Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Àwọn Kan Ń Ṣọ́ Ọ?

Ǹjẹ́ Àwọn Kan Ń Ṣọ́ Ọ?

Ǹjẹ́ Àwọn Kan Ń Ṣọ́ Ọ?

OJOOJÚMỌ́ ni kámẹ́rà kan máa ń ṣọ́ Elizabeth ní ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan láti mọ gbogbo ohun tó ń ṣe. Gbàrà tó bá ti dá ẹsẹ̀ lé ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ibi iṣẹ́ rẹ̀ báyìí ni ojú rẹ̀ á ṣe kòńgẹ́ kámẹ́rà kan. Ní gbogbo àkókò tó bá sì fi wà níbi iṣẹ́ ni àìmọye kámẹ́rà mìíràn ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì. Bí wọ́n ṣe ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ yìí ò gbọ́dọ̀ máà rí bẹ́ẹ̀ torí pé owó tí ilé iṣẹ́ tó ti ń ṣíṣẹ́ ń bójú tó lójúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan wọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù dọ́là.

Elizabeth mọ̀ pé wọn ò lè ṣàì máà ṣọ́ òun lójú méjèèjì níbi iṣẹ́; wọ́n kúkú ti ṣàlàyé èyí fún un yékéyéké kó tó gba iṣẹ́ náà. Àmọ́ ṣá o, nǹkan ò rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, nítorí pé wọn ò kì í mọ̀ nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun tí wọ́n fi ń ṣọ́ wọn lójoojúmọ́.

Gbígbé Nínú Àwùjọ Tí Wọ́n Ti Ń Ṣọ́ni

Ǹjẹ́ wọ́n máa ń ṣọ́ ọ níbi iṣẹ́? Kárí ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òṣìṣẹ́ làwọn kan ń ṣọ́ lemọ́lemọ́ láti kíyè sí bí wọ́n ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì àti bí wọ́n ṣe ń fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ránṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́. Ìwádìí ọlọ́dọọdún kan, tó wá látọ̀dọ̀ Ẹ̀ka Tó Wà fún Ìwádìí Nípa Iṣẹ́ Ṣíṣe Nílẹ̀ Amẹ́ríkà fún Ọdún 2001, fi hàn pé “nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà . . . ló ń ṣàkọsílẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò gbogbo ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àti ìgbòkègbodò àwọn òṣìṣẹ́ wọn lẹ́nu iṣẹ́, títí kan ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá sọ lórí tẹlifóònù, ohun tó wà nínú lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà wọn, bí wọ́n ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, àti irú ìsọfúnni tó wà nínú kọ̀ǹpútà wọn.”

Owó gegere ni ìjọba ń ná sórí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣọ́ni. Ìròyìn kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Yúróòpù ní July 11, 2001, sọ lápá ìparí rẹ̀ pé “ètò kan wà kárí ayé tí wọ́n fi ń dábùú ìsọfúnni, èyí tí wọ́n gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ . . . tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Kánádà, Ọsirélíà, àti New Zealand.” Ìròyìn náà fi hàn pé nípa lílo ẹ̀rọ tó ń tàtaré ìsọfúnni kárí ayé, tí wọ́n ń pè ní ECHELON, ó ṣeé ṣe fún àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè wọ̀nyí láti dábùú gbogbo ìsọfúnni tí ẹ̀rọ sátẹ́láìtì ń fi ránṣẹ́ kí wọ̀n sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀, irú bíi ti tẹlifóònù, ẹ̀rọ tí ń fi àdàkọ ìsọfúnni ránṣẹ́, Íńtánẹ́ẹ̀tì, àti lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà. Ìwé ìròyìn The Australian sọ pé bí ìjọba bá lo ètò ẹ̀rọ yìí, “wọ́n á lè fi ṣàṣàyàn àwọn ìsọfúnni pàtó kan nínú ẹ̀rọ tí ń fi àdàkọ ìsọfúnni ránṣẹ́ àti lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà, bí wọ́n bá sì ti ṣètò ẹ̀rọ náà láti dá ohùn ẹnì kan pàtó mọ̀, èyí yóò mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dá ohùn ẹni náà mọ̀ nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù.”

Bákan náà, àwọn agbófinró gbọ́kàn lé àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó wà fún ṣíṣọ́ àwọn èèyàn. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìwé ìròyìn BusinessWeek sọ pé ilé iṣẹ́ FBI [Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀] máa ń lo ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ kan tí wọ́n ń pè ní Carnivore, èyí tí wọ́n máa ń fi “ṣàyẹ̀wò lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà, àwọn ìsọfúnni tó ń fara hàn lójú kọ̀ǹpútà, àti ìkésíni orí tẹlifóònù.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn BBC News ṣe sọ, ní báyìí, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ṣe òfin tuntun kan tí yóò fún àwọn agbófinró láǹfààní láti máa “ṣọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọ́n bá ń lo tẹlifóònù, ẹ̀rọ tí ń fi àdàkọ ìsọfúnni ránṣẹ́ àti Íńtánẹ́ẹ̀tì.”

Àwọn Kámẹ́rà Tó Wà Níkọ̀kọ̀ àti Àkójọ Ìsọfúnni Inú Kọ̀ǹpútà

Kódà nígbà téèyàn ò bá fi tẹlifóònù, ẹ̀rọ tí ń fi àdàkọ ìsọfúnni ránṣẹ́, tàbí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ pàápàá, wọ́n ṣì lè máa ṣọ́ ọ. Ní ìpínlẹ̀ New South Wales lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ààbọ̀ [5,500] kámẹ́rà tó ń ṣọ́ àwọn tó ń wọ ọkọ̀ ojú irin. Ní ìpínlẹ̀ yẹn kan náà, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tó jẹ́ ti ìjọba ni wọ́n tún fi àwọn kámẹ́rà tó ń ṣọ́ àwọn èèyàn sí nínú.

Níbàámu pẹ̀lú ìwádìí kan, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ní àwọn kámẹ́rà tó ń ṣọ́ni jù lọ lágbàáyé, nítorí pé tá a bá fi iye tí wọ́n ní wéra pẹ̀lú àwọn olùgbé ibẹ̀, kámẹ́rà kan ló ń ṣọ́ èèyàn márùndínlọ́gọ́ta. Lọ́dún 1996, àwọn ìlú kékeré tàbí ìlú ńlá mẹ́rìnléláàádọ́rin nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ní àwọn kámẹ́rà tó ń ṣọ́ àwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí. Nígbà tó fi máa di ọdún 1999, àwọn ìlú kékeré àtàwọn ìlú ńlá tí iye wọn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ló ti ní irú àwọn kámẹ́rà bẹ́ẹ̀. Wọ́n ti ń ṣe àwọn ètò tuntun kan sórí kọ̀ǹpútà tó máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn kámẹ́rà tó ń ṣọ́ni, kó lè ṣeé ṣe fún àwọn kámẹ́rà náà láti lè máa fi ojú ẹnì kan pàtó hàn, kódà bó bá wà láàárín ògìdìgbó èèyàn ní pápákọ̀ òfuurufú tàbí ní gbàgede ńlá kan táwọn èèyàn pọ̀ sí.

Láyé òde òní, wọ́n lè máa ṣọ́ gbogbo ohun tó ò ń ṣe níkọ̀kọ̀ láìjẹ́ pé o mọ̀. Simon Davies, alága ẹgbẹ́ kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìyẹn Privacy International, sọ pé: “Kò tíì sí ìgbà kankan nínú ìtàn tí àjọ kan tàbí ìjọba èyíkéyìí tíì mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni nípa gbogbo èèyàn lápapọ̀ bíi ti òde òní. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni lórí owó tó ń wọlé fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àgbàlagbà tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà àti bí wọ́n ṣe ń náwó ló wà nínú nǹkan bí irínwó ètò orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n fi ń ṣàkójọ ìsọfúnni—àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí sì pọ̀ tó láti kún inú ìwé atọ́ka ńlá kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”

Kí làwọn ìgbésẹ̀ tó o lè gbé láti pa àṣírí rẹ mọ́?