Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Sísọ Pàǹtírí Di Góòlù

Ilé iṣẹ́ ìwakùsà kan lórílẹ̀-èdè Japan ti rí ọ̀nà rírọrùn kan tó sì tún ń mú èrè gọbọi wọlé láti ṣàwárí àwọn mẹ́táàlì ṣíṣeyebíye. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn IHT Asahi Shimbun ti ìlú Tokyo sọ, dípò tí wọn ì bá fi máa lo ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n sì máa ná owó gọbọi lórí wíwá àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀, ohun tí ilé iṣẹ́ kan tó ń yọ́ mẹ́táàlì ní Àgbègbè Akita ń ṣe báyìí ni pé, wọ́n ń yọ́ àwọn tẹlifóònù alágbèérìn àti ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà táwọn èèyàn ń gbé sọ nù kí wọ́n lè yọ àwọn mẹ́táàlì ṣíṣeyebíye tó wà lára wọn. Alága ilé iṣẹ́ náà sọ pé, “Nǹkan bíi tọ́ọ̀nù kan tẹlifóònù alágbèérìn táwọn èèyàn gbé sọ nù—láìní bátìrì nínú—lè mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún gíráàmù góòlù jáde.” Bá a bá fi èyí wéra pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ ìwakùsà láti wa àwọn èròjà inú ilẹ̀ jáde, ohun téèyàn máa rí látinú “àwọn ohun ìbánisọ̀rọ̀ táwọn aráàlú ńlá ń gbé sọ nù” yìí lè fi bí ìlọ́po mẹ́wàá tọ́ọ̀nù ju èyí tá a lè rí látinú iṣẹ́ ìwakùsà lọ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, kò pọn dandan láti ná àfikún owó láti fi wá àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń yọ́ mẹ́táàlì, torí pé yíyọ́ góòlù ara tẹlifóònù alágbèérìn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí yíyọ́ mẹ́táàlì tó wà lára àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀.

Fífi Àwọn Ẹranko Llama Ṣọ́ Àwọn Àgùntàn

Ní báyìí o, àwọn àgbẹ̀ tó ń sin ẹran ní Àríwá Amẹ́ríkà ti ń lo ẹranko llama, èyí tó fara jọ ràkúnmí, láti máa fi ṣọ́ àwọn àgùntàn wọn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti ilẹ̀ Kánádà sọ, àwọn ẹranko llama “máa ń fẹ́ràn àwọn ẹranko mìíràn tí wọ́n bá jọ ń jẹ̀ pa pọ̀ gan-an.” Wọ́n kì í gba gbẹ̀rẹ́ rárá tó bá di pé kí wọ́n dáàbò bo agbo ẹran tí wọ́n ń ṣọ́ nípa kíkígbe ìkìlọ̀, dídarí àwọn àgùntàn gba ibòmíràn, lílé àwọn tó bá fẹ́ yọ wọ́n lẹ́nu dà nù, àti bíbá àwọn ẹranko mìíràn tó bá fẹ́ pa àwọn àgùntàn jẹ jà. Àwọn àgbẹ̀ kan tiẹ̀ fẹ́ràn ẹranko llama ju àwọn ajá ọdẹ lọ torí pé iye tí wọ́n ń tà wọ́n kéré gan-an sí iye tí wọ́n ń ta ajá. Láfikún sí i, ìwé ìròyìn náà sọ pé, “torí pé àwọn ẹranko llama máa ń jẹko tí wọ́n sì tún máa ń sùn pẹ̀lú àwọn àgùntàn, kò sí pé àwọn àgbẹ̀ tún ń ṣe ìnáwó àrà ọ̀tọ̀ láti bójú tó wọn—àti pé wọ́n tún máa ń pẹ́ láyé ju ọ̀pọ̀ àwọn ajá ọdẹ lọ.” Àgbẹ̀ kan tó ń sin àgùntàn lórílẹ̀-èdè Kánádà, tó sì ní àwọn ẹranko llama, sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní tí wọ́n ní, ó sọ pé: “Wọn kì í náni ní ohunkóhun,” bẹ́ẹ̀ ni “wọn kì í gbó bí ajá.”

Ṣíṣàwárí Èròjà Amúǹkantutù Yìn-Ìn

Àwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì ti ṣàwárí kẹ́míkà àdánidá kan tó lágbára láti mú nǹkan tutù yìn-ìn ní ìlọ́po márùndínlógójì ju èròjà menthol tó máa ń ta yẹ́ríyẹ́rí lọ, síbẹ̀ tí òun kì í ta bẹ́ẹ̀. Kẹ́míkà náà, tó máa ń wà nínú ọtí bíà àti ọtí whiskey, ni wọ́n ṣàwárí rẹ̀ ní Ibùdó Ìṣèwádìí Lórí Oúnjẹ Nílẹ̀ Jámánì, èyí tó wà lágbègbè Garching, nílùú Munich. Ìwé ìròyìn New Scientist fa ọ̀rọ̀ Thomas Hofmann tó jẹ́ alága àwùjọ olùṣèwádìí náà yọ, nígbà tó sọ pé: “Ó lè mú kí ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn ilé iṣẹ́ ń mú jáde máa tutù yìn-ìn lẹ́nu, irú bí ọtí bíà, omi inú ike, àwọn nǹkan mímu olómi ọsàn, ṣokoléètì àti àwọn ìpápánu.” Bákan náà, nítorí pé èròjà náà máa ń mú kí ara tutù yìn-ìn béèyàn bá fi para, fífi ìwọ̀nba rẹ̀ sínú àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe nǹkan ìpara àti òróró ìṣaralóge á mú kí wọ́n túbọ̀ dára sí i.

Ajílẹ̀ Ń Fa Àwọn Kòkòrò Àrùn Tí Kì Í Gbóògùn

Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé, “àpọ̀jù oògùn tó ń gbógun ti àrùn tí wọ́n ń fún àwọn ẹran ọ̀sìn ń ṣàkóbá fún àwọn oko ọ̀gbìn jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù.” Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tọ́ọ̀nù oògùn agbóguntàrùn tí wọ́n máa ń fún àwọn ẹran ọ̀sìn lọ́dọọdún ní ilẹ̀ Yúróòpù àti ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti mú kí wọ́n dàgbà àti láti dènà àrùn. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, “àmọ́, àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé, bí wọ́n ṣe ń lo àwọn oògùn agbóguntàrùn fún àwọn ẹran ọ̀sìn lọ́pọ̀ yanturu ló ń ṣokùnfà bí àwọn àrùn tí kì í gbóògùn ṣe ń ran àwọn èèyàn.” Ìwé ìròyìn New Scientist ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé, “àwọn oògùn náà, èyí tí wọ́n máa ń lú mọ́ ìgbẹ́ ẹran tí wọ́n ń fọ́n sórí oko ọ̀gbìn bí ajílẹ̀, lè máa wọnú oúnjẹ àti omi wa . . . , [wọ́n sì] máa ń wà nínú àwọn irè oko, èyí táwọn èèyàn á wá jẹ lẹ́yìn náà.”

“Gbígba” Àwọn Òbí Àgbà “Sílé”

Ìwé ìròyìn El País ti ilẹ̀ Sípéènì ròyìn pé, àwọn ìdílé kan lórílẹ̀-èdè Sípéènì ti ṣètò láti “gba” àwọn àgbàlagbà mẹ́rìndínláàádọ́rin tí kò ní ẹbí tàbí ará èyíkéyìí “sílé.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ìdí tí wọ́n fi gbé ètò yìí kalẹ̀ ni . . . láti fún àwọn àgbàlagbà tí kò bá lè dá gbé mọ́ láǹfààní láti gbé ibòmíràn yàtọ̀ sí ilé àwọn arúgbó.” Lára àwọn tó kọ̀wé ránṣẹ́ pé àwọn fẹ́ láti gba àwọn arúgbó sílé káwọn sì máa bójú tó wọn ni àwọn tọkọtaya tí wọ́n wà láàárín àádọ́ta ọdún sí ọgọ́ta ọdún, tí wọ́n fẹ́ kí àwọn àgbàlagbà wà pẹ̀lú àwọn. Àwọn ìdílé mìíràn tí wọ́n láwọn ọmọ kéékèèké sọ pé àwọn fẹ́ láti ní òbí àgbà kan nílé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílé tó ń gba àwọn àgbàlagbà tira máa ń gba owó àjẹmọ́nú látọ̀dọ̀ ìjọba, Marisa Muñoz-Caballero tó jẹ́ alága gbogbo gbòò fún ètò náà ṣàlàyé pé, “kì í ṣe owó yẹn gan-an lohun tó ń sún wọn ṣe é. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kò ní pẹ́ rárá tó fi máa sú wọn torí pé bíbójútó àwọn àgbàlagbà kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá.”

Ìwà Ipá Inú Ilé Nílẹ̀ Yúróòpù

Anna Diamantopoulou, alábòójútó ètò ìgbanisíṣẹ́ àti ọ̀ràn tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ nílẹ̀ Yúróòpù, sọ pé, “ìdá kan nínú márùn-ún àwọn obìnrin nílẹ̀ Yúróòpù ni ọkọ wọn máa ń hùwà ipá sí ní àkókò kan nínú ìgbésí ayé wọn.” Níbi Àpérò Ìjọba Lórí Híhùwà Ipá sí Àwọn Obìnrin, èyí tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Sípéènì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2002, Diamantopoulou sọ pé: “Kárí ayé, àwọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógójì ló ṣeé ṣe kí wọ́n di aláàbọ̀ ara tàbí kí wọ́n kú nítorí ìwà ipá táwọn ọkùnrin hù sí wọn, ju kí wọ́n di aláàbọ̀ ara tàbí kí wọ́n kú nítorí àwọn nǹkan bí àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ibà, jàǹbá ọkọ̀ tàbí ogun lọ, bí a bá pa ìwọ̀nyí pọ̀.” Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, “obìnrin kan máa ń kú ní gbogbo ọjọ́ mẹ́ta-mẹ́ta nítorí ìwà ipá inú ilé,” nígbà tó jẹ́ pé “ní ilẹ̀ Ireland, ohun tó lé ní ìdajì àwọn obìnrin tí wọ́n ń ṣekú pa níbẹ̀ ló jẹ́ pé àtọwọ́ àwọn ọkọ wọn ló ti ń wá.” Ìwé ìròyìn Le Monde ti ilẹ̀ Faransé sọ pé, ní ilẹ̀ Austria “ìdajì gbogbo ẹjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ ló máa ń dá lórí àròyé tí àwọn ìyàwó máa ń ṣe pé àwọn ọkọ wọn ń hùwàkiwà sí wọn.”

Dídènà Bí Àwọn Ọmọdé Ṣe Ń Kú Sómi

Ìwé ìròyìn BMJ (èyí tó ń jẹ́ British Medical Journal tẹ́lẹ̀) sọ pé, nínú àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tó lọ́rọ̀ jù lọ lágbàáyé, kíkú sómi ni ohun kejì tó sábà máa ń fa ikú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ títí dórí àwọn tí ọjọ́ orí wọn tó ọdún mẹ́rìnlá. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn náà sọ, “àwọn ìkókó ló ṣeé ṣe jù lọ kí wọ́n kú sínú omi tó wà nínú ilé (lọ́pọ̀ ìgbà èyí máa ń jẹ́ nínú ọpọ́n ìwẹ̀); àwọn ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ ló sì ṣeé ṣe jù pé kí wọ́n kú sínú omi tó sún mọ́ etílé, irú bí odò ìlúwẹ̀ẹ́ tàbí odò kékeré kan; àwọn ọmọdé tí wọ́n ti dàgbà díẹ̀ sì lè kú sínú àwọn omi tó pọ̀ díẹ̀, irú bí adágún omi tàbí odò.” Láti dènà irú àwọn jàǹbá bẹ́ẹ̀, àwọn ògbógi dámọ̀ràn àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí: Máa rí i pé ìgbà gbogbo ni ẹnì kan ń mójú tó àwọn ìkókó tí wọ́n bá wà nínú ọpọ́n ìwẹ̀ tàbí létí omi èyíkéyìí; rí i pé o ṣe ọgbà tó lágbára yí ká odò kékeré tó wà nínú ọgbà rẹ tàbí odò ìlúwẹ̀ẹ́, èyí tí kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọdé láti gba inú ilé débẹ̀; má ṣe fàyè gba àwọn ọmọdé láti dá nìkan lúwẹ̀ẹ́ tàbí láti lọ wẹ̀ ní ibi tó jẹ́ àdádó; lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe lè mú kí ẹni tó mu omi yó jí sáyé.

Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Yára Bàlágà

Ìwé ìròyìn Berliner Zeitung ti ilẹ̀ Jámánì sọ pé, “ńṣe ni ọjọ́ orí táwọn ọ̀dọ́ ti ń bàlágà túbọ̀ ń yára wálẹ̀ sí i.” Kò yani lẹ́nu mọ́ láti rí i pé ìgbà ọmọdé kì í pẹ́ dópin mọ́, ó kéré tán nínú ara, nígbà tí àwọn ọmọdé ṣì wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́wàá sí méjìlá tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ pàápàá. Àwọn olùṣèwádìí kárí ayé ti kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀dí abájọ. Wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, báwọn èwe ṣe ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore ju ti ìgbà àtijọ́ lọ àti bí àwọn àrùn tó ń gbèèràn ṣe ń dín kù ló ń fà á. Àwọn mìíràn sọ pé àwọn èròjà onímájèlé tó wà nínú atẹ́gùn ló ń fà á, àgàgà àwọn kẹ́míkà tó máa ń ṣiṣẹ́ bíi ti àwọn èròjà inú ẹ̀jẹ̀ obìnrin. Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ okùnfà rẹ̀, bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń yára bàlágà lè mú kí wọ́n tètè máa ní ìbálòpọ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, “lọ́pọ̀ ìgbà, ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló máa ń wà láàárín ìgbà ọmọdé àti ìgbà téèyàn á fi kọ́kọ́ ní ìbálòpọ̀.”

Ìbínú Lè Ṣekú Pa Ọ

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Sípéènì tó ń jẹ́ Diario Médico sọ pé, “ó rọrùn gan-an pé kí àwọn èèyàn tó ń bínú ní àrùn ẹ̀gbà.” Ọjọ́ pẹ́ táwọn dókítà ti máa ń sọ pé jíjẹ́ oníbìínú èèyàn máa ń mú kí ewu níní àìsàn ọkàn-àyà pọ̀ sí i. Àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí ti wá fi hàn pé irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ tún lè mú kéèyàn ní àrùn ẹ̀gbà. Nígbà tí wọ́n ṣèwádìí àwọn àgbàlagbà tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá, àbájáde ìwádìí náà fi hàn pé ewu níní àrùn ẹ̀gbà lọ sókè tó ìlọ́po mẹ́ta fún àwọn oníbìínú èèyàn tí wọn kò tíì pé ọmọ ọgọ́ta ọdún. Kí nìdí? Ìròyìn náà sọ pé, ó dà bíi pé ìbínú lè mú kí ìwọ̀n ìfúnpá “lọ sókè gan-an,” kí òpójẹ̀ máa sún kì, àti kí àwọn èròjà tó ń mú ẹ̀jẹ̀ dá máà máa ṣiṣẹ́ dáadáa, èyí tó jẹ́ pé “bí àkókò ṣe ń lọ, ó lè ṣàkóbá fún bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń ṣàn nínú ọpọlọ.”