Kí Ló Dé Tí Ìṣòro Yìí Fi Ń peléke Sí I?
Kí Ló Dé Tí Ìṣòro Yìí Fi Ń peléke Sí I?
ǸJẸ́ o mọ̀ pé ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn èèyàn ló wà nípò kẹta nínú ìwà ọ̀daràn tó tóbi jù lọ lágbàáyé, títa oògùn olóró àtàwọn ohun ìjà ogun nìkan ló ta á yọ? Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ, ńṣe ni iṣẹ́ aṣẹ́wó lónírúurú túbọ̀ ń peléke sí i.
Ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí fún Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀-èdè náà ròyìn pé, ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ka iṣẹ́ náà léèwọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà.
Ní orílẹ̀-èdè mìíràn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000] ọmọdé ló ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó lẹ́gbẹ̀ẹ́
títì, àgàgà láwọn àgbègbè tí wọ́n ti máa ń ta oògùn olóró.Láwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan àwọn ọmọdébìnrin la gbọ́ pé wọ́n ń lò fún iṣẹ́ aṣẹ́wó, bí ẹrú ni wọ́n sì ṣe ń lò wọ́n. Àwọn ilẹ̀ kan tiẹ̀ wà tá a mọ̀ bí ẹní mowó fún lílo ọmọdé fún iṣẹ́ aṣẹ́wó tí àwọn èèyàn sì máa ń rìnrìn àjò afẹ́ lọ síbẹ̀ nítorí ìbálòpọ̀.
Nítorí bí àwọn àrùn tí wọ́n ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, irú bí àrùn éèdì, àwọn oníbàárà máa ń gbà láti san owó gọbọi lórí àwọn ọmọdé tí wọ́n wò pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì jẹ́ wúńdíá nítorí kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ àkóràn. Luíza Nagib Eluf, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Nítorí ìbẹ̀rù kíkó àrùn éèdì, àwọn ọmọbìnrin àtàwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn kéré gan-an làwọn ọkùnrin ń wá báyìí, èyí sì ti mú kí ìṣòro náà burú sí i.” Obìnrin náà sọ pé: “Lílo àwọn ọmọdébìnrin àtàwọn ọ̀dọ́ tí ò tí ì pé ọmọ ogún ọdún fún ìbálòpọ̀ ni ìṣòro tó tíì burú jù lọ tó ń kojú àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ akúùṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Brazil.”
Àiríná-àìrílò Máa Ń Mú Kí Àwọn Ọmọdé Ṣiṣẹ́ Aṣẹ́wó
Ibi tí òṣì àti àre bá pọ̀ sí làwọn ọmọdé tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó máa ń pọ̀ sí jù. Gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba kan ṣe sọ, ṣíṣe àwọn ọmọdé níṣekúṣe àti lílò wọ́n fún iṣẹ́ aṣẹ́wó ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ “ni ẹ̀rí fi hàn gbangba pé kò ṣẹ̀yìn bí ìdílé ṣe ń tú ká, èyí sì jẹ́ àbájáde ìṣẹ́ àti ebi.” Àwọn òbí kan sọ pé ìṣẹ́ ló mú kí àwọn máa ta ọmọ àwọn sínú iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ohun tó sì ń mú àwọn ọmọ tó jẹ́ asùnta ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ni pé, wọ́n wò ó pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwọn fi lè rí oúnjẹ òòjọ́ nìyẹn.
Ìwé ìròyìn O Estado de S. Paulo ṣàlàyé pé, ọmọbìnrin kan lè di aṣẹ́wó tó bá ń bá ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta rìn. Kó bàa lè rí oúnjẹ jẹ, ó lè máa jalè kó sì máa ta ara rẹ̀ fáwọn ọkùnrin lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, nígbà tó bá yá, yóò di ọ̀gá nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó.
Nígbà míì, wọ́n máa ń rán àwọn ọ̀dọ́langba lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé UNESCO Sources sọ pé: “Owó tí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó nílẹ̀ òkèèrè bá fi ránṣẹ́ sí àwọn ará ilé sábà máa ń jọ wọ́n lójú gan-an nítorí ìṣẹ́ tó ń ṣẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Áfíríkà àti Éṣíà. Wọ́n tún máa ń fọwọ́ sí ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, nítorí pé àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń dìídì wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tó rí já jẹ torí àtiwá gbádùn ‘ọjà’ táwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ọmọdé ń tà.”
Nígbà tí ìwé ìròyìn Time ń sọ̀rọ̀ nípa ewu táwọn ọmọ asùnta tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ní ìlú ńlá kan nílẹ̀ Látìn
Amẹ́ríkà fi ara wọn sínú rẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn kan lára àwọn aṣẹ́wó náà kò ju ọmọ ọdún méjìlá lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń jẹ́ àwọn ọmọ tó wá látinú ìdílé tó ti tú ká, tí wọ́n á máa sùn níbikíbi tí wọ́n bá rí lọ́sàn-án, tó bá wá di alẹ́, wọ́n á gba ilé dísíkò lọ, níbi tí àwọn atukọ̀ ojú omi ti máa ń ṣe fàájì.”Nígbà tí ọmọ kan tó jẹ́ aṣẹ́wó bá ti joògùn yó kẹ́ri, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ara rẹ̀ fún oríṣiríṣi ìwà pálapàla, tó jẹ́ pé, ká ní kì í ṣe ti oògùn tó ti jẹ yó ni, òun fúnra rẹ̀ kò jẹ́ fara mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Veja ti sọ, àwọn ọlọ́pàá rí kásẹ́ẹ̀tì fídíò méjìléláàádọ́rùn-ún kan, èyí tí dókítà kan ká ìsọfúnni sínú rẹ̀ nípa bó ṣe dá àwọn obìnrin tó lé ní àádọ́ta lóró lóríṣiríṣi ọ̀nà tó kọjá àfẹnusọ, ọjọ́ orí àwọn kan nínú wọn sì kéré gan-an.
Láìka bí àṣà yìí ṣe burú jáì tó sí, ohun tí
ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó sọ ni pé: “Bí mo bá lọ wáṣẹ́, owó tí màá rí kò lè tó mi jẹun nítorí pé mi ò mọ iṣẹ́ kankan. Àwọn aráalé mi mọ̀ nípa ohun tí mò ń ṣe yìí, mi ò sì fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀. Èmi ni mo ni ara mi, bó bá sì ṣe wù mí ni mo ṣe lè lò ó.”Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tó ń ṣe iṣẹ́ yìí kò gbàdúrà pé iṣẹ́ aṣẹ́wó ni kí àwọn ṣe láyé àwọn. Gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan ti sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ aṣẹ́wó “ló fẹ́ ṣègbéyàwó,” ó sì wù wọ́n pé kí àwọn náà ní “Olùfẹ́ Àtàtà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro ńláǹlà ló sọ wọ́n dẹni tó ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó nígbèésí ayé wọn, olùṣèwádìí kan sọ pé: “Ohun tó bani lẹ́rù jù níbẹ̀ ni pé, èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ pé inú ilé wọn gangan ni wọ́n ti fipá bá wọn lò pọ̀.”
Ṣé Òpin Lè Dé Bá Iṣẹ́ Aṣẹ́wó Tí Àwọn Ọmọdé Ń Ṣe?
Bí ó ti wù kó rí, ìrètí kò ṣàì sí fún àwọn ọmọ tó ti kàgbákò yìí o. Àwọn aṣẹ́wó, lọ́mọdé àti lágbà, ti yí ìgbésí ayé wọn padà. (Wo àpótí náà, “Àwọn Èèyàn Lè Yí Padà,” ní ojú ìwé 7.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí í ṣe Bíbélì, ti ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé láti di aládùúgbò rere àti mẹ́ńbà ìdílé tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. A kà nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ti jẹ́ alágbèrè, panṣágà, olè, olójúkòkòrò, àti ọ̀mùtípara nígbà kan rí pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Lónìí, gẹ́gẹ́ bó ti rí lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, à ń rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń yí ìgbésí ayé wọn padà sí dáradára. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì yẹ ní ṣíṣe láti lè dáwọ́ lílo àwọn èèyàn fún ìbálòpọ̀ dúró. Àwọn ìjọba kan àtàwọn oríṣiríṣi àjọ ń jà fitafita láti fòpin sí àṣà lílo àwọn ọmọdé fún iṣẹ́ aṣẹ́wó àti káwọn èèyàn máa rìnrìn àjò afẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí ìbálòpọ̀. Àmọ́, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ìwọ̀nba làwọn èèyàn lè ṣe láti mú òṣì àti àre kúrò. Àwọn tó ń ṣòfin kò lè ṣe nǹkan kan sí ìrònú àti ìṣesí tó jẹ́ gbòǹgbò ìwà pálapàla.
Àmọ́ o, dípò kó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìsapá èèyàn ni gbogbo àwọn ìṣòro yìí fi máa yanjú, ọ̀nà àbáyọ mìíràn wà—ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Àìríná-àìrílò ló sábà máa ń mú kí àwọn ọmọdé máa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Kì Í Ṣe Ohun Kékeré Ló Ná An
Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni Daisy nígbà tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ̀ bá a lò pọ̀. Èyí ló mú kó lọ máa gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin títí tó fi pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó sì lọ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ilé ìgbafàájì alaalẹ́ kan. Kò ju ọjọ́ mélòó kan lọ tí Daisy débẹ̀ tí àìsàn dá a wólẹ̀. Nígbà tára rẹ̀ yá, àwọn tó ni ilé ìgbafàájì náà sọ iye gbèsè tó jẹ wọ́n, wọ́n sì fipá mú un láti máa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, kò tíì bọ́ nínú gbèsè, ó sì dà bí ẹni pé bóyá ló lè bọ́ láéláé. Àmọ́ o, awakọ̀ ojú omi kan bá a san ìyókù gbèsè náà ó sì mú un lọ sí ìlú mìíràn, níbi tó ti ń lò ó nílò ẹrú. Ni Daisy bá fi sílẹ̀, lẹ́yìn náà ló lọ gbé pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn fún ọdún mẹ́ta, ẹ̀yìn èyí ni wọ́n sì ṣègbéyàwó. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Daisy gbìyànjú láti pa ara rẹ̀ nítorí àwọn ìṣòro kàǹkàkàǹkà tó ń rí nínú ìgbéyàwó náà.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, òun àti ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ Daisy máa ń wo ara rẹ̀ pé irú òun kọ́ ló ń di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí wọ́n fi hàn án nínú Bíbélì pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn tó bá ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún un. Daisy sapá gidigidi láti ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ kò gbà pé òún tíì ṣe é tó, nípa bẹ́ẹ̀, ó máa ń ní ìdààmú ọkàn tó pọ̀ gan-an. Àmọ́, nǹkan ayọ̀ ló jẹ́ pé, ó tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fún un láti borí ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń ní látàrí bí wọ́n ti ṣe fi ìbálòpọ̀ fìtínà rẹ̀ àti ìgbésí ayé aṣẹ́wó tó ti gbé sẹ́yìn, ó wá ṣeé ṣe fún un láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Èèyàn Lè Yí Padà
Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, àánú àwọn èèyàn tí wọ́n ti pọ́n lójú, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe é. Ó mọ̀ pé àwọn aṣẹ́wó, láìka ọjọ́ orí wọn sí, lè yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn padà. Jésù tiẹ̀ sọ fún àwọn tó jẹ́ aṣáájú ìsìn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó ń lọ sínú ìjọba Ọlọ́run ṣáájú yín.” (Mátíù 21:31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú burúkú làwọn èèyàn fi ń wò wọ́n nítorí irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé, irú àwọn ọlọ́kàn títọ́ bẹ́ẹ̀ rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọmọ Ọlọ́run. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà múra tán láti jáwọ́ nínú ìgbésí ayé aṣẹ́wó tí wọ́n ń gbé kí wọ́n bàa lè gba àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n wá ń gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, onírúurú àwọn èèyàn ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì ń yí ìgbésí ayé wọn padà.
Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Maria, Carina, àti Estela yẹ̀ wò, tá a dárúkọ wọn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́. Yàtọ̀ sí pé Maria kọ̀ jálẹ̀ fún ìyá rẹ̀ pé òun ò ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó mọ́, ó tún ní láti ṣe ìsapá àrà ọ̀tọ̀ láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Ó sọ pé: “Mo máa ń lo oògùn olóró láti fi pa ìrònú àìjámọ́ nǹkan kan tí mo máa ń ní rẹ́ nítorí ìgbésí ayé aṣẹ́wó tí mò ń gbé.” Maria sọ nípa bí ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tẹ́wọ́ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, ó ní: “Ìfẹ́ tí àwọn tó wà nínú ìjọ náà fi hàn sí mi wú mi lórí gan-an ni. Gbogbo wọn pátá—lọ́mọdé àti lágbà—ló fi ọ̀wọ̀ hàn sí mi. Mo ṣàkíyèsí pé àwọn ọkùnrin tó ti ṣègbéyàwó kì í dalẹ̀ àwọn ìyàwó wọn. Inú mi dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ pé wọ́n gbà mí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ wọn.”
Nígbà tí Carina wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì ń bá iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe lọ fún sáà kan. Díẹ̀díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì bí àwọn òtítọ́ Bíbélì ṣe ṣeyebíye tó. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pinnu láti kó lọ sí ìlú kan tó jìnnà síbi tó ń gbé, ibẹ̀ ló sì ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Estela, ẹni tó jẹ́ pé kékeré ló ti gbégbá aṣẹ́wó, tó máa ń lọ sí òde àríyá, tó sì máa ń mu ọtí nímukúmu pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn sí Bíbélì. Àmọ́, ó máa ń rò ó lọ́kàn pé Ọlọ́run kò lè dárí ji òun láé. Bó ti wù kó rí, bí àkókò ti ń lọ, ó wá lóye pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Ní báyìí tí Estela ti di ara ìjọ Kristẹni, tó ti ṣègbéyàwó, tó sì ń tọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta, ó sọ pé: “Inú mi dùn gan-an mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe yọ mí jáde nínú ìgbésí ayé ẹlẹ́gbin tí mò ń gbé tó sì tẹ́wọ́ gbà mí sínú ètò àjọ rẹ̀ mímọ́.”
Àwọn ìrírí wọ̀nyí jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn [àtọkùnrin àtobìnrin] là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ọmọdé tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó sábà máa ń lo oògùn olóró
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
© Fọ́tò Jan Banning/Panos, 1997