Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rí I Pé Ò Ń Sùn Dáadáa!

Rí I Pé Ò Ń Sùn Dáadáa!

Rí I Pé Ò Ń Sùn Dáadáa!

Ǹjẹ́ a lè rí ẹni tí kò ní gbà pé sísùn dáadáa lóru ṣe kókó láti ní ìlera tó jí pépé? Bóyá la fi lè rẹ́ni tí kò ní í gbà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ka oorun sí nǹkan pàtàkì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Shawn Currie, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá ní Yunifásítì Calgary, lórílẹ̀-èdè Kánádà, sọ pé: “Síbẹ̀ wàá rí àbájáde rẹ̀ lọ́jọ́ kejì.” Bí o kì í bá sùn tó bó ṣe yẹ lóru, ó ṣeé ṣe kí o máa kanra, àní kó o tiẹ̀ tún máa ní ìdààmú ọkàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pàápàá.

Ìwé ìròyìn Calgary Herald sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì méfò pé oorun máa ń mú kí ọpọlọ jí pépé, àti pé ọpọlọ ṣì ń ṣiṣẹ́ nígbà téèyàn bá ń sùn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Currie sọ pé: “Lóru, ńṣe lèèyàn ń fún agbára ìrántí rẹ̀ lókun, ìgbà yẹn sì ni ohunkóhun téèyàn bá kọ́ lójúmọmọ á ríbi jókòó dáadáa nínú ọpọlọ. Àìsí àkókò ìsinmi yìí máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ ṣòro gan-⁠an ni.” Láfikún sí i, ó sọ pé “bó o bá ń sùn dáadáa, kò sí àní-àní pé èyí á ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí ara rẹ túbọ̀ balẹ̀.”

Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni oorun téèyàn nílò ṣe pọ̀ tó? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi máa ń sọ pé kéèyàn máa sun oorun wákàtí mẹ́jọ ló dára jù lọ, Currie sọ pé: “Oorun tí ara ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò yàtọ̀ síra.” Látàrí èyí, ó dábàá pé kéèyàn ṣáà gbìyànjú láti sun oorun àsùngbádùn tó máa wọra dáadáa. Ṣùgbọ́n báwo ni èyí ṣe lè ṣeé ṣe, pàápàá fún àwọn tó ní ìṣòro àìróorunsùn? Àwọn àbá díẹ̀ nìwọ̀nyí:

◼ Máa fi omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ wẹ̀ kó o tó lọ sùn.

◼ Máa ṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n ní ìgbà bíi mélòó kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀; àmọ́ má ṣe ṣe eré ìmárale tó ń tánni lókun bó bá kù díẹ̀ kó o lọ sùn.

◼ Má ṣe jẹ́ kí ariwo èyíkéyìí wà nínú yàrá tó ò ń sùn, jẹ́ kó ṣókùnkùn, kó o sì jẹ́ kó tutù níwọ̀nba.

◼ Gbìyànjú láti máa jí ní àkókò kan náà láràárọ̀, kí o sì jẹ́ kí àsìkò tó ò ń sùn àtèyí tó ò ń jí máa dọ́gba lójoojúmọ́.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àǹfààní kékeré kọ́ ni oorun ń ṣe fún ara, máa fọgbọ́n ṣètò rẹ, kó o sì jẹ́ kí oorun wà lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún ọ.