Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 13. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Ibo ni Mósè àti Áárónì wà nígbà tí wọ́n kùnà láti bọlá fún Jèhófà, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí? (Númérì 20:12, 13)
2. Àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí wo ni wọ́n jí àwọn màlúù àtàwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jóòbù tí wọ́n sì tún pa àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀? (Jóòbù 1:14, 15)
3. Èwo nínú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n fún ní orúkọ náà, Méṣákì, nígbà tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Bábílónì? (Dáníẹ́lì 1:7)
4. Èso ẹ̀mí wo ni a dárúkọ kété lẹ́yìn ìfẹ́? (Gálátíà 5:22)
5. Ibo ni áńgẹ́lì alágbára náà sọ “òkúta kan tí ó dà bí ọlọ ńlá” sí, láti ṣàpẹẹrẹ bí ìparun Bábílónì Ńlá ṣe máa yára kánkán? (Ìṣípayá 18:21)
6. Àwọn ẹ̀bùn wo ni Géhásì fi ẹ̀tàn béèrè lọ́wọ́ Náámánì lórúkọ Èlíṣà? (2 Ọba 5:22)
7. Ọba Ámórì wo ló kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn la àárín ilẹ̀ ọba rẹ̀ kọjá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ṣèlérí pé àwọn kò ní fọwọ́ kan ohunkóhun níbẹ̀, kódà omi pàápàá àwọn kò ní í mu? (Númérì 21:21-23)
8. Ta ló ta hòrò Mákípẹ́là fún Ábúráhámù láti lò ó fún ibi ìsìnkú Sárà? (Jẹ́nẹ́sísì 23:8-10)
9. Níbàámu pẹ̀lú Òwe 29:25, ìṣòro wo ló máa ń jẹ yọ látinú “wíwárìrì nítorí ènìyàn,” báwo la sì ṣe lè yàgò fún èyí?
10. Èso ẹ̀mí Ọlọ́run wo la dárúkọ ṣìkẹta? (Gálátíà 5:22)
11. Ìgbésẹ̀ wo ni Fíníhásì gbé tó dùn mọ́ Jèhófà nínú tó sì fòpin sí òjòjò àrànkálẹ̀ tó pa egbèjìlá [24,000] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Númérì 25:6-14)
12. Báàfù, káàbù, kọ́ọ̀, éèfà, hínì, hómérì, lọ́ọ̀gì, ómérì àti séà, gbogbo wọn jẹ́ kí ni? (Ẹ́kísódù 16:32)
13. Àwọn ohun wo ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn “nǹkan pípọndandan” nígbà tí wọ́n ń kọ lẹ́tà sí àwọn arákùnrin ní ìlú Áńtíókù, Síríà, àti Sìlíṣíà? (Ìṣe 15:28, 29)
14. Kí nìdí tí ọbabìnrin Ṣébà fi rìnrìn àjò gígùn lọ sí Jerúsálẹ́mù? (1 Àwọn Ọba 10:4)
15. Kí lohun pàtàkì kan tó so mọ́ gbogbo àpéjọpọ̀ mímọ́ tí Jèhófà sọ pé kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ṣe? (Léfítíkù 23:7)
16. Èwo ló kúrú jù nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin?
17. Nígbà tí àwọn èrò rọ́ dé láti wá fi àṣẹ ọba mú Jésù, ta ni Pétérù fi idà gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọ nù? (Jòhánù 18:10)
18. Àwọn èdè mẹ́ta wo la fi kọ Bíbélì níbẹ̀rẹ̀? (Ẹ́sírà 4:7; Ìṣípayá 9:11)
19. Àwọn èèyàn wo la mọ̀ tí wọ́n sábà máa ń rìn kiri, tí wọ́n máa ń gbé nínú àgọ́, tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ darandaran ni wọ́n ń ṣe? (Jeremáyà 3:2)
20. Kí nìdí tí a fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti má ṣe kárúgbìn eteetí pápá oko wọn? (Léfítíkù 19:9, 10)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Ní ibi omi Mẹ́ríbà
2. Àwọn Sábéà
3. Míṣáẹ́lì
4. Ìdùnnú
5. Inú òkun
6. .“Tálẹ́ńtì fàdákà kan àti ìpààrọ̀ ẹ̀wù méjì”
7. Síhónì
8. Éfúrónì ọmọ Hétì
9. Ó ń dẹ ìdẹkùn. Nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà
10. Àlàáfíà
11. Ó pa Símírì, ìjòyè kan tó jẹ́ ẹ̀ya Síméónì àti ọmọbìnrin Mídíánì tí Símírì mú wá sínú àgọ́ rẹ̀ láti bá a ṣe àgbèrè
12. Òṣùwọ̀n
13. “Láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa àti sí àgbèrè”
14. Láti “wá rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì”
15. Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe òpò èyíkéyìí
16. Máàkù
17. Málíkọ́sì, ẹrú àlùfáà àgbà
18. Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì
19. Àwọn ará Arébíà
20. Láti lè fi ọkà díẹ̀ sílẹ̀ “fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àtìpó”