Kí Ló Burú Nínú Jíjíwèé Wò?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Burú Nínú Jíjíwèé Wò?
“Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé jíjíwèé wò burú, ṣùgbọ́n òun ló rọrùn jù.”—Jimmy ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ló sọ bẹ́ẹ̀.
ǸJẸ́ o ti garùn wo iṣẹ́ ọmọ kíláàsì ẹlẹgbẹ́ rẹ kan rí nígbà tẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdánwò? Bó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí, mọ̀ pé kì í ṣe ìwọ nìkan nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Jenna, akẹ́kọ̀ọ́ kan tó wà ní kíláàsì tó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, ṣàlàyé bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ṣe máa ń jíwèé wò láìfibò rárá. Ó sọ pé: “Wọ́n máa ń fọ́nnu nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe é. Sùẹ̀gbẹ̀ ni wọ́n máa ń pe ẹni tí kì í bá wọn jíwèé wò!”
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba tó máa ń mókè ní kíláàsì ni wọ́n sọ pé àwọn máa ń jíwèé wò, nígbà tó jẹ́ pé, ìdá márùn-dín-lọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń “gbégbá orókè” wọ̀nyí ni ọwọ́ kì í tẹ̀. Lẹ́yìn tí Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ìlànà Ìwà Híhù ti Josephson ṣe ìwádìí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí iye wọ́n lé ní ọ̀kẹ́ kan [20,000], wọ́n jábọ̀ pé: “Bá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà àìlábòsí àti ìwà títọ́, nǹkan ti bà jẹ́ jìnnà.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn olùkọ́ láti rí bí àṣà jíjíwèé wò nínú ìdánwò ṣe gbilẹ̀ tó! Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń jẹ́ Gary J. Niels tiẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé: “Ṣàṣà làwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kì í jíwèé wò, iye wọn kéré jọjọ.”
Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn ṣe gudugudu méje nínú àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ wọn. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, jíjíwèé wò ti sọ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ di aláìṣòótọ́. Àwọn ọ̀nà tuntun wo ni wọ́n ń gbà ṣe é? Kí nìdí táwọn ọ̀dọ́ kan fi máa ń jíwèé wò? Kí nìdí tó sì fi yẹ kó o yẹra fún àṣà yìí?
Àwọn Ọ̀nà Ìgbàlódé Tí Wọ́n Ń Gbà Jíwèé Wò
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà àrékérekè làwọn tó ń jíwèé wò lóde òní máa ń gbà. Ní tòótọ́, jíjíwèé wò nípa ṣíṣe àdàkọ iṣẹ́ àṣetiléwá tí ẹnì kan ti ṣe tàbí kíkọ ìdáhùn sílẹ̀ fún lílò lásìkò ìdánwò kò jẹ́ bàbàrà mọ́ bá a bá fi wé àwọn ọ̀nà ìgbàlódé táwọn èèyàn ń gbà jíwèé wò lónìí. Lára ohun tí wọ́n ń lò láti fi hùwà ìrẹ́jẹ nínú ìdánwò ni ẹ̀rọ àfipeni (pager), èyí tí wọ́n máa ń fi gba ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó jáde nínú ìdánwò látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó wà lọ́nà jíjìn; ẹ̀rọ ìṣèṣirò tí wọ́n ti ṣe ètò “àkànṣe” sínú rẹ̀; kámẹ́rà pẹnpẹ tí wọ́n ń fi sábẹ́ aṣọ, èyí tí wọ́n máa ń lò láti fi ìbéèrè ránṣẹ́ sí olùrànlọ́wọ́ kan tó wà níbòmíràn; ẹ̀rọ ìṣèṣirò tó lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn nínú kíláàsì kan náà; kódà, àwọn ibì kan wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì téèyàn ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó máa jáde nínú àwọn ìdánwò iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ fún sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ kan!
Àwọn olùkọ́ ń ṣakitiyan láti dáwọ́ àṣà jíjíwèé wò tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i yìí dúró, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Ó ṣe tán, kì í ṣe gbogbo akẹ́kọ̀ọ́—tàbí gbogbo olùkọ́—ló ní èrò kan náà nípa ohun tí jíjíwèé wò túmọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwùjọ àwọn
akẹ́kọ̀ọ́ kan bá jọ ń ṣe iṣẹ́ kan, kì í fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn tó ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ náà àti àwọn tó ń ṣe awúrúju nídìí iṣẹ́ ọ̀hún. Àwọn kan sì wà tó máa fẹ́ lo àǹfààní pé wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti jẹ́ kí àwọn mìíràn forí fá gbogbo ohun tó wà nídìí iṣẹ́ náà. Ọ̀dọ́langba kan tó ń jẹ́ Yuji, tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga kan tó jẹ́ ti ìjọba, sọ pé: “Ọ̀lẹ paraku ni àwọn kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí—wọn kì í ṣe ohunkóhun rárá! Máàkì kan náà ni wọ́n á sì tún gbà pẹ̀lú àwọn tó fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́. Lójú tèmi, ìrẹ́jẹ ni!”Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Jíwèé Wò?
Ìwádìí kan fi hàn pé, àìsí ìmúrasílẹ̀ ni olórí ìdí tí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ fi máa ń jíwèé wò. Ní tàwọn mìíràn sì rèé, ẹ̀mí ìbára-ẹni-díje tó wọ́pọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí bí àwọn òbí wọn ṣe máa ń fínná mọ́ wọn láti gba máàkì púpọ̀ ló máa ń mú kí wọ́n jíwèé wò. Sam ọmọ ọdún mẹ́tàlá sọ pé: “Gbígba máàkì púpọ̀ lohun tó ṣe pàtàkì jù lójú àwọn òbí mi. Wọ́n á máa bi mí pé: ‘Kí lo gbà nínú ìdánwò ìṣirò tó o ṣe? Kí lo gbà nínú ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì tó o ṣe?’ Ìyẹn máa ń bí mi nínú gan-an ni!”
Ní tàwọn kan, ìfẹ́ láti gba máàkì tó dára jù lọ lọ́nàkọnà ló máa ń sún wọn dédìí jíjíwèé wò. Ìwé The Private Life of the American Teenager sọ pé: “Kì í ṣe ohun tó bójú mu rárá pé, dípò káwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa rí ìgbádùn tó wà nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́, eré àtigbégbá orókè ṣáá ni wọ́n máa ń sá, tí èyí sì máa ń sún wọn hùwà àìṣòótọ́ nígbà míì.” Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló gbà bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó fẹ́ kóun fìdí rẹmi nínú ìdánwò, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ nínú gbogbo iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ lápapọ̀. Jimmy, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan, sọ pé: “Ẹ̀rù máa ń ba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan gan-an pé àwọn máa fìdí rẹmi. Kódà bí wọ́n bá mọ àwọn ìdáhùn ọ̀hún, wọ́n á ṣì rí i pé àwọn jíwèé wò láti lè rí i dájú pé ìdáhùn tó tọ̀nà làwọ́n kọ sílẹ̀.”
Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣe ń jíwèé wò láìbìkítà nípa àwọn ìlànà òdodo lè mú kó dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú àṣà yìí. Kódà, nígbà míì pàápàá, ó tiẹ̀ lè dà bíi pé òun ló ṣàǹfààní jù. Greg ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Lánàá, mo rí akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń jíwèé wò nígbà tá à ń ṣe ìdánwò kan ní kíláàsì. Àmọ́ nígbà tá a gba èsì ìdánwò wa lónìí, ó gba máàkì tó pọ̀ ju tèmi lọ.” Bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ojúgbà wọn ṣe ń jíwèé wò máa ń nípa lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan. Yuji sọ pé: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan máa ń rò pé ‘bí àwọn ẹlòmíràn bá ń ṣe é, èmi náà lè ṣe é.’” Ṣùgbọ́n ṣé òótọ́ nìyẹn?
Àṣà Bárakú Tí Ń Tanni Jẹ
Fi àṣà jíjíwèé wò wéra pẹ̀lú olè jíjà. Ǹjẹ́ a lè sọ pé olè jíjà bójú mu torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń jalè? O lè dáhùn pé, ‘kò bójú mu,’ pàápàá bó bá jẹ́ owó rẹ ni ẹnì kan jí! Nípa jíjíwèé wò, ńṣe là ń gba ògo fún ohun kan tí kò tọ́ sí wa—àfàìmọ̀ kó máà tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe là ń rẹ́ àwọn tó fi òótọ́ inú ṣiṣẹ́ wọn jẹ. (Éfésù 4:28) Tommy, ọ̀dọ́ kan tó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga lẹ́nu àìpẹ́ yìí, sọ pé: “Kò tiẹ̀ dáa rárá ni. Ò ń sọ pé, ‘Mo mọ iṣẹ́ yìí,’ nígbà tó ò mọ nǹkan kan rárá nípa rẹ̀. Nítorí náà, irọ́ lò ń pa.” Ojú tí Bíbélì fi wo ọ̀ràn yìí fara hàn kedere nínú Kólósè 3:9: “Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”
Jíjíwèé wò lè di àṣà bárakú kan tó máa ṣòro láti fi sílẹ̀. Jenna sọ pé: “Àwọn tó ń jíwèé wò máa ń rò pé kò pọn dandan kí àwọn kàwé láti yege nínú ìdánwò, torí náà wọ́n á kúkú dara dé jíjíwèé wò. Àmọ́, nígbà tí wọ́n bá ti wá dá wà láyè ara wọn, wọn ò ní lè dá nǹkankan ṣe yọrí.”
Ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:7 gba ìrònújinlẹ̀ gidigidi, ó sọ pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Lára àwọn ohun tó lè jẹ́ àbájáde jíjíwèé wò nílé ẹ̀kọ́ ni pé, ẹ̀rí ọkàn á máa dá ọ lẹ́bi, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ò ní fọkàn tán ọ mọ́, àti pé kíkẹ́kọ̀ọ́ á wá ṣòro fún ọ nítorí pé kò mọ́ ọ lára. Bí àrùn jẹjẹrẹ ṣe ń di egbò kíkẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àṣà tó gbòde kan yìí ṣe lè nípa lórí gbogbo ohun tó ò ń ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ, ó sì lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó o nífẹ̀ẹ́ gan-an jẹ́. Kò sí àní-àní pé, yóò nípa lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹni tó kórìíra ẹ̀tàn.—Òwe 11:1.
Òwe 12:19) Nípa ìwà wọn, wọ́n ń fara wé àwọn olùṣàkóso oníwà ìbàjẹ́ tó wà ní ìlú Jerúsálẹ́mù ìgbàanì, àwọn tí wọ́n ń sọ pé: “A ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa, inú èké sì ni a fi ara wa pa mọ́ sí.” (Aísáyà 28:15) Àmọ́, ká sòótọ́, ẹni tó ń jíwèé wò kò lè fi àwọn ìwà rẹ̀ pa mọ́ fún Ọlọ́run.—Hébérù 4:13.
Ńṣe làwọn tó ń dara dé jíjíwèé wò kàn ń tan ara wọn jẹ. (Má Ṣe Jíwèé Wò O!
Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀pọ̀ ìsapá làwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe, wọ́n sì máa ń lo ọgbọ́n láti fi jíwèé wò—èyí tó jẹ́ pé wọn ì bá ti lò dáadáa fún kíkẹ́kọ̀ọ́ láìṣàbòsí. Abby, ọmọ ọdún méjìdínlógún sọ pé: “Ká ní wọ́n lè gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ kíkọ́ bí wọ́n ṣe ń gbájú mọ́ jíjíwèé wò ni, ó dájú pé wọ́n á ṣe dáadáa gan-an nínú ìdánwò.”
Òótọ́ ni pé, ìfẹ́ láti jíwèé wò lágbára gan-an. Ṣùgbọ́n o gbọ́dọ̀ yàgò fún ìwà ìbàjẹ́ yìí! (Òwe 2:10-15) Báwo lo ṣe lè ṣe é? Lákọ̀ọ́kọ́, rántí ìdí tó o fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́—ìyẹn ni láti kẹ́kọ̀ọ́. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí àǹfààní kankan nínú kíkọ́ onírúurú ẹ̀kọ́ tó lè máà wúlò fún ọ rárá lẹ́yìnwá ọ̀la. Ṣùgbọ́n bó o bá ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú tó ò ń jíwèé wò, o ò ní lè lo ọpọlọ rẹ fún kíkọ́ àwọn ohun tuntun, o ò sì ní lè fi ìmọ̀ tó o ní ṣiṣẹ́ yọrí. Kò ṣeé ṣe láti ní òye ohun kan lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láìṣe ìsapá èyíkéyìí; èèyàn ní láti ṣe nǹkan kan kí ọwọ́ tó lè tẹ̀ ẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ra òtítọ́, má sì tà á-ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.” (Òwe 23:23) Bẹ́ẹ̀ ni o, o ní láti fi ojú pàtàkì wo ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti ìmúrasílẹ̀. Jimmy dámọ̀ràn pé: “O gbọ́dọ̀ kàwé ṣáájú ìdánwò. Èyí á fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ pé o mọ ìdáhùn.”
Lóòótọ́ o, nígbà míì, o lè má mọ gbogbo ìdáhùn, èyí sì lè mú kí máàkì rẹ lọ sílẹ̀. Síbẹ̀, bí o kò bá hùwà àìṣòótọ́, o ṣeé ṣe kó o rí ohun tó yẹ kó o ṣe láti tẹ̀ síwájú.—Òwe 21:5.
Yuji, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣe bí àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bá ń rọ̀ ọ́ pé kó jẹ́ káwọn jí iṣẹ́ rẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná—màá wulẹ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ìyẹn ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an nítorí wọ́n mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Bí ẹnikẹ́ni bá sọ pé kí n sọ ìdáhùn fún òun nígbà tá à ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́, ń kì í dáhùn. Ìgbà tá a bá wá ṣe tán ni màá tó ṣàlàyé ìdí tí èmi kì í fi í ṣe bẹ́ẹ̀.”
Yuji gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Hébérù pé: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Fífi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ìwà títọ́ ní gbogbo ìgbà àti kíkọ̀ láti hùwà àìṣòótọ́ yóò mú kí máàkì púpọ̀ tó o gbà túbọ̀ jẹ́ ojúlówó. Wàá mú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn dídára jù lọ tó o lè fún àwọn òbí rẹ wá láti ilé ẹ̀kọ́, ìyẹn ni ẹ̀rí ìwà títọ́ Kristẹni. (3 Jòhánù 4) Láfikún sí i, wàá ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́, wàá sì máa láyọ̀ pé ò ń mú ọkàn Jèhófà Ọlọ́run yọ̀.—Òwe 27:11.
Nítorí náà, láìka bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe lè máa jíwèé wò sí, yàgò fún un! Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti pé, ní pàtàkì jù lọ, wàá ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́.—Sáàmù 11:7; 31:5.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]
Ẹni tó ń jíwèé wò kì í sábà mọ̀ pé olè ni òun ń jà
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]
Jíjíwèé wò sábà máa ń yọrí sí àwọn ìwà àìṣòótọ́ bíburú jáì mìíràn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Ẹni tó ń jíwèé wò kò lè fi ìwà rẹ̀ pa mọ́ fún Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Kíkàwé dáadáa ṣáájú ìdánwò yóò mú kí ọkàn rẹ balẹ̀