Mo Borí Ẹ̀mí Ìkórìíra
Mo Borí Ẹ̀mí Ìkórìíra
GẸ́GẸ́ BÍ JOSÉ GÓMEZ ṢE SỌ Ọ́
WỌ́N bí mi ní September 8, 1964 ní ìlú Rognac, tó jẹ́ ìlú kékeré kan ní apá gúúsù ilẹ̀ Faransé. Ẹ̀yà Íńdíà Adúláwọ̀ làwọn òbí mi àtàwọn òbí mi àgbà, orílẹ̀-èdè Algeria àti Morocco tó wà ní Àríwá Áfíríkà ni wọ́n sì ti bí wọn. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wọ́pọ̀ nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ẹ̀yà Íńdíà Adúláwọ̀, ìdílé amẹ́bí-múbàátan ni ìdílé wa.
Oníjàgídíjàgan ni bàbá tó bí mi lọ́mọ. Lára àwọn nǹkan tí mo ṣì rántí nípa ìgbà ọmọdé mi ni bó ṣe máa ń lu màmá mi. Nígbà tó yá, màmá mi pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀—ohun kan tó ṣọ̀wọ́n láàárín àwa Íńdíà tó jẹ́ Adúláwọ̀. Ó mú èmi, àbúrò mi ọkùnrin, àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, dání lọ sí orílẹ̀-èdè Belgium, níbi tá a gbé fún ọdún mẹ́jọ láìsí wàhálà kankan.
Àmọ́ nígbà tó yá, nǹkan yí padà. Àwa ọmọ sọ pé a fẹ́ rí bàbá wa, nítorí náà Màmá kó wa lọ sí ilẹ̀ Faransé níbi tí gbogbo wa ti wà pa pọ̀ pẹ̀lú bàbá mi. Pípadà lọ gbé pẹ̀lú bàbá mi yìí dá ìṣòro sílẹ̀ fún mi. Nígbà tá a wà ní Belgium, gbogbo ibi tí Màmá bá ń lọ ló máa ń mú wa dání lọ. Àmọ́ ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ bàbá mi, ẹgbẹ́-ẹyẹ-lẹyẹ-ń-wọ́-tọ̀ ni tiẹ̀. Ọkùnrin lọkùnrin gbọ́dọ̀ máa bá rìn. Èrò òdì tí wọ́n ní ni pé, ọkùnrin ló gbọ́dọ̀ máa pàṣẹ, obìnrin ló sì gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo fẹ́ ran àǹtí mi, tó jẹ́ àbúrò bàbá mi lọ́wọ́, láti palẹ̀ àwo mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ kí n sì fọ̀ wọ́n, àbúrò bàbá mi tó jẹ́ ọkùnrin pè mí ní abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀. Nínú ìdílé tirẹ̀, obìnrin nìkan ló gbọ́dọ̀ fọ abọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí ní irú èrò òdì yìí.
Kò pẹ́ tí màmá mi tún fi bẹ̀rẹ̀ sí jìyà lẹ́ẹ̀kan sí i nítorí ìwà ipá bàbá mi. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tá a bá gbìyànjú láti dá sí i, ojú fèrèsé lèmi àti àbúrò mi ọkùnrin máa gbà bẹ́ síta kí ẹ̀ṣẹ́ tí Bàbá fẹ́ dà bò wá má bàa bà wá. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin pàápàá kò bọ́ lọ́wọ́ lílù yìí. Fún ìdí yìí, àkókò tí mò ń lò níta ju èyí tí mò ń lò nílé lọ. Ní ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ìgbésí ayé mi kò ní ibi tó forí lé.
Bí àkókò ti ń lọ, àwọn èèyàn wá mọ̀ mí sí ìpáǹle èèyàn. Inú mi máa ń dùn láti rí bí àwọn èèyàn ṣe máa ń bẹ̀rù mi yìí. Nígbà míì, màá mọ̀ọ́mọ̀ lọ tọ́ ìjà àwọn ọ̀dọ́kùnrin mìíràn, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni kò jẹ́ yọwọ́ ìjà sí mi—pàápàá níwọ̀n bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń mú ọ̀bẹ tàbí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dání. Kò pẹ́ kò jìnnà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jí mọ́tò gbé tí màá sì lọ tà wọ́n. Láwọn ìgbà míì, ńṣe ni màá kàn sọ iná sí wọn tí inú mi á sì máa dùn bí mo bá ṣe ń wo àwọn panápaná tí wọ́n ń pa iná náà. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ṣọ́ọ̀bù àtàwọn ilé ìkẹ́rùsí. Àwọn ọlọ́pàá mú mi nígbà bíi mélòó kan. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá sì mú mi ni mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́!
Òótọ́ ni, mo nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Nígbà tá à ń gbé ní Belgium, ilé ẹ̀kọ́ onísìn ni mo lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, mo mọ̀ pé ìwà tí mò ń hù kò dára. Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Ọlọ́run kò nípa kankan lórí ìwà mi. Mo máa ń ronú pé tí mo bá ṣáà ti tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, á dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.
Lọ́dún 1984, wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n oṣù mọ́kànlá torí ẹ̀sùn olè jíjà. Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Baumettes tó wà nílùú
Marseilles ni wọ́n mú mi lọ. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo fín nǹkan sí ara mi káàkiri. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí mo fín sára kà pé, “ìkórìíra àti ìgbẹ̀san.” Dípò kí n yí ìwàkiwà tí mò ń hù padà, ńṣe ni mo jẹ́ kí ọgbà ẹ̀wọ̀n túbọ̀ mú kí ìkórìíra tí mo ní fún àwọn aláṣẹ àti àwùjọ lápapọ̀ gogò sí i. Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀, lẹ́yìn tí mo ti ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta péré, ńṣe ni ẹ̀mí ìkórìíra túbọ̀ wá jọba lọ́kàn mi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àmọ́, àjálù kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé mi padà.Gbígbẹ̀san Di Ohun Tí Mò Ń Lépa
Èdèkòyédè kan ṣẹlẹ̀ láàárín ìdílé mi àti ìdílé Íńdíà Adúláwọ̀ mìíràn. Lèmi àtàwọn arákùnrin bàbá mi bá pinnu pé ńṣe la máa lọ kò wọ́n lójú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àwa ìdílé méjèèjì la dira ìjà. Nínú àríyànjiyàn tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e, wọ́n yìnbọn pa Pierre, ẹ̀gbọ́n bàbá mi, àti ọmọ ìbátan bàbá mi mìíràn. Orí mi gbóná gan-an débi pé, ńṣe ni mo gbé ìbọn tí mo sì lọ dúró sí òpópónà, tí mo wá ń ké rara pẹ̀lú ìbínú. Níkẹyìn, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin bàbá mi ló wá fipá gba ìbọn náà lọ́wọ́ mi.
Ikú Pierre, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n bàbá mi, ẹni tí mò ń wò bíi bàbá, mu mí lómi gan-an ni. Mo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwa Íńdíà Adúláwọ̀. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, mi ò fá irùngbọ̀n mi bẹ́ẹ̀ ni mi ò fẹnu kan ẹran. Mo kọ̀ láti wo tẹlifíṣọ̀n tàbí láti gbọ́ orin. Mo búra pé màá rí i pé mo gbẹ̀san ikú ẹ̀gbọ́n bàbá mi, àmọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí mi kò jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ ìbọn.
Ní August 1984, wọ́n gbà mí síṣẹ́ ológun. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún ọdún, mo lọ forúkọ sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń rán lọ pẹ̀tù síjà lórílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì. Mo ṣe tán láti pààyàn tàbí kí wọ́n pa mí. Ní àkókò yẹn, hashish tí mo máa ń mu, èyí tó tún lágbára ju igbó lọ, kúrò ní kékeré. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń jẹ́ kára tù mí, oògùn olóró yìí tún máa ń mú kí n nímọ̀lára pé kò sí ohun burúkú kankan tó lè ṣẹlẹ̀ sí mi.
Níwọ̀n bí kò ti ṣòro rárá láti rí nǹkan ìjà rà nílẹ̀ Lẹ́bánónì, mo pinnu láti rà wọ́n ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Faransé, kí n lè máa bá ìwéwèé mi láti gbẹ̀san ẹ̀gbọ́n bàbá mi lọ. Mo ra ìbọn ìléwọ́ méjì, pa pọ̀ pẹ̀lú ọta ìbọn lóríṣiríṣi, lọ́wọ́ àwọn èèyàn ibẹ̀. Mo tú àwọn ìbọn náà palẹ̀, mo wá fi wọ́n pa mọ́ sínú rédíò méjì, lẹ́yìn èyí ni mo fi wọ́n ránṣẹ́ sílé.
Nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ méjì péré kí n parí iṣẹ́ ológun mi, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi mẹ́ta kan jọ kúrò níbi tí wọ́n fi wá sí láìgba àṣẹ. Nígbà tá a padà dé sí àgọ́ wa, ńṣe ni wọ́n fi wá sínú ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, inú mi ru sí ẹ̀ṣọ́ kan mo sì lù ú bolẹ̀. Mi ò tiẹ̀ lè gbà rárá ni kí ẹnì kan tó jẹ́ payo—ìyẹn ẹni tí kì í ṣe Íńdíà Adúláwọ̀—máa rí mi fín. Lọ́jọ́ kejì, mo tún bá ẹlòmíràn ja ìjà àjàkú akátá kan, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ọ̀gá lẹni tí mo bá jà náà. Ni wọ́n bá lọ jù mí sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Montluc tó wà nílùú Lyons, ibẹ̀ ni mo sì ti lo àkókò mi tó kù nínú iṣẹ́ ológun.
Mo Rí Òmìnira Nínú Ẹ̀wọ̀n
Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo dé sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Montluc, ọkùnrin kan tó ṣọmọlúwàbí kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Mo wá mọ̀ lẹ́yìn náà pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àti pé, ohun tó gbé òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ìsìn kan náà dé ẹ̀wọ̀n kò ju pé wọ́n kọ̀ láti gbé nǹkan ìjà. Ìyẹn jọ mi lójú. Mo fẹ́ mọ̀ sí i.
Mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run, ọwọ́ pàtàkì tí wọ́n fi mú àwọn ìlànà ìwà rere wú mi lórí gidigidi. Síbẹ̀, mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti béèrè. Pàápàá jù lọ, mo fẹ́ mọ̀ bóyá lóòótọ́ làwọn òkú lè bá alààyè sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àlá—ohun kan tí ọ̀pọ̀ àwọn Íńdíà Adúláwọ̀ gbà gbọ́. Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jean-Paul sọ pé òun á kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa lílo ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. a
Alẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo ni mo ka gbogbo ìwé náà tán láti páálí dé páálí, ohun tí mo kà sì wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. Nínú ẹ̀wọ̀n tí mo wà níbí, mo rí òmìnira tòótọ́! Nígbà tí wọ́n sì dá mi sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo wọ ọkọ̀-ojú irin padà sílé, pẹ̀lú báàgì mi tó kún fọ́fọ́ fún onírúurú àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì.
Kí n lè rí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àgbègbè ibi tí mò ń gbé, mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Martigues. Mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi nìṣó, àmọ́ ní báyìí, ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eric, ló wá ń kọ́ mi. Láàárín ọjọ́ díẹ̀ péré, mo jáwọ́ nínú sìgá mímu, mi ò sì wá àwọn ẹgbẹ́ mi tá a jọ ń hu ìwà ọ̀daràn lọ mọ́. Mo pinnu lọ́kàn mi pé màá fi ohun tó wà nínú Òwe 27:11 sílò, èyí tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Mo wá rí i pé Jèhófà jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́ fún mi, mo sì fẹ́ láti múnú rẹ̀ dùn.
Kò Rọrùn Láti Yí Padà
Kò rọrùn fún mi láti fi àwọn ìlànà Kristẹni sílò. Bí àpẹẹrẹ, mo tún padà sídìí lílo àwọn oògùn olóró tí mo ti kọ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí sì ń bá a lọ fún bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan. Àmọ́ èyí tó wá nira fún mi jù lọ ni láti mú ẹ̀mí ìgbẹ̀san tó wà lọ́kàn mi kúrò. Láìjẹ́ kí Eric mọ̀, mo máa ń mú ìbọn kiri, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ń bá ìwéwèé mi lọ lójú méjèèjì láti gbẹ̀san lára àwọn tó pa ẹ̀gbọ́n bàbá mi. Tòrutòru ni mo máa ń fi wá wọn kiri.
Nígbà tí mo sọ nípa èyí fún Eric, ó ṣàlàyé fún mi ní kedere pé, mi ò lè ní àjọṣe tó fìdí múlẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run bí mo bá ṣì ń di ìbọn mọ́ra tí mo sì ń wá ọ̀nà láti gbẹ̀san. Mo ní láti yan ọ̀kan. Mo ronú jinlẹ̀ gidigidi lórí ìṣílétí Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù 12:19, èyí tó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú.” Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú gbígbàdúrà kíkankíkan, ràn mí lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìrònú òdì mi. (Sáàmù 55:22) Níkẹyìn, mo kó àwọn ohun ìjà mi dà nù. Ní December 26, 1986, lẹ́yìn tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọdún kan, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi.
Àwọn Ìdílé Mi Náà Yí Padà
Àwọn ìyípadà tí mo ṣe nínú ìwà mi fún àwọn òbí mi níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n tún fẹ́ra wọn padà, màmá mi sì ṣèrìbọmi ní July 1989. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn mìíràn nínú ìdílé mi náà tẹ́wọ́ gba ìhìn Bíbélì, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ní August 1988, mo pinnu láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ọkàn mi fà mọ́ omidan kan nínú ìjọ wa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Katia. A ṣègbéyàwó ní June 10, 1989. Ọdún àkọ́kọ́ ìgbéyàwó wa kò rọrùn rárá, torí pé àwọn àtúnṣe ṣì wà fún mi láti ṣe nínú bí mo ṣe ń hùwà sáwọn obìnrin. Ó ṣòro fún mi láti fi àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Pétérù 3:7 sílò, èyí tó rọ àwọn ọkọ láti máa fi ọlá fún àwọn aya wọn. Léraléra ni mo ní láti gbàdúrà fún okun láti tẹ ẹ̀mí ìgbéraga mi rì kí n sì yí bí mo ṣe ń ronú padà. Díẹ̀díẹ̀, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í sàn sí i.
Ikú ẹ̀gbọ́n bàbá mi ṣì máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an, nígbà míì tí mo bá sì ronú nípa rẹ̀, ńṣe lomi á kàn máa dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú mi. Ìbànújẹ́ kékeré kọ́ ni mò máa ń mú mọ́ra nígbà tí mo bá rántí bí wọ́n ṣe pa á. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, kódà lẹ́yìn ìrìbọmi mi, ni ẹ̀rù ṣì máa ń bà mí pé mo lè lọ ṣàdédé pàdé àwọn tó jẹ́ ara ìdílé tá a ti jọ ní aáwọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ náà. Kí ni màá ṣe ká ní wọ́n tún wá gbéjà kò mí? Báwo ni màá ṣe hùwà padà? Ṣé ìwà mi àtijọ́ á tún nípa lórí mi?
Lọ́jọ́ kan, mo lọ sọ àsọyé ní ìjọ kan nítòsí. Níbẹ̀ mo rí Pepa, tó jẹ́ ẹbí àwọn ọkùnrin tó pa ẹ̀gbọ́n bàbá mi. Kí n sòótọ́, rírí tí mo rí i dán àkópọ̀ ìwà Kristẹni mi wò. Àmọ́ mo gbé ìrònú òdì mi tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ tí Pepa ṣèrìbọmi, mo gbá a mọ́ra mo sì kí i dáadáa fún ìpinnu rẹ̀ láti sin Jèhófà. Láìka gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá sí, mo tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí arábìnrin mi nípa tẹ̀mí.
Ojoojúmọ́ ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ríràn tó ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ìkórìíra mi. Ká ní kì í ṣe àánú Jèhófà ni, ibo ni ǹ bá wà lọ́jọ́ òní? Mo tún dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ìdílé mi jẹ́ ìdílé aláyọ̀. Bákan náà, mo tún nírètí lọ́jọ́ iwájú—ìyẹn ayé kan níbi tí ìkórìíra àti ìwà ipá kò ti ní sí mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Wọn yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”—Míkà 4:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Nígbà tí mo wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun apẹ̀tùsíjà ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní ilẹ̀ Lẹ́bánónì lọ́dún 1985
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Èmi pẹ̀lú Katia àtàwọn ọmọkùnrin mi, Timeo àti Pierre