Ǹjẹ́ Ẹ̀ṣẹ̀ kan Wà Tí Kò ní Ìdáríjì?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ẹ̀ṣẹ̀ kan Wà Tí Kò ní Ìdáríjì?
ǸJẸ́ ìjìyà kan wà tó tún le ju ikú lọ? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìyẹn ni ikú tí kò ní ìrètí àjíǹde nítorí pé ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Jésù sọ pé irú ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí “a kì yóò dárí [rẹ̀] jini.”—Mátíù 12:31.
Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni tó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè máa di èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn sínú kí wọ́n sì kọ̀ láti dárí jini, Ọlọ́run máa ń “dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 55:7-9) Ká sòótọ́, nǹkan bàǹtàbanta ni Ọlọ́run fi du ara rẹ̀ nípa rírán Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ wá sí ayé láti jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù fún wa, tàbí láti dá wa sílẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, èyí tó níye lórí débi pé, ó lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́.—Jòhánù 3:16, 17; Ìṣe 3:19; 1 Jòhánù 2:1, 2.
Nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, yóò jí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo dìde, àmọ́ tí wọn kò ní jíhìn mọ́ fún àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. (Ìṣe 24:15; Róòmù 6:23) Ní tòótọ́, Jésù sọ pé “gbogbo onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a óò dárí [rẹ̀ jini],” àyàfi ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. (Mátíù 12:31) Nígbà náà, o lè máa rò ó pé, ‘Ẹ̀ṣẹ̀ wo ló lè burú burú débi pé Ọlọ́run kò ní dárí rẹ̀ jini?’
Mímọ̀ọ́mọ̀ Dẹ́ṣẹ̀ Láìronúpìwàdà
Ohun tí ìkìlọ̀ Jésù ń tọ́ka sí ni mímọ̀ọ́mọ̀ sọ “ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí.” Kò sí ìtúsílẹ̀ fún irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí. Ó fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí tàbí nínú èyí tí ń bọ̀.” (Mátíù 12:31, 32) Kò ní í sí àjíǹde fún àwọn tó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn.
Kí ni ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí? Inú ọkàn ló ti ń wá, ó sì ń fi ìṣarasíhùwà bíburú jáì àti ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kan hàn. Mímọ̀ọ́mọ̀ ní in lọ́kàn láti ṣòdì sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí di èyí tó túbọ̀ wúwo gan-an. Àpẹẹrẹ kan rè é: Láwọn apá ibì kan láyé, òfin máa ń fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ẹ̀sùn ìpànìyàn tó ń wáyé. Ọ̀kan wà tí wọ́n ń pè ní ìpele kìíní àti òmíràn tí wọ́n ń pè ní ìpele kejì, ó sinmi lórí ohun tó sún ọ̀daràn náà pànìyàn àti ọ̀nà tó gbà pa ẹni náà, ìyà ikú ni wọ́n sì máa ń fi jẹ ẹni tó bá ti wéwèé ìpànìyàn tẹ́lẹ̀ tàbí tó mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì nígbà kan rí àmọ́ ó sọ pé: “A fi àánú hàn sí mi, nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan.” (1 Tímótì 1:13) Láti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ túmọ̀ sí mímọ̀ọ́mọ̀ ta kò ó. Ó tún túmọ̀ sí níní ọkàn búburú, èyí tó ti mú kí ẹnì kan bá a débi tí kò lè yí padà mọ́.
Ó dájú pé irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó kọ̀wé pé: “Kò ṣeé ṣe ní ti àwọn tí a ti là lóye lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti ọ̀run wò, tí wọ́n ti di alábàápín nínú ẹ̀mí mímọ́, tí wọ́n sì ti tọ́ àtàtà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn agbára ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀ wò, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti yẹsẹ̀, láti tún mú wọn sọ jí sí ìrònúpìwàdà.” (Hébérù 6:4-6) Àpọ́sítélì náà tún sọ pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.”—Hébérù 10:26.
Ìwà tí àwọn aṣáájú ìsìn kan lọ́jọ́ Jésù ń hù ló mú kí Jésù ṣe ìkìlọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Àmọ́ wọn kò ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ rẹ̀ náà. Kódà, wọ́n rí i dájú pé àwọ́n pa á. Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n fetí ara wọn gbọ́ ọ pé ẹ̀mí mímọ́ ti ṣe ohun ìyanu kan. Wọ́n sọ fún wọn pé a ti jí Jésù dìde kúrò nínú òkú! Ó hàn gbangba pé Jésù ni Kristi náà! Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣe ohun búburú sí ẹ̀mí mímọ́ nípa fífún àwọn ọmọ ogun Róòmù lówó pé kí wọ́n parọ́ pé Jésù kò jí dìde.—Mátíù 28:11-15.
Ìkìlọ̀ fún Àwọn Kristẹni Tòótọ́
Ìdí wo làwọn Kristẹni tòótọ́ ò ṣe gbọ́dọ̀ fojú kéré ìkìlọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì? Nítorí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run tí a sì mọ àwọn ohun tí ẹ̀mí rẹ̀ ń jẹ́ kó ṣeé ṣe, ọkàn búburú ṣì lè dìde nínú wa. (Hébérù 3:12) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má fi àṣìṣe ronú pé èyí kò lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Júdásì Ísíkáríótù yẹ̀ wò. Olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni tẹ́lẹ̀. Ó wà lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá tí Jésù yàn, nípa bẹ́ẹ̀ ó ti ní láti ní àwọn ànímọ́ dídára nígbà kan rí. Àmọ́ nígbà tó tó àkókò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ kí èrò òdì gbilẹ̀ nínú ọkàn òun, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn èròkerò náà borí rẹ̀. Ní gbogbo àkókò tó ń fojú ara rẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ ìyanu kíkàmàmà tí Jésù ń ṣe, ó ń jí owó. Lẹ́yìn náà, nítorí owó, ó mọ̀ọ́mọ̀ fi Ọmọ Ọlọ́run hàn.
Àwọn èèyàn kan tí wọ́n ti jẹ́ Kristẹni olóòótọ́ nígbà kan rí ti mọ̀ọ́mọ̀ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bóyá nítorí ìbínú, ìgbéraga, tàbí ìwọra, wọ́n sì ti di apẹ̀yìndà tó ń ta ko ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run báyìí. Wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣòdì sí àwọn ohun tí ẹ̀mí mímọ́ ń mú kó ṣeé ṣe. Ǹjẹ́ àwọn ẹni wọ̀nyí ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì? Jèhófà nìkan ni Onídàájọ́ ọ̀ràn náà.—Róòmù 14:12.
Dípò tí a óò fi máa ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn, ńṣe ló yẹ kí àwa fúnra wa máa ṣọ́ra fún dídá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ tó lè mú kí ọkàn wa máa yigbì díẹ̀díẹ̀. (Éfésù 4:30) A sì láyọ̀ láti mọ̀ pé, Jèhófà yóò dárí jì wá lọ́pọ̀lọpọ̀, kódà bí a bá ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo gan-an pàápàá, ìyẹn bí a bá ronú pìwà dà.—Aísáyà 1:18, 19.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Àwọn Farisí kan dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì