Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Burú Jáì”

“Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Burú Jáì”

“Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Burú Jáì”

ỌMỌ ọdún mẹ́rìnlá péré ni Maria a nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ìyá rẹ̀ ló tì í sínú ìgbésí ayé játijàti yìí, nítorí pé ìgbà gbogbo ló máa ń sọ fún un pé ó rẹwà àti pé àwọn ọkùnrin á fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Ìyá rẹ̀ tún máa ń sọ fún un pé, owó kékeré kọ́ ló máa rí nínú iṣẹ́ yìí. Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ìyá Maria á mú un lọ sí òtẹ́ẹ̀lì kékeré kan níbi tí wọ́n ti ń pàdé àwọn ọkùnrin. Ìyá rẹ̀ á wá dúró sí tòsí ibẹ̀ láti gba owó tí wọ́n bá san fún un. Lálaalẹ́, ọkùnrin mẹ́ta tàbí mẹ́rin ló máa ń bá Maria lò pọ̀.

Ọmọbìnrin mìíràn wà nítòsí ilé àwọn Maria tó ń jẹ́ Carina, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni nígbà tí wọ́n fipá ti òun náà sínú iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé tó ń ṣiṣẹ́ lóko ìrèké lágbègbè rẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ sí òun náà. Ńṣe ni ìdílé Carina ń ta ara ọmọbìnrin yìí láti rí owó kún owó táṣẹ́rẹ́ tó ń wọlé fún wọn. Lágbègbè mìíràn, Estela kéré gan-an lọ́jọ́ orí nígbà tó fi iléèwé sílẹ̀, kò mọ̀ ọ́n kọ bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n kà, àmọ́ ó di ọmọ asùnta tó ń ṣe aṣẹ́wó. Bẹ́ẹ̀ náà ni Daisy, ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin bá a lò pọ̀—ìyẹn sì làkọ́kọ́ nínú àìmọye irú ìwà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n hù sí i. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ó di aṣẹ́wó.

Ní ọ̀pọ̀ ibi lágbàáyé, káwọn ọmọdé máa gbégbá iṣẹ́ aṣẹ́wó ti di àṣà tó gbòde, ó sì ń bani nínú jẹ́. Àwọn àbájáde rẹ̀ máa ń burú jáì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó yìí, ì báà jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí tí wọ́n mú un lójú páálí, tún máa ń lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn wọ́n sì máa ń lo oògùn olóró. Ọ̀pọ̀ wọn layé máa ń sú tí wọ́n á sì máa wo ara wọn pé àwọn kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì tún máa ń wò ó pé kò dájú pé àwọn á bọ́ nínú ìgbésí ayé játijàti tí àwọ́n ń gbé.

Àwọn tó jẹ́ abẹnugan láwùjọ mọ àwọn àbájáde bíburú jáì tó ń wá látinú káwọn ọmọdé máa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ ni Fernando Henrique Cardoso, tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Brazil nígbà kan rí, ṣe sọ ọ́ pé: “Ìwà ìbàjẹ́ tó burú jáì ni kí ọmọdé máa ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.” Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil kan tẹ ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí jáde nípa bí àwọn ọmọdé ṣe ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó, ó sọ pé: “Láwọn orílẹ̀-èdè tí irú àṣà yìí wọ́pọ̀ sí, tí wọ́n gbà á láyè, àní tí wọ́n tiẹ̀ fọwọ́ sí i pàápàá látàrí [owó] tí wọ́n ń rí níbẹ̀, ojoojúmọ́ làwọn fúnra wọn ń rí ìbànújẹ́ tó ń tìdí rẹ̀ jáde. Bópẹ́bóyá, owó èyíkéyìí tí wọ́n ti lè rí nínú àṣà yìí kì í jẹ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àjálù tó máa ń mú bá ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìdílé, àti àwùjọ.”

Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó fẹ́ fòpin sí àṣà kí ọmọdé máa ṣíṣẹ́ aṣẹ́wó ní èrò tó dára lọ́kàn, kàkà kí ewé àgbọn dẹ̀, líle ló ń le sí i ni ọ̀ràn ìṣòro yìí. Kí ló ń ṣokùnfà ìṣòro tó burú jáì yìí ná? Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi fàyè gba irú ìwà ọ̀daràn yìí, tí wọ́n tiẹ̀ tún fi ń gbé e lárugẹ pàápàá?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tá a lò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí kókó yìí padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

“Ìwà ìbàjẹ́ tó burú jáì ni kí ọmọdé máa ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.”—ÀÀRẸ ORÍLẸ̀-ÈDÈ BRAZIL NÍGBÀ KAN RÍ, FERNANDO HENRIQUE CARDOSO

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Gbogbo irú ọ̀nà yòówù kí wọ́n máa gbà lo èèyàn fún ìwà ìṣekúṣe ni kò buyì kúnni, nítorí náà, ó lòdì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, láìka ọjọ́ orí sí, ẹ̀yà akọ tàbí abo tí ẹni náà lè jẹ́, ìṣẹ̀dálẹ̀ tẹ́ni ọ̀hún ti wá, tàbí ipò rẹ̀ láwùjọ.”UNESCO SOURCES