Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Fa Ẹjọ́ Náà

Ohun Tó Fa Ẹjọ́ Náà

Ohun Tó Fa Ẹjọ́ Náà

STRATTON, NÍ ÌPÍNLẸ̀ OHIO, LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ jẹ́ àgbègbè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi. Ìtòsí Odò Ohio, èyí tó ya Ìpínlẹ̀ Ohio kúrò lára ìpínlẹ̀ West Virginia, ló wà. Abúlé ni wọ́n kà á sí, ó sì ní baálẹ̀ kan. Àgbègbè kékeré táwọn olùgbé ibẹ̀ kò tó ọ̀ọ́dúnrún yìí ṣàdédé di ojúkò àríyànjiyàn lọ́dún 1999 nígbà táwọn aláṣẹ ibẹ̀ sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àtàwọn mìíràn, gbọ́dọ̀ lọ gba àṣẹ kí wọ́n tó lè máa ṣèbẹ̀wò sí ilé àwọn èèyàn láti sọ ìhìn Bíbélì tí wọ́n ń jẹ́ fún wọn.

Kí nìdí tí ọ̀ràn yìí fi ṣe pàtàkì? Bó o ti ń kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ, wàá rí i pé láìsí àní-àní, irú òfin tí ìjọba àgbègbè náà ṣe yìí yóò dín ẹ̀tọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira kù, àmọ́ kì í ṣe tiwọn nìkan o, á tún dín ẹ̀tọ́ gbogbo olùgbé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kù pẹ̀lú.

Bí Wàhálà Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú Ìjọ Wellsville lábúlé Stratton ti ń wàásù dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé abúlé náà, àmọ́ ọdún 1979 ni àwọn aláṣẹ kan níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si fa ìṣòro fún àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí látàrí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé tí wọ́n ń ṣe. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní 1990, ọlọ́pàá ìlú Stratton kan lé àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan jáde kúrò nínú ìlú náà. Ó sọ pé: “Kò sí nǹkan kan tó kàn mí pẹ̀lú ẹ̀tọ́ yín.”

Ọdún 1998 gan-an ni iná wá jó dórí kókó, nígbà tí baálẹ̀ abúlé Stratton fúnra rẹ̀ ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin lójú. Jẹ́jẹ́ wọn ni wọ́n ń wa ọkọ̀ jáde kúrò lábúlé náà lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn olùgbé ibẹ̀ tó ti fìfẹ́ hàn sí ìjíròrò Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí baálẹ̀ náà kò lójú ti sọ, baálẹ̀ náà sọ pé, ká ní ọkùnrin ni wọ́n ni, ńṣe lòun ò bá jù wọ́n sẹ́wọ̀n.

Ohun tó wá dá wàhálà tuntun yìí sílẹ̀ ni òfin kan tí wọ́n gbé jáde ní abúlé náà, èyí tó dá lórí ọ̀ràn “Ọjà Títà àti Yíyajúlékiri.” Ohun téyìí ń béèrè ni pé kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ máa lọ láti ilé-dé-ilé kọ́kọ́ lọ gbàṣẹ, láìsan kọ́bọ̀, lọ́dọ̀ baálẹ̀ ná. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka òfin yìí sí títẹ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, òmìnira ìsìn, àti òmìnira ìwé títẹ̀ lójú. Nítorí náà, nígbà táwọn aláṣẹ abúlé náà kọ̀ láti ṣàtúnṣe sí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo òfin náà, àwọn Ẹlẹ́rìí gbé ọ̀ràn náà lọ sí ilé ẹjọ́ gíga.

Ní July 27, 1999, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ náà níwájú adájọ́ ilé ẹjọ́ kan ní àgbègbè Apá Ìhà Gúúsù ìpínlẹ̀ Ohio nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Adájọ́ náà ṣèdájọ́ pé àṣẹ tí abúlé náà pa bá òfin orílẹ̀-èdè mu. Lẹ́yìn náà, ní February 20, 2001, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó wà ní Wọ́ọ̀dù Kẹfà náà tún sọ pé àṣẹ tí abúlé náà pa bá òfin mu.

Láti yanjú ọ̀ràn ẹjọ́ náà, àjọ kan tí a fòfin gbé kalẹ̀ láti máa bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn Watchtower Bible and Tract Society of New York, pa pọ̀ pẹ̀lú Ìjọ Wellsville ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè Stratton bẹ̀bẹ̀ pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà tún ẹjọ́ náà gbọ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Los Angeles

New York

OHIO

Stratton