Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Àìmọ̀wàáhù Ń Gbilẹ̀ Sí I

“Àìmọ̀wàáhù àwọn ará Japan ti burú bùrùjà.” Ohun tí nǹkan bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn bí ẹgbẹ̀rún méjì sọ nìyẹn nínú ìwádìí kan tí ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn The Yomiuri Shimbun ṣe láìpẹ́ yìí. Kí làwọn ohun tó ń bí wọn nínú? Ìdá méjìdínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn náà sọ pé ohun tí kò bójú mu ni “kí àwọn ẹlòmíràn máa ju àmukù sìgá, àjẹkù ṣingọ́ọ̀mù, àti páńgolo ọtí síbikíbi tí wọ́n bá rí.” Ó lé ní ìdajì wọn tó tọ́ka sí bí àwọn òbí kì í ṣe bá àwọn ọmọ wọn wí tí wọ́n bá ń pariwo. Àròyé àwọn mìíràn sì dá lórí lílo tẹlifóònù alágbèérìn níbi táwọn èrò bá wà, kíkọ̀ láti palẹ̀ ìgbẹ́ àwọn ẹran ọ̀sìn mọ́, àti kí àwọn èèyàn máa gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti kẹ̀kẹ́ síbikíbi tó bá ti wù wọ́n. Àwọn ọ̀dọ́ ni wọ́n nàka àléébù sí jù lọ. “Nínú àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogún ọdún sí ogójì ọdún tí wọ́n sọ̀rọ̀, ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rin ló sọ nípa ìwà àìlẹ́kọ̀ọ́ táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga máa ń hù.”

Àlégbà Àtọwọ́dá

Ẹyẹ òkun tó ń jẹ́ cormorant, èyí tó hàn gbangba pé ó lè jẹ ẹja tó tó nǹkan bíi kìlógíráàmù kan lójúmọ́, “sábà máa ń jẹ́ ìyọlẹ́nu fún àwọn tó ń fi iṣẹ́ ẹja pípa ṣe fàájì,” lohun tí ìwé ìròyìn Calgary Herald ti ilẹ̀ Kánádà sọ. Ìwé ìròyìn náà sọ pé láti lè lé àwọn ẹyẹ yìí àtàwọn ẹyẹ mìíràn tó máa ń jẹ ẹja dà nù, àwọn àgbẹ̀ ọlọ́sìn ẹja àtàwọn alábòójútó ilé iṣẹ́ tó ń sin ẹja ní Àríwá Amẹ́ríkà ti ń lo ọ̀nà tuntun báyìí—ìyẹn ni lílo àwọn àlégbà oníke. Ìwé ìròyìn Herald ṣàlàyé pé, àwọn àlégbà àtọwọ́dá tí wọ́n gùn ní mítà mẹ́rin náà “ní ojú ńlá méjì tó ń tàn yanran-yanran, wọ́n sì fara jọ àlégbà inú igbó gẹ́lẹ́.” Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè kan rí i pé àlégbà oníke kan tí wọ́n gbé sórí omi ṣiṣẹ́ fún nǹkan bí oṣù kan. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ sí í jágbọ́n pé àtọwọ́dá ni kì í ṣe àlégbà gidi. Wọ́n tiẹ̀ rí ẹyẹ àkọ̀ kan “tó rọra bà téńté lórí àlégbà oníke náà.” Àmọ́ nígbà tí wọ́n gbé e lọ sí apá ibòmíràn, ó tún dẹ́rù ba àwọn ẹyẹ tó máa ń jẹ ẹja náà lẹ́ẹ̀kan sí i.

“Híhanni Léèmọ̀” Níbi Iṣẹ́

Ìwé ìròyìn El País Semanal sọ pé, olórí ohun tó máa ń mú kí àwọn èèyàn máa pa ibi iṣẹ́ jẹ ní ilẹ̀ Sípéènì ni “ìfòòró ẹ̀mí.” Ó ju mílíọ̀nù méjì àwọn ará Sípéènì lọ tí ojú wọn máa ń rí màbo lẹ́nu iṣẹ́ fún àkókò gígùn, èyí táwọn ará Yúróòpù mọ̀ sí híhanni léèmọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀gbẹ́ni Iñaki Piñuel tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú sọ, àwọn tí wọ́n máa ń dájú sọ sábà máa ń jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó gbájú mọ́ṣẹ́ tí àwọn mìíràn ń jowú wọn nítorí pé wọ́n mọṣẹ́ dáadáa. Àwọn alábàáṣiṣẹ́ lè máa fàbùkù kan ẹnì kan nípa ṣíṣàì fún un ní iṣẹ́ tó yẹ kó ṣe, kí wọ́n máa kọ̀ láti pè é sí ọ̀rọ̀, kí wọ́n máa ṣe bíi pé wọn ò rí i, kí wọ́n máa ṣàríwísí rẹ̀ ṣáá, tàbí kí wọ́n máa tan àhesọ ọ̀rọ̀ kálẹ̀ láti bà á lórúkọ jẹ́. Ìròyìn náà sọ pé: “Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé, ìdá kan nínú márùn-ún ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni tó ń ṣẹlẹ̀ ní Yúróòpù ni kò ṣẹ̀yìn ìṣòro yìí.” Kí ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe? Ìwé ìròyìn náà dámọ̀ràn pé: “Má ṣe bò ó mọ́ra o. Wá àwọn ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn náà ṣojú wọn. Sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fáwọn aláṣẹ ibiṣẹ́. Má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi fún ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Bí ọ̀rọ̀ náà bá fẹ́ dójú ẹ̀, yí ẹ̀ka tó o ti ń ṣiṣẹ́ padà [tàbí] kó o pààrọ̀ iṣẹ́ rẹ.”

Àrùn Ọpọlọ Láàárín Àwọn Ọmọdé

Ìwé ìròyìn The Independent ti ìlú London sọ pé: “Ọmọ kan nínú márùn-ún lágbàáyé ló ní àrùn ọpọlọ tàbí ìṣòro híhùwà lódìlódì tó lè ba ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ ráúráú.” Nínú ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé pawọ́ pọ̀ gbé jáde, wọ́n ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé, ọ̀nà tí ìdààmú ọkàn, ìpara-ẹni, àti fífọwọ́-ara-ẹni-ṣera-ẹni-léṣe fi ń gbà ròkè láàárín àwọn ọ̀dọ́ “kọjá sísọ.” Àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn burú jù lọ làwọn tó ń gbé ní àgbègbè tí ogun ti ń jà àtàwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí ipò ìṣúnná owó wọn ò ti fara rọ rárá tí ìwàkiwà sì gbilẹ̀ níbẹ̀. Níbàámu pẹ̀lú ìwé ìròyìn The Independent, ìròyìn ọ̀hún sọ pé, àwọn ọmọdé tó ń ní ìdààmú ọkàn “tún lè ní àwọn àìsàn àtàwọn àṣà eléwu mìíràn tó lè ké ìgbésí ayé wọn kúrú. Ó tún sọ pé “nǹkan bí ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ikú àìtọ́jọ́ tó ń pa àwọn àgbàlagbà ló ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àṣà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n wà ní ọ̀dọ́langba, irú bíi sìgá mímu, ọtí mímú àti lílo oògùn olóró.”

Títì Abẹ́ Òkun

Ìwé ìròyìn The Sunday Times ti ìlú London sọ pé: “Òun ni òpópónà tó tóbi jù lọ lábẹ́ òkun. Nísàlẹ̀ Òkun Pàsífíìkì, òpópónà kan wà níbẹ̀ tó wá láti etíkun California tí oòrùn ti sábà máa ń ràn, tó sì gba Hawaii kọjá lọ sí àwọn etídò olókùúta ilẹ̀ Japan.” Jeff Polovina, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òkun ní ìpínlẹ̀ Hawaii ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí òpópónà yìí ni, ó sì yàwòrán bó ṣe rí nípa lílẹ àmì mọ́ ara àwọn ẹja àbùùbùtán, ìjàpá òkun, ẹja tuna, àtàwọn ẹja lámùsóò. Àwọn ẹ̀dá tín-tìn-tín abẹ́ òkun pọ̀ jaburata ní òpópónà náà, èyí táwọn akàn, ẹja jellyfish, àti ẹran omi tó ń jẹ́ squid máa ń jẹ. Àwọn wọ̀nyí ló máa wá jẹ́ oúnjẹ fáwọn arìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn náà. Àwọn ìjàpá òkun ńlá, tí ìwé ìròyìn náà pè ní “arìnrìn-àjò tí kò lẹ́gbẹ́,” máa ń yé ẹyin wọn ní ilẹ̀ Japan, wọ́n máa ń wò wọ́n dàgbà lẹ́bàá etíkun California, wọ́n sì máa ń lọ láti etíkun kan sí èkejì. Ní ìgbà òtútù, ọ̀nà abẹ́ òkun náà máa ń yí padà. Ó máa ń fi bí ẹgbẹ̀rún kan kìlómítà yà sí ìhà gúúsù, tí yóò wá láti gúúsù California lọ sí Òkun Gúúsù China.

Bí O Ṣe Lè Ní Ìlera Tó Jí Pépé

Ìwé àtìgbàdégbà náà, Tufts University Health and Nutrition Letter sọ pé: “Ṣíṣe eré ìmárale kì í jẹ́ kéèyàn sanra, ó máa ń gbani lọ́wọ́ àìsàn bí àrùn àtọ̀gbẹ àti àrùn osteoporosis (àìlágbára egungun), ó máa ń jẹ́ kí ara èèyàn balẹ̀ sí i, ó sì máa ń jẹ́ kí oorun alẹ́ túbọ̀ gbádùn mọ́ni.” Àmọ́ yàtọ̀ sí gbogbo èyí, “bí ara rẹ bá ṣe jí pépé tó jẹ́ ohun pàtàkì kan tó ń pinnu bí wàá ṣe pẹ́ láyé tó.” Nínú ìwádìí ọlọ́dún-mẹ́tàlá kan tí àwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì Stanford àti Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Àbọ̀dé Ológun Nílẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe nípa àwọn ọkùnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, tí wọ́n á ti máa sún mọ́ ẹni àádọ́ta ọdún, wọ́n ríi pé bí àkókò tí ẹnì kan fi ṣe eré ìmárale bá ṣe gùn tó kó tó di pé ó rẹ onítọ̀hún jẹ́ kókó pàtàkì kan tó ń fi bí ẹni náà ṣe máa pẹ́ láyé tó hàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwádìí mìíràn fi hàn pé àbùdá kálukú máa ń nípa lórí bí ẹnì kan ṣe lè ṣe eré ìmárale tó, síbẹ̀, àwọn eré ìmárale “tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára”—irú bí rírìn kánmọ́kánmọ́—máa ń ṣèrànwọ́ gan-an láti mú kí ara èèyàn jí pépé.

Pípolówó Ọtí Líle fún Àwọn Ọ̀dọ́

Ìwé ìròyìn Sunday Telegraph ti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Ọsirélíà tó ti sọ ọtí líle di bára kú.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Ian Webster, tó jẹ́ alábòójútó fún Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ọtí Líle Àtàwọn Oògùn Olóró Mìíràn Nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé, àṣà kan ti ń gbilẹ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ báyìí, ìyẹn ni pé, òpin ọ̀sẹ̀ tí wọ́n bá lò láti “mu ọtí yó bìnàkò” ni wọ́n kà sí òpin ọ̀sẹ̀ gidi. Ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald sọ pé, ominú ń kọ àwọn ògbóǹkangí kan nípa bí pípolówó ọtí líle fún àwọn ọ̀dọ́ “ṣe ń ròkè sí i yíká ayé.” Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn oníṣòwò ọtí líle ló ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń polówó ọjà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n dìídì ṣe nítorí àwọn ọ̀dọ́. “Àwọn ibi tí wọ́n ń lò fún ìpolówó ọjà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí máa ń pèsè tíkẹ́ẹ̀tì fún àwọn ọ̀dọ́ láti wá síbi táwọn olórin ti ń ṣeré, wọ́n máa ń pèsè ìsọfúnni nípa àwọn fíìmù tó wà, bẹ́ẹ̀ ni àlàyé lórí ọtí tí iléeṣẹ́ náà ń mú jáde kì í gbẹ́yìn.” Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, Àjọ Ìlera Àgbáyé ń ṣàníyàn pé ńṣe ni gbogbo ìpolówó ọjà yìí “máa mú kí ọtí líle di apá pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé àwọn ọ̀dọ́.”

Yíyẹra fún Àwùjọ

Ní orílẹ̀-èdè Japan, ohun àràmàǹdà kan tó jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́langba àtàwọn tó ti dàgbà díẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ sí jù ti yọjú báyìí o. Orúkọ tí wọ́n ń pe àṣà tuntun náà ni hikikomori, ìyẹn ni yíyẹra pátápátá fún àwùjọ. Ìgbà tí wọ́n ń ṣe ìwádìí lórí oríṣiríṣi ìwà ọ̀daràn bíburú jáì tí àwọn ọ̀dọ́ tó máa ń séra wọn mọ́lé hù ni ìṣòro náà yọjú sí gbangba. Ìwé ìròyìn ìṣègùn tó ń jẹ́ The Lancet sọ pé: “Ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa irú ìgbésí ayé tí àwọn tó hu ìwà ọ̀daràn náà ń gbé fi hàn pé bí wọ́n ṣe máa ń ya ara wọn láṣo kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu rárá, nítorí pé ńṣe ni wọ́n máa ń séra wọn mọ́lé fún ọ̀pọ̀ oṣù láìjáde síta, tí wọ́n á sì máa dá ṣe eré ìdárayá orí fídíò tàbí ti orí kọ̀ǹpútà láwọn nìkan.” Àwọn ẹ̀rí mìíràn fi hàn pé kí àwọn ọ̀dọ́ máa ṣe sùẹ̀sùẹ̀ ni ọ̀nà tó wọ́pọ̀ jù lọ tí àṣà yìí máa ń gbà fara hàn dípò kó jẹ́ nípasẹ̀ ìwà ọ̀daràn. Àmọ́ ṣá o, níbàámu pẹ̀lú ìwé ìròyìn The Lancet, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbà pé ìṣòro yìí kò ṣẹ̀yìn irú ìgbésí ayé táwọn ará Japan ń gbé láyé òde òní, ìyẹn ni ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀, ti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ti ìdẹ̀ra. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ náà ló jẹ́ pé ìdí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ṣíṣe eré orí fídíò ni wọ́n sábà máa ń wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀, tí wọ́n á kàn máa jẹ ìpápánu àti ohun mímu tí wọ́n bá wá tà fún wọn nílé.” Àwọn ìṣirò kan tí wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tó ń séra wọn mọ́lé nílẹ̀ Japan tó mílíọ̀nù kan.