Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀rín Músẹ́ Dáa fún Ara

Ẹ̀rín Músẹ́ Dáa fún Ara

Ẹ̀rín Músẹ́ Dáa fún Ara

BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé wẹ́rẹ́ báyìí náà ni, tí kì í sì í pẹ́, ó ṣeé ṣe kó o má gbàgbé rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ohun náà níye lórí gidigidi, àmọ́ kò sẹ́ni tó tòṣì débi pé kò lè ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn bẹ́ẹ̀ sì ni kò sẹ́ni tó lọ́rọ̀ débi pé kò nílò rẹ̀. Kí lohun tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gan-an? Ẹ̀rín músẹ́ ni.

Ẹ̀rín músẹ́ lèèyàn ń rín nígbà tí iṣu ẹ̀rẹ̀kẹ́ bá gbéra sókè, tójú ẹni sì ṣe rekete láti fi hàn pé inú ẹni yọ́ sí ohun kan. Níwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí a bí ọmọ kan ni ọmọ ọwọ́ náà ti máa ń mọ bá a ti í rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì dájú pé èyí máa ń múnú àwọn òbí rẹ̀ dùn. Ńṣe ni ẹ̀rín músẹ́ àwọn ọmọdé yìí máa ń wá fúnra rẹ̀. Àwọn ògbógi ṣàlàyé pé irú ẹ̀rín músẹ́ tó ń ṣàdédé wá bẹ́ẹ̀ sábà máa ń wáyé nígbà téèyàn bá ń lálàá, ó sì dà bíi pé ó máa ń wáyé nítorí àwọn ohun tó ń rò lọ́kàn àti ọ̀nà tí ìgbékalẹ̀ iṣan ara rẹ ń gbà ṣiṣẹ́. Kódà lẹ́yìn tá a ti dàgbà pàápàá, ẹ̀rín músẹ́ tó ń ṣàdédé wá yìí ṣì lè wáyé lẹ́yìn tá a bá jẹun tán tàbí nígbà tá a bá ń fetí sí orin.

Àmọ́ ṣá o, láti nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà sókè, ọmọ ọwọ́ kan máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà tó bá wo ojú ẹnì kan tàbí tó bá gbọ́ ohùn ẹnì kan. ‘Ẹ̀rín músẹ́ tá à ń rín sáwọn ẹlòmíràn’—èyí tá à ń fúnra wa rín—máa ń mú kára wa yá gágá, yálà a jẹ́ ọmọ ọwọ́ tàbí àgbàlagbà. Àwọn ògbógi sọ pé irú ẹ̀rín tá à ń rín sáwọn ẹlòmíràn bẹ́ẹ̀ máa ń nípa rere lórí ìlera wa. Àwọn oníṣègùn kan nípa ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ tí orúkọ wọn ń jẹ́ Mirtha Mannoàti RubénDelauro, tí wọ́n jẹ́ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n pè ní Ẹ̀rín Músẹ́ àti Ìlera, sọ pé wíwulẹ̀ rẹ́rìn-ín músẹ́ máa ń mú àwọn èròjà kan jáde nínú ọpọlọ tó máa ń nípa lórí ẹṣẹ́ pituitary. Ẹṣẹ́ pituitary yìí ló máa ń mú kí àwọn èròjà endorphin sun jáde nínú ọpọlọ, èyí tó jẹ́ èròjà kan tó máa ń mú inú èèyàn dùn.

Ìdí pàtàkì mìíràn tí ẹ̀rín músẹ́ fi ṣe pàtàkì ni pé ó máa ń ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní. Ojúlówó ẹ̀rín músẹ́ máa ń jẹ́ káwọn ẹlòmíràn mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa láìsí pé a sọ̀rọ̀ jáde, yálà ẹ̀rín músẹ́ náà jẹ́ ti ìkíni, ti ìbánikẹ́dùn, tàbí ti fífúnni-níṣìírí. Àní nígbà míì pàápàá, wíwo ojú ọmọ kékeré kan tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nínú fọ́tò lè dẹ́rìn-ín pa àwa náà.

Nígbà tí ẹnì kan bá rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wa, ó máa ń jẹ́ kára túbọ̀ tù wá, ó sì máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti túbọ̀ kojú ìjákulẹ̀ tàbí ìṣòro. Bíbélì dámọ̀ràn pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀rín músẹ́ kò náni ní ohunkóhun, àmọ́ ó lè ṣe àwa àtàwọn ẹlòmíràn láǹfààní. O ò ṣe gbìyànjú láti máa fọ̀yàyà rẹ́rìn-ín músẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn? Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ ni o!