‘Mo Padà Rí Jésù Tí a Ti Gbàgbé’
‘Mo Padà Rí Jésù Tí a Ti Gbàgbé’
Lẹ́yìn tí obìnrin kan láti ìlú Saint-Jérôme, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà, ka ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ó kọ̀wé pé: “Pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà ni mo fi tún padà rí Jésù tí a ti gbàgbé, ẹni tí àwọn ayàwòrán sábà máa ń yà bí ẹni pé kì í ṣe ẹni gidi.”
Obìnrin náà sọ bí àwòrán inú ìwé náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Àwọn àwòrán inú ìwé yín wú mi lórí gan-an ni. Àwọn èèyàn tẹ́ ẹ yà sínú rẹ̀ dà bí ẹni gidi lójú mi, ńṣe ni wọ́n rí bí àwọn èèyàn tó gbé ayé nígbà tí Jésù wà láàyè tó ń wàásù.” Ó parí lẹ́tà rẹ̀ pé: “Ẹ káre láé fún ṣíṣe tẹ́ ẹ ṣe ìwé yìí jáde. Atọ́nà tó lè ṣamọ̀nà àwọn tó ń sapá láti túbọ̀ kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni ló jẹ́.”
Nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla, a sapá láti jíròrò gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé, èyí tí a sọ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, títí kan àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ, àwọn àkàwé, àtàwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Dé ibi tó ṣeé ṣe dé, a ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀-lé gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbà gbọ́ pé wọ́n ṣẹlẹ̀. Àti pé, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ lókè, ìwé náà ní àwọn àwòrán ẹlẹ́wà tí wọ́n sì jẹ́ àwòrán gidi, èyí tá a yà láti fi bí nǹkan ṣe rí lára Jésù àti lára àwọn tó gbé ayé nígbà tirẹ̀ hàn.
Bó o bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 448 yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.