa lẹ́nu mọ́ nípasẹ̀ irú àwọn òfin tí Abúlé náà ṣe.”

Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ ní sísọ pé “kì í ṣe pé” òfin náà “tàbùkù àwọn ìlànà tí Àtúnṣe Òfin Kìíní gbà láyè nìkan ni, àmọ́ ó tún tako òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tó yẹ kó wà láwùjọ àwọn èèyàn tó wà lómìnira—ìyẹn nígbà tá a bá ń sọ pé aráàlú gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ sọ fún ìjọba pé òun fẹ́ bá aládùúgbò òun fọ̀rọ̀ wérọ̀, àti pé ó ní láti gba ìyọ̀ǹda kó tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. . . . Òfin kan tó ń sọ pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gba ìyọ̀ǹda kí wọ́n tó lè bá ẹlòmíràn fọ̀rọ̀ wérọ̀ ti yà kúrò pátápátá nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè wa tí òfin tì lẹ́yìn.” Àkọsílẹ̀ náà wá sọ nípa “aburú ńlá tí irú òfin bẹ́ẹ̀ máa ṣe.”

Ewu Ìwà Ọ̀daràn

Ojú wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga fi wo èrò àwọn aláṣẹ abúlé náà pé torí àtidáàbò bo àwọn aráàlú lọ́wọ́ àwọn fọ́léfọ́lé àtàwọn ọ̀daràn ni àwọn fi ṣe ṣòfin gbígba ìyọ̀ǹda náà? Ilé Ẹjọ́ náà ṣàlàyé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbà pé àníyàn tí wọ́n ń ṣe nípa ọ̀ràn ààbò yẹn bọ́gbọ́n mu, àwọn ẹjọ́ tá a ti dá rí ti mú kó ṣe kedere pé, a ò gbọ́dọ̀ torí pé a fẹ́ dènà ìwà ọ̀daràn ká wá fojú kéré àkóbá tí irú òfin bẹ́ẹ̀ máa ṣe fún ohun tí Àtúnṣe Òfin Kìíní gbà láyè.”

Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà ń tẹ̀ síwájú pé: “Kò jọ pé ṣíṣàìgba ìyọ̀ǹda yìí á dí àwọn ọ̀daràn lọ́wọ́ láti má ṣe lọ kan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn kí wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí òfin náà kò mẹ́nu kàn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní kí àwọn èèyàn júwe ọ̀nà fún àwọn tàbí kí wọ́n ní kí wọ́n yá àwọn ní tẹlifóònù wọn lò, . . . tàbí kí wọ́n kọ orúkọ olórúkọ sílẹ̀, tí kò sì ní sí ìjìyà kankan fún wọn.”

Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ náà ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹjọ́ tí wọ́n dá ní ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní 1940, wọ́n kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò nínú àkọsílẹ̀ àwọn ẹjọ́ tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó dá àwọn ẹlẹ́sìn tó mú ẹjọ́ yìí wá [ìyẹn Watch Tower Society] sílẹ̀ léraléra lọ́wọ́ àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn wọ́n nítorí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí wọn, fi hàn pé Ilé Ẹjọ́ yìí ti gbé àwọn òmìnira tí Àtúnṣe Òfin Kìíní pèsè yẹ̀ wò dáadáa, èyí tí ẹjọ́ yìí dá lé.”

Báwo ni wọ́n wá ṣe dá ẹjọ́ yìí? Ìdájọ́ wọn ni pé: “Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti yí ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣe padà, a sì ti dá ẹjọ́ náà padà síbẹ̀ fún àgbéyẹ̀wò síwájú sí i níbàámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ wa. A pa á láṣẹ bẹ́ẹ̀.”

Ibi tí ẹjọ́ náà parí sí nìyẹn. Ìwé ìròyìn Chicago Sun-Times sọ pé: “Ilé Ẹjọ́ Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́yìn,” èyí sì wáyé látàrí bí àwọn adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án ṣe fọwọ́ sí ìpinnu náà.

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?

Ojú wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ìjọ Wellsville nítòsí abúlé Stratton fi wo ìjagunmólú wọn yìí ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ? Kò sí ìdí kankan fún wọn láti máa fi yangàn kí ojú lè ti àwọn olùgbé Stratton. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò ní èrò òdì kankan lọ́kàn sí àwọn ọmọlúwàbí èèyàn tó ń gbé ní abúlé náà. Gregory Kuhar tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí níbẹ̀ sọ pé: “Kì í ṣe pé ó wù wá láti ṣẹjọ́ rárá. Ó kàn jẹ́ pé òfin tí wọ́n gbé jáde náà kò bójú mu ni. Kì í ṣe àwa nìkan lohun tá a ṣe yìí wà fún, àmọ́ gbogbo èèyàn ni.”

Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé àwọn ò mú àwọn èèyàn ìlú náà bínú. Gene Koontz, tí òun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí níbẹ̀, ṣàlàyé pé: “March 7, 1998 la ti wàásù kẹ́yìn ní abúlé Stratton—ìyẹn ti lé lọ́dún mẹ́rin báyìí.” Ó fi kún un pé: “Wọ́n dìídì sọ fún mi pé àwọn á fi ọlọ́pàá mú mi bi mo bá wàásù. Ọ̀pọ̀ ọdún la fi gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìròyìn nípa bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń halẹ̀ pé ńṣe làwọ́n máa tì wá mọ́lé. Nígbà tá a sì béèrè pé kí wọ́n jẹ́ ká rí ibi tí wọ́n kọ òfin náà sí, wọn ò fún wa lésì kankan.”

Koontz fi kún un pé: “A fẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn aládùúgbò wa. Bí àwọn kan bá sọ pé àwọn ò fẹ́ ká wá sílé àwọn, a óò bọ̀wọ̀ fún ìpinnu wọn. Àmọ́ àwọn mìíràn wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí wa tí wọ́n sì ń gbà ká máa bá àwọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.”

Gregory Kuhar ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe láti di ọ̀tá àwọn èèyàn Stratton ló mú wa tẹpẹlẹ mọ́ ẹjọ́ yìí. A wulẹ̀ fẹ́ fìdí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wa múlẹ̀ lábẹ́ Òfin ni.”

Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bópẹ́bóyá, a retí láti padà lọ máa wàásù ní Stratton. Inú mi á dùn láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé kan nígbà tá a bá padà síbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Kristi ti pa á láṣẹ, dandan ni pé ká padà lọ.”

Ipa kékeré kọ́ ni àbájáde ẹjọ́ tó wà láàárín “Watchtower pẹ̀lú Abúlé Stratton” yìí ti ní o. Lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gbọ́ nípa ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà, wọ́n rí i pé àwọn kò lè lo òfin tí ìjọba ìbílẹ̀ bá ṣe mọ́ láti fi gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rùn-ún àgbègbè ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tí àwọn ìṣòro tó so mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ti di èyí tó yanjú.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

“ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ TÚN TI JÀRE NÍ ILÉ ẸJỌ́ GÍGA JÙ LỌ”

Charles C. Haynes, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó sì tún jẹ́ alága ètò tó ń la àwọn èèyàn lọ́yẹ̀ nípa Àtúnṣe Òfin Kìíní, ló kọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí lábẹ́ àkọlé náà, “Òmìnira Ìsìn,” èyí tí iléeṣẹ́ ìròyìn MSNBC tó máa ń ròyìn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì gbé jáde. Haynes ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lọ́sẹ̀ tó kọjá, [àwọn Ẹlẹ́rìí] tún ti jagun mólú ní ìgbà Kejìndínláàádọ́ta ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ—àwọn ẹjọ́ yìí sì ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé, wọ́n ti mú kí ẹ̀tọ́ àwọn ará Amẹ́ríkà lábẹ́ Àtúnṣe Òfin Kìíní gbòòrò sí i.” Ó wá kìlọ̀ pé: “Ẹ máa rántí kókó yìí o: Bí ìjọba bá lè gbẹ́sẹ̀ lé òmìnira ìsìn kan, ó lágbára láti gbẹ́sẹ̀ lé òmìnira ìsìn èyíkéyìí— tàbí ti gbogbo ìsìn. . . . Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé àwọn kò fẹ́ gbọ́— kí wọ́n sì ti ilẹ̀kùn wọn. Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé ìjọba ni yóò wá máa pàṣẹ pé ẹni báyìí làwọ́n fún láṣẹ láti máa kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn. Fún ìdí yìí, a gbóṣùbà fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ.”

Haynes wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Gbogbo wa la jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbèsè ọpẹ́. Láìka iye ìgbà tí wọ́n lè tàbùkù wọn sí, tí wọ́n á lé wọn jáde nínú ìlú, tàbí tí wọ́n á tiẹ̀ lù wọ́n pàápàá, wọn ò jẹ́ jáwọ́ nínú jíjà fún òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn (wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jà fún òmìnira ìsìn tiwa náà). Nígbà tí wọ́n bá sì jàre, gbogbo wa là ń jàǹfààní rẹ̀.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Ohun Tí Àwọn Ìwé Ìròyìn Sọ Nípa—Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ

“Ilé Ẹjọ́ Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́yìn; Ìwàásù Ilé-dé-Ilé Kò Nílò Gbígba Ìyọ̀ǹda

Nínú iṣẹ́ kíkan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, ìgbà gbogbo ni [àwọn Ẹlẹ́rìí] gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń ti àwọn lẹ́yìn. Ní báyìí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà tún ti tì wọ́n lẹ́yìn.”—Ìwé Ìròyìn Chicago Sun-Times, June 18, 2002.

“Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ Borí

Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tún wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbi tó o ti ń jẹun lọ́wọ́, á dára kó o dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Nípa fífi tọkàntara tẹ̀ lé ìlànà ìsìn wọn, ìsìn tó yàtọ̀ sí gbogbo ìsìn tó kù yìí, tí àwọn tó ń ṣe é [ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] fi díẹ̀ dín ní mílíọ̀nù kan, ti ṣe ju gbogbo àwọn àjọ mìíràn lọ láti rí i pé tẹrútọmọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. . . .

“Ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí, lílọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́. Nínú ẹjọ́ tó ju mẹ́rìnlélógún lọ láàárín ọdún márùnlélọ́gọ́ta, wọ́n ti borí lílò tí àwọn tó pọ̀ jù wọ́n lọ ń lo agbára òdì lórí wọn.”—Ìwé Ìròyìn USA TODAY, June 18, 2002.

“Lílọ Láti Ilé Dé Ilé Bófin Mu. Ìjagunmólú Lèyí Jẹ́ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà pàṣẹ lọ́jọ́ Monday pé, àwọn olóṣèlú, àwọn onísìn, àwọn ẹgbẹ́ Girl Scouts àtàwọn mìíràn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti máa lọ láti ilé dé ilé láti sọ̀rọ̀ nípa ìlànà wọn láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ ń gba ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀.”—Ìwé Ìròyìn San Francisco Chronicle, June 18, 2002.

“Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Sọ Pé: Kò Sẹ́ni Tó Lè Ní Kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Àtàwọn Ẹgbẹ́ Girl Scouts Má Ṣe Kan Ilẹ̀kùn Àwọn Èèyàn

WASHINGTON—Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti sọ lónìí pé, . . . lábẹ́ Òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn òṣèlú, àtàwọn mìíràn lẹ́tọ̀ọ́ láti máa kan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ ń gba ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀.

“Nínú ìdájọ́ tí àwọn adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án fọwọ́ sí, ilé ẹjọ́ náà sọ pé, lára àwọn ẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí Àtúnṣe Òfin Kìíní fàyè gbà ni pé, èèyàn lè lọ sí ẹnu ọ̀nà ẹnì kan ní tààràtà kó sì lọ sọ nǹkan kan fún onítọ̀hún.”—Ìwé Ìròyìn Star Tribune, Minneapolis, June 18, 2002.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Adájọ́ Stevens

[Credit Line]

Stevens: Collection, The Supreme Court Historical Society/Joseph Bailey