Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Lóye Ọ̀ràn Dáadáa Kó o Tó Gbà á Gbọ́

Máa Lóye Ọ̀ràn Dáadáa Kó o Tó Gbà á Gbọ́

Máa Lóye Ọ̀ràn Dáadáa Kó o Tó Gbà á Gbọ́

Níní òye tó pé nípa oríṣiríṣi ọ̀ràn kì í ṣe ohun tó rọrùn. Àwọn ìjọba àtàwọn ilé iṣẹ́ máa ń lú irọ́ mọ́ òtítọ́. Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn sábà máa ń ṣèlérí pé ìròyìn tó pé pérépéré làwọ́n á máa gbé jáde, àmọ́ wọn kì í tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ wọn. Àwọn dókítà kì í fìgbà gbogbo ṣàlàyé àwọn ìṣòro tí àwọn oògùn tí wọ́n ń fún àwọn aláìsàn lè mú wá. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà tá a fi lè rí ìsọfúnni tó ṣeé fọkàn tán?

Nígbà tí Íńtánẹ́ẹ̀tì kọ́kọ́ dé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kókìkí rẹ̀ pé ó jẹ́ ohun kan tá a lè lò láti rí ìsọfúnni tó ṣeé fọkàn tán gbà láti ibikíbi lágbàáyé. Ní tòótọ́, èyí ṣeé ṣe bó o bá mọ ibi tó yẹ kó o wò fún ìsọfúnni tó ṣeé gbara lé. Ọ̀rọ̀ olótùú inú ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Íńtánẹ́ẹ̀tì ní ibi tó dára sí, nítorí ó lè kọ́ àìmọye èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kíákíá ju bí ohunkóhun mìíràn tó ń gbé ìròyìn jáde ṣe lè ṣe lọ. Àmọ́ ó tún ní ibi tó burú sí, nítorí ó lè mú kí orí àwọn èèyàn dọ́ta kíákíá ju bí ohunkóhun mìíràn tó ń gbé ìròyìn jáde ṣe lè ṣe lọ.”

Ọ̀rọ̀ olótùú náà ń bá a lọ pé: “Nítorí pé Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ ‘ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ’ kan tó ṣì ń jọ àwọn èèyàn lójú, èyí ló mú kí àwọn tí kò dákan mọ̀ máa gba gbogbo ohun tó bá ti gbé jáde gbọ́. Wọn ò mọ̀ pé, níbi tí Íńtánẹ́ẹ̀tì burú bògìrì sí, kò yàtọ̀ sí kòtò ẹ̀gbin: ìyẹn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ kan tó jẹ́ pé ibẹ̀ ni orísun àwọn ìsọfúnni tí wọn ò ṣàyẹ̀wò wọn tí wọn ò sì sẹ́ àwọn ohun ẹlẹ́gbin inú wọn kúrò.” Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé náà ti sọ, ó dunni pé kò sí ọgbọ́n kankan tí wọ́n fi lè mú àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀gbin inú rẹ̀ kúrò.

Ẹnikẹ́ni ló lè kọ ohunkóhun sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, sínú ìwé ìròyìn, tàbí sínú ìwé èyíkéyìí. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa lo òye ká sì kọ́ ara wa dáadáa, ká má bàa máa gba gbogbo ohun tá a bá ṣáà ti kà gbọ́ láìronú jinlẹ̀. Àwa tá a bá ń fẹ́ ìsọfúnni tó jẹ́ òótọ́ ní láti rí i dájú pé ibi tó ṣeé gbára lé la yíjú sí. Èyí lè gba àkókò. Àmọ́ lẹ́yìn tá a bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ tá a sì wá ní òye tó túbọ̀ pé, ìrònú wa á di èyí tó já gaara sí i, a óò máa fi ojú tó tọ́ wo nǹkan, ọkàn wa á sì balẹ̀ nígbà tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.