Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tẹ́wọ́ Gba Ẹjọ́ Náà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tẹ́wọ́ Gba Ẹjọ́ Náà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tẹ́wọ́ Gba Ẹjọ́ Náà

LÁWỌN ỌDÚN ÀÌPẸ́ YÌÍ, gbogbo ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa ń tẹ́wọ́ gbà lọ́dún kan fún àyẹ̀wò kì í ju ọgọ́rin sí àádọ́rùn-ún nínú ẹgbẹ̀rún méje ẹjọ́ lọ—díẹ̀ ni èyí sì fi lé ní ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún!

Ní May 2001, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi Ìwé Ẹ̀bẹ̀ Láti Ṣàtúnyẹ̀wò Ẹjọ́ náà ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, kí wọ́n lè gbé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré ti kọ́kọ́ dá yẹ̀ wò. Ohun tó wà nínú ìwé náà rèé: “Lábẹ́ òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ǹjẹ́ ohun kan náà ni àwọn òjíṣẹ́ tó ń ṣe iṣẹ́ tó ti wà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá, tó sì bá Ìwé Mímọ́ mu, ìyẹn ni iṣẹ́ sísọ nípa ìgbàgbọ́ wọn fún àwọn èèyàn láti ilé dé ilé, ń ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń ta ọjà láti ojúlé dé ojúlé? Ǹjẹ́ ó sì pọn dandan fún wọn láti ṣègbọràn sí òfin ìjọba ìbílẹ̀ tó sọ pé kí wọ́n kọ́kọ́ lọ gba àṣẹ kí wọ́n tó lè sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì tàbí kí wọ́n tó lè fi àwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì lọ àwọn èèyàn láìgba owó kankan?”

Ní October 15, 2001, wọ́n jẹ́ kí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní Ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà mọ̀ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti tẹ́wọ́ gba ẹjọ́ tí wọ́n pè, ìyẹn ẹjọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., pẹ̀lú Abúlé Stratton. Èyí túmọ̀ sí pé Ilé Ẹjọ́ náà ti gbà láti ṣàtúnyẹ̀wò ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré ti kọ́kọ́ dá!

Ìṣòro pàtàkì kan tó so mọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ló mú kí Ilé Ẹjọ́ náà tẹ́wọ́ gba ẹjọ́ ọ̀hún. Ìyẹn ni pé, bóyá Àtúnṣe Òfin Kìíní nínú ìwé òfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tó fàyè gba òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kan ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn pàtàkì kan láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ lọ fi ara hàn lọ́dọ̀ ìjọba.

Ní báyìí, ẹnu làwọn agbẹjọ́rò tó wà fún ìhà kọ̀ọ̀kan máa fi ṣàlàyé ẹjọ́ yìí níwájú àwọn adájọ́ mẹ́sàn-án tó wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò ní àwọn agbẹjọ́rò tiwọn; Abúlé Stratton tó jẹ́ alátakò wọn náà á sì ní àwọn agbẹjọ́rò tirẹ̀. Ibo ni àpérò yìí máa wá já sí o?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

ÈWO NI WỌ́N Ń PÈ NÍ ÀTÚNṢE ÒFIN KÌÍNÍ?

“ÀTÚNṢE ÒFIN KÌÍNÍ (DÍDÁ ÌSÌN SÍLẸ̀; ÒMÌNIRA ÌSÌN, ÒMÌNIRA Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ, ÒMINIRA LÁTI TẸ̀WÉ JÁDE, ÒMINIRA LÁTI PÉJỌ PỌ̀, ÒMINIRA LÁTI KỌ̀WÉ Ẹ̀BẸ̀ SÍ ÌJỌBA) Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kò ní ṣe òfin kankan lórí ìdásílẹ̀ ìsìn, tàbí kó ka ìgbòkègbodò ìsìn ní fàlàlà léèwọ̀, tàbí kó fi òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tàbí ti kíkọ ìròyìn jáde du ẹnì kankan; bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn láti péjọ pọ̀ láìsí wàhálà, àti ẹ̀tọ́ láti kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí Ìjọba láti gbani lọ́wọ́ ìyà dù wọ́n.”—Ìwé Òfin Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

“Àtúnṣe Òfin Kìíní ni ìpìlẹ̀ fún ètò ìjọba tiwa-n-tiwa Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àtúnṣe Òfin Kìíní yìí kò fàyè gba Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti ṣe òfin tó máa ka òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, títẹ ìwé jáde, ṣíṣe ìpàdé tí kò mú wàhálà lọ́wọ́, tàbí kíkọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba nípa ohun tó ń dunni léèwọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ka òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ sí òmìnira tó ṣe pàtàkì jù lọ àti pé òun ni ìpìlẹ̀ fún gbogbo òmìnira yòókù. Bákan náà, Àtúnṣe Òfin Kìíní yìí kò fàyè gba Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti ṣe òfin pé ìsìn kan ní pàtó ni ìjọba tì lẹ́yìn, tàbí kó fi òmìnira ìsìn duni.” (The World Book Encyclopedia) Ó dùn mọ́ni pé, nínú ẹjọ́ kan tó ti wáyé ṣáájú, ìyẹn ti Cantwell pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Connecticut, tí nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ 310 U.S. 296 (1940), Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà dá ẹjọ́ mánigbàgbé kan tó ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn. Ilé Ẹjọ́ náà dájọ́ pé kì í ṣe “Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin” (ìjọba àpapọ̀) nìkan ni àwọn ìpinnu tó wà nínú Àtúnṣe Òfin Kìíní náà ká lọ́wọ́ kò láti má ṣe ṣe àwọn òfin tó lè tẹ àwọn ẹ̀tọ́ tó wà nínú Àtúnṣe Òfin Kìíní náà lójú, àmọ́ pé èyí tún kan àwọn ìjọba àgbègbè kọ̀ọ̀kan (ìyẹn àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀).

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn ohun tí ẹjọ́ náà ní nínú kan oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ láti ilé dé ilé

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Photograph by Franz Jantzen, Collection of the Supreme Court of the United States