Atẹ́gùn Ló Gbé E Wá
Atẹ́gùn Ló Gbé E Wá
Ọkùnrin kan ń rìn lọ lójú títì ní ìlú Mumbai, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, latẹ́gùn líle kan bá gbé ìwé ìléwọ́ kan wá síbi ẹsẹ̀ rẹ̀. Ìwé ìléwọ́ náà ni Ìròyìn Ìjọba No. 36, tó ní àkọlé náà, “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?” Àkọlé yẹn gba àfiyèsí rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló mú un nílẹ̀, tó sì kà á tán látòkèdélẹ̀. Ohun tó kà wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, èyí ló fà á tó fi béèrè fún Bíbélì àtàwọn ìwé mìíràn.
Ìwé ìléwọ́ náà, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, kún fún àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun. Ó ṣàlàyé ní kedere pé, àwọn ìṣòro tí à ń kojú, títí kan àìsàn, àìríná-àìrílò, àti ogun, ń wáyé nítorí “ìwọra, àìgbẹ́kẹ̀léni, àti ìmọtara-ẹni-nìkan, èyí tó jẹ́ àwọn ìwà tí ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ti ìmọ̀ ẹ̀rọ, tàbí ti ìṣèlú kò lè mú kúrò.” Ìwé ìléwọ́ náà tún fi hàn pé láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
Ṣé wàá fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí Bíbélì fún ọjọ́ iwájú? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn, nípa lílo àwọn ìwé tá a gbé ka Bíbélì, irú bí ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ìwé pẹlẹbẹ yìí dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Ta ni Ọlọ́run? Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo ni Bíbélì ṣe lè mú kí ìdílé rẹ láyọ̀ sí i?
Bó o bá fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé rẹ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, inú wọn yóò dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n yóò sì fún ọ ní ìsọfúnni síwájú sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run. Jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí wọ́n bàa lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.