Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Tálákà?

Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Tálákà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Tálákà?

nígbà kan rí, jésù sọ fún ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ olùṣàkóso àti ọlọ́rọ̀ pé ó ní láti lọ ta gbogbo nǹkan ìní rẹ̀, kí ó sì fún àwọn òtòṣì. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, inú ọkùnrin náà bà jẹ́ nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù, ó sì lọ pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, “nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.” Lẹ́yìn èyí ni Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó láti wọ ìjọba Ọlọ́run!” Jésù fi kún un pé: “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run.”—Máàkù 10:21-23; Mátíù 19:24.

Kí lọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé jíjẹ́ ọlọ́rọ̀ kò ní jẹ́ kéèyàn lè ṣe ìjọsìn tòótọ́ ni? Ṣé ó yẹ kí ọkàn àwọn Kristẹni máa dá wọn lẹ́bi bí wọ́n bá jẹ́ ọlọ́rọ̀? Ṣé ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé kí wọ́n má jẹ̀gbádùn ìgbésí ayé?

Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gba “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”

Ní ayé ìgbàanì, Ọlọ́run ò sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé ìgbé ayé tálákà. Ronú lórí èyí ná: Lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ilẹ̀ tí a pín fún wọn, àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe kí wọ́n lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún ara wọn àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Àwọn nǹkan bí ipò ọrọ̀ ajé, ojú ọjọ́, ìlera tàbí mímọ òwò ṣe, ló máa pinnu bí gbogbo ìsapá wọn lẹ́nu iṣẹ́ wọn ṣe máa kẹ́sẹ járí tó. Òfin Mósè sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi àánú hàn bí ọrọ̀ ajé ẹnikẹ́ni lára wọn bá dẹnu kọlẹ̀ tó sì wá di òtòṣì. (Léfítíkù 25:35-40) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn kan di ọlọ́rọ̀. Bíbélì sọ pé, Bóásì, ọkùnrin kan tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tó sì tún jẹ́ oníwàtítọ́, ẹni tó wá di baba ńlá fún Jésù Kristi, jẹ́ “ọkùnrin kan tí ọlà rẹ̀ yamùrá.”—Rúùtù 2:1.

Bákan náà ni ipò nǹkan ṣe rí nígbà ayé Jésù. Nígbà tí Jésù ń bá ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ sọ̀rọ̀, kì í ṣe ohun tó ní lọ́kàn ni pé a ní láti yàgò fún fàájì pátápátá ká wá máa gbé ìgbésí ayé ìṣẹ́ òun àre. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ló ń fi kọ́ni. Lójú ẹ̀dá èèyàn, ó lè dà bíi pé kò ṣeé ṣe fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ètò tí Ọlọ́run ti ṣe fún ìgbàlà. Síbẹ̀, Jésù sọ pé: “Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:26.

Ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tẹ́wọ́ gba “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (1 Tímótì 2:4) Àwọn kan níbẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀, àwọn mìíràn jẹ́ kòlàkòṣagbe, ọ̀pọ̀ ló sì jẹ́ tálákà. Àwọn kan lára wọn lè ti kó ọrọ̀ jọ ṣáájú kí wọ́n tó di Kristẹni. Ní tàwọn mìíràn sì rèé, ó lè jẹ́ pé ipò nǹkan tó ṣẹnuure fún wọn àti mímọ béèyàn ṣe ń ṣòwò ló wá sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀.

Bákan náà ló jẹ́ pé nínú ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni lóde òní, ipò ìṣúnná owó àwọn èèyàn yàtọ̀ síra. Gbogbo wọn ń làkàkà láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Bíbélì lórí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ owó, níwọ̀n bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ti lè nípa lórí ẹnikẹ́ni. Ó yẹ kí ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni nípa ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ olùṣàkóso àti ọlọ́rọ̀ náà mú kí gbogbo Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan wà lójúfò sí agbára tí owó àti ohun ìní lè ní lórí ẹni.—Máàkù 4:19.

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọlọ́rọ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò dẹ́bi fún ọrọ̀ gan-an fúnra rẹ̀, àmọ́ ó dẹ́bi fún ìfẹ́ owó. Pọ́ọ̀lù tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” Ó sọ pé, nípa fífọwọ́ rọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí sẹ́yìn nítorí ìfẹ́ láti di ọlọ́rọ̀, “a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé, Pọ́ọ̀lù pèsè àwọn ìtọ́ni pàtó fún àwọn ọlọ́rọ̀. Ó sọ pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” (1 Tímótì 6:17) Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ọlọ́rọ̀ di agbéraga kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rò pé àwọn sàn ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Bákan náà, wọ́n lè máa rò pé ọrọ̀ lè fún àwọn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tòótọ́—èyí tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló lè fúnni lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

Àwọn Kristẹni tó jẹ́ olówó lè yẹra fún àwọn ewu wọ̀nyí nípa jíjẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Lára àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ni jíjẹ́ “aláìṣahun, kí wọ́n [sì] múra tán láti ṣe àjọpín,” ìyẹn ni fífi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní. (1 Tímótì 6:18) Àwọn Kristẹni—àtolówó àti tálákà—tún lè lò lára àwọn ohun ìní wọn láti fi tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀, èyí tó jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí. Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yìí ń fi ojú ìwòye títọ̀nà tí ẹnì kan ní nípa àwọn nǹkan tara hàn, ó sì ń mú kí onítọ̀hún ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn olùfúnni ọlọ́yàyà.—Mátíù 24:14; Lúùkù 16:9; 2 Kọ́ríńtì 9:7.

Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Ó ṣe kedere pé, a ò sọ pé kí àwọn Kristẹni jẹ́ tálákà. Bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí wọ́n “pinnu láti di ọlọ́rọ̀.” (1 Tímótì 6:9) Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára láti lè rí ohun tí wọ́n á fi gbọ́ bùkátà ara wọn lọ́nà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé onírúurú ipò ló yí ẹnì kọ̀ọ̀kan ká, tó sì jẹ́ pé ètò ọrọ̀ ajé àgbègbè kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, owó tí yóò máa wọlé fún kálukú wọn yóò yàtọ̀ síra.—Oníwàásù 11:6.

Yálà wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà, àwọn Kristẹni ní láti máa làkàkà láti “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Nípa fífi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, wọ́n ń “fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:19.